Jeremáyà 6:1-30
6 Ẹ wá ibi ààbò kúrò ní Jerúsálẹ́mù, ẹ̀yin ọmọ Bẹ́ńjámínì.
Ẹ fun ìwo+ ní Tékóà;+Ẹ sì gbé àmì iná sókè lórí Bẹti-hákérémù!
Torí pé àjálù ń rọ̀ dẹ̀dẹ̀ láti àríwá, àjálù ńlá.+
2 Ọmọbìnrin Síónì jọ arẹwà obìnrin tó gbẹgẹ́.+
3 Àwọn olùṣọ́ àgùntàn àti agbo ẹran wọn yóò wá.
Wọ́n á pa àgọ́ wọn yí i ká,+Kálukú wọn á máa kó agbo ẹran wọn jẹ̀.+
4 “Ẹ múra* láti bá a jagun!
Ẹ dìde, ẹ jẹ́ ká bá a jà ní ọ̀sán gangan!”
“A gbé! Nítorí ọjọ́ ti lọ,Ilẹ̀ sì ti ń ṣú.”
5 “Ẹ dìde, ẹ jẹ́ ká bá a jà ní òruKá sì pa àwọn ilé gogoro rẹ̀ tó láàbò run.”+
6 Ohun tí Jèhófà Ọlọ́run àwọn ọmọ ogun sọ nìyí:
“Gé igi lulẹ̀, kí o sì mọ òkìtì láti dó ti Jerúsálẹ́mù.+
Ìlú tí ó gbọ́dọ̀ jíhìn ni;Ìnilára nìkan ló wà nínú rẹ̀.+
7 Bí omi tútù ṣe máa ń wà nínú àmù,*Bẹ́ẹ̀ ni ìwà burúkú ṣe wà nínú ìlú yìí.
Ìwà ipá àti ìparun ni ìròyìn tí à ń gbọ́ nínú rẹ̀;+Àìsàn àti àjálù ni mò ń rí níbẹ̀ nígbà gbogbo.
8 Gba ìkìlọ̀, ìwọ Jerúsálẹ́mù, kí n* má bàa bínú fi ọ́ sílẹ̀;+Màá sọ ọ́ di ahoro, ilẹ̀ tí kò sí ẹni tó ń gbé ibẹ̀.”+
9 Ohun tí Jèhófà Ọlọ́run àwọn ọmọ ogun sọ nìyí:
“Wọ́n á fara balẹ̀ ṣa* èyí tó ṣẹ́ kù lára Ísírẹ́lì bí èso àjàrà tó kẹ́yìn.
Pa dà lọ ṣà wọ́n bí ẹni tó ń ṣa èso àjàrà lórí àwọn àjàrà.”
10 “Ta ló yẹ kí n bá sọ̀rọ̀, kí n sì kìlọ̀ fún?
Ta ló máa gbọ́?
Wò ó! Etí wọn ti di,* tí wọn kò fi lè fetí sílẹ̀.+
Wò ó! Ọ̀rọ̀ Jèhófà ti di ohun tí wọ́n fi ń ṣe ẹlẹ́yà;+Inú wọn ò sì dùn sí ọ̀rọ̀ rẹ̀.
11 Torí náà, ìbínú Jèhófà ti kún inú mi,Ara mi ò sì gbà á mọ́.”+
“Dà á sórí ọmọ tó wà lójú ọ̀nà,+Sórí àwọn àwùjọ ọ̀dọ́kùnrin tó kóra jọ.
Gbogbo wọn ni ọwọ́ máa tẹ̀, láìyọ ọkùnrin kan àti ìyàwó rẹ̀ sílẹ̀,Àwọn àgbàlagbà pẹ̀lú àwọn arúgbó.*+
12 Ilé wọn máa di ti àwọn ẹlòmíì,Títí kan àwọn oko wọn àti ìyàwó wọn.+
Torí màá na ọwọ́ mi sí àwọn tó ń gbé ilẹ̀ náà,” ni Jèhófà wí.
13 “Látorí ẹni kékeré títí dórí ẹni ńlá, kálukú wọn ń jẹ èrè tí kò tọ́;+Látorí wòlíì títí dórí àlùfáà, kálukú wọn ń lu jìbìtì.+
14 Wọ́n sì ń wo àárẹ̀* àwọn èèyàn mi sàn láàbọ̀,* wọ́n ń sọ pé,‘Àlàáfíà wà! Àlàáfíà wà!’
Nígbà tí kò sí àlàáfíà.+
15 Ǹjẹ́ ojú tì wọ́n nítorí àwọn ohun ìríra tí wọ́n ṣe?
Ojú kì í tì wọ́n!
Àní wọn ò tiẹ̀ lójútì rárá!+
Torí náà, wọ́n á ṣubú láàárín àwọn tó ti ṣubú.
Nígbà tí mo bá fìyà jẹ wọ́n, wọ́n á kọsẹ̀,” ni Jèhófà wí.
16 Ohun tí Jèhófà sọ nìyí:
“Ẹ dúró ní oríta, kí ẹ sì wò.
Ẹ béèrè àwọn ọ̀nà àtijọ́,Ẹ béèrè ibi tí ọ̀nà tó dára wà, kí ẹ sì máa rìn ín,+Kí ẹ* lè rí ìsinmi.”
