Málákì 4:1-6

  • Èlíjà yóò wá kí ọjọ́ Jèhófà tó dé (1-6)

    • “Oòrùn òdodo yóò ràn” (2)

4  “Wò ó! ọjọ́ náà ń bọ̀, ó ń jó bí iná ìléru,+ nígbà tí gbogbo àwọn agbéraga àti gbogbo àwọn tó ń hùwà burúkú yóò dà bí àgékù pòròpórò. Ọjọ́ tó ń bọ̀ náà yóò jẹ wọ́n run,” ni Jèhófà Ọlọ́run àwọn ọmọ ogun wí, “kò sì ní fi gbòǹgbò tàbí ẹ̀ka sílẹ̀ fún wọn. 2  Àmọ́ oòrùn òdodo yóò ràn sórí ẹ̀yin tó bọlá fún* orúkọ mi, ìtànṣán* rẹ̀ yóò mú yín lára dá; ẹ ó sì máa tọ pọ́n-ún pọ́n-ún kiri bí àwọn ọmọ màlúù tí wọ́n bọ́ sanra.” 3  Jèhófà Ọlọ́run àwọn ọmọ ogun sọ pé: “Ẹ ó tẹ àwọn ẹni burúkú mọ́lẹ̀, torí wọ́n á dà bí eruku lábẹ́ ẹsẹ̀ yín, ní ọjọ́ tí mo bá ṣe ohun tí mo sọ.” 4  “Ẹ rántí Òfin Mósè ìránṣẹ́ mi, àwọn ìlànà àti àṣẹ tí mo pa fún gbogbo Ísírẹ́lì ní Hórébù pé kí wọ́n tẹ̀ lé.+ 5  “Wò ó! Èmi yóò rán wòlíì Èlíjà sí yín+ kí ọjọ́ ńlá Jèhófà tó ń bani lẹ́rù tó dé.+ 6  Ó sì máa yí ọkàn àwọn bàbá pa dà sọ́dọ̀ àwọn ọmọ+ àti ọkàn àwọn ọmọ pa dà sọ́dọ̀ àwọn bàbá, kí n má bàa fìyà jẹ ayé, kí n sì pa á run.”

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé

^ Ní Héb., “bẹ̀rù.”
^ Ní Héb., “àwọn ìyẹ́.”