Àkọsílẹ̀ Lúùkù 24:1-53

  • Jésù jíǹde (1-12)

  • Lójú ọ̀nà tó lọ sí Ẹ́máọ́sì (13-35)

  • Jésù fara han àwọn ọmọ ẹ̀yìn (36-49)

  • Jésù pa dà sí ọ̀run (50-53)

24  Àmọ́ ní ọjọ́ kìíní ọ̀sẹ̀, wọ́n wá síbi ibojì* náà ní àárọ̀ kùtù, wọ́n gbé èròjà tó ń ta sánsán tí wọ́n ṣe dání.+  Ṣùgbọ́n wọ́n rí i pé òkúta náà ti yí kúrò níbi ibojì* náà,+  nígbà tí wọ́n sì wọlé, wọn ò rí òkú Jésù Olúwa.+  Bí wọ́n ṣe ń ro ọ̀rọ̀ náà torí ó rú wọn lójú, wò ó! ọkùnrin méjì tí aṣọ wọn ń kọ mànà dúró lẹ́gbẹ̀ẹ́ wọn.  Ẹ̀rù ba àwọn obìnrin náà, wọ́n sì sorí kodò, àwọn ọkùnrin náà wá sọ fún wọn pé: “Kí ló dé tí ẹ̀ ń wá alààyè láàárín àwọn òkú?+  Kò sí níbí, a ti gbé e dìde. Ẹ rántí bó ṣe bá yín sọ̀rọ̀ nígbà tó wà ní Gálílì,  tó sọ pé a gbọ́dọ̀ fi Ọmọ èèyàn lé àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ lọ́wọ́, kí wọ́n kàn án mọ́gi, kó sì dìde ní ọjọ́ kẹta.”+  Wọ́n wá rántí àwọn ọ̀rọ̀ rẹ̀,+  wọ́n dé látibi ibojì* náà, wọ́n sì ròyìn gbogbo nǹkan yìí fún àwọn Mọ́kànlá náà àti gbogbo àwọn yòókù.+ 10  Àwọn obìnrin náà ni Màríà Magidalénì, Jòánà àti Màríà ìyá Jémíìsì. Bákan náà, àwọn obìnrin yòókù tó wà pẹ̀lú wọn ń sọ àwọn nǹkan yìí fún àwọn àpọ́sítélì. 11  Àmọ́ àwọn ọ̀rọ̀ yìí dà bí ìsọkúsọ létí wọn, wọn ò sì gba àwọn obìnrin náà gbọ́. 12  Àmọ́ Pétérù dìde, ó sì sáré lọ sí ibojì* náà, nígbà tó bẹ̀rẹ̀ wo iwájú, aṣọ ọ̀gbọ̀* nìkan ló rí níbẹ̀. Torí náà, ó lọ, ó ń ronú ohun tó lè ti ṣẹlẹ̀. 13  Àmọ́ wò ó! lọ́jọ́ yẹn gangan, méjì nínú wọn ń rìnrìn àjò lọ sí abúlé kan tí wọ́n ń pè ní Ẹ́máọ́sì, ó tó nǹkan bíi máìlì méje* láti Jerúsálẹ́mù, 14  wọ́n sì jọ ń sọ̀rọ̀ nípa gbogbo nǹkan tó ti ṣẹlẹ̀ yìí. 15  Bí wọ́n ṣe jọ ń sọ̀rọ̀, tí wọ́n sì ń jíròrò àwọn nǹkan yìí, Jésù fúnra rẹ̀ sún mọ́ wọn, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí í bá wọn rìn, 16  àmọ́ a ò jẹ́ kí wọ́n dá a mọ̀.