Àkọsílẹ̀ Mátíù 18:1-35

  • Ẹni tó tóbi jù nínú Ìjọba náà (1-6)

  • Àwọn ohun ìkọ̀sẹ̀ (7-11)

  • Àpèjúwe àgùntàn tó sọ nù (12-14)

  • Bí o ṣe lè jèrè arákùnrin (15-20)

  • Àpèjúwe ẹrú tí kò dárí jini (21-35)

18  Ní wákàtí yẹn, àwọn ọmọ ẹ̀yìn wá sí tòsí Jésù, wọ́n sì bi í pé: “Ní tòótọ́, ta ló tóbi jù lọ nínú Ìjọba ọ̀run?”+  Torí náà, ó pe ọmọ kékeré kan wá sọ́dọ̀ rẹ̀, ó mú un dúró ní àárín wọn,  ó sì sọ pé: “Lóòótọ́ ni mo sọ fún yín, láìjẹ́ pé ẹ yí pa dà,* kí ẹ sì dà bí àwọn ọmọdé,+ ó dájú pé ẹ ò ní wọ Ìjọba ọ̀run.+  Torí náà, ẹnikẹ́ni tó bá rẹ ara rẹ̀ sílẹ̀ bí ọmọ kékeré yìí ni ẹni tó tóbi jù lọ nínú Ìjọba ọ̀run;+  ẹnikẹ́ni tó bá sì gba irú ọmọ kékeré bẹ́ẹ̀ nítorí orúkọ mi gba èmi náà.  Àmọ́ ẹnikẹ́ni tó bá mú ọ̀kan nínú àwọn ẹni kékeré yìí tó ní ìgbàgbọ́ nínú mi kọsẹ̀, ó sàn ká so ọlọ mọ́ ọn lọ́rùn, irú èyí tí kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ máa ń yí, ká sì jù ú sínú agbami òkun, kó sì rì.+  “Ó mà ṣe fún ayé o, nítorí àwọn ohun ìkọ̀sẹ̀! Lóòótọ́, ó di dandan kí àwọn ohun ìkọ̀sẹ̀ wá, àmọ́ ó mà ṣe o, fún ẹni tí ohun ìkọ̀sẹ̀ náà tipasẹ̀ rẹ̀ wá!  Torí náà, tí ọwọ́ rẹ tàbí ẹsẹ̀ rẹ bá ń mú ọ kọsẹ̀, gé e, kí o sì sọ ọ́ nù kúrò lọ́dọ̀ rẹ.+ Ó sàn fún ọ láti jogún ìyè ní aláàbọ̀ ara tàbí ní arọ ju kí a jù ọ́ sínú iná àìnípẹ̀kun+ pẹ̀lú ọwọ́ méjèèjì tàbí ẹsẹ̀ méjèèjì.  Bákan náà, tí ojú rẹ bá ń mú ọ kọsẹ̀, yọ ọ́, kí o sì sọ ọ́ nù kúrò lọ́dọ̀ rẹ. Ó sàn fún ọ láti jogún ìyè ní olójú kan ju kí a jù ọ́ sínú Gẹ̀hẹ́nà* oníná+ pẹ̀lú ojú méjèèjì. 10  Ẹ rí i pé ẹ ò kẹ́gàn ọ̀kan nínú àwọn ẹni kékeré yìí, torí mò ń sọ fún yín pé ìgbà gbogbo ni àwọn áńgẹ́lì wọn ní ọ̀run máa ń wo ojú Baba mi tó wà ní ọ̀run.+ 11 * —— 12  “Kí lèrò yín? Tí ọkùnrin kan bá ní ọgọ́rùn-ún (100) àgùntàn, tí ọ̀kan nínú wọn sì sọ nù,+ ṣebí ó máa fi mọ́kàndínlọ́gọ́rùn-ún (99) yòókù sílẹ̀ lórí òkè ni, kó sì bẹ̀rẹ̀ sí í wá èyí tó sọ nù?+ 13  Tó bá sì rí i, mò ń sọ fún yín, ó dájú pé ó máa yọ̀ gidigidi torí rẹ̀ ju mọ́kàndínlọ́gọ́rùn-ún (99) tí kò tíì sọ nù. 14  Bákan náà, kò wu Baba mi* tó wà ní ọ̀run pé kí ọ̀kan péré nínú àwọn ẹni kékeré yìí ṣègbé.+ 15  “Bákan náà, tí arákùnrin rẹ bá ṣẹ̀, lọ sọ ẹ̀bi rẹ̀ fún un* láàárín ìwọ àti òun nìkan.+ Tó bá fetí sí ọ, o ti jèrè arákùnrin rẹ.+ 16  Àmọ́ tí kò bá fetí sí ọ, mú ẹnì kan tàbí méjì dání, kó lè jẹ́ pé nípa ẹ̀rí* ẹni méjì tàbí mẹ́ta, a ó fìdí gbogbo ọ̀rọ̀ múlẹ̀.+ 17  Tí kò bá fetí sí wọn, sọ fún ìjọ. Tí kò bá fetí sí ìjọ pàápàá, bí èèyàn àwọn orílẹ̀-èdè+ àti agbowó orí+ ni kó rí sí ọ gẹ́lẹ́. 