Jeremáyà 20:1-18
20 Ó ṣẹlẹ̀ pé Páṣúrì, ọmọ Ímérì, àlùfáà, tó tún jẹ́ olórí àwọn kọmíṣọ́nnà nínú ilé Jèhófà fetí sí Jeremáyà nígbà tó ń sọ àsọtẹ́lẹ̀ àwọn nǹkan yìí.
2 Ni Páṣúrì bá lu wòlíì Jeremáyà, ó sì fi í sínú àbà+ tó wà ní Ẹnubodè Òkè ti Bẹ́ńjámínì, tó wà ní ilé Jèhófà.
3 Ṣùgbọ́n ní ọjọ́ kejì, nígbà tí Páṣúrì tú Jeremáyà sílẹ̀ nínú àbà, Jeremáyà sọ fún un pé:
“Jèhófà ti fún ọ lórúkọ, o kì í ṣe Páṣúrì mọ́, bí kò ṣe Ẹ̀rù Yí Mi Ká.+
4 Nítorí ohun tí Jèhófà sọ nìyí, ‘Màá sọ ọ́ di ohun ẹ̀rù sí ara rẹ àti sí gbogbo àwọn ọ̀rẹ́ rẹ, àwọn ọ̀tá wọn á sì fi idà pa wọ́n ní ìṣojú rẹ.+ Màá fa gbogbo Júdà lé ọwọ́ ọba Bábílónì, á kó wọn lọ sí ìgbèkùn ní Bábílónì, á sì fi idà pa wọ́n.+
5 Màá fi gbogbo ọrọ̀ ìlú yìí, gbogbo ohun àmúṣọrọ̀ rẹ̀ pẹ̀lú gbogbo ohun iyebíye rẹ̀ àti gbogbo ìṣúra àwọn ọba Júdà lé àwọn ọ̀tá wọn lọ́wọ́.+ Wọ́n á gba tọwọ́ wọn, wọ́n á mú wọn, wọ́n á sì kó wọn lọ sí Bábílónì.+
6 Ní tìrẹ, ìwọ Páṣúrì àti gbogbo àwọn tó ń gbé inú ilé rẹ, ẹ ó lọ sí oko ẹrú. Wàá lọ sí Bábílónì, ibẹ̀ ni wàá kú sí, ibẹ̀ sì ni wọ́n á sin ìwọ àti gbogbo àwọn ọ̀rẹ́ rẹ sí torí o ti sọ àsọtẹ́lẹ̀ èké fún wọn.’”+
7 O ti yà mí lẹ́nu, Jèhófà, ẹnu sì yà mí.
O lo agbára rẹ lórí mi, o sì borí.+
Mo di ẹni ẹ̀sín láti àárọ̀ ṣúlẹ̀;Gbogbo èèyàn ló ń fi mí ṣe yẹ̀yẹ́.+
8 Nítorí nígbàkigbà tí mo bá sọ̀rọ̀, ṣe ni mò ń ké jáde, tí mo sì ń kéde pé,“Ìwà ipá àti ìparun!”
Nítorí pé ọ̀rọ̀ Jèhófà ti di ohun tó ń fa èébú àti yẹ̀yẹ́ fún mi láti àárọ̀ ṣúlẹ̀.+
9 Torí náà, mo sọ pé: “Mi ò ní sọ nípa rẹ̀ mọ́,Mi ò sì ní sọ̀rọ̀ ní orúkọ rẹ̀ mọ́.”+
Àmọ́ nínú ọkàn mi, ńṣe ló dà bí iná tó ń jó, tí wọ́n sé mọ́ inú egungun mi,Mi ò lè pa á mọ́ra mọ́,Mi ò sì lè fara dà á mọ́.+
10 Nítorí mo ti gbọ́ ọ̀pọ̀ àhesọ ọ̀rọ̀ tó burú;Ohun ẹ̀rù yí mi ká.+
“Ẹ fẹ̀sùn kàn án; ẹ jẹ́ ká fẹ̀sùn kàn án!”
Gbogbo àwọn tó ń sọ pé àwọn fẹ́ àlàáfíà fún mi, ìṣubú mi ni wọ́n ń wá:+
“Bóyá ó máa ṣàṣìṣe torí pé kò kíyè sára,Tí a ó sì lè borí rẹ̀, kí a sì gbẹ̀san lára rẹ̀.”
11 Ṣùgbọ́n Jèhófà wà pẹ̀lú mi bíi jagunjagun tó ń bani lẹ́rù.+
Ìdí nìyẹn tí àwọn tó ń ṣe inúnibíni sí mi á fi fẹsẹ̀ kọ, wọn ò sì ní borí.+
Ojú á tì wọ́n wẹ̀lẹ̀mù, torí pé wọn ò ní ṣàṣeyọrí.
Wọ́n á tẹ́ títí láé, ẹ̀tẹ́ wọn ò sì ní ṣeé gbàgbé.+
12 Ṣùgbọ́n ìwọ, Jèhófà Ọlọ́run àwọn ọmọ ogun, ń ṣàyẹ̀wò àwọn olódodo;Ò ń rí èrò inú* àti ọkàn.+
Jẹ́ kí n rí ẹ̀san rẹ lára wọn,+Nítorí ọwọ́ rẹ ni mo fi ẹjọ́ mi lé.+
13 Ẹ kọrin sí Jèhófà! Ẹ yin Jèhófà!
Nítorí ó ti gba àwọn aláìní* sílẹ̀ lọ́wọ́ àwọn aṣebi.
14 Ègún ni fún ọjọ́ tí wọ́n bí mi!
Kí ọjọ́ tí ìyá mi bí mi má gba ìbùkún! +
15 Ègún ni fún ọkùnrin tó mú ìròyìn ayọ̀ wá fún bàbá mi pé:
“Ìyàwó rẹ ti bímọ, ọkùnrin ló bí!”
Tó mú inú rẹ̀ dùn gidigidi.
16 Kí ọkùnrin yẹn dà bí àwọn ìlú tí Jèhófà wó lulẹ̀ láìkẹ́dùn.
Kí ó gbọ́ igbe ẹkún ní òwúrọ̀ àti ìró ogun ní ọ̀sán gangan.
17 Kí nìdí tí ò kúkú fi pa mí nígbà tí mo wà nínú ikùn,Kí inú ìyá mi lè di ibi ìsìnkú miKí oyún wà nínú ikùn rẹ̀ nígbà gbogbo?+
18 Kí nìdí tí mo fi jáde kúrò nínú ikùnLáti rí ìdààmú àti ẹ̀dùn ọkàn,Láti mú kí àwọn ọjọ́ mi dópin nínú ìtìjú?+