Jeremáyà 22:1-30

  • Ọ̀rọ̀ ìdájọ́ sí àwọn ọba búburú (1-30)

    • Nípa Ṣálúmù (10-12)

    • Nípa Jèhóákímù (13-23)

    • Nípa Konáyà (24-30)

22  Ohun tí Jèhófà sọ nìyí: “Lọ sí ilé* ọba Júdà, kí o sì jẹ́ iṣẹ́ yìí.  Kí o sọ pé, ‘Gbọ́ ọ̀rọ̀ Jèhófà, ìwọ ọba Júdà tí o jókòó sórí ìtẹ́ Dáfídì, ìwọ àti àwọn ìránṣẹ́ rẹ àti àwọn èèyàn rẹ, àwọn tó ń gba àwọn ẹnubodè yìí wọlé.  Ohun tí Jèhófà sọ nìyí: “Ẹ máa dá ẹjọ́ bó ṣe tọ́, kí ẹ sì máa ṣe òdodo. Ẹ gba ẹni tí àwọn oníjìbìtì jà lólè sílẹ̀. Ẹ má ṣe ni àjèjì èyíkéyìí lára, ẹ má ṣèkà sí ọmọ aláìníbaba* èyíkéyìí tàbí opó.+ Ẹ má sì ta ẹ̀jẹ̀ aláìṣẹ̀ sílẹ̀ ní ibí yìí.+  Torí bí ẹ bá ṣe ohun tí mo sọ yìí tọkàntọkàn, nígbà náà àwọn ọba tó ń jókòó lórí ìtẹ́ Dáfídì+ máa gba àwọn ẹnubodè ilé yìí wọlé, àwọn àti àwọn ìránṣẹ́ wọn pẹ̀lú àwọn èèyàn wọn á gun kẹ̀kẹ́ ẹṣin àti àwọn ẹṣin.”’+  “‘Àmọ́ bí ẹ ò bá ṣe ohun tí mo sọ yìí, mo fi ara mi búra pé, ilé yìí máa di ahoro,’+ ni Jèhófà wí.  “Nítorí ohun tí Jèhófà sọ nípa ilé ọba Júdà nìyí,‘Bíi Gílíádì lo rí sí mi,Bí orí òkè Lẹ́bánónì. Ṣùgbọ́n màá sọ ọ́ di aginjù;Kò ní sí ọ̀kan nínú àwọn ìlú rẹ tó máa ṣeé gbé.+   Màá yan àwọn apanirun* láti wá bá ọ,Ẹnì kọ̀ọ̀kan pẹ̀lú àwọn ohun ìjà rẹ̀.+ Wọ́n á gé àwọn tó dára jù lọ lára igi kédárì rẹ lulẹ̀Wọ́n á sì mú kí wọ́n ṣubú sínú iná.+  “‘Ọ̀pọ̀ orílẹ̀-èdè máa kọjá lẹ́gbẹ̀ẹ́ ìlú yìí, wọ́n á sì bi ara wọn pé: “Kí nìdí tí Jèhófà fi ṣe irú èyí sí ìlú ńlá yìí?”+  Wọ́n á fèsì pé: “Torí pé wọ́n fi májẹ̀mú Jèhófà Ọlọ́run wọn sílẹ̀, wọ́n forí balẹ̀ fún àwọn ọlọ́run míì, wọ́n sì ń sìn wọ́n.”’+ 10  Ẹ má sunkún nítorí ẹni tó ti kú,Ẹ má sì ṣọ̀fọ̀ rẹ̀. Kàkà bẹ́ẹ̀, ẹ máa sunkún pẹ̀rẹ̀pẹ̀rẹ̀ nítorí ẹni tó ń lọ,Torí kò ní pa dà mọ́ láti rí ilẹ̀ tí wọ́n bí i sí. 11  “Èyí ni ohun tí Jèhófà sọ nípa Ṣálúmù*+ ọmọ Jòsáyà, ọba Júdà tó ń jọba nípò Jòsáyà bàbá rẹ̀,+ ẹni tó jáde kúrò ní ibí yìí: ‘Kò ní pa dà mọ́. 12  Nítorí ibi tí wọ́n mú un lọ ní ìgbèkùn ló máa kú sí, kò sì ní rí ilẹ̀ yìí mọ́.’+ 13  Ẹni tó ń fi àìṣòdodo kọ́ ilé rẹ̀ ti gbé! Tó ń fi àìṣẹ̀tọ́ kọ́ àwọn yàrá òkè rẹ̀,Tó ń mú kí ọmọnìkejì rẹ̀ sìn ín láìgba nǹkan kan,Tí kò sì fún un ní owó iṣẹ́ rẹ̀;+ 14  Ẹni tó sọ pé, ‘Màá kọ́ ilé ńlá fún ara miTí àwọn yàrá òkè rẹ̀ tóbi. Màá ṣe àwọn fèrèsé* sí iMàá fi igi kédárì bò ó, màá sì fi ọ̀dà tó pupa fòò kùn ún.’ 15  Ṣé wàá máa ṣàkóso lọ torí pé àwọn igi kédárì tí ò ń lò pọ̀ ju ti àwọn míì lọ ni? Bàbá rẹ jẹ, ó sì mu,Àmọ́, ó dá ẹjọ́ bó ṣe tọ́, ó ṣe òdodo,+Nǹkan sì lọ dáadáa fún un. 16  Ó gbèjà ẹ̀tọ́ àwọn tí ìyà ń jẹ àti àwọn aláìní,Nǹkan sì lọ dáadáa. ‘Ǹjẹ́ kì í ṣe ohun tó fi hàn pé ẹnì kan mọ̀ mí nìyẹn?’ ni Jèhófà wí. 17  ‘Àmọ́ ojú rẹ àti ọkàn rẹ ò kúrò lórí bí o ṣe máa jẹ èrè tí kò tọ́,Lórí bí o ṣe máa ta ẹ̀jẹ̀ aláìṣẹ̀ sílẹ̀Àti lórí bí o ṣe máa lu jìbìtì àti bí o ṣe máa lọ́ni lọ́wọ́ gbà.’ 18  “Nítorí náà, ohun tí Jèhófà sọ nípa Jèhóákímù+ ọmọ Jòsáyà, ọba Júdà nìyí,‘Wọn kò ní ṣọ̀fọ̀ rẹ̀ pé: “Áà, arákùnrin mi! Áà, arábìnrin mi!” Wọn kò sì ní ṣọ̀fọ̀ rẹ̀ pé: “Áà, ọ̀gá! Áà, kábíyèsí!” 19  Bí wọ́n ṣe ń sin kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ ni wọ́n máa sin ín,+Wọ́n á wọ́ ọ kiri, wọ́n á sì gbé e sọ nù,Sí ìta ẹnubodè Jerúsálẹ́mù.’+ 20  Gòkè lọ sí Lẹ́bánónì kí o sì ké,Gbé ohùn rẹ sókè ní Báṣánì,Sì ké láti Ábárímù,+Torí pé gbogbo àwọn olólùfẹ́ rẹ àtàtà ni wọ́n ti pa.+ 21  Mo bá ọ sọ̀rọ̀ nígbà tí o rò pé kò séwu. Àmọ́, o sọ pé, ‘Mi ò ní ṣègbọràn.’+ Bí o ṣe máa ń ṣe nìyẹn láti ìgbà èwe rẹ,Nítorí ìwọ kò ṣègbọràn sí ohùn mi.+ 22  Ẹ̀fúùfù á gbé gbogbo olùṣọ́ àgùntàn rẹ lọ,*+Àwọn olólùfẹ́ rẹ àtàtà á sì lọ sí oko ẹrú. Ìgbà yẹn ni ojú máa tì ọ́, wàá sì di ẹni ẹ̀tẹ́ nítorí gbogbo àjálù rẹ. 23  Ẹ̀yin tó ń gbé ní Lẹ́bánónì,+Tí ìtẹ́ yín wà láàárín igi kédárì,+Ẹ wo bí ẹ ó ti kérora tó nígbà tí ìrora bá dé bá yín,Ìdààmú* bíi ti obìnrin tó ń rọbí!”+ 24  “‘Bí mo ti wà láàyè,’ ni Jèhófà wí, ‘kódà bí Konáyà*+ ọmọ Jèhóákímù,+ ọba Júdà, bá tiẹ̀ jẹ́ òrùka èdìdì ní ọwọ́ ọ̀tún mi, ibẹ̀ ni màá ti yọ ọ́ kúrò! 25  Màá fi ọ́ lé ọwọ́ àwọn tó fẹ́ gba ẹ̀mí rẹ,* lé ọwọ́ àwọn tí ò ń bẹ̀rù, lé ọwọ́ Nebukadinésárì* ọba Bábílónì àti lé ọwọ́ àwọn ará Kálídíà.+ 26  Màá fi ẹ̀yin àti ìyá tó bí yín lọ́mọ sọ̀kò sí ilẹ̀ míì tí kì í ṣe ibi tí wọ́n bí yín sí, ibẹ̀ sì ni ẹ máa kú sí. 27  Wọn kò sì ní lè pa dà láé sí ilẹ̀ tí ọkàn wọn fẹ́.*+ 28  Ṣé ọkùnrin yìí, Konáyà, jẹ́ ẹni ẹ̀sín, ìkòkò tó ti fọ́,Ohun èlò tí ẹnikẹ́ni kò fẹ́? Kí nìdí tí a fi wó òun pẹ̀lú àtọmọdọ́mọ rẹ̀ lulẹ̀ Tí a sì sọ wọ́n sí ilẹ̀ tí wọn kò mọ̀?’+ 29  “Ìwọ ilẹ̀, ilẹ̀, ilẹ̀, gbọ́ ọ̀rọ̀ Jèhófà. 30  Ohun tí Jèhófà sọ nìyí: ‘Ẹ kọ ọ́ sílẹ̀ pé ọkùnrin yìí kò bímọ,Pé ọkùnrin yìí kò ní ṣe àṣeyọrí kankan jálẹ̀ ayé rẹ̀,*Nítorí kò sí ìkankan nínú àtọmọdọ́mọ rẹ̀ tó máa ṣàṣeyọríLáti jókòó sórí ìtẹ́ Dáfídì kí ó sì ṣàkóso ní Júdà lẹ́ẹ̀kan sí i.’”+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé

Tàbí “ààfin.”
Tàbí “aláìlóbìí.”
Ní Héb., “ya àwọn apanirun sí mímọ́.”
Wọ́n tún ń pè é ní Jèhóáhásì.
Tàbí “wíńdò.”
Ní Héb., “ṣe olùṣọ́ àgùntàn rẹ.”
Ní Héb., “Ìrora ìrọbí.”
Wọ́n tún ń pè é ní Jèhóákínì àti Jekonáyà.
Tàbí “tó ń lépa ọkàn rẹ.”
Ní Héb., “Nebukadirésárì,” ọ̀nà míì tí wọ́n ń gbà kọ orúkọ yìí.
Tàbí “tí ọkàn wọn fà sí.”
Ní Héb., “ní ọjọ́ ayé rẹ̀.”