Jeremáyà 11:1-23

  • Júdà da májẹ̀mú Ọlọ́run (1-17)

    • Àwọn ọlọ́run pọ̀ bí ìlú ṣe pọ̀ (13)

  • Jeremáyà dà bí ọ̀dọ́ àgùntàn tí wọ́n fẹ́ lọ pa (18-20)

  • Àtakò tí àwọn ará ìlú Jeremáyà ṣe (21-23)

11  Ọ̀rọ̀ tí Jèhófà sọ fún Jeremáyà nìyí, ó ní:  “Ẹ gbọ́ ọ̀rọ̀ májẹ̀mú yìí! “Sọ* ọ́ fún àwọn èèyàn Júdà àti fún àwọn tó ń gbé ní Jerúsálẹ́mù,  kí o sì sọ fún wọn pé, ‘Ohun tí Jèhófà Ọlọ́run Ísírẹ́lì sọ nìyí: “Ègún ni fún ẹni tí kò bá pa ọ̀rọ̀ májẹ̀mú yìí mọ́,+  tí mo pa láṣẹ fún àwọn baba ńlá yín ní ọjọ́ tí mo mú wọn jáde kúrò ní ilẹ̀ Íjíbítì,+ kúrò nínú iná ìléru tí wọ́n fi ń yọ́ irin,+ pé, ‘Ẹ ṣègbọràn sí ohùn mi, ẹ sì ṣe gbogbo ohun tí mo bá pa láṣẹ fún yín, ẹ ó sì di èèyàn mi, màá sì di Ọlọ́run yín,+  kí n lè mú ẹ̀jẹ́ tí mo jẹ́ fún àwọn baba ńlá yín ṣẹ, pé màá fún wọn ní ilẹ̀ tí wàrà àti oyin ti ń ṣàn,+ bó ṣe rí lónìí.’”’” Mo sì dáhùn pé: “Àmín,* Jèhófà.”  Jèhófà sì sọ fún mi pé: “Kéde gbogbo ọ̀rọ̀ yìí ní àwọn ìlú Júdà àti ní àwọn ojú ọ̀nà Jerúsálẹ́mù pé: ‘Ẹ gbọ́ ọ̀rọ̀ májẹ̀mú yìí, kí ẹ sì pa wọ́n mọ́.  Nítorí mo kìlọ̀ fún àwọn baba ńlá yín gidigidi ní ọjọ́ tí mò ń mú wọn jáde kúrò ní ilẹ̀ Íjíbítì títí di òní, léraléra ni mo sì ń kìlọ̀* fún wọn pé: “Ẹ ṣègbọràn sí ohùn mi.”+  Ṣùgbọ́n wọn ò tẹ́tí sí mi, bẹ́ẹ̀ ni wọn ò fetí sílẹ̀. Kàkà bẹ́ẹ̀, kálukú wọn ya alágídí, wọ́n sì ń ṣe ohun tí ọkàn búburú wọn sọ.+ Torí náà, mo mú gbogbo ọ̀rọ̀ májẹ̀mú yìí wá sórí wọn, èyí tí mo pa láṣẹ fún wọn, ṣùgbọ́n wọn ò pa wọ́n mọ́.’”  Jèhófà sì sọ fún mi pé: “Àwọn èèyàn Júdà àti àwọn tó ń gbé ní Jerúsálẹ́mù ń dìtẹ̀. 10  Wọ́n ti pa dà sínú ẹ̀ṣẹ̀ àwọn baba ńlá wọn àtijọ́ tí wọ́n kọ̀ láti ṣègbọràn sí ọ̀rọ̀ mi.+ Àwọn náà tẹ̀ lé àwọn ọlọ́run míì, wọ́n sì sìn wọ́n.+ Ilé Ísírẹ́lì àti ilé Júdà ti da májẹ̀mú mi tí mo bá àwọn baba ńlá wọn dá.+ 11  Torí náà, ohun tí Jèhófà sọ nìyí, ‘Wò ó, màá mú àjálù+ tí wọn kò ní lè bọ́ nínú rẹ̀ wá bá wọn. Nígbà tí wọ́n bá ké pè mí fún ìrànlọ́wọ́, mi ò ní fetí sí wọn.+ 12  Ìgbà náà ni àwọn ìlú Júdà àti àwọn tó ń gbé ní Jerúsálẹ́mù yóò wá ìrànlọ́wọ́ lọ sọ́dọ̀ àwọn ọlọ́run tí wọ́n ń rú ẹbọ* sí,+ ṣùgbọ́n wọn ò ní lè gbà wọ́n lọ́nàkọnà ní àkókò àjálù wọn. 13  Torí pé bí ìlú rẹ ṣe pọ̀ tó ni àwọn ọlọ́run rẹ ṣe pọ̀ tó, ìwọ Júdà, o sì ti ṣe pẹpẹ tó pọ̀ bí àwọn ojú ọ̀nà Jerúsálẹ́mù ṣe pọ̀ fún ohun ìtìjú* láti máa fi rú ẹbọ sí Báálì.’