Nọ́ńbà 2:1-34

  • Wọ́n pàgọ́ bí wọ́n ṣe pín àwọn ẹ̀yà wọn ní mẹ́ta-mẹ́ta (1-34)

    • Ẹ̀yà mẹ́ta ti ibùdó Júdà wà ní apá ìlà oòrùn (3-9)

    • Ẹ̀yà mẹ́ta ti ibùdó Rúbẹ́nì wà ní apá gúúsù (10-16)

    • Àgọ́ àwọn ọmọ Léfì wà ní àárín (17)

    • Ẹ̀yà mẹ́ta ti ibùdó Éfúrémù wà ní apá ìwọ̀ oòrùn (18-24)

    • Ẹ̀yà mẹ́ta ti ibùdó Dánì wà ní apá àríwá (25-31)

    • Iye gbogbo ọkùnrin tí wọ́n forúkọ wọn sílẹ̀ (32-34)

2  Jèhófà wá sọ fún Mósè àti Áárónì pé:  “Kí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì pàgọ́ síbi tí wọ́n pín àwọn ẹ̀yà wọn sí ní mẹ́ta-mẹ́ta,+ kí ọkùnrin kọ̀ọ̀kan pàgọ́ síbi àsíá* agbo ilé bàbá rẹ̀. Kí àgọ́ wọn dojú kọ àgọ́ ìpàdé, kí wọ́n pàgọ́ yí i ká.  “Kí ẹ̀yà mẹ́ta ti ibùdó Júdà pàgọ́ sí ìlà oòrùn, lápá ibi tí oòrùn ti ń yọ, ní àwùjọ-àwùjọ;* Náṣónì+ ọmọ Ámínádábù ni ìjòyè àwọn ọmọ Júdà.  Àwọn tí wọ́n forúkọ wọn sílẹ̀ nínú àwọn ọmọ ogun rẹ̀ jẹ́ ẹgbẹ̀rún mẹ́rìnléláàádọ́rin ó lé ọgọ́rùn-ún mẹ́fà (74,600).+  Kí ẹ̀yà Ísákà pàgọ́ sí ẹ̀gbẹ́ wọn; Nétánélì+ ọmọ Súárì ni ìjòyè àwọn ọmọ Ísákà.  Àwọn tí wọ́n forúkọ wọn sílẹ̀ nínú àwọn ọmọ ogun rẹ̀ jẹ́ ẹgbẹ̀rún mẹ́rìnléláàádọ́ta ó lé ọgọ́rùn-ún mẹ́rin (54,400).+  Kí ẹ̀yà Sébúlúnì wá tẹ̀ lé wọn; Élíábù+ ọmọ Hélónì ni ìjòyè àwọn ọmọ Sébúlúnì.  Àwọn tí wọ́n forúkọ wọn sílẹ̀ nínú àwọn ọmọ ogun rẹ̀ jẹ́ ẹgbẹ̀rún mẹ́tàdínlọ́gọ́ta ó lé ọgọ́rùn-ún mẹ́rin (57,400).+  “Gbogbo àwọn tí wọ́n forúkọ wọn sílẹ̀ nínú àwọn ọmọ ogun ibùdó Júdà jẹ́ ọ̀kẹ́ mẹ́sàn-án ó lé ẹgbẹ̀rún mẹ́fà àti ọgọ́rùn-ún mẹ́rin (186,400). Àwọn ni kó kọ́kọ́ máa tú àgọ́ wọn ká.+ 10  “Kí ẹ̀yà mẹ́ta ti ibùdó Rúbẹ́nì+ wà ní apá gúúsù, ní àwùjọ-àwùjọ;* Élísúrì+ ọmọ Ṣédéúrì ni ìjòyè àwọn ọmọ Rúbẹ́nì. 11  Àwọn tí wọ́n forúkọ wọn sílẹ̀ nínú àwọn ọmọ ogun rẹ̀ jẹ́ ẹgbẹ̀rún mẹ́rìndínláàádọ́ta ó lé ọgọ́rùn-ún márùn-ún (46,500).