Jeremáyà 49:1-39

  • Àsọtẹ́lẹ̀ lórí àwọn ọmọ Ámónì (1-6)

  • Àsọtẹ́lẹ̀ lórí Édómù (7-22)

    • Édómù kò ní jẹ́ orílẹ̀-èdè mọ́ (17, 18)

  • Àsọtẹ́lẹ̀ lórí Damásíkù (23-27)

  • Àsọtẹ́lẹ̀ lórí Kédárì àti Hásórì (28-33)

  • Àsọtẹ́lẹ̀ lórí Élámù (34-39)

49  Sí àwọn ọmọ Ámónì,+ ohun tí Jèhófà sọ nìyí: “Ṣé Ísírẹ́lì kò ní ọmọ ni? Ṣé kò ní ẹni tó máa jogún rẹ̀ ni? Kí ló dé tí Málíkámù+ fi gba Gádì?+ Tí àwọn èèyàn rẹ̀ sì ń gbé inú àwọn ìlú Ísírẹ́lì?”   “‘Nítorí náà, wò ó! ọjọ́ ń bọ̀,’ ni Jèhófà wí,‘Tí màá mú kí a gbọ́ ìró ogun* ní Rábà+ àwọn ọmọ Ámónì.+ Ó máa di àwókù,Wọ́n á sì dáná sun àwọn àrọko* rẹ̀.’ ‘Ísírẹ́lì á sì sọ àwọn tó gba tọwọ́ rẹ̀ di ohun ìní,’+ ni Jèhófà wí.   ‘Pohùn réré ẹkún, ìwọ Hẹ́ṣíbónì nítorí wọ́n ti pa Áì run! Ẹ figbe ta, ẹ̀yin àrọko Rábà. Wọ aṣọ ọ̀fọ̀.* Pohùn réré ẹkún, kí o sì lọ káàkiri láàárín àwọn ọgbà ẹran tí a fi òkúta ṣe,*Nítorí Málíkámù máa lọ sí ìgbèkùn,Pẹ̀lú àwọn àlùfáà rẹ̀ àti àwọn ọmọ aládé rẹ̀.+   Kí nìdí tí o fi ń fọ́nnu nípa àwọn àfonífojì* rẹ,Nípa pẹ̀tẹ́lẹ̀ rẹ tó lọ́ràá,* ìwọ aláìṣòótọ́ ọmọbìnrin,Tí o gbẹ́kẹ̀ lé àwọn ìṣúra rẹ Tí o sì ń sọ pé: “Ta ló lè wá bá mi jà?”’”   “‘Wò ó, màá mú ohun tó ń dẹ́rù bani wá bá ọ,’ ni Olúwa Ọba Aláṣẹ, Jèhófà Ọlọ́run àwọn ọmọ ogun wí,‘Láti ọ̀dọ̀ gbogbo àwọn tó yí ọ ká. Wọ́n á fọ́n yín ká sí ibi gbogbo,Ẹnikẹ́ni kò sì ní kó àwọn tó sá lọ jọ.’”   “‘Àmọ́ lẹ́yìn náà, màá kó àwọn ọmọ Ámónì tó wà lóko ẹrú jọ,’ ni Jèhófà wí.”  Sí Édómù, ohun tí Jèhófà Ọlọ́run àwọn ọmọ ogun sọ nìyí: “Ṣé kò sí ọgbọ́n mọ́ ní Témánì ni?+ Ṣé kò sí ìmọ̀ràn rere mọ́ lọ́dọ̀ àwọn olóye ni? Ṣé ọgbọ́n wọn ti jẹrà ni?   Ẹ sá pa dà! Ẹ lọ máa gbé ní àwọn ibi tó jin kòtò, ẹ̀yin tó ń gbé ní Dédánì!+ Nítorí màá mú àjálù bá Ísọ̀Nígbà tí àkókò tí màá yí ojú mi sí i bá tó.   Bí àwọn tó ń kó èso àjàrà jọ bá wá bá ọ,Ṣé wọn ò ní ṣẹ́ díẹ̀ kù fáwọn tó ń pèéṣẹ́?* Bí àwọn olè bá wá bá ọ ní òru,Gbogbo ohun tí wọ́n bá fẹ́ nìkan ni wọ́n á kó.+ 10  Ṣùgbọ́n, ṣe ni màá tú Ísọ̀ sí borokoto. Màá tú àwọn ibi tó ń sá pa mọ́ sí síta,Kó má lè rí ibi sá pa mọ́ sí mọ́. Àwọn ọmọ rẹ̀ àti àwọn arákùnrin rẹ̀ àti àwọn aládùúgbò rẹ̀ ni a ó pa run,+Kò sì ní sí mọ́.+ 11  Fi àwọn ọmọ rẹ tí kò ní baba sílẹ̀,Màá sì mú kí wọ́n máa wà láàyè,Àwọn opó rẹ á sì gbẹ́kẹ̀ lé mi.” 12  Nítorí ohun tí Jèhófà sọ nìyí: “Wò ó! Bí àwọn tí kò jẹ̀bi láti mu ife náà bá ní láti mu ún ní dandan, ṣé ó wá yẹ kí a fi ọ́ sílẹ̀ láìjìyà? A ò ní fi ọ́ sílẹ̀ láìjìyà, nítorí o gbọ́dọ̀ mu ún.”