Àkọsílẹ̀ Mátíù 21:1-46

  • Jésù wọ Jerúsálẹ́mù tiyì-tẹ̀yẹ (1-11)

  • Jésù fọ tẹ́ńpìlì mọ́ (12-17)

  • Ó gégùn-ún fún igi ọ̀pọ̀tọ́ (18-22)

  • Wọ́n béèrè àṣẹ tí Jésù fi ń ṣe nǹkan (23-27)

  • Àpèjúwe àwọn ọmọ méjì (28-32)

  • Àpèjúwe àwọn tó ń dáko, tí wọ́n sì pààyàn (33-46)

    • Wọ́n pa olórí òkúta igun ilé tì (42)

21  Nígbà tí wọ́n sún mọ́ Jerúsálẹ́mù, tí wọ́n sì dé Bẹtifágè lórí Òkè Ólífì, Jésù rán ọmọ ẹ̀yìn méjì jáde,+  ó sọ fún wọn pé: “Ẹ lọ sínú abúlé ọ̀ọ́kán yìí, gbàrà tí ẹ bá débẹ̀, ẹ máa rí kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ kan tí wọ́n so àti ọmọ kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́* tó wà pẹ̀lú rẹ̀. Ẹ tú wọn, kí ẹ sì mú wọn wá fún mi.  Tí ẹnì kan bá bá yín sọ ohunkóhun, kí ẹ sọ pé, ‘Olúwa fẹ́ lò wọ́n.’ Ẹsẹ̀kẹsẹ̀ ló máa fi wọ́n ránṣẹ́.”  Èyí ṣẹlẹ̀ kí ohun tí a sọ nípasẹ̀ wòlíì lè ṣẹ, ẹni tó sọ pé:  “Ẹ sọ fún ọmọbìnrin Síónì pé: ‘Wò ó! Ọba rẹ ń bọ̀ lọ́dọ̀ rẹ,+ oníwà tútù ni,+ ó sì gun kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́, àní, ọmọ kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́, ọmọ ẹran akẹ́rù.’”+  Àwọn ọmọ ẹ̀yìn wá lọ, wọ́n sì ṣe ohun tí Jésù ní kí wọ́n ṣe gẹ́lẹ́.+  Wọ́n mú kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ náà àti ọmọ rẹ̀ wá, wọ́n tẹ́ aṣọ àwọ̀lékè wọn sórí wọn, ó sì jókòó sórí wọn.+  Ọ̀pọ̀ nínú àwọn èrò náà tẹ́ aṣọ àwọ̀lékè wọn sí ojú ọ̀nà,+ àwọn míì ń gé àwọn ẹ̀ka igi, wọ́n sì ń tẹ́ wọn sí ojú ọ̀nà.  Bákan náà, àwọn èrò tó ń lọ níwájú rẹ̀ àti àwọn tó ń tẹ̀ lé e ń kígbe ṣáá pé: “A bẹ̀ ọ́, gba Ọmọ Dáfídì là!+ Ìbùkún ni fún ẹni tó ń bọ̀ ní orúkọ Jèhófà!*+ A bẹ̀ ọ́, gbà á là, ní ibi gíga lókè!”+ 10  Nígbà tó wọ Jerúsálẹ́mù, ariwo sọ ní gbogbo ìlú náà, wọ́n ń sọ pé: “Ta nìyí?” 11  Àwọn èrò náà ń sọ ṣáá pé: “Jésù nìyí, wòlíì+ tó wá láti Násárẹ́tì ti Gálílì!” 12  Jésù wọnú tẹ́ńpìlì, ó lé gbogbo àwọn tó ń tajà àti àwọn tó ń rajà nínú tẹ́ńpìlì síta, ó sì dojú tábìlì àwọn tó ń pààrọ̀ owó dé àti bẹ́ǹṣì àwọn tó ń ta àdàbà.+ 13  Ó sọ fún wọn pé: “A ti kọ ọ́ pé, ‘A ó máa pe ilé mi ní ilé àdúrà,’+ àmọ́ ẹ̀ ń sọ ọ́ di ihò àwọn olè.”+ 14  Bákan náà, àwọn afọ́jú àti àwọn arọ wá sọ́dọ̀ rẹ̀ nínú tẹ́ńpìlì, ó sì wò wọ́n sàn. 15  Nígbà tí àwọn olórí àlùfáà àti àwọn akọ̀wé òfin rí àwọn ohun ìyanu tó ṣe àti àwọn ọmọkùnrin tó ń kígbe nínú tẹ́ńpìlì pé, “A bẹ̀ ọ́, gba Ọmọ Dáfídì là!”