Jeremáyà 35:1-19

  • Àwọn ọmọ Rékábù jẹ́ onígbọràn tó ṣeé fara wé (1-19)

35  Ọ̀rọ̀ tí Jèhófà bá Jeremáyà sọ nígbà ayé Jèhóákímù+ ọmọ Jòsáyà, ọba Júdà nìyí, ó ní:  “Lọ sí ilé àwọn ọmọ Rékábù,+ kí o bá wọn sọ̀rọ̀, kí o sì mú wọn wá sínú ilé Jèhófà, sí ọ̀kan lára àwọn yàrá ìjẹun;* kí o sì fi wáìnì lọ̀ wọ́n pé kí wọ́n mu.”  Torí náà, mo mú Jaasanáyà ọmọ Jeremáyà ọmọ Habasináyà àti àwọn arákùnrin rẹ̀ pẹ̀lú gbogbo ọmọ rẹ̀ àti agbo ilé àwọn ọmọ Rékábù  wá sínú ilé Jèhófà. Mo mú wọn wá sínú yàrá ìjẹun àwọn ọmọ Hánánì ọmọ Igidaláyà, èèyàn Ọlọ́run tòótọ́, èyí tó wà lẹ́gbẹ̀ẹ́ yàrá ìjẹun àwọn ìjòyè, tó sì wà lókè yàrá ìjẹun Maaseáyà ọmọ Ṣálúmù tó jẹ́ aṣọ́nà.  Ni mo bá gbé àwọn ife àti àwọn aago tí wáìnì kún inú wọn síwájú àwọn èèyàn ilé Rékábù, mo sì sọ fún wọn pé: “Ẹ mu wáìnì.”  Ṣùgbọ́n wọ́n sọ pé: “À kò ní mu wáìnì, nítorí Jèhónádábù*+ ọmọ Rékábù, baba ńlá wa, tí pàṣẹ fún wa pé, ‘Ẹ̀yin àti àwọn ọmọ yín kò gbọ́dọ̀ mu wáìnì láé.  Ẹ kò gbọ́dọ̀ kọ́ ilé, ẹ kò gbọ́dọ̀ fún irúgbìn, ẹ kò gbọ́dọ̀ gbin ọgbà àjàrà, bẹ́ẹ̀ sì ni ẹ kò gbọ́dọ̀ ní ọgbà àjàrà. Kàkà bẹ́ẹ̀, inú àgọ́ ni kí ẹ máa gbé, kí ẹ bàa lè pẹ́ lórí ilẹ̀ tí ẹ ti jẹ́ àjèjì.’  Nítorí náà, à ń ṣègbọràn sí ohùn Jèhónádábù ọmọ Rékábù baba ńlá wa nínú ohun gbogbo tó pa láṣẹ fún wa, a kò sì jẹ́ fẹnu kan wáìnì, àwa fúnra wa, àwọn ìyàwó wa, àwọn ọmọkùnrin wa àti àwọn ọmọbìnrin wa.  Àti pé a ò kọ́ ilé láti máa gbé, a kò sì ní ọgbà àjàrà tàbí oko tàbí irúgbìn. 10  À ń gbé inú àgọ́, a sì ń ṣègbọràn sí gbogbo ohun tí Jèhónádábù* baba ńlá wa pa láṣẹ fún wa. 11  Àmọ́ nígbà tí Nebukadinésárì* ọba Bábílónì wá gbéjà ko ilẹ̀ tí à ń gbé,+ a sọ pé, ‘Ẹ wá, ẹ jẹ́ kí a wọnú Jerúsálẹ́mù kí a má bàa bọ́ sọ́wọ́ àwọn ọmọ ogun Kálídíà àti ti Síríà.’ Bó ṣe di pé à ń gbé Jerúsálẹ́mù nìyẹn.” 12  Jèhófà bá Jeremáyà sọ̀rọ̀, ó ní: 13  “Ohun tí Jèhófà Ọlọ́run àwọn ọmọ ogun, Ọlọ́run Ísírẹ́lì sọ nìyí, ‘Lọ sọ fún àwọn èèyàn Júdà àti àwọn tó ń gbé ní Jerúsálẹ́mù pé: “Ǹjẹ́ kì í ṣe léraléra ni mo gbà yín níyànjú pé kí ẹ ṣègbọràn sí ọ̀rọ̀ mi?”