+ 12  Kí ẹ̀yà Síméónì pàgọ́ sí ẹ̀gbẹ́ wọn; Ṣẹ́lúmíẹ́lì+ ọmọ Súríṣádáì ni ìjòyè àwọn ọmọ Síméónì. 13  Àwọn tí wọ́n forúkọ wọn sílẹ̀ nínú àwọn ọmọ ogun rẹ̀ jẹ́ ẹgbẹ̀rún mọ́kàndínlọ́gọ́ta ó lé ọgọ́rùn-ún mẹ́ta (59,300).+ 14  Kí ẹ̀yà Gádì wá tẹ̀ lé wọn; Élíásáfù+ ọmọ Rúẹ́lì ni ìjòyè àwọn ọmọ Gádì. 15  Àwọn tí wọ́n forúkọ wọn sílẹ̀ nínú àwọn ọmọ ogun rẹ̀ jẹ́ ẹgbẹ̀rún márùndínláàádọ́ta ó lé ọgọ́rùn-ún mẹ́fà àti àádọ́ta (45,650).+ 16  “Gbogbo àwọn tí wọ́n forúkọ wọn sílẹ̀ nínú àwọn ọmọ ogun ibùdó Rúbẹ́nì jẹ́ ẹgbẹ̀rún mọ́kànléláàádọ́jọ ó lé ọgọ́rùn-ún mẹ́rin àti àádọ́ta (151,450), àwọn ni kó sì máa tú àgọ́ wọn ká ṣìkejì.+ 17  “Nígbà tí ẹ bá ń gbé àgọ́ ìpàdé kúrò,+ àgọ́ àwọn ọmọ Léfì ni kó wà láàárín àwọn àgọ́ yòókù. “Bí wọ́n bá ṣe pàgọ́ náà ni kí wọ́n ṣe tẹ̀ léra tí wọ́n bá ń rìnrìn àjò,+ kí kálukú wà ní àyè rẹ̀, bí wọ́n ṣe pín ẹ̀yà wọn ní mẹ́ta-mẹ́ta. 18  “Kí ẹ̀yà mẹ́ta ti ibùdó Éfúrémù wà ní apá ìwọ̀ oòrùn, ní àwùjọ-àwùjọ;* Élíṣámà+ ọmọ Ámíhúdù ni ìjòyè àwọn ọmọ Éfúrémù. 19  Àwọn tí wọ́n forúkọ wọn sílẹ̀ nínú àwọn ọmọ ogun rẹ̀ jẹ́ ẹgbẹ̀rún lọ́nà ogójì ó lé ọgọ́rùn-ún márùn-ún (40,500).+ 20  Kí ẹ̀yà Mánásè+ pàgọ́ sí ẹ̀gbẹ́ wọn; Gàmálíẹ́lì+ ọmọ Pédásúrì ni ìjòyè àwọn ọmọ Mánásè. 21  Àwọn tí wọ́n forúkọ wọn sílẹ̀ nínú àwọn ọmọ ogun rẹ̀ jẹ́ ẹgbẹ̀rún méjìlélọ́gbọ̀n ó lé igba (32,200).+ 22  Kí ẹ̀yà Bẹ́ńjámínì wá tẹ̀ lé wọn; Ábídánì+ ọmọ Gídéónì ni ìjòyè àwọn ọmọ Bẹ́ńjámínì. 23  Àwọn tí wọ́n forúkọ wọn sílẹ̀ nínú àwọn ọmọ ogun rẹ̀ jẹ́ ẹgbẹ̀rún márùndínlógójì ó lé ọgọ́rùn-ún mẹ́rin (35,400).+ 24  “Gbogbo àwọn tí wọ́n forúkọ wọn sílẹ̀ nínú àwọn ọmọ ogun ibùdó Éfúrémù jẹ́ ẹgbẹ̀rún méjìdínláàádọ́fà ó lé ọgọ́rùn-ún (108,100), àwọn ni kó sì máa tú àgọ́ wọn ká ṣìkẹta.