+ inú bí wọn gidigidi,+ 16  wọ́n sì sọ fún un pé: “Ṣé o gbọ́ ohun tí àwọn yìí ń sọ?” Jésù sọ fún wọn pé: “Bẹ́ẹ̀ ni. Ṣé ẹ ò kà á rí pé, ‘Láti ẹnu àwọn ọmọdé àti àwọn ọmọ jòjòló lo ti mú kí ìyìn jáde’?”+ 17  Ó wá fi wọ́n sílẹ̀, ó kúrò ní ìlú náà lọ sí Bẹ́tánì, ó sì sun ibẹ̀ mọ́jú.+ 18  Nígbà tó ń pa dà sí ìlú náà ní àárọ̀ kùtù, ebi ń pa á.+ 19  Ó tajú kán rí igi ọ̀pọ̀tọ́ kan létí ọ̀nà, ó sì lọ sí ìdí rẹ̀, àmọ́ kò rí nǹkan kan lórí rẹ̀ àfi ewé,+ ó wá sọ fún un pé: “Kí èso kankan má so lórí rẹ mọ́ títí láé.”+ Igi ọ̀pọ̀tọ́ náà sì rọ lójú ẹsẹ̀. 20  Nígbà tí àwọn ọmọ ẹ̀yìn rí èyí, ó yà wọ́n lẹ́nu, wọ́n sì sọ pé: “Kí ló mú kí igi ọ̀pọ̀tọ́ náà rọ lójú ẹsẹ̀?”+ 21  Jésù fèsì pé: “Lóòótọ́ ni mo sọ fún yín, tí ẹ bá ní ìgbàgbọ́, tí ẹ ò sì ṣiyèméjì, ohun tí mo ṣe sí igi ọ̀pọ̀tọ́ náà nìkan kọ́ lẹ máa lè ṣe, àmọ́ tí ẹ bá sọ fún òkè yìí pé, ‘Dìde, wọnú òkun,’ ó máa ṣẹlẹ̀.+ 22  Gbogbo ohun tí ẹ bá sì béèrè nínú àdúrà, tí ẹ bá ní ìgbàgbọ́, ẹ máa rí i gbà.”+ 23  Lẹ́yìn tó lọ sínú tẹ́ńpìlì, àwọn olórí àlùfáà àti àwọn àgbààgbà àwọn èèyàn náà wá sọ́dọ̀ rẹ̀ nígbà tó ń kọ́ni, wọ́n sì sọ pé: “Àṣẹ wo lo fi ń ṣe àwọn nǹkan yìí? Ta ló sì fún ọ ní àṣẹ yìí?”+ 24  Jésù dá wọn lóhùn pé: “Èmi náà á bi yín ní ohun kan, tí ẹ bá sọ fún mi, èmi náà á sọ àṣẹ tí mo fi ń ṣe àwọn nǹkan yìí fún yín: 25  Ìrìbọmi tí Jòhánù ṣe fún àwọn èèyàn, ibo ló ti wá? Ṣé láti ọ̀run ni àbí látọ̀dọ̀ èèyàn?”* Wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí í rò ó láàárín ara wọn pé: “Tí a bá sọ pé, ‘Láti ọ̀run,’ ó máa sọ fún wa pé, ‘Kí ló wá dé tí ẹ ò gbà á+ gbọ́?’ 26  Àmọ́ tí a bá sọ pé, ‘Látọ̀dọ̀ èèyàn,’ ẹ̀rù àwọn èrò yìí ń bà wá, torí wòlíì ni gbogbo wọn ka Jòhánù sí.” 27  Torí náà, wọ́n dá Jésù lóhùn pé: “A ò mọ̀.” Ó wá sọ fún wọn pé: “Èmi náà ò ní sọ àṣẹ tí mo fi ń ṣe àwọn nǹkan yìí fún yín. 28  “Kí lèrò yín? Ọkùnrin kan ní ọmọ méjì. Ó lọ bá àkọ́kọ́, ó sọ pé, ‘Ọmọ, lọ ṣiṣẹ́ nínú ọgbà àjàrà lónìí.’ 