Jónà 3:1-10

  • Jónà ṣègbọràn sí Ọlọ́run, ó sì lọ sí Nínéfè (1-4)

  • Ọ̀rọ̀ Jónà mú kí àwọn ará Nínéfè ronú pìwà dà (5-9)

  • Ọlọ́run pinnu pé òun ò ní pa Nínéfè run (10)

3  Jèhófà tún bá Jónà sọ̀rọ̀ lẹ́ẹ̀kejì pé:+  “Gbéra, lọ sí Nínéfè  + ìlú ńlá náà, kí o sì lọ jíṣẹ́ tí mo rán ọ.”  Torí náà, Jónà gbéra, ó sì lọ sí Nínéfè,+ bí Jèhófà ṣe sọ fún un.+ Ìlú Nínéfè tóbi gan-an,* ọjọ́ mẹ́ta ló máa ń gbà láti rìn yí i ká.  Jónà bá wọnú ìlú náà, ó rin ìrìn ọjọ́ kan, ó sì ń kéde pé: “Ogójì [40] ọjọ́ péré ló kù kí Nínéfè pa run.”  Àwọn ará ìlú Nínéfè wá gba Ọlọ́run gbọ́,+ wọ́n kéde pé kí gbogbo ìlú gbààwẹ̀, wọ́n sì wọ aṣọ ọ̀fọ̀,* látorí ẹni tó tóbi jù dórí ẹni tó kéré jù.  Nígbà tí ọba Nínéfè gbọ́ ọ̀rọ̀ náà, ó dìde lórí ìtẹ́ rẹ̀, ó bọ́ aṣọ oyè rẹ̀, ó sì wọ aṣọ ọ̀fọ̀, ó sì jókòó sínú eérú.  Yàtọ̀ síyẹn, ó ní kí wọ́n kéde ní gbogbo ìlú Nínéfè pé: “Ọba àti àwọn ìjòyè rẹ̀ ti pàṣẹ pé: Èèyàn tàbí ẹran èyíkéyìí, títí kan agbo ẹran àti ọ̀wọ́ ẹran, kò gbọ́dọ̀ fi ẹnu kan ohunkóhun. Wọn ò gbọ́dọ̀ jẹun, wọn ò sì gbọ́dọ̀ mu omi.  Kí wọ́n wọ aṣọ ọ̀fọ̀, èèyàn àti ẹran; kí wọ́n ké pe Ọlọ́run tọkàntọkàn, kí wọ́n yí ìwà burúkú wọn pa dà, kí wọ́n sì jáwọ́ nínú ìwà ipá.  Ta ló mọ̀ bóyá Ọlọ́run tòótọ́ máa pèrò dà* nípa ohun tó ní lọ́kàn, kó sì yí ìbínú rẹ̀ pa dà, ká má bàa ṣègbé?” 10  Nígbà tí Ọlọ́run tòótọ́ rí ohun tí wọ́n ṣe, bí wọ́n ṣe yí ìwà burúkú wọn pa dà,+ ó pèrò dà* nípa àjálù tó sọ pé òun máa mú kó dé bá wọn, kò sì jẹ́ kó ṣẹlẹ̀ sí wọn.+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé

Ní Héb., “tóbi lójú Ọlọ́run.”
Ní Héb., “aṣọ àpò ìdọ̀họ.”
Tàbí “yí ìpinnu pa dà.”
Tàbí “yí ìpinnu pa dà.”