Jeremáyà 48:1-47

  • Àsọtẹ́lẹ̀ lórí Móábù (1-47)

48  Sí Móábù,+ ohun tí Jèhófà Ọlọ́run àwọn ọmọ ogun, Ọlọ́run Ísírẹ́lì, sọ nìyí: “Nébò gbé! + nítorí wọ́n ti pa á run. Ìtìjú ti bá Kiriátáímù,+ wọ́n sì ti gbà á. Ìtìjú ti bá ibi ààbò,* wọ́n sì ti wó o lulẹ̀.+   Wọn ò yin Móábù mọ́. Hẹ́ṣíbónì+ ni wọ́n ti gbèrò ìṣubú rẹ̀, pé: ‘Ẹ wá, ẹ jẹ́ kí a pa á run, kí ó má ṣe jẹ́ orílẹ̀-èdè mọ́.’ Kí ìwọ Mádíménì pẹ̀lú dákẹ́,Torí idà ń tẹ̀ lé ọ.   Ìró ẹkún wá láti Hórónáímù,+Ti ìparun àti ìwópalẹ̀ tó bùáyà.   A ti pa Móábù run. Àwọn ọmọ rẹ̀ kéékèèké figbe ta.   Bí wọ́n ṣe ń gòkè lọ ní Lúhítì, wọn ò dákẹ́ ẹkún. Nígbà tí wọ́n sì ń sọ̀ kalẹ̀ láti Hórónáímù, wọ́n ń gbọ́ igbe ìdààmú nítorí àjálù.+   Ẹ fẹsẹ̀ fẹ, ẹ sá àsálà fún ẹ̀mí* yín! Kí ẹ sì dà bí igi júnípà ní aginjù.   Nítorí o gbẹ́kẹ̀ lé iṣẹ́ rẹ àti àwọn ìṣúra rẹ,A ó mú ìwọ náà lẹ́rú. Kémóṣì+ máa lọ sí ìgbèkùn,Pẹ̀lú àwọn àlùfáà rẹ̀ àti àwọn ìjòyè rẹ̀.   Apanirun máa wá sórí gbogbo ìlú,Ìlú kankan ò sì ní yè bọ́.+ Àfonífojì* á ṣègbé,Ilẹ̀ tó tẹ́jú* á sì pa run, bí Jèhófà ti sọ.   Ẹ ṣe àmì tó máa fọ̀nà han Móábù,Torí nígbà tí àwọn ìlú rẹ̀ bá di àwókù, á sá lọ,Àwọn ìlú rẹ̀ á sì di ohun àríbẹ̀rù,Ẹnì kankan kò sì ní gbé ibẹ̀.+ 10  Ègún ni fún ẹni tó ń fi ọwọ́ dẹngbẹrẹ mú iṣẹ́ tí Jèhófà rán an! Ègún ni fún ẹni tí kò fi idà rẹ̀ ta ẹ̀jẹ̀ sílẹ̀! 11  Àwọn ọmọ Móábù ti wà láìsí ìyọlẹ́nu látìgbà èwe wọn,Bíi wáìnì tó silẹ̀ sórí gẹ̀dẹ̀gẹ́dẹ̀ rẹ̀. A kò dà á látinú ohun èlò kan sínú ohun èlò míì,Wọn ò sì lọ sí ìgbèkùn rí. Ìdí nìyẹn tí ìtọ́wò wọn kò fi yí pa dà,Tí ìtasánsán wọn kò sì yàtọ̀. 12  “‘Nítorí náà, wò ó! ọjọ́ ń bọ̀,’ ni Jèhófà wí, ‘tí màá rán àwọn ọkùnrin láti dojú wọn dé. Wọ́n á dojú wọn kọlẹ̀, wọ́n á da gbogbo ohun tó wà nínú ohun èlò wọn jáde, wọ́n á sì fọ́ àwọn ìṣà ńlá wọn sí wẹ́wẹ́. 13  Ojú á ti àwọn ọmọ Móábù nítorí Kémóṣì, bí ojú ṣe ti ilé Ísírẹ́lì nítorí Bẹ́tẹ́lì tí wọ́n gbọ́kàn lé.+ 14  Ẹ ṣe lè sọ pé: “Jagunjagun tó lákíkanjú ni wá, a ti múra ogun”?’+ 15  ‘Wọ́n ti pa Móábù run,Wọ́n ti ya wọnú àwọn ìlú rẹ̀,+Àwọn ọ̀dọ́kùnrin wọn tó dára jù lọ ni a ti pa,’+Ni Ọba tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Jèhófà Ọlọ́run àwọn ọmọ ogun wí.+ 16  Àjálù àwọn ọmọ Móábù kò ní pẹ́ dé mọ́,Ìṣubú wọn sì ń yára bọ̀ kánkán.