+ 13  “Nítorí mo ti fi ara mi búra,” ni Jèhófà wí, “pé Bósírà á di ohun àríbẹ̀rù,+ ohun ẹ̀gàn, ibi ìparun àti ègún; gbogbo àwọn ìlú rẹ̀ á sì di àwókù títí láé.”+ 14  Mo ti gbọ́ ìròyìn kan látọ̀dọ̀ Jèhófà,Aṣojú kan ti lọ jíṣẹ́ fún àwọn orílẹ̀-èdè pé: “Ẹ kóra jọ, ẹ wá gbéjà kò ó;Ẹ sì múra ogun.”+ 15  “Nítorí, wò ó! Mo ti sọ ọ́ di ẹni tí kò já mọ́ nǹkan kan láàárín àwọn orílẹ̀-èdè,O ti tẹ́ láàárín àwọn èèyàn.+ 16  Bí o ṣe ń kó jìnnìjìnnì bá àwọn èèyànÀti ìgbéraga* ọkàn rẹ ti tàn ọ́ jẹ,Ìwọ tó ń gbé ihò inú àpáta,Tí ò ń gbé ní òkè tó ga jù lọ. Bí o bá tiẹ̀ kọ́ ìtẹ́ rẹ sí ibi gíga bí ẹyẹ idì,Màá rẹ̀ ọ́ wálẹ̀ láti ibẹ̀,” ni Jèhófà wí. 17  “Édómù á di ohun àríbẹ̀rù.+ Gbogbo ẹni tó bá ń kọjá lọ lẹ́gbẹ̀ẹ́ rẹ̀ á wò ó, ẹ̀rù á bà á, á sì súfèé nítorí gbogbo ìyọnu tó bá Édómù. 18  Bí Sódómù àti Gòmórà àti àwọn ìlú tó yí wọn ká ṣe pa run,”+ ni Jèhófà wí, “kò ní sí ẹnì kankan tí á máa gbé ibẹ̀, kò sì ní sí èèyàn kankan tó máa tẹ̀ dó síbẹ̀.+ 19  “Wò ó! Ẹnì kan máa wá gbéjà ko àwọn ibi ìjẹko Édómù tó wà ní ààbò bíi kìnnìún+ tó jáde látinú igbó kìjikìji lẹ́gbẹ̀ẹ́ Jọ́dánì, ṣùgbọ́n ní ìṣẹ́jú kan, màá mú kí ó sá kúrò lọ́dọ̀ rẹ̀. Màá sì yan àyànfẹ́ lé e lórí. Nítorí ta ló dà bí èmi, ta ló lè sọ pé kí ni mò ń ṣe? Olùṣọ́ àgùntàn wo ló sì lè dúró níwájú mi?+ 20  Nítorí náà, ẹ gbọ́ ìpinnu* tí Jèhófà ṣe lórí Édómù àti ohun tí ó ti rò nípa àwọn tó ń gbé ní Témánì:+ Ó dájú pé, a ó wọ́ àwọn ẹran kéékèèké inú agbo ẹran lọ. Ó máa sọ ibùgbé wọn di ahoro nítorí wọn.+ 21  Nígbà tí wọ́n ṣubú, ìró wọn mú kí ilẹ̀ mì tìtì. Igbe ẹkún wà! A gbọ́ ìró wọn títí dé Òkun Pupa.+ 22  Wò ó! Bí ẹyẹ idì ṣe ń ròkè tí á sì já ṣòòrò wálẹ̀,+Ọ̀tá máa na ìyẹ́ rẹ̀ bo Bósírà.+ Ní ọjọ́ yẹn, ọkàn àwọn jagunjagun ÉdómùMáa dà bí ọkàn obìnrin tó ń rọbí.” 23  Sí Damásíkù:+ “Ìtìjú ti bá Hámátì+ àti Áápádì,Nítorí wọ́n ti gbọ́ ìròyìn búburú. Ìbẹ̀rù mú kí ọkàn wọn domi. Wọ́n dà bí òkun tó ń ru gùdù, tí kò ṣeé mú rọlẹ̀. 24  Damásíkù ti rẹ̀wẹ̀sì. Ó pẹ̀yìn dà láti sá lọ, àmọ́ jìnnìjìnnì bò ó. Ìdààmú àti ìrora ti bá a,Bí obìnrin tó ń rọbí. 25  Báwo ló ṣe jẹ́ pé a kò tíì pa ìlú ìyìn tì,Ìlú ayọ̀? 26  Nítorí àwọn ọ̀dọ́kùnrin rẹ̀ á ṣubú ní àwọn gbàgede rẹ̀,Gbogbo àwọn ọmọ ogun á ṣègbé ní ọjọ́ yẹn,” ni Jèhófà Ọlọ́run àwọn ọmọ ogun wí. 27  “Màá sọ iná sí ògiri Damásíkù,Á sì jó àwọn ilé gogoro tó láàbò ti Bẹni-hádádì run.”