18  “Lóòótọ́ ni mo sọ fún yín, ohunkóhun tí ẹ bá dè ní ayé máa jẹ́ ohun tí a ti dè ní ọ̀run, ohunkóhun tí ẹ bá sì tú ní ayé máa jẹ́ ohun tí a ti tú ní ọ̀run. 19  Mo tún sọ fún yín lóòótọ́ pé, tí ẹni méjì nínú yín ní ayé bá fohùn ṣọ̀kan lórí ohunkóhun tó ṣe pàtàkì tí wọ́n máa béèrè, ó máa rí bẹ́ẹ̀ fún wọn nítorí Baba mi tó wà ní ọ̀run.+ 20  Torí ibi tí ẹni méjì tàbí mẹ́ta bá kóra jọ sí ní orúkọ mi,+ mo wà níbẹ̀ láàárín wọn.” 21  Pétérù wá, ó sì sọ fún un pé: “Olúwa, ìgbà mélòó ni arákùnrin mi máa ṣẹ̀ mí, tí màá sì dárí jì í? Ṣé kó tó ìgbà méje?” 22  Jésù sọ fún un pé: “Mò ń sọ fún ọ pé, kì í ṣe ìgbà méje, àmọ́ kó tó ìgbà àádọ́rin lé méje (77).+ 23  “Ìdí nìyẹn tí a ṣe lè fi Ìjọba ọ̀run wé ọba kan tó fẹ́ yanjú ọ̀rọ̀ owó pẹ̀lú àwọn ẹrú rẹ̀. 24  Nígbà tó bẹ̀rẹ̀ sí í yanjú rẹ̀, wọ́n mú ọkùnrin kan wọlé tó jẹ ẹ́ ní gbèsè ẹgbẹ̀rún mẹ́wàá (10,000) tálẹ́ńtì.* 25  Àmọ́ torí pé kò ní ohun tó máa fi san án pa dà, ọ̀gá rẹ̀ pàṣẹ pé kí wọ́n ta òun, ìyàwó rẹ̀, àwọn ọmọ rẹ̀ àti gbogbo ohun tó ní, kí wọ́n sì fi san gbèsè náà.+ 26  Ni ẹrú náà bá wólẹ̀, ó sì forí balẹ̀* fún un, ó sọ pé, ‘Ní sùúrù fún mi, màá sì san gbogbo rẹ̀ pa dà fún ọ.’ 27  Àánú ẹrú náà wá ṣe ọ̀gá rẹ̀, ó fi sílẹ̀, ó sì fagi lé gbèsè rẹ̀.+ 28  Àmọ́ ẹrú yẹn jáde lọ, ó sì rí ọ̀kan lára àwọn tí wọ́n jọ jẹ́ ẹrú, tó jẹ ẹ́ ní gbèsè ọgọ́rùn-ún (100) owó dínárì,* ó rá a mú, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí í fún un lọ́rùn, ó sọ pé, ‘San gbogbo gbèsè tí o jẹ pa dà.’ 29  Torí náà, ẹrú ẹlẹgbẹ́ rẹ̀ wólẹ̀, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí í bẹ̀ ẹ́, ó sọ pé, ‘Ní sùúrù fún mi, màá sì san án pa dà fún ọ.’ 30  Àmọ́ kò gbà, ló bá ní kí wọ́n jù ú sẹ́wọ̀n títí ó fi máa san gbèsè tó jẹ pa dà. 31  Nígbà tí àwọn tí wọ́n jọ jẹ́ ẹrú rí ohun tó ṣẹlẹ̀, inú wọn bà jẹ́ gan-an, wọ́n sì lọ ròyìn gbogbo ohun tó ṣẹlẹ̀ fún ọ̀gá wọn. 32  Ọ̀gá rẹ̀ wá ránṣẹ́ pè é, ó sì sọ fún un pé: ‘Ẹrú burúkú, mo fagi lé gbogbo gbèsè yẹn fún ọ nígbà tí o bẹ̀ mí. 33  Ṣé kò yẹ kí ìwọ náà ṣàánú ẹrú ẹlẹgbẹ́ rẹ bí mo ṣe ṣàánú rẹ?’+ 34  Èyí múnú bí ọ̀gá rẹ̀ gidigidi, ló bá fà á lé àwọn tó ń ṣọ́ àwọn ẹlẹ́wọ̀n lọ́wọ́, títí ó fi máa san gbogbo gbèsè tó jẹ pa dà. 35  Bẹ́ẹ̀ náà ni Baba mi ọ̀run máa ṣe sí yín+ tí kálukú yín kò bá dárí ji arákùnrin rẹ̀ látọkàn wá.”+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé

Tàbí “yíwà pa dà.”
Tàbí kó jẹ́, “yín.”
Ní Grk., “lọ bá a wí.”
Ní Grk., “láti ẹnu.”
10,000 tálẹ́ńtì fàdákà jẹ́ 60,000,000 owó dínárì. Wo Àfikún B14.
Tàbí “tẹrí ba.”