Jeremáyà 32:1-44

  • Jeremáyà ra ilẹ̀ (1-15)

  • Àdúrà Jeremáyà (16-25)

  • Ohun tí Jèhófà sọ (26-44)

32  Ọ̀rọ̀ tí Jèhófà bá Jeremáyà sọ ní ọdún kẹwàá Sedekáyà ọba Júdà, ìyẹn ní ọdún kejìdínlógún ìjọba Nebukadinésárì.*+  Ní àkókò yẹn, àwọn ọmọ ogun ọba Bábílónì dó ti Jerúsálẹ́mù, wòlíì Jeremáyà sì wà ní àhámọ́ ní Àgbàlá Ẹ̀ṣọ́+ ní ilé* ọba Júdà.  Nítorí Sedekáyà ọba Júdà ti fi í sí àhámọ́,+ ọba sì sọ pé, “Kí nìdí tí o fi sọ tẹ́lẹ̀ báyìí? O sọ pé, ‘Ohun tí Jèhófà sọ nìyí: “Màá fi ìlú yìí lé ọwọ́ ọba Bábílónì, á sì gbà á,+  Sedekáyà ọba Júdà kò ní lè sá mọ́ àwọn ará Kálídíà lọ́wọ́, nítorí ó dájú pé a ó fi í lé ọba Bábílónì lọ́wọ́, wọ́n á jọ rí ara wọn, wọ́n á sì sọ̀rọ̀ lójúkojú.”’+  ‘Á mú Sedekáyà lọ sí Bábílónì, ibẹ̀ ló sì máa wà títí màá fi yíjú sí i,’ ni Jèhófà wí. ‘Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ẹ̀ ń bá àwọn ará Kálídíà jà, ẹ kò ní borí.’”+  Jeremáyà sọ pé: “Jèhófà ti bá mi sọ̀rọ̀, ó ní,  ‘Wò ó, Hánámélì ọmọ Ṣálúmù, arákùnrin bàbá rẹ á wá bá ọ, á sì sọ pé: “Ra ilẹ̀ mi tó wà ní Ánátótì,+ torí pé ìwọ lo lẹ́tọ̀ọ́ láti kọ́kọ́ tún un rà.”’”+  Hánámélì ọmọ arákùnrin bàbá mi wá bá mi, bí Jèhófà ti sọ, nínú Àgbàlá Ẹ̀ṣọ́, ó sì sọ fún mi pé: “Jọ̀wọ́, ra ilẹ̀ mi tó wà ní Ánátótì, nílẹ̀ Bẹ́ńjámínì, torí pé ìwọ ló tọ́ sí, kí o sì tún un rà. Rà á fún ara rẹ.” Ìgbà náà ni mo wá mọ̀ pé ọ̀rọ̀ tí Jèhófà sọ ló ṣẹ yẹn.  Nítorí náà, mo ra ilẹ̀ tó wà ní Ánátótì lọ́wọ́ Hánámélì ọmọ arákùnrin bàbá mi. Mo sì wọn owó+ fún un, ṣékélì* méje àti ẹyọ fàdákà mẹ́wàá. 10  Lẹ́yìn náà, mo ṣe ìwé àdéhùn,+ mo sì gbé èdìdì lé e, mo pe àwọn ẹlẹ́rìí wá,+ mo sì wọn owó náà lórí òṣùwọ̀n. 11  Mo mú ìwé àdéhùn tí mo fi ra ilẹ̀ náà, èyí tó ní èdìdì gẹ́gẹ́ bí àṣẹ àti òfin ti sọ àti èyí tí kò ní èdìdì, 12  mo sì fún Bárúkù,+ ọmọ Neráyà,+ ọmọ Maseáyà ní ìwé àdéhùn náà lójú Hánámélì ọmọ arákùnrin bàbá mi àti lójú àwọn ẹlẹ́rìí tó buwọ́ lu ìwé àdéhùn náà àti lójú gbogbo àwọn Júù tó jókòó sí Àgbàlá Ẹ̀ṣọ́.