Ṣùgbọ́n wọ́n sọ pé: “A ò ní rin ọ̀nà náà.”+
17 “Mo sì yan àwọn olùṣọ́+ tí wọ́n sọ pé,‘Ẹ fetí sí ìró ìwo!’”+
Àmọ́ wọ́n sọ pé: “A ò ní fetí sí i.”+
18 “Torí náà, ẹ gbọ́, ẹ̀yin orílẹ̀-èdè!
Kí o sì mọ̀, ìwọ àpéjọ,Ohun tó máa ṣẹlẹ̀ sí wọn.
19 Ẹ fetí sílẹ̀, ẹ̀yin orílẹ̀-èdè ayé!
Màá mú àjálù bá àwọn èèyàn yìí+Wọ́n á jèrè èrò ibi wọn,Torí wọn kò fiyè sí ọ̀rọ̀ miWọ́n sì kọ òfin* mi.”
20 “Kò já mọ́ nǹkan kan lójú mi pé ẹ̀ ń mú oje igi tùràrí wá láti ṢébàÀti pòròpórò olóòórùn dídùn* láti ilẹ̀ tó jìnnà.
Àwọn odindi ẹbọ sísun yín kò ní ìtẹ́wọ́gbà,Àwọn ẹbọ yín kò sì mú inú mi dùn.”+
21 Nítorí náà, ohun tí Jèhófà sọ nìyí:
“Wò ó, màá fi àwọn ohun ìkọ̀sẹ̀ sí iwájú àwọn èèyàn yìí,Wọ́n á sì mú wọn kọsẹ̀,Àwọn bàbá àti àwọn ọmọ,Aládùúgbò àti ọ̀rẹ́,Gbogbo wọn yóò sì ṣègbé.”+
22 Ohun tí Jèhófà sọ nìyí:
“Wò ó! Àwọn èèyàn kan ń bọ̀ láti ilẹ̀ àríwá,Orílẹ̀-èdè ńlá kan yóò ta jí láti ibi tó jìnnà jù lọ láyé.+
23 Wọ́n á di ọfà* àti ọ̀kọ̀* mú.
Ìkà ni wọ́n, wọn ò sì lójú àánú.
Ìró wọn dà bíi ti òkun,Wọ́n sì gun ẹṣin.+
Wọ́n to ara wọn bí àwọn jagunjagun láti bá ọ jà, ìwọ ọmọbìnrin Síónì.”
24 A ti gbọ́ ìròyìn nípa rẹ̀.
Ọwọ́ wa rọ;+Wàhálà ti bá wa,Ìdààmú* sì bá wa bíi ti obìnrin tó ń rọbí.+
25 Má ṣe lọ sí oko,Má sì rìn lójú ọ̀nà,Nítorí ọ̀tá ní idà;Ìpayà sì wà níbi gbogbo.
26 Ìwọ ọmọbìnrin àwọn èèyàn mi,Wọ aṣọ ọ̀fọ̀,*+ kí o sì yí nínú eérú.
Ṣọ̀fọ̀ bí ẹni tí ọmọkùnrin rẹ̀ kan ṣoṣo kú, kí o sì sunkún gidigidi,+Torí lójijì ni apanirun máa dé bá wa.+
27 “Mo ti fi ọ́* ṣe ẹni tó ń yọ́ wúrà àti fàdákà mọ́,Nítorí o ní láti yọ́ àwọn èèyàn mi mọ́;Màá fiyè sí wọn, màá sì ṣàyẹ̀wò ohun tí wọ́n ń ṣe.
28 Kò sí ẹni tó lágídí tó wọn láyé,+Wọ́n ń rìn káàkiri bí abanijẹ́.+
Wọ́n dà bíi bàbà àti irin;Ìwà ìbàjẹ́ kún ọwọ́ gbogbo wọn.
29 Ẹwìrì* wọn ti jóná.
Òjé ló ń jáde látinú iná wọn.
Ẹni tó ń yọ́ nǹkan mọ́ kàn ń ṣiṣẹ́ lásán ni,+Àwọn tí kò dára kò sì yọ́ kúrò.+
30 Ó dájú pé fàdákà tí a kọ̀ ni àwọn èèyàn máa pè wọ́n,Nítorí Jèhófà ti kọ̀ wọ́n.”+
Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé
^ Ní Héb., “Ẹ ya ara yín sí mímọ́.”
^ Tàbí “kòtò omi.”
^ Tàbí “ọkàn mi.”
^ Ní Héb., “pèéṣẹ́.”
^ Ní Héb., “Wọn ò dádọ̀dọ́ etí.”
^ Ní Héb., “àwọn tí wọ́n lọ́jọ́ lórí.”
^ Tàbí “ọgbẹ́.”
^ Tàbí “fẹ́ẹ́rẹ́fẹ́.”
^ Tàbí “ọkàn yín.”
^ Tàbí “ìtọ́ni.”
^ Esùsú tó ń ta sánsán.
^ Tàbí “ẹ̀ṣín.”
^ Ní Héb., “ọrun.”
^ Ní Héb., “Ìrora ìrọbí.”
^ Ní Héb., “aṣọ àpò ìdọ̀họ.”
^ Ìyẹn, Jeremáyà.
^ Ìyẹn, ohun tí àwọn alágbẹ̀dẹ fi ń fẹ́ná.