29  Ọmọ náà fèsì pé, ‘Mi ò lọ,’ àmọ́ lẹ́yìn náà, ó pèrò dà, ó sì lọ. 30  Ó lọ bá ìkejì, ó sọ ohun kan náà fún un. Ọmọ náà sì fèsì pé, ‘Màá lọ Sà,’ àmọ́ kò lọ. 31  Èwo nínú àwọn méjèèjì ló ṣe ìfẹ́ bàbá rẹ̀?” Wọ́n sọ pé: “Èyí àkọ́kọ́.” Jésù sọ fún wọn pé: “Lóòótọ́ ni mo sọ fún yín pé, àwọn agbowó orí àti àwọn aṣẹ́wó máa ṣáájú yín lọ sínú Ìjọba Ọlọ́run. 32  Torí Jòhánù wá sọ́dọ̀ yín ní ọ̀nà òdodo, àmọ́ ẹ ò gbà á gbọ́. Ṣùgbọ́n àwọn agbowó orí àti àwọn aṣẹ́wó gbà á gbọ́,+ kódà nígbà tí ẹ rí èyí, ẹ ò pèrò dà lẹ́yìn náà kí ẹ lè gbà á gbọ́. 33  “Ẹ gbọ́ àpèjúwe míì: Ọkùnrin kan wà, ó ní ilẹ̀, ó gbin àjàrà, ó sì ṣe ọgbà yí i ká,+ ó gbẹ́ ibi tí wọ́n ti ń fún wáìnì sínú rẹ̀, ó sì kọ́ ilé gogoro kan;+ ó wá gbé e fún àwọn tó ń dáko, ó sì rin ìrìn àjò lọ sí ilẹ̀ òkèèrè.+ 34  Nígbà tó di àsìkò tí èso ń so, ó rán àwọn ẹrú rẹ̀ lọ sọ́dọ̀ àwọn tó ń dáko náà pé kí wọ́n gba àwọn èso rẹ̀ wá. 35  Àmọ́ àwọn tó ń dáko náà mú àwọn ẹrú rẹ̀, wọ́n lu ọ̀kan nílùkulù, wọ́n pa ìkejì, wọ́n sì sọ òmíràn lókùúta.+ 36  Ó tún rán àwọn ẹrú míì, tí wọ́n pọ̀ ju àwọn ti àkọ́kọ́ lọ, àmọ́ ohun kan náà ni wọ́n ṣe sí àwọn yìí.+ 37  Níkẹyìn, ó rán ọmọ rẹ̀ sí wọn, ó ní, ‘Wọ́n máa bọ̀wọ̀ fún ọmọ mi.’ 38  Nígbà tí wọ́n rí ọmọ náà, àwọn tó ń dáko náà sọ fún ara wọn pé, ‘Ẹni tó máa jogún rẹ̀ nìyí.+ Ẹ wá, ẹ jẹ́ ká pa á, ká sì gba ogún rẹ̀!’ 39  Torí náà, wọ́n mú un, wọ́n jù ú sí ìta ọgbà àjàrà náà, wọ́n sì pa á.+ 40  Tí ẹni tó ni ọgbà àjàrà náà bá wá dé, kí ló máa ṣe fún àwọn tó ń dáko yẹn?” 41  Wọ́n sọ fún un pé: “Torí pé èèyàn burúkú ni wọ́n, ó máa mú ìparun tó lágbára* wá sórí wọn, ó sì máa gbé ọgbà àjàrà náà fún àwọn míì tó ń dáko, tí wọ́n máa fún un ní èso nígbà tí àkókò bá tó.” 42  Jésù sọ fún wọn pé: “Ṣé ẹ ò tíì kà á nínú Ìwé Mímọ́ rí pé, ‘Òkúta tí àwọn kọ́lékọ́lé kọ̀ sílẹ̀, òun ló wá di olórí òkúta igun ilé.*+ Ọ̀dọ̀ Jèhófà* ni èyí ti wá, ó sì jẹ́ ìyanu lójú wa’?+ 43  Ìdí nìyí tí mo fi sọ fún yín pé, a máa gba Ìjọba Ọlọ́run kúrò lọ́wọ́ yín, a sì máa fún orílẹ̀-èdè tó ń mú èso rẹ̀ jáde. 44  Bákan náà, ẹni tó bá kọ lu òkúta yìí máa fọ́ túútúú.+ Tó bá sì bọ́ lu ẹnikẹ́ni, ó máa rún ẹni náà wómúwómú.”+ 45  Nígbà tí àwọn olórí àlùfáà àti àwọn Farisí gbọ́ àwọn àpèjúwe rẹ̀, wọ́n mọ̀ pé àwọn ló ń bá wí.+ 46  Bó tiẹ̀ jẹ́ pé wọ́n fẹ́ mú un,* wọ́n ń bẹ̀rù àwọn èrò, torí wòlíì ni àwọn èèyàn náà kà á sí.+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé

Tàbí “agódóńgbó.”
Tàbí “ó pilẹ̀ṣẹ̀ látọ̀dọ̀ èèyàn?”
Tàbí “burú.”
Ní Grk., “olórí igun.”
Tàbí “fàṣẹ ọba mú un.”