+ 13  Mo wá pàṣẹ fún Bárúkù lójú wọn, pé: 14  “Ohun tí Jèhófà Ọlọ́run àwọn ọmọ ogun, Ọlọ́run Ísírẹ́lì sọ nìyí, ‘Mú ìwé àdéhùn méjèèjì yìí, ìwé àdéhùn tí o fi ra ilẹ̀ náà, èyí tó ní èdìdì àti èyí tí kò ní èdìdì, kí o sì fi wọ́n sínú ìkòkò, kí a lè tọ́jú wọn, kí wọ́n sì pẹ́.’ 15  Nítorí ohun tí Jèhófà Ọlọ́run àwọn ọmọ ogun, Ọlọ́run Ísírẹ́lì sọ nìyí, ‘Àwọn èèyàn á tún ra ilé àti ilẹ̀ àti ọgbà àjàrà ní ilẹ̀ yìí.’”+ 16  Lẹ́yìn náà, mo gbàdúrà sí Jèhófà lẹ́yìn tí mo fún Bárúkù ọmọ Neráyà ní ìwé àdéhùn tí mo fi ra ilẹ̀ náà, mo sọ pé: 17  “Áà, Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ! Wò ó! Agbára ńlá rẹ+ àti apá rẹ tí o nà jáde lo fi dá ọ̀run àti ayé. Kò sí ohun tó ṣòroó ṣe fún ọ, 18  ìwọ Ẹni tó ní ìfẹ́ tí kì í yẹ̀ sí ẹgbẹẹgbẹ̀rún, àmọ́ tí ò ń bẹ ẹ̀ṣẹ̀ àwọn baba wò lára* àwọn ọmọ tí wọ́n fi sílẹ̀,+ ìwọ Ọlọ́run tòótọ́, tí o jẹ́ Ẹni ńlá àti alágbára ńlá, Jèhófà Ọlọ́run àwọn ọmọ ogun ni orúkọ rẹ. 19  Ìpinnu rẹ* ga, àwọn iṣẹ́ rẹ sì tóbi,+ ìwọ tí ojú rẹ ń wo gbogbo ọ̀nà àwọn èèyàn,+ láti san èrè fún ẹnì kọ̀ọ̀kan gẹ́gẹ́ bí ọ̀nà rẹ̀ àti gẹ́gẹ́ bí ohun tí ó ṣe.+ 20  O ti ṣe àwọn iṣẹ́ àmì àti àwọn iṣẹ́ ìyanu ní ilẹ̀ Íjíbítì, tí a mọ̀ títí di òní yìí, o sì tipa bẹ́ẹ̀ ṣe orúkọ fún ara rẹ ní Ísírẹ́lì àti láàárín aráyé+ bó ṣe rí lónìí yìí. 21  O sì mú àwọn èèyàn rẹ Ísírẹ́lì jáde kúrò ní ilẹ̀ Íjíbítì nípasẹ̀ àwọn iṣẹ́ àmì àti àwọn iṣẹ́ ìyanu àti ọwọ́ agbára àti apá tó nà jáde pẹ̀lú àwọn iṣẹ́ tó ń bani lẹ́rù.+ 22  “Nígbà tó yá, o fún wọn ní ilẹ̀ yìí tí o búra pé wàá fún àwọn baba ńlá wọn,+ ilẹ̀ tí wàrà àti oyin ti ń ṣàn.+ 23  Wọ́n sì wọlé wá, wọ́n sì gbà á, ṣùgbọ́n wọn kò ṣègbọràn sí ohùn rẹ, wọn kò sì tẹ̀ lé òfin rẹ. Wọn kò ṣe ìkankan nínú ohun tí o pàṣẹ fún wọn pé kí wọ́n ṣe, torí náà, o mú kí gbogbo àjálù yìí bá wọn.+ 24  Wò ó! Àwọn èèyàn ti wá mọ òkìtì láti dó ti ìlú náà kí wọ́n lè gbà á,+ ó sì dájú pé idà+ àti ìyàn pẹ̀lú àjàkálẹ̀ àrùn*+ yóò mú kí ìlú náà ṣubú sọ́wọ́ àwọn ará Kálídíà tó ń bá a jà; gbogbo ohun tí o sọ ló ti ṣẹ bí ìwọ náà ṣe rí i báyìí. 