Àkọsílẹ̀ Máàkù 11:1-33

  • Jésù gun kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ wọnú ìlú (1-11)

  • Ó gégùn-ún fún igi ọ̀pọ̀tọ́ (12-14)

  • Jésù fọ tẹ́ńpìlì mọ́ (15-18)

  • Ohun tí a rí kọ́ lára igi ọ̀pọ̀tọ́ tó rọ (19-26)

  • Wọ́n béèrè ẹni tó fún Jésù ní àṣẹ (27-33)

11  Bí wọ́n ṣe ń sún mọ́ Jerúsálẹ́mù, Bẹtifágè àti Bẹ́tánì + ní Òkè Ólífì, ó rán méjì lára àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ jáde,+  ó sọ fún wọn pé: “Ẹ lọ sínú abúlé ọ̀ọ́kán yìí, bí ẹ bá ṣe ń wọ ibẹ̀, ẹ máa rí ọmọ kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́* kan tí wọ́n so, èyí tí èèyàn kankan ò jókòó lé rí títí di báyìí. Ẹ tú u, kí ẹ sì mú un wá síbí.  Tí ẹnikẹ́ni bá sọ fún yín pé, ‘Kí ló dé tí ẹ fi ń ṣe èyí?’ kí ẹ sọ pé, ‘Olúwa fẹ́ lò ó, ó sì máa fi ránṣẹ́ pa dà síbí lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀.’”  Ni wọ́n bá lọ, wọ́n rí ọmọ kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ náà tí wọ́n so sí ẹnu ilẹ̀kùn, níta lójú ọ̀nà, wọ́n sì tú u.+  Àmọ́ àwọn kan lára àwọn tó dúró síbẹ̀ sọ fún wọn pé: “Kí ló dé tí ẹ̀ ń tú ọmọ kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ náà?”  Ohun tí Jésù sọ fún wọn gẹ́lẹ́ ni wọ́n fi dá wọn lóhùn, wọ́n sì jẹ́ kí wọ́n lọ.  Wọ́n mú ọmọ kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́+ náà wá sọ́dọ̀ Jésù, wọ́n tẹ́ aṣọ àwọ̀lékè wọn sórí rẹ̀, ó sì jókòó sórí rẹ̀.+  Bákan náà, ọ̀pọ̀ èèyàn tẹ́ aṣọ àwọ̀lékè wọn sí ojú ọ̀nà, àmọ́ àwọn míì gé àwọn ẹ̀ka igi tó ní ewé látinú pápá.+  Àwọn tó ń lọ níwájú àti àwọn tó ń bọ̀ lẹ́yìn sì ń kígbe ṣáá pé: “A bẹ̀ ọ́, gbà là!+ Ìbùkún ni fún ẹni tó ń bọ̀ ní orúkọ Jèhófà!*+ 10  Ìbùkún ni fún Ìjọba Dáfídì bàbá wa tó ń bọ̀!+ A bẹ̀ ọ́, gbà là, ní ibi gíga lókè!” 11  Ó wọ Jerúsálẹ́mù, ó sì lọ sínú tẹ́ńpìlì, ó wo ohun gbogbo yí ká, àmọ́ torí pé ọjọ́ ti lọ, ó jáde lọ sí Bẹ́tánì pẹ̀lú àwọn Méjìlá náà.+ 12  Ní ọjọ́ kejì, nígbà tí wọ́n ń kúrò ní Bẹ́tánì, ebi ń pa á.+ 13  Ó wá tajú kán rí igi ọ̀pọ̀tọ́ kan tó ní ewé lọ́ọ̀ọ́kán, ó sì lọ wò ó bóyá òun máa rí nǹkan kan lórí rẹ̀. Àmọ́, nígbà tó débẹ̀, kò rí nǹkan kan àfi ewé, torí kì í ṣe àsìkò èso ọ̀pọ̀tọ́. 14  Torí náà, ó sọ fún un pé: “Kí ẹnì kankan má ṣe jẹ èso lórí rẹ mọ́ títí láé.”+ Àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ sì ń gbọ́. 