+ 28  Sí Kídárì+ àti àwọn ìjọba Hásórì, àwọn tí Nebukadinésárì* ọba Bábílónì pa run, ohun tí Jèhófà sọ nìyí: “Ẹ dìde, ẹ gòkè lọ sí Kídárì,Kí ẹ sì pa àwọn ọmọ Ìlà Oòrùn. 29  A ó gba àgọ́ wọn àti àwọn agbo ẹran wọn,Aṣọ àgọ́ wọn àti gbogbo ohun ìní wọn. Àwọn ràkúnmí wọn ni a ó kó lọ,Wọ́n á sì kígbe sí wọn pé, ‘Ìbẹ̀rù wà níbi gbogbo!’” 30  “Ẹ sá, ẹ lọ jìnnà! Ẹ lọ máa gbé ní àwọn ibi tó jin kòtò, ẹ̀yin tó ń gbé ní Hásórì,” ni Jèhófà wí. “Nítorí Nebukadinésárì* ọba Bábílónì ti gbèrò ohun kan tó fẹ́ ṣe sí yín,Ó sì ti ro ohun kan tó fẹ́ ṣe sí yín.” 31  “Ẹ dìde, ẹ gòkè lọ láti gbéjà ko orílẹ̀-èdè tó wà lálàáfíà,Tó ń gbé lábẹ́ ààbò!” ni Jèhófà wí. “Kò ní ilẹ̀kùn, bẹ́ẹ̀ ni kò ní ọ̀pá ìdábùú; ṣe ni wọ́n ń dá gbé. 32  A ó kó ràkúnmí wọn lọ,Ohun ọ̀sìn wọn tó pọ̀ rẹpẹtẹ ni a ó sì kó bí ẹrù ogun. Màá tú wọn ká síbi gbogbo,*Àwọn tí wọ́n gé irun wọn mọ́lẹ̀ ní ẹ̀bátí,+Màá sì mú àjálù wọn wá láti ibi gbogbo,” ni Jèhófà wí. 33  “Hásórì máa di ibi tí ajáko* ń gbé,Á di ahoro títí láé. Ẹnì kankan ò ní gbé ibẹ̀,Èèyàn kankan ò sì ní tẹ̀ dó sí ibẹ̀.” 34  Ọ̀rọ̀ tí Jèhófà sọ fún wòlíì Jeremáyà nípa Élámù+ ní ìbẹ̀rẹ̀ ìṣàkóso Sedekáyà+ ọba Júdà, nìyí: 35  “Ohun tí Jèhófà Ọlọ́run àwọn ọmọ ogun sọ nìyí, ‘Wò ó, màá ṣẹ́ ọrun Élámù,+ tó jẹ́ agbára tó gbójú lé.* 36  Màá mú ẹ̀fúùfù mẹ́rin láti igun mẹ́rẹ̀ẹ̀rin ọ̀run wá sórí Élámù, màá sì tú wọn ká sí gbogbo ẹ̀fúùfù yìí. Kò ní sí orílẹ̀-èdè kankan tí àwọn tí a fọ́n ká láti Élámù kò ní dé.’” 37  “Màá fọ́ àwọn ọmọ Élámù túútúú níwájú àwọn ọ̀tá wọn àti níwájú àwọn tó fẹ́ gba ẹ̀mí wọn,”* ni Jèhófà wí, “màá sì mú àjálù bá wọn, ìbínú mi tó ń jó bí iná. Màá sì rán idà tẹ̀ lé wọn títí màá fi pa wọ́n run.” 38  “Màá gbé ìtẹ́ mi kalẹ̀ ní Élámù,+ màá sì pa ọba àti àwọn ìjòyè run kúrò níbẹ̀,” ni Jèhófà wí. 39  “Àmọ́ ní ọjọ́ ìkẹyìn, màá kó àwọn ará Élámù tó wà lóko ẹrú jọ,” ni Jèhófà wí.

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé

Tàbí kó jẹ́, “ariwo ogun.”
Tàbí “ìlú tó yí i ká.”
Ní Héb., “aṣọ àpò ìdọ̀họ.”
Tàbí “ọgbà àgùntàn.”
Tàbí “pẹ̀tẹ́lẹ̀.”
Ní Héb., “tó ń ṣàn.”
Ó túmọ̀ sí ṣíṣà lára irè oko tí wọ́n bá fi sílẹ̀.
Lédè Hébérù, ó tún túmọ̀ sí “ìgbójú” tàbí “ìkọjá àyè.”
Tàbí “ìmọ̀ràn.”
Ní Héb., “Nebukadirésárì,” ọ̀nà míì tí wọ́n ń gbà kọ orúkọ yìí.
Ní Héb., “Nebukadirésárì,” ọ̀nà míì tí wọ́n ń gbà kọ orúkọ yìí.
Ní Héb., “sínú afẹ́fẹ́.”
Tàbí “akátá.”
Ní Héb., “ìbẹ̀rẹ̀ agbára wọn.”
Tàbí “àwọn tó ń lépa ọkàn wọn.”