+ ni Jèhófà wí. 14  “Jèhónádábù ọmọ Rékábù pàṣẹ fún àtọmọdọ́mọ rẹ̀ pé kí wọ́n má ṣe mu wáìnì, wọ́n ṣègbọràn sí ọ̀rọ̀ rẹ̀, wọn kò sì mu wáìnì títí di òní yìí, nípa bẹ́ẹ̀, wọ́n ṣègbọràn sí àṣẹ baba ńlá wọn.+ Àmọ́, léraléra ni mo ti bá yín sọ̀rọ̀,* síbẹ̀ ẹ kò ṣègbọràn sí mi.+ 15  Mo sì ń rán gbogbo àwọn ìránṣẹ́ mi wòlíì sí yín, mò ń rán wọn léraléra,*+ wọ́n ń sọ pé, ‘Ẹ jọ̀wọ́, ẹ yí pa dà, kí kálukú yín kúrò ní ọ̀nà búburú rẹ̀,+ kí ẹ sì ṣe ohun tí ó tọ́! Ẹ má ṣe tẹ̀ lé àwọn ọlọ́run míì, ẹ má sì sìn wọ́n. Nígbà náà, ẹ ó máa gbé ní ilẹ̀ tí mo fún ẹ̀yin àti àwọn baba ńlá yín.’+ Ṣùgbọ́n ẹ kò dẹ etí yín sílẹ̀, ẹ kò sì fetí sí mi. 16  Àwọn ọmọ Jèhónádábù ọmọ Rékábù tẹ̀ lé àṣẹ tí baba ńlá wọn pa fún wọn,+ ṣùgbọ́n àwọn èèyàn yìí kò fetí sí mi.”’” 17  “Nítorí náà, ohun tí Jèhófà, Ọlọ́run àwọn ọmọ ogun, Ọlọ́run Ísírẹ́lì sọ nìyí: ‘Wò ó, màá mú gbogbo àjálù tí mo ti kìlọ̀ fún Júdà àti gbogbo àwọn tó ń gbé ní Jerúsálẹ́mù wá sórí wọn,+ torí pé mo ti bá wọn sọ̀rọ̀, ṣùgbọ́n wọn kò fetí sílẹ̀, mo sì ń pè wọ́n, ṣùgbọ́n wọn kò dáhùn.’”+ 18  Jeremáyà sì sọ fún agbo ilé àwọn ọmọ Rékábù pé: “Ohun tí Jèhófà Ọlọ́run àwọn ọmọ ogun, Ọlọ́run Ísírẹ́lì sọ nìyí, ‘Nítorí pé ẹ ṣègbọràn sí àṣẹ Jèhónádábù baba ńlá yín, tí ẹ̀ ń pa gbogbo àṣẹ rẹ̀ mọ́, tí ẹ sì ń ṣe ohun tó pa láṣẹ fún yín gẹ́lẹ́, 19  ohun tí Jèhófà Ọlọ́run àwọn ọmọ ogun, Ọlọ́run Ísírẹ́lì, sọ nìyí: “Kò sígbà tí kò ní sí ẹnì kan lára àtọmọdọ́mọ Jèhónádábù* ọmọ Rékábù tí yóò máa sìn níwájú mi.”’”

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé

Tàbí “yàrá ńlá.”
Ní Héb., “Jónádábù,” ìkékúrú Jèhónádábù.
Ní Héb., “Jónádábù,” ìkékúrú Jèhónádábù.
Ní Héb., “Nebukadirésárì,” ọ̀nà míì tí wọ́n ń gbà kọ orúkọ yìí.
Ní Héb., “mò ń dìde ní kùtùkùtù láti bá yín sọ̀rọ̀.”
Ní Héb., “mò ń dìde ní kùtùkùtù, mo sì ń rán wọn.”
Ní Héb., “Jónádábù,” ìkékúrú Jèhónádábù.