Jónà 1:1-17

  • Jónà fẹ́ sá fún Jèhófà (1-3)