25  Àmọ́, Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ, o ti sọ fún mi pé, ‘Fi owó ra ilẹ̀ náà fún ara rẹ, kí o sì pe àwọn ẹlẹ́rìí wá,’ bó tilẹ̀ jẹ́ pé, a ó fi ìlú náà lé ọwọ́ àwọn ará Kálídíà dájúdájú.” 26  Ìgbà náà ni Jèhófà bá Jeremáyà sọ̀rọ̀, ó ní: 27  “Èmi rèé, Jèhófà, Ọlọ́run gbogbo aráyé.* Ǹjẹ́ ohun kan wà tó ṣòroó ṣe fún mi? 28  Nítorí náà, ohun tí Jèhófà sọ nìyí, ‘Wò ó, màá fi ìlú yìí lé ọwọ́ àwọn ará Kálídíà àti Nebukadinésárì* ọba Bábílónì, á sì gbà á.+ 29  Àwọn ará Kálídíà tó ń bá ìlú yìí jà máa wọlé wá, wọ́n á sọ iná sí i, wọ́n á sì sun ún kanlẹ̀+ pẹ̀lú àwọn ilé tí àwọn èèyàn náà ti ń rú ẹbọ lórí òrùlé wọn sí Báálì, tí wọ́n sì ti ń da ọrẹ ohun mímu sí àwọn ọlọ́run míì láti mú mi bínú.’+ 30  “‘Nítorí pé kìkì ohun tó burú lójú mi ni àwọn èèyàn Ísírẹ́lì àti ti Júdà ń ṣe láti ìgbà èwe wọn wá;+ ńṣe ni àwọn èèyàn Ísírẹ́lì ń fi iṣẹ́ ọwọ́ wọn mú mi bínú,’ ni Jèhófà wí. 31  ‘Nítorí ìlú yìí, láti ọjọ́ tí wọ́n ti tẹ̀ ẹ́ dó, títí di òní yìí, jẹ́ ohun tó ń fa ìbínú àti ìrunú fún mi,+ màá sì mú un kúrò níwájú mi,+ 32  nítorí gbogbo ìwà ibi tí àwọn èèyàn Ísírẹ́lì àti ti Júdà ti hù láti mú mi bínú, látorí àwọn fúnra wọn, àwọn ọba wọn,+ àwọn ìjòyè wọn,+ àwọn àlùfáà wọn àti àwọn wòlíì wọn,+ dórí àwọn èèyàn Júdà àti àwọn tó ń gbé Jerúsálẹ́mù. 33  Wọ́n ń kẹ̀yìn sí mi dípò kí wọ́n máa yíjú sí mi; + bí mo tiẹ̀ ń kọ́ wọn léraléra,* kò sí ìkankan nínú wọn tó fetí sílẹ̀, tó sì gba ìbáwí.+ 34  Wọ́n gbé àwọn òrìṣà ẹ̀gbin wọn sínú ilé tí a fi orúkọ mi pè, láti sọ ọ́ di ẹlẹ́gbin.+ 35  Yàtọ̀ síyẹn, wọ́n kọ́ àwọn ibi gíga Báálì, tó wà ní Àfonífojì Ọmọ Hínómù,*+ láti sun àwọn ọmọkùnrin wọn àti àwọn ọmọbìnrin wọn nínú iná fún Mólékì,+ ohun tí mi ò pa láṣẹ fún wọn,+ tí kò sì wá sí mi lọ́kàn rí* pé kí wọ́n ṣe irú ohun ìríra bẹ́ẹ̀ láti mú kí Júdà dẹ́ṣẹ̀.’ 