+ 14  “Ní tìrẹ,* má ṣe gbàdúrà nítorí àwọn èèyàn yìí. Má sì sunkún nítorí wọn tàbí kí o gbàdúrà fún wọn,+ torí mi ò ní fetí sílẹ̀ tí wọ́n bá ń ké pè mí nígbà àjálù wọn. 15  Ẹ̀tọ́ wo ni olólùfẹ́ mi ní láti wà nínú ilé miNígbà tó jẹ́ pé ọ̀pọ̀ nínú wọn ń ṣe ibi tó wà lọ́kàn wọn? Ṣé ẹran mímọ́* tí wọ́n fi ń rúbọ lè mú àjálù kúrò nígbà tó bá dé bá ọ? Ǹjẹ́ inú rẹ máa dùn nígbà náà? 16  Nígbà kan Jèhófà pè ọ́ ní igi ólífì tó gbẹ̀rẹ̀gẹ̀jigẹ̀,Tó rẹwà tó sì ní èso tó dáa. Ó ti sọ iná sí i pẹ̀lú ariwo ńlá,Wọ́n sì ti ṣẹ́ àwọn ẹ̀ka rẹ̀. 17  “Jèhófà Ọlọ́run àwọn ọmọ ogun, Ẹni tó gbìn ọ́,+ ti kéde pé àjálù yóò bá ọ nítorí ìwà ibi tí ilé Ísírẹ́lì àti ilé Júdà hù, tí wọ́n ń mú mi bínú bí wọ́n ṣe ń rú ẹbọ sí Báálì.”+ 18  Jèhófà sọ fún mi kí n lè mọ̀;Ní àkókò yẹn, o jẹ́ kí n rí ohun tí wọ́n ń ṣe. 19  Mo dà bí ọ̀dọ́ àgùntàn tí kò lágbaja tí wọ́n ń mú bọ̀ níbi tí wọ́n ti fẹ́ pa á. Mi ò mọ̀ pé wọ́n ń gbèrò ohun búburú sí mi pé:+ “Ẹ jẹ́ ká pa igi náà àti èso rẹ̀ run,Ká sì gé e kúrò ní ilẹ̀ alààyè,Kí a má bàa rántí orúkọ rẹ̀ mọ́.” 20  Ṣùgbọ́n Jèhófà Ọlọ́run àwọn ọmọ ogun ń fi òdodo ṣe ìdájọ́;Ó ń ṣàyẹ̀wò èrò inú* àti ọkàn.+ Jẹ́ kí n rí ẹ̀san rẹ lára wọn,Nítorí ọwọ́ rẹ ni mo fi ẹjọ́ mi lé. 21  Nítorí náà, èyí ni ohun tí Jèhófà sọ sí àwọn èèyàn Ánátótì+ tí wọ́n fẹ́ gba ẹ̀mí rẹ,* tí wọ́n sì sọ pé: “O ò gbọ́dọ̀ sọ tẹ́lẹ̀ ní orúkọ Jèhófà,+ àìjẹ́ bẹ́ẹ̀ a ó fi ọwọ́ ara wa pa ọ́.” 22  Ohun tí Jèhófà Ọlọ́run àwọn ọmọ ogun sọ nìyí: “Wò ó, màá pè wọ́n wá jíhìn. Idà ni yóò pa àwọn ọ̀dọ́kùnrin wọn,+ ìyàn sì ni yóò pa àwọn ọmọkùnrin àti àwọn ọmọbìnrin wọn.+ 23  Àní kò ní sí ẹnì kankan tó máa ṣẹ́ kù lára wọn, nítorí màá mú àjálù bá àwọn èèyàn Ánátótì+ ní ọdún tí màá pè wọ́n wá jíhìn.”

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé

Ó jọ pé Jeremáyà ló ń bá sọ̀rọ̀.
Tàbí “Kó rí bẹ́ẹ̀.”
Ní Héb., “mò ń dìde ní kùtùkùtù, mo sì ń kìlọ̀.”
Tàbí “mú ẹbọ rú èéfín.”
Tàbí “ọlọ́run ìtìjú.”
Ìyẹn, Jeremáyà.
Ìyẹn, àwọn ẹbọ tí wọ́n ń rú nínú tẹ́ńpìlì.
Tàbí “inú lọ́hùn-ún.” Ní Héb., “kíndìnrín.”
Tàbí “tí wọ́n ń lépa ọkàn rẹ.”