+ 17  Ó sọ fún wọn pé: “Àwọn ọ̀rọ̀ wo lẹ̀ ń bá ara yín fà bí ẹ ṣe ń rìn lọ?” Wọ́n wá dúró sójú kan, inú wọn ò sì dùn. 18  Èyí tó ń jẹ́ Kíléópà dá a lóhùn pé: “Ṣé àjèjì tó ń dá gbé ní Jerúsálẹ́mù ni ọ́ ni, tó ò fi mọ* àwọn nǹkan tó ṣẹlẹ̀ lẹ́nu ọjọ́ mélòó kan yìí?” 19  Ó bi wọ́n pé: “Àwọn nǹkan wo?” Wọ́n sọ fún un pé: “Àwọn nǹkan tó ṣẹlẹ̀ sí Jésù ará Násárẹ́tì,+ ẹni tó fi hàn pé wòlíì tó lágbára ni òun nínú ọ̀rọ̀ àti ìṣe níwájú Ọlọ́run àti gbogbo èèyàn;+ 20  àti bí àwọn olórí àlùfáà àti àwọn alákòóso wa ṣe fà á kalẹ̀ pé kí wọ́n dájọ́ ikú fún un,+ tí wọ́n sì kàn án mọ́gi. 21  Àmọ́ àwa ń retí pé ọkùnrin yìí ni ẹni tó máa gba Ísírẹ́lì sílẹ̀.+ Àní, yàtọ̀ sí gbogbo nǹkan yìí, ọjọ́ kẹta nìyí tí àwọn nǹkan yìí ṣẹlẹ̀. 22  Bákan náà, àwọn obìnrin kan láàárín wa tún mú kí ẹnu yà wá, torí wọ́n lọ síbi ibojì* náà ní àárọ̀ kùtù,+ 23  nígbà tí wọn ò sì rí òkú rẹ̀, wọ́n wá sọ fún wa pé àwọn tún rí ohun kan tó ju agbára ẹ̀dá lọ, àwọn áńgẹ́lì, tí wọ́n sọ pé ó wà láàyè. 24  Lẹ́yìn náà, àwọn kan lára àwọn tó wà pẹ̀lú wa lọ sí ibojì* náà,+ wọ́n sì bá ibẹ̀ bí àwọn obìnrin náà ṣe sọ gẹ́lẹ́, àmọ́ wọn ò rí i.” 25  Torí náà, ó sọ fún wọn pé: “Ẹ̀yin aláìlóye, tí ọkàn yín ò tètè gba gbogbo ohun tí àwọn wòlíì sọ gbọ́! 26  Ṣé kò pọn dandan kí Kristi jìyà àwọn nǹkan yìí,+ kó sì wọnú ògo rẹ̀ ni?”+ 27  Ó wá bẹ̀rẹ̀ látọ̀dọ̀ Mósè àti gbogbo àwọn Wòlíì,+ ó sì túmọ̀ àwọn nǹkan tó jẹ mọ́ òun fúnra rẹ̀ nínú gbogbo Ìwé Mímọ́ fún wọn. 28  Níkẹyìn, wọ́n sún mọ́ abúlé tí wọ́n ń rìnrìn àjò lọ, ó sì ṣe bí ẹni ń bá ìrìn àjò rẹ̀ lọ. 29  Àmọ́ wọ́n rọ̀ ọ́ pé kó dúró, wọ́n ní: “Dúró sọ́dọ̀ wa, torí ó ti ń di ọwọ́ alẹ́, ọjọ́ sì ti lọ.” Ló bá wọlé, ó sì dúró sọ́dọ̀ wọn. 30  Bó ṣe ń bá wọn jẹun,* ó mú búrẹ́dì, ó súre sí i, ó bù ú, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí í fún wọn.+ 31  Ìgbà yẹn ni ojú wọn là rekete, wọ́n sì dá a mọ̀; àmọ́ ó pòórá láàárín wọn.+ 32  Wọ́n wá ń sọ fúnra wọn pé: “Àbí ẹ ò rí i bí ọkàn wa ṣe ń jó fòfò nínú wa bó ṣe ń bá wa sọ̀rọ̀ lójú ọ̀nà, tó ń ṣàlàyé Ìwé Mímọ́* fún wa ní ẹ̀kúnrẹ́rẹ́!” 33  Wọ́n gbéra ní wákàtí yẹn gangan, wọ́n pa dà sí Jerúsálẹ́mù, wọ́n sì rí àwọn Mọ́kànlá náà àti àwọn tó kóra jọ pẹ̀lú wọn, 34  tí wọ́n sọ pé: “Ní tòótọ́, a ti gbé Olúwa dìde, ó sì fara han Símónì!”+ 35  Wọ́n wá ròyìn àwọn ohun tó ṣẹlẹ̀ lójú ọ̀nà àti bí wọ́n ṣe dá a mọ̀ nígbà tó ń bu búrẹ́dì.+ 36  Bí wọ́n ṣe ń sọ àwọn nǹkan yìí, ó fara hàn ní àárín wọn, ó sì sọ fún wọn pé: “Àlàáfíà fún yín o.”