15  Wọ́n wá dé Jerúsálẹ́mù. Ó wọnú tẹ́ńpìlì níbẹ̀, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí í lé àwọn tó ń tajà àti àwọn tó ń rajà nínú tẹ́ńpìlì síta, ó sì dojú tábìlì àwọn tó ń pààrọ̀ owó dé àti bẹ́ǹṣì àwọn tó ń ta àdàbà,+ 16  kò sì jẹ́ kí ẹnì kankan gbé ohun èlò gba tẹ́ńpìlì kọjá. 17  Ó ń kọ́ wọn, ó sì ń sọ fún wọn pé: “Ṣebí a ti kọ ọ́ pé, ‘A ó máa pe ilé mi ní ilé àdúrà fún gbogbo orílẹ̀-èdè’?+ Àmọ́ ẹ ti sọ ọ́ di ihò àwọn olè.”+ 18  Nígbà tí àwọn olórí àlùfáà àti àwọn akọ̀wé òfin gbọ́ èyí, wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí í wá bí wọ́n ṣe máa pa á;+ àmọ́ wọ́n bẹ̀rù rẹ̀, torí pé ẹ̀kọ́ rẹ̀ ya gbogbo àwọn èèyàn náà lẹ́nu.+ 19  Nígbà tí ilẹ̀ ṣú, wọ́n kúrò nínú ìlú náà. 20  Àmọ́ nígbà tí wọ́n ń kọjá lọ ní àárọ̀ kùtù, wọ́n rí i tí igi ọ̀pọ̀tọ́ náà ti gbẹ láti gbòǹgbò rẹ̀.+ 21  Pétérù rántí rẹ̀, ó sì sọ fún un pé: “Rábì, wò ó! igi ọ̀pọ̀tọ́ tí o gégùn-ún fún ti gbẹ.”+ 22  Jésù fèsì pé: “Ẹ ní ìgbàgbọ́ nínú Ọlọ́run. 23  Lóòótọ́ ni mo sọ fún yín pé ẹnikẹ́ni tó bá sọ fún òkè yìí pé, ‘Dìde, wọnú òkun,’ tí kò sì ṣiyèméjì nínú ọkàn rẹ̀, àmọ́ tó ní ìgbàgbọ́ pé ohun tí òun sọ máa rí bẹ́ẹ̀, ó máa rí bẹ́ẹ̀ fún un.+ 24  Ìdí nìyí tí mo fi ń sọ fún yín pé, gbogbo ohun tí ẹ bá gbàdúrà fún, tí ẹ sì béèrè, ẹ ní ìgbàgbọ́ pé ẹ ti rí i gbà, ó sì máa jẹ́ tiyín.+ 25  Nígbà tí ẹ bá dúró láti gbàdúrà, ẹ dárí ji ẹnikẹ́ni tí ẹ bá ní ohunkóhun lòdì sí, kí Baba yín tó wà ní ọ̀run náà lè dárí àwọn ẹ̀ṣẹ̀ yín jì yín.”+ 26 * —— 27  Wọ́n tún wá sí Jerúsálẹ́mù. Bó ṣe ń rìn nínú tẹ́ńpìlì, àwọn olórí àlùfáà àti àwọn akọ̀wé òfin àti àwọn àgbààgbà wá, 28  wọ́n sì bi í pé: “Àṣẹ wo lo fi ń ṣe àwọn nǹkan yìí? Àbí ta ló fún ọ ní àṣẹ yìí pé kí o máa ṣe àwọn nǹkan yìí?”+ 29  Jésù sọ fún wọn pé: “Èmi náà á bi yín ní ìbéèrè kan. Tí ẹ bá dá mi lóhùn, màá wá sọ àṣẹ tí mo fi ń ṣe àwọn nǹkan yìí fún yín. 30  Ṣé láti ọ̀run ni ìrìbọmi tí Jòhánù+ ṣe fún àwọn èèyàn ti wá àbí látọ̀dọ̀ èèyàn?* Ẹ dá mi lóhùn.”+ 31  Wọ́n wá bẹ̀rẹ̀ sí í rò ó láàárín ara wọn, wọ́n ní: “Tí a bá sọ pé, ‘Láti ọ̀run,’ ó máa sọ pé, ‘Kí ló wá dé tí ẹ ò gbà á gbọ́?’ 32  Àmọ́, ṣé a lè sọ pé, ‘Látọ̀dọ̀ èèyàn’?” Wọ́n ń bẹ̀rù àwọn èrò, torí gbogbo àwọn yìí gbà pé wòlíì ni Jòhánù lóòótọ́.+ 33  Nítorí náà, wọ́n dá Jésù lóhùn pé: “A ò mọ̀.” Jésù wá sọ fún wọn pé: “Èmi náà ò ní sọ àṣẹ tí mo fi ń ṣe àwọn nǹkan yìí fún yín.”

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé

Tàbí “agódóńgbó.”
Tàbí “àbí ó pilẹ̀ṣẹ̀ látọ̀dọ̀ èèyàn?”