Orin Sólómọ́nì 4:1-16

  • Olùṣọ́ àgùntàn (1-5)

    • “O rẹwà gan-an, olólùfẹ́ mi” (1)

  • Ọ̀dọ́bìnrin (6)

  • Olùṣọ́ àgùntàn (7-16a)

    • ‘O ti gbà mí lọ́kàn, ìyàwó mi’ (9)

  • Ọ̀dọ́bìnrin (16b)

4  “Wò ó! O rẹwà gan-an, olólùfẹ́ mi. Wò ó! O rẹwà gan-an. Ojú rẹ rí bíi ti àdàbà, lábẹ́ aṣọ tí o fi bojú. Irun rẹ dà bí agbo ewúrẹ́Tí wọ́n ń rọ́ bọ̀ láti orí àwọn òkè Gílíádì.+  2  Eyín rẹ dà bí agbo àgùntàn tí wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ gé irun wọn,Tí wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ wẹ̀ fún,Gbogbo wọn bí ìbejì,Ọmọ ìkankan nínú wọn ò sì sọ nù.  3  Ètè rẹ rí bí òwú aláwọ̀ rírẹ̀dòdò,Ọ̀rọ̀ ẹnu rẹ sì dùn. Ẹ̀rẹ̀kẹ́* rẹ rí bí awẹ́ pómégíránétìLábẹ́ aṣọ tí o fi bojú.  4  Ọrùn rẹ+ dà bí ilé gogoro Dáfídì,+Tí wọ́n fi òkúta kọ́,Tí wọ́n gbé ẹgbẹ̀rún apata kọ́ sí ara rẹ̀,Gbogbo apata* tó jẹ́ ti àwọn ọkùnrin alágbára.+  5  Ọmú rẹ méjèèjì dà bí ọmọ àgbọ̀nrín méjì,Ó dà bí ọmọ egbin+ tí wọ́n jẹ́ ìbejì,Tí wọ́n ń jẹko láàárín àwọn òdòdó lílì.”  6  “Màá lọ sórí òkè òjíá,Màá gba ọ̀nà òkè tùràrí lọ,+Títí afẹ́fẹ́ yóò fi bẹ̀rẹ̀ sí í fẹ́,* tí òjìji kò sì ní sí mọ́.”  7  “O rẹwà látòkè délẹ̀, olólùfẹ́ mi,+Kò sí àbààwọ́n kankan lára rẹ.  8  Jẹ́ ká jọ máa bọ̀ láti Lẹ́bánónì, ìyàwó mi,Jẹ́ ká jọ máa bọ̀ láti Lẹ́bánónì.+ Sọ̀ kalẹ̀ láti téńté òkè Ámánà,*Láti téńté òkè Sénírì, téńté òkè Hámónì,+Látinú ihò kìnnìún, látorí àwọn òkè tí àwọn àmọ̀tẹ́kùn ń gbé.  9  O ti gbà mí lọ́kàn,+ arábìnrin mi, ìyàwó mi,Bí o ṣe ṣíjú wò mí báyìí, tí mo rí ọ̀kan nínú ẹ̀gbà ọrùn rẹ,Bẹ́ẹ̀ lo gbà mí lọ́kàn. 10  Arábìnrin mi, ìyàwó mi, ìfẹ́ tí ò ń fi hàn sí mi mà dára o!+ Ìfẹ́ tí ò ń fi hàn sí mi dára ju wáìnì lọ,+Kò sì sí lọ́fínńdà tó ń ta sánsán bíi tìrẹ!+ 11  Oyin inú afárá+ ń kán tótó ní ètè rẹ, ìyàwó mi. Oyin àti wàrà wà lábẹ́ ahọ́n rẹ,+Aṣọ rẹ sì ń ta sánsán bíi ti Lẹ́bánónì. 12  Arábìnrin mi, ìyàwó mi, dà bí ọgbà tí wọ́n tì,Ọgbà tí wọ́n tì, orísun omi tí wọ́n sé pa. 13  Àwọn ẹ̀ka* rẹ dà bí ọgbà pómégíránétì,* Tó ní àwọn èso tó dára jù, àwọn ewé làálì pẹ̀lú ewé sípíkénádì, 14  Sípíkénádì+ àti òdòdó sáfúrónì, pòròpórò*+ àti igi sínámónì,+Pẹ̀lú oríṣiríṣi igi tùràrí, òjíá àti álóè+Àti gbogbo lọ́fínńdà tó dára jù.+ 15  Orísun omi inú ọgbà ni ọ́, kànga omi tó mọ́Àti odò tó ń ṣàn láti Lẹ́bánónì.+ 16  Jí, ìwọ atẹ́gùn àríwá;Wọlé wá, ìwọ atẹ́gùn gúúsù. Fẹ́* sórí ọgbà mi. Jẹ́ kí ìtasánsán rẹ̀ gbalẹ̀ kan.” “Jẹ́ kí olólùfẹ́ mi wá sínú ọgbà rẹ̀ Kó sì jẹ àwọn èso rẹ̀ tó dára jù lọ.”

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé

^ Tàbí “Ẹ̀bátí.”
^ Tàbí “apata ribiti.”
^ Ní Héb., “Títí ọjọ́ yóò fi bẹ̀rẹ̀ sí í mí.”
^ Tàbí “Òkè Lẹ́bánónì Kejì.”
^ Tàbí kó jẹ́, “Awọ.”
^ Tàbí “párádísè pómégíránétì.”
^ Esùsú tó ń ta sánsán.
^ Tàbí “Fẹ́ yẹ́ẹ́.”