+ 37  Àmọ́ torí pé ẹ̀rù ń bà wọ́n, tí àyà wọn sì ń já, wọ́n rò pé ẹ̀mí ni àwọn ń rí. 38  Ó wá sọ fún wọn pé: “Kí ló dé tí ọkàn yín ò balẹ̀, kí sì nìdí tí ẹ fi bẹ̀rẹ̀ sí í ṣiyèméjì lọ́kàn yín? 39  Ẹ wo ọwọ́ mi àti ẹsẹ̀ mi, kí ẹ lè mọ̀ pé èmi náà ni; ẹ fọwọ́ kàn mí kí ẹ lè rí i, torí pé ẹ̀mí ò ní ẹran ara àti egungun bí ẹ ṣe rí i pé èmi ní.” 40  Bó ṣe ń sọ èyí, ó fi ọwọ́ rẹ̀ àti ẹsẹ̀ rẹ̀ hàn wọ́n. 41  Síbẹ̀, wọn ò gbà gbọ́ torí pé inú wọn ń dùn gan-an, ẹnu sì yà wọ́n, ó wá bi wọ́n pé: “Ṣé ẹ ní nǹkan jíjẹ níbẹ̀?” 42  Wọ́n wá fún un ní ẹja yíyan kan, 43  ó gbà á, ó sì jẹ ẹ́ níṣojú wọn. 44  Lẹ́yìn náà, ó sọ fún wọn pé: “Àwọn ọ̀rọ̀ tí mo bá yín sọ nìyí, nígbà tí mo ṣì wà lọ́dọ̀ yín,+ pé gbogbo ohun tí a kọ nípa mi nínú Òfin Mósè àti nínú ìwé àwọn Wòlíì àti Sáàmù gbọ́dọ̀ ṣẹ.”+ 45  Ó wá là wọ́n lóye ní ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ kí ìtúmọ̀ Ìwé Mímọ́ lè yé wọn,+ 46  ó sì sọ fún wọn pé: “Ohun tí a kọ nìyí: pé Kristi máa jìyà, ó sì máa dìde láàárín àwọn òkú ní ọjọ́ kẹta,+ 47  àti pé ní gbogbo orílẹ̀-èdè,+ bẹ̀rẹ̀ láti Jerúsálẹ́mù,+ a máa wàásù ní orúkọ rẹ̀ pé kí àwọn èèyàn ronú pìwà dà kí wọ́n lè rí ìdáríjì ẹ̀ṣẹ̀.+ 48  Ẹ máa jẹ́ ẹlẹ́rìí àwọn nǹkan yìí.+ 49  Ẹ wò ó! màá rán ohun tí Baba mi ti ṣèlérí sórí yín. Àmọ́ kí ẹ dúró sínú ìlú náà títí a fi máa fi agbára wọ̀ yín láti òkè.”+ 50  Ó wá mú wọn jáde títí dé Bẹ́tánì, ó gbé ọwọ́ rẹ̀ sókè, ó sì súre fún wọn. 51  Bó ṣe ń súre fún wọn, a mú un kúrò lọ́dọ̀ wọn lọ sí ọ̀run.+ 52  Wọ́n tẹrí ba* fún un, inú wọn sì dùn gan-an bí wọ́n ṣe ń pa dà sí Jerúsálẹ́mù.+ 53  Ìgbà gbogbo ni wọ́n sì ń wà nínú tẹ́ńpìlì, tí wọ́n ń yin Ọlọ́run.+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé

Tàbí “ibojì ìrántí.”
Tàbí “ibojì ìrántí.”
Tàbí “ibojì ìrántí.”
Tàbí “aṣọ àtàtà.”
Tàbí “ibojì ìrántí.”
Nǹkan bíi kìlómítà 11. Ní Grk., “60 sítédíọ̀mù.” Sítédíọ̀mù kan jẹ́ mítà 185 (606.95 ẹsẹ̀ bàtà). Wo Àfikún B14.
Tàbí kó jẹ́, “Ṣé ìwọ nìkan ni àlejò ní Jerúsálẹ́mù tí kò mọ.”
Tàbí “ibojì ìrántí.”
Tàbí “ibojì ìrántí.”
Tàbí “jókòó sídìí tábìlì pẹ̀lú wọn.”
Ní Grk., “ṣí Ìwé Mímọ́.”
Tàbí “forí balẹ̀.”