+ 17  Gbogbo àwọn tó yí wọn ká máa ní láti bá wọn kẹ́dùn,Gbogbo àwọn tó mọ orúkọ wọn. Ẹ sọ fún wọn pé: ‘Ẹ wo bí a ti ṣẹ́ ọ̀pá tó lágbára, ọ̀pá ẹwà!’ 18  Sọ̀ kalẹ̀ kúrò nínú ògo rẹ,Sì jókòó nínú òùngbẹ,* ìwọ ọmọbìnrin tó ń gbé ní Díbónì,+Nítorí ẹni tó pa Móábù run ti wá gbéjà kò ọ́,Ó sì máa pa àwọn ibi olódi rẹ run.+ 19  Dúró lẹ́gbẹ̀ẹ́ ọ̀nà, kí o sì máa ṣọ́nà, ìwọ tó ń gbé ní Áróérì.+ Béèrè lọ́wọ́ ọkùnrin tó ń sá lọ àti lọ́wọ́ obìnrin tó ń sá àsálà pé, ‘Kí ló ṣẹlẹ̀?’ 20  Ìtìjú ti bá Móábù, jìnnìjìnnì sì ti bò ó. Ẹ pohùn réré ẹkún, kí ẹ sì figbe ta. Ẹ kéde rẹ̀ ní Áánónì+ pé wọ́n ti pa Móábù run. 21  “Ìdájọ́ ti dé sí ilẹ̀ tó tẹ́jú,*+ sórí Hólónì àti Jáhásì+ àti sórí Mẹ́fáátì;+ 22  sórí Díbónì+ àti Nébò+ àti sórí Bẹti-dibilátáímù; 23  sórí Kiriátáímù + àti Bẹti-gámúlì àti sórí Bẹti-méónì;+ 24  sórí Kéríótì+ àti Bósírà àti sórí gbogbo àwọn ìlú tó wà ní ilẹ̀ Móábù, àwọn tó jìnnà àti àwọn tó wà nítòsí. 25  ‘A ti gba agbára* Móábù;A sì ti ṣẹ́ apá rẹ̀,’ ni Jèhófà wí. 26  ‘Ẹ rọ ọ́ yó,+ nítorí ó ti gbé ara rẹ̀ ga sí Jèhófà.+ Móábù ń yíràá nínú èébì rẹ̀,Ó sì ti di ẹni ẹ̀sín. 27  Ǹjẹ́ kì í ṣe ẹni ẹ̀sín ni Ísírẹ́lì jẹ́ lójú rẹ?+ Ṣé o rí i láàárín àwọn olè ni,Tí o fi mi orí rẹ, tí o sì sọ̀rọ̀ tí kò dáa sí i? 28  Ẹ fi àwọn ìlú sílẹ̀, kí ẹ sì lọ máa gbé lórí àpáta, ẹ̀yin tó ń gbé ní Móábù,Kí ẹ sì dà bí àdàbà tó kọ́ ìtẹ́ rẹ̀ sí gẹ̀rẹ́gẹ̀rẹ́ àfonífojì.’” 29  “A ti gbọ́ nípa ìgbéraga Móábù, ó gbéra ga gan-an,Nípa ìjọra-ẹni-lójú rẹ̀, ìgbéraga rẹ̀, ìṣefọ́nńté rẹ̀ àti nípa ọkàn gíga rẹ̀.”+ 30  “‘Mo mọ̀ pé inú bí i gan-an,’ ni Jèhófà wí,‘Àmọ́, ó kàn ń fọ́nnu lásán ni. Kò lè ṣe nǹkan kan. 31  Ìdí nìyẹn tí màá fi pohùn réré ẹkún lórí Móábù,Màá figbe ta nítorí gbogbo MóábùMàá sì kédàárò nítorí àwọn ọkùnrin Kiri-hérésì.+ 32  Ẹkún tí mo sun fún Jásérì,+Kò ní tó èyí tí màá sun fún ọ, ìwọ àjàrà Síbúmà.+ Àwọn ọ̀mùnú rẹ tó yọ ti sọdá òkun. Wọ́n ti dé òkun, wọ́n sì ti dé Jásérì. Apanirun ti balẹ̀+Sórí èso ìgbà ẹ̀ẹ̀rùn rẹ àti èso àjàrà tí o kó jọ. 33  Ìdùnnú àti ayọ̀ ti kúrò nínú ọgbà elésoÀti ní ilẹ̀ Móábù.+ Mo sì ti mú kí wáìnì dá níbi tí wọ́n ti ń fún wáìnì. Kò sí ẹni tí á máa kígbe ayọ̀ bí wọ́n ṣe ń tẹ̀ ẹ́. Igbe náà máa yàtọ̀ pátápátá.’”+ 34  “‘Igbe kan dún láti Hẹ́ṣíbónì+ títí lọ dé Éléálè.+ Wọ́n gbé ohùn wọn sókè tó fi dé Jáhásì,+Láti Sóárì dé Hórónáímù,+ dé Ẹgilati-ṣẹ́líṣíyà. Àní omi Nímúrímù máa gbẹ.