36  “Nítorí náà, ohun tí Jèhófà Ọlọ́run Ísírẹ́lì sọ nìyí nípa ìlú tí ẹ̀ ń sọ pé a ó fi lé ọwọ́ ọba Bábílónì nípasẹ̀ idà, ìyàn àti àjàkálẹ̀ àrùn, 37  ‘Wò ó, màá kó wọn jọ láti inú gbogbo ilẹ̀ tí mo fọ́n wọn ká sí nínú ìbínú mi àti nínú ìrunú mi àti nínú ìkannú ńlá mi,+ màá sì mú wọn pa dà wá sí ibí yìí láti máa gbé lábẹ́ ààbò.+ 38  Wọ́n á jẹ́ èèyàn mi, màá sì jẹ́ Ọlọ́run wọn.+ 39  Màá fún wọn ní ọkàn kan+ àti ọ̀nà kan kí wọ́n lè máa bẹ̀rù mi nígbà gbogbo, fún ire wọn àti ti àwọn ọmọ wọn lẹ́yìn wọn.+ 40  Màá sì bá wọn dá májẹ̀mú tó máa wà títí láé,+ pé mi ò ní jáwọ́ nínú ṣíṣe rere fún wọn;+ màá fi ìbẹ̀rù mi sínú ọkàn wọn, kí wọ́n má bàa kúrò lọ́dọ̀ mi.+ 41  Ṣe ni inú mi á máa dùn nítorí wọn láti máa ṣe rere fún wọn,+ màá sì fi gbogbo ọkàn mi àti gbogbo ara* mi gbìn wọ́n sí ilẹ̀ yìí.’”+ 42  “Nítorí ohun tí Jèhófà sọ nìyí, ‘Bí mo ti mú gbogbo àjálù ńlá yìí bá àwọn èèyàn yìí, bẹ́ẹ̀ ni màá ṣe mú gbogbo oore* tí mo ṣèlérí fún wọn wá sórí wọn.+ 43  Àwọn èèyàn á tún ra ilẹ̀ ní ilẹ̀ yìí,+ bí ẹ tilẹ̀ ń sọ pé: “Ahoro ni, tí kò sí èèyàn àti ẹranko lórí rẹ̀, a sì ti fi í lé ọwọ́ àwọn ará Kálídíà.”’ 44  “‘Àwọn èèyàn á fi owó ra ilẹ̀, wọ́n á ṣe ìwé àdéhùn tí wọ́n fi rà á, wọ́n á gbé èdìdì lé e, wọ́n á sì pe àwọn ẹlẹ́rìí ní ilẹ̀ Bẹ́ńjámínì,+ ní agbègbè Jerúsálẹ́mù àti ní àwọn ìlú Júdà,+ ní àwọn ìlú tó wà ní àwọn agbègbè olókè àti ní àwọn ìlú tó wà ní pẹ̀tẹ́lẹ̀+ pẹ̀lú àwọn ìlú tó wà ní gúúsù, torí pé màá mú àwọn èèyàn wọn tó wà lóko ẹrú pa dà wá,’+ ni Jèhófà wí.”

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé

Ní Héb., “Nebukadirésárì,” ọ̀nà míì tí wọ́n ń gbà kọ orúkọ yìí.
Tàbí “ààfin.”
Ṣékélì kan jẹ́ gíráàmù 11.4. Wo Àfikún B14.
Ní Héb., “ní oókan àyà.”
Tàbí “Àwọn ohun tí o ní lọ́kàn.”
Tàbí “àìsàn.”
Ní Héb., “gbogbo ẹran ara.”
Ní Héb., “Nebukadirésárì,” ọ̀nà míì tí wọ́n ń gbà kọ orúkọ yìí.
Ní Héb., “ń dìde ní kùtùkùtù tí mo sì ń kọ́ wọn.”
Wo Àlàyé Ọ̀rọ̀, “Gẹ̀hẹ́nà.”
Tàbí “ohun tí èmi kò ronú rẹ̀ rí.”
Wo Àlàyé Ọ̀rọ̀, “Ọkàn.”
Tàbí “ohun rere.”