+ 25  “Kí ẹ̀yà mẹ́ta ti ibùdó Dánì wà ní apá àríwá, ní àwùjọ-àwùjọ;* Áhíésérì+ ọmọ Ámíṣádáì ni ìjòyè àwọn ọmọ Dánì. 26  Àwọn tí wọ́n forúkọ wọn sílẹ̀ nínú àwọn ọmọ ogun rẹ̀ jẹ́ ẹgbẹ̀rún méjìlélọ́gọ́ta ó lé ọgọ́rùn-ún méje (62,700).+ 27  Kí ẹ̀yà Áṣérì pàgọ́ sí ẹ̀gbẹ́ wọn; Págíẹ́lì+ ọmọ Ókíránì ni ìjòyè àwọn ọmọ Áṣérì. 28  Àwọn tí wọ́n forúkọ wọn sílẹ̀ nínú àwọn ọmọ ogun rẹ̀ jẹ́ ẹgbẹ̀rún mọ́kànlélógójì ó lé ọgọ́rùn-ún márùn-ún (41,500).+ 29  Kí ẹ̀yà Náfútálì wá tẹ̀ lé wọn; Áhírà+ ọmọ Énánì ni ìjòyè àwọn ọmọ Náfútálì. 30  Àwọn tí wọ́n forúkọ wọn sílẹ̀ nínú àwọn ọmọ ogun rẹ̀ jẹ́ ẹgbẹ̀rún mẹ́tàléláàádọ́ta ó lé ọgọ́rùn-ún mẹ́rin (53,400).+ 31  “Gbogbo àwọn tí wọ́n forúkọ wọn sílẹ̀ nínú ibùdó Dánì jẹ́ ẹgbẹ̀rún mẹ́tàdínlọ́gọ́jọ ó lé ọgọ́rùn-ún mẹ́fà (157,600). Àwọn ni kó máa tú àgọ́ wọn ká kẹ́yìn,+ bí wọ́n ṣe pín ẹ̀yà wọn ní mẹ́ta-mẹ́ta.” 32  Èyí ni àwọn ọmọ Ísírẹ́lì tí wọ́n forúkọ wọn sílẹ̀ gẹ́gẹ́ bí agbo ilé bàbá wọn; gbogbo àwọn tó wà nínú àwọn ibùdó tí wọ́n forúkọ wọn sílẹ̀ láti dara pọ̀ mọ́ àwọn ọmọ ogun jẹ́ ọgbọ̀n ọ̀kẹ́ ó lé ẹgbẹ̀rún mẹ́ta ààbọ̀ àti àádọ́ta (603,550).+ 33  Àmọ́ wọn ò forúkọ àwọn ọmọ Léfì sílẹ̀+ pẹ̀lú àwọn ọmọ Ísírẹ́lì+ yòókù, bí Jèhófà ṣe pa á láṣẹ fún Mósè. 34  Àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ṣe gbogbo ohun tí Jèhófà pa láṣẹ fún Mósè. Báyìí ni wọ́n ṣe ń pàgọ́, lọ́nà mẹ́ta-mẹ́ta tí wọ́n pín ẹ̀yà wọn sí,+ tí wọ́n sì máa ń tú àgọ́ wọn ká,+ ní ìdílé-ìdílé àti agbo ilé bàbá wọn.

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé

Tàbí “àmì.”
Ní Héb., “ẹgbẹ́ ọmọ ogun kọ̀ọ̀kan.”
Ní Héb., “ẹgbẹ́ ọmọ ogun kọ̀ọ̀kan.”
Ní Héb., “ẹgbẹ́ ọmọ ogun kọ̀ọ̀kan.”
Ní Héb., “ẹgbẹ́ ọmọ ogun kọ̀ọ̀kan.”