+ 35  Màá mú kí òpin dé bá wọn ní Móábù,’ ni Jèhófà wí,‘Á dé bá ẹni tó ń mú ọrẹ wá sí ibi gígaÀti ẹni tó ń rú ẹbọ sí ọlọ́run rẹ̀. 36  Ìdí nìyẹn tí ọkàn mi á fi kédàárò* nítorí Móábù bíi fèrè,*+Ọkàn mi á sì kédàárò* nítorí àwọn ọkùnrin Kiri-hérésì bíi fèrè.* Nítorí ọrọ̀ tí ó kó jọ máa ṣègbé. 37  Nítorí gbogbo orí ti pá,+Gbogbo irùngbọ̀n ni a sì gé mọ́lẹ̀. Ọgbẹ́ wà ní gbogbo ọwọ́,+Aṣọ ọ̀fọ̀* sì wà ní ìbàdí wọn!’”+ 38  “‘Lórí gbogbo òrùlé MóábùÀti ní àwọn gbàgede ìlú rẹ̀,Kò sí nǹkan míì, àfi ìpohùnréré ẹkún. Nítorí mo ti fọ́ MóábùBí ìṣà tí a sọ nù,’ ni Jèhófà wí. 39  ‘Ẹ wo bi ẹ̀rù ti bà á tó! Ẹ pohùn réré ẹkún! Ẹ wo bí Móábù ṣe sá pa dà nítorí ìtìjú! Móábù ti di ẹni ẹ̀sín,Ó sì jẹ́ ohun tó ń bani lẹ́rù sí gbogbo àwọn tó yí i ká.’” 40  “Nítorí ohun tí Jèhófà sọ nìyí: ‘Wò ó! Bí ẹyẹ idì ṣe ń já ṣòòrò wálẹ̀,+Ni ọ̀tá ṣe máa na ìyẹ́ rẹ̀ bo Móábù.+ 41  Wọ́n á gba àwọn ìlú rẹ̀,Wọ́n á sì gba àwọn odi agbára rẹ̀. Ní ọjọ́ yẹn, ọkàn àwọn jagunjagun MóábùMáa dà bí ọkàn obìnrin tó ń rọbí.’” 42  “‘Wọ́n á pa Móábù run, kò ní jẹ́ orílẹ̀-èdè mọ́,+Nítorí ó ti gbé ara rẹ̀ ga+ sí Jèhófà. 43  Ìbẹ̀rù àti kòtò àti pańpẹ́ wà níwájú rẹ,Ìwọ tó ń gbé ní Móábù,’ ni Jèhófà wí. 44  ‘Ẹnikẹ́ni tó bá ń sá lọ nítorí ìbẹ̀rù á já sínú kòtò,Pańpẹ́ sì máa mú ẹnikẹ́ni tó bá jáde látinú kòtò.’ ‘Nítorí màá jẹ́ kí ọdún ìyà Móábù dé bá a,’ ni Jèhófà wí. 45  ‘Lábẹ́ òjìji Hẹ́ṣíbónì ni àwọn tó ń sá lọ ti dúró láìní agbára. Nítorí iná máa jáde wá láti Hẹ́ṣíbónìÀti ọwọ́ iná láti àárín Síhónì.+ Á jó iwájú orí MóábùÀti agbárí àwọn ọmọ ìdàrúdàpọ̀.’+ 46  ‘O gbé! Ìwọ Móábù. Àwọn èèyàn Kémóṣì+ ti ṣègbé. Nítorí a ti mú àwọn ọmọkùnrin rẹ lẹ́rú,Àwọn ọmọbìnrin rẹ sì ti lọ sí ìgbèkùn.+ 47  Ṣùgbọ́n màá kó àwọn ará Móábù tó wà lóko ẹrú jọ ní ọjọ́ ìkẹyìn,’ ni Jèhófà wí. ‘Ibí ni ìdájọ́ Móábù parí sí.’”+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé

Tàbí “ibi gíga tó láàbò.”
Tàbí “ọkàn.”
Tàbí “Pẹ̀tẹ́lẹ̀.”
Tàbí “Òkè tí orí rẹ̀ rí pẹrẹsẹ.”
Tàbí kó jẹ́, “lórí ilẹ̀ gbígbẹ.”
Tàbí “òkè tí orí rẹ̀ rí pẹrẹsẹ.”
Ní Héb., “ṣẹ́ ìwo.”
Ìyẹn, fèrè tí wọ́n máa ń fun nígbà tí wọ́n bá ń kédàárò níbi ìsìnkú.
Tàbí “gbé sókè.”
Tàbí “gbé sókè.”
Ìyẹn, fèrè tí wọ́n máa ń fun nígbà tí wọ́n bá ń kédàárò níbi ìsìnkú.
Ní Héb., “Aṣọ àpò ìdọ̀họ.”