Jeremáyà 21:1-14
21 Jeremáyà gbọ́ ọ̀rọ̀ látọ̀dọ̀ Jèhófà, nígbà tí Ọba Sedekáyà+ rán Páṣúrì+ ọmọ Málíkíjà àti Sefanáyà+ ọmọ Maaseáyà, àlùfáà sí i, pé:
2 “Jọ̀wọ́ bá wa wádìí lọ́dọ̀ Jèhófà, torí pé Nebukadinésárì* ọba Bábílónì ń bá wa jà.+ Bóyá Jèhófà á ṣe ọ̀kan lára àwọn iṣẹ́ àrà rẹ̀ nítorí wa, kí ọba yìí lè pa dà lẹ́yìn wa.”+
3 Jeremáyà sọ fún wọn pé: “Ẹ sọ fún Sedekáyà pé,
4 ‘Ohun tí Jèhófà Ọlọ́run Ísírẹ́lì sọ nìyí: “Wò ó, màá jẹ́ kí àwọn ohun ìjà tó wà ní ọwọ́ yín dojú kọ yín,* àwọn ohun tí ẹ fi ń bá ọba Bábílónì jà+ pẹ̀lú àwọn ará Kálídíà tí wọ́n dó tì yín lẹ́yìn odi. Màá sì kó wọn jọ sí àárín ìlú yìí.
5 Èmi fúnra mi máa na apá mi àti ọwọ́ mi tó lágbára jáde láti bá yín jà+ pẹ̀lú ìbínú àti ìrunú àti ìkannú ńlá.+
6 Màá pa àwọn tó ń gbé ìlú yìí, látorí èèyàn dórí ẹranko. Àjàkálẹ̀ àrùn* ńlá ni yóò sì pa wọ́n.”’+
7 “‘Jèhófà sọ pé, “Lẹ́yìn náà, màá fi Sedekáyà ọba Júdà àti àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ àti àwọn èèyàn ìlú yìí, ìyẹn àwọn tó bọ́ lọ́wọ́ àjàkálẹ̀ àrùn, idà àti ìyàn, lé ọwọ́ Nebukadinésárì* ọba Bábílónì, lé ọwọ́ àwọn ọ̀tá wọn àti lé ọwọ́ àwọn tó fẹ́ gba ẹ̀mí wọn.*+ Á fi idà pa wọ́n. Kò ní bá wọn kẹ́dùn, bẹ́ẹ̀ ni kò ní yọ́nú sí wọn tàbí kó ṣàánú wọn.”’+
8 “Kí o sì sọ fún àwọn èèyàn yìí pé, ‘Ohun tí Jèhófà sọ nìyí: “Wò ó, mò ń fi ọ̀nà ìyè àti ọ̀nà ikú síwájú yín.
9 Idà àti ìyàn pẹ̀lú àjàkálẹ̀ àrùn ni yóò pa àwọn tó bá dúró nínú ìlú yìí. Àmọ́ ẹni tó bá jáde, tó sì fi ara rẹ̀ lé ọwọ́ àwọn ará Kálídíà tí wọ́n dó tì yín, á máa wà láàyè, á sì jèrè ẹ̀mí rẹ̀.”’*+
10 “‘“Nítorí mo ti dojú mi kọ ìlú yìí láti mú àjálù bá a, kì í ṣe fún ire,”+ ni Jèhófà wí. “Màá fi lé ọba Bábílónì lọ́wọ́,+ á sì dáná sun ún.”+
11 “‘Ẹ̀yin agbo ilé ọba Júdà: Ẹ gbọ́ ọ̀rọ̀ Jèhófà.
12 Ẹ̀yin ilé Dáfídì, ohun tí Jèhófà sọ nìyí:
“Ẹ máa dá ẹjọ́ bó ṣe tọ́ ní àràárọ̀,Kí ẹ sì gba ẹni tí àwọn oníjìbìtì jà lólè sílẹ̀,+Kí ìbínú mi má bàa sọ bí iná+Tó ń jó tí ẹnì kankan kò lè paNítorí ìwà ibi yín.”’+
13 ‘Wò ó, mo dojú kọ ọ́, ìwọ tó ń gbé àfonífojì,*Ìwọ àpáta tó wà ní ilẹ̀ tó tẹ́jú,’ ni Jèhófà wí.
‘Ní ti ẹ̀yin tí ẹ̀ ń sọ pé: “Ta ló lè wá bá wa jà?
Ta ló sì lè ya wọnú àwọn ibùgbé wa?”
14 Màá mú kí ẹ jíhìnGẹ́gẹ́ bí ìṣe yín,’+ ni Jèhófà wí.
‘Màá dáná sun igbó rẹ̀,Á sì jó gbogbo ohun tó yí i ká run.’”+
Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé
^ Ní Héb., “Nebukadirésárì,” ọ̀nà míì tí wọ́n ń gbà kọ orúkọ yìí.
^ Tàbí “yí pa dà sí yín.”
^ Tàbí “Àìsàn.”
^ Tàbí “tó ń lépa ọkàn wọn.”
^ Ní Héb., “Nebukadirésárì,” ọ̀nà míì tí wọ́n ń gbà kọ orúkọ yìí.
^ Tàbí “sá àsálà fún ọkàn rẹ̀.”
^ Tàbí “pẹ̀tẹ́lẹ̀.”