Jeremáyà 42:1-22

  • Àwọn èèyàn ní kí Jeremáyà gbàdúrà fún ìtọ́sọ́nà (1-6)

  • Jèhófà fèsì pé: “Ẹ má lọ sí Íjíbítì” (7-22)

42  Nígbà náà, gbogbo olórí àwọn ọmọ ogun àti Jóhánánì+ ọmọ Káréà àti Jesanáyà ọmọ Hóṣáyà pẹ̀lú gbogbo àwọn èèyàn náà wá, látorí ẹni tó kéré jù dórí ẹni tó dàgbà jù,  wọ́n sì sọ fún wòlíì Jeremáyà pé: “Jọ̀wọ́, gbọ́ ẹ̀bẹ̀ wa, kí o sì bá wa gbàdúrà sí Jèhófà Ọlọ́run rẹ nítorí gbogbo àṣẹ́kù yìí, torí a pọ̀ gan-an tẹ́lẹ̀, àmọ́ àwa díẹ̀ ló ṣẹ́ kù báyìí,+ bí ìwọ náà ṣe rí i.  Kí Jèhófà Ọlọ́run rẹ sọ ọ̀nà tó yẹ kí a rìn fún wa àti ohun tó yẹ ká ṣe.”  Wòlíì Jeremáyà fèsì pé: “Mo ti gbọ́ yín, màá bá yín gbàdúrà sí Jèhófà Ọlọ́run yín bí ẹ ṣe sọ; gbogbo ọ̀rọ̀ tí Jèhófà bá fi dá yín lóhùn ni màá sì sọ fún yín. Mi ò ní ṣẹ́ ọ̀rọ̀ kankan kù.”  Wọ́n sọ fún Jeremáyà pé: “Kí Jèhófà jẹ́ ẹlẹ́rìí tòótọ́ àti olódodo sí wa tí a bá ṣe ohunkóhun tó yàtọ̀ sí ọ̀rọ̀ tí Jèhófà Ọlọ́run rẹ fi rán ọ sí wa.  Bóyá ó dára ni o tàbí ó burú, a ó ṣègbọràn sí ohùn Jèhófà Ọlọ́run wa, ẹni tí à ń rán ọ sí, kí nǹkan lè máa lọ dáadáa fún wa nítorí pé a ṣègbọràn sí ohùn Jèhófà Ọlọ́run wa.”  Ọjọ́ mẹ́wàá lẹ́yìn náà, Jèhófà bá Jeremáyà sọ̀rọ̀.  Nítorí náà, ó pe Jóhánánì ọmọ Káréà àti gbogbo olórí àwọn ọmọ ogun tó wà pẹ̀lú rẹ̀ àti gbogbo àwọn èèyàn náà látorí ẹni tó kéré jù dórí ẹni tó dàgbà jù.+  Ó sọ fún wọn pé: “Ohun tí Jèhófà Ọlọ́run Ísírẹ́lì sọ nìyí, ẹni tí ẹ rán mi sí pé kí n bá yín bẹ̀ pé kó ṣojú rere sí yín, ó ní: 10  ‘Bí ẹ kò bá kúrò ní ilẹ̀ yìí, màá gbé yín ró, mi ò sì ní ya yín lulẹ̀, màá gbìn yín, mi ò sì ní fà yín tu, torí màá pèrò dà* lórí àjálù tí mo mú bá yín.+ 11  Ẹ má fòyà nítorí ọba Bábílónì, ẹni tí ẹ̀ ń bẹ̀rù.’+ “‘Ẹ má bẹ̀rù rẹ̀,’ ni Jèhófà wí, ‘torí mo wà pẹ̀lú yín, láti gbà yín àti láti yọ yín lọ́wọ́ rẹ̀. 12  Màá fi àánú hàn sí yín,+ yóò sì ṣàánú yín, yóò sì dá yín pa dà sí ilẹ̀ yín. 13  “‘Ṣùgbọ́n tí ẹ bá sọ pé, “Rárá, a ò ní dúró ní ilẹ̀ yìí!” tí ẹ sì ṣàìgbọràn sí ohùn Jèhófà Ọlọ́run yín, 14  tí ẹ sọ pé, “Rárá o, kàkà bẹ́ẹ̀, ilẹ̀ Íjíbítì ni a máa lọ,+ níbi tí a ò ti ní rí ogun, tí a ò ní gbọ́ ìró ìwo, tí ebi kò sì ní pa wá; ibẹ̀ sì ni a ó máa gbé,” 15  torí náà, gbọ́ ọ̀rọ̀ Jèhófà, ìwọ àṣẹ́kù Júdà. Ohun tí Jèhófà Ọlọ́run àwọn ọmọ ogun, Ọlọ́run Ísírẹ́lì, sọ nìyí: “Tí ẹ bá kọ̀ jálẹ̀ pé dandan ni ẹ máa lọ sí Íjíbítì, tí ẹ sì lọ ń gbé ibẹ̀,* 16  idà tí ẹ̀ ń bẹ̀rù rẹ̀ yẹn gan-an ni yóò lé yín bá níbẹ̀, ní ilẹ̀ Íjíbítì, ìyàn tó sì ń dẹ́rù bà yín yẹn ni yóò tẹ̀ lé yín dé Íjíbítì, ibẹ̀ sì ni ẹ ó kú sí.+ 17  Gbogbo àwọn tí ó fi dandan lé e pé àwọn yóò lọ máa gbé ní Íjíbítì ni idà, ìyàn àti àjàkálẹ̀ àrùn* yóò pa. Kò sí ẹnì kankan tó máa sá àsálà tàbí tó máa la àjálù tí màá mú bá wọn já.”’ 18  “Nítorí ohun tí Jèhófà Ọlọ́run àwọn ọmọ ogun, Ọlọ́run Ísírẹ́lì sọ nìyí: ‘Bí mo ṣe da ìbínú mi àti ìrunú mi sórí àwọn tó ń gbé Jerúsálẹ́mù,+ bẹ́ẹ̀ ni màá da ìrunú mi sórí yín tí ẹ bá lọ sí Íjíbítì, ẹ ó sì di ẹni ègún àti ohun àríbẹ̀rù, ẹni ìfiré àti ẹni ẹ̀gàn,+ ẹ kò sì ní rí ibí yìí mọ́.’ 19  “Jèhófà ti sọ̀rọ̀ sí yín, ẹ̀yin àṣẹ́kù Júdà. Ẹ má lọ sí Íjíbítì. Ẹ̀yin náà mọ̀ dájú lónìí pé mo ti kìlọ̀ fún yín 20  pé ẹ̀ṣẹ̀ yín máa gba ẹ̀mí* yín. Nítorí ẹ̀yin fúnra yín ni ẹ rán mi sí Jèhófà Ọlọ́run yín pé, ‘Bá wa gbàdúrà sí Jèhófà Ọlọ́run wa, kí o sì sọ gbogbo ohun tí Jèhófà Ọlọ́run wa bá sọ fún wa, a ó sì ṣe é.’+ 21  Mo kúkú sọ fún yín lónìí, ṣùgbọ́n ẹ kò ní ṣègbọràn sí ohùn Jèhófà Ọlọ́run yín, ẹ kò sì ní ṣe ìkankan lára ohun tó ní kí n sọ fún yín.+ 22  Nítorí náà, ẹ mọ̀ dájú pé idà, ìyàn àti àjàkálẹ̀ àrùn ni yóò pa yín ní ibi tí ẹ fẹ́ lọ máa gbé.”+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé

Tàbí “kẹ́dùn.”
Tàbí “láti gbé fúngbà díẹ̀ níbẹ̀.”
Tàbí “àìsàn.”
Tàbí “ọkàn.”