Rúùtù 3:1-18

  • Náómì sọ ohun tí Rúùtù máa ṣe (1-4)

  • Rúùtù àti Bóásì ní ibi ìpakà (5-15)

  • Rúùtù pa dà sọ́dọ̀ Náómì (16-18)

3  Náómì ìyá ọkọ rẹ̀ wá sọ fún un pé: “Ọmọ mi, ǹjẹ́ kò yẹ kí n wá ọkọ míì* fún ọ báyìí,+ kí nǹkan lè lọ dáadáa fún ọ?  Ṣé o rántí pé mọ̀lẹ́bí wa+ ni Bóásì tí o máa ń lọ sọ́dọ̀ àwọn òṣìṣẹ́ rẹ̀ obìnrin? Ó máa lọ fẹ́ ọkà bálì ní ibi ìpakà* ní alẹ́ òní.  Torí náà, wẹ̀, fi òróró olóòórùn dídùn para, wọ aṣọ,* kí o wá lọ sí ibi ìpakà náà. Má ṣe jẹ́ kó mọ̀ pé o wà níbẹ̀ títí tó fi máa jẹun tó sì máa mu.  Tó bá ti lọ sùn, kíyè sí ibi tó bá dùbúlẹ̀ sí, kí o lọ ká aṣọ kúrò ní ẹsẹ̀ rẹ̀, kí o sì dùbúlẹ̀ síbẹ̀. Ó máa sọ ohun tó yẹ kí o ṣe fún ọ.”  Rúùtù fèsì pé: “Gbogbo ohun tí o sọ fún mi ni màá ṣe.”  Torí náà, ó lọ sí ibi ìpakà, ó sì ṣe gbogbo ohun tí ìyá ọkọ rẹ̀ sọ fún un.  Ní gbogbo ìgbà yẹn, Bóásì ń jẹ, ó ń mu, inú rẹ̀ sì ń dùn. Lẹ́yìn náà, ó lọ dùbúlẹ̀ sí ẹ̀gbẹ́ ibi tí wọ́n kó ọkà jọ sí. Obìnrin náà sì yọ́ kẹ́lẹ́kẹ́lẹ́ lọ síbẹ̀, ó ká aṣọ kúrò ní ẹsẹ̀ Bóásì, ó sì dùbúlẹ̀.  Ní ọ̀gànjọ́ òru, ọkùnrin náà bẹ̀rẹ̀ sí í gbọ̀n, ó dìde jókòó, ó rọra tẹ̀ síwájú, ó wá rí i pé obìnrin kan dùbúlẹ̀ síbi ẹsẹ̀ òun.  Ó bi í pé: “Ta nìyí?” Ó fèsì pé: “Èmi Rúùtù ìránṣẹ́ rẹ ni. Jọ̀ọ́ fi aṣọ rẹ* bo ìránṣẹ́ rẹ, torí ìwọ jẹ́ olùtúnrà.”+ 10  Ó wá sọ pé: “Kí Jèhófà bù kún ọ, ọmọ mi. Ìfẹ́ tí kì í yẹ̀ tí o fi hàn lọ́tẹ̀ yìí dáa ju ti ìgbà àkọ́kọ́ lọ,+ torí pé o ò lọ wá ọ̀dọ́kùnrin, ì báà jẹ́ olówó tàbí tálákà. 11  Ọmọ mi, má bẹ̀rù. Gbogbo ohun tí o sọ ni màá ṣe fún ọ,+ kò kúkú sí ẹni tí kò mọ̀ ní ìlú yìí* pé obìnrin àtàtà ni ọ́. 12  Òótọ́ ni pé olùtúnrà+ ni mí, àmọ́ olùtúnrà kan wà tó bá ọ tan jù mí lọ.+ 13  Dúró síbí ní alẹ́ yìí, bó bá tún ọ rà ní àárọ̀ ọ̀la, kò burú! Jẹ́ kó tún ọ rà.+ Àmọ́ bí kò bá fẹ́ tún ọ rà, bí Jèhófà ti ń bẹ, màá tún ọ rà. Torí náà, sùn síbí di àárọ̀.” 14  Ó sì sùn síbi ẹsẹ̀ rẹ̀ títí di àárọ̀, lẹ́yìn náà, ó dìde kí ilẹ̀ tó mọ́ kí ẹnikẹ́ni má bàa rí i. Bóásì wá sọ pé: “Má ṣe jẹ́ kí ẹnì kankan mọ̀ pé obìnrin kan wá sí ibi ìpakà.” 15  Ó tún sọ fún un pé: “Mú ìborùn rẹ wá, kí o sì tẹ́ ẹ.” Torí náà, ó tẹ́ ẹ, ọkùnrin náà sì wọn ọkà bálì òṣùwọ̀n mẹ́fà* sínú ìborùn náà, ó sì gbé e rù ú. Lẹ́yìn èyí, ọkùnrin náà lọ sínú ìlú. 16  Rúùtù lọ sọ́dọ̀ ìyá ọkọ rẹ̀, ìyá ọkọ rẹ̀ sì bi í pé: “Báwo nibi tí o lọ,* ọmọ mi?” Ó sì sọ gbogbo ohun tí ọkùnrin náà ṣe fún un. 17  Ó tún sọ pé: “Ó fún mi ní ọkà bálì òṣùwọ̀n mẹ́fà yìí, ó wá sọ fún mi pé, ‘Má pa dà sọ́dọ̀ ìyá ọkọ rẹ lọ́wọ́ òfo.’” 18  Torí náà, Náómì sọ pé: “Jókòó síbí, ọmọ mi, títí wàá fi mọ ibi tí ọ̀rọ̀ náà máa já sí, torí ọkùnrin náà kò ní sinmi títí yóò fi yanjú ọ̀rọ̀ náà lónìí.”

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé

Ní Héb., “ibi ìsinmi.”
Tàbí “wọ aṣọ àwọ̀lékè rẹ.”
Tàbí “etí aṣọ rẹ.”
Ní Héb., “ní gbogbo ẹnubodè àwọn èèyàn mi.”
Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ òṣùwọ̀n síà mẹ́fà tàbí nǹkan bíi Lítà 44. Wo Àfikún B14.
Ní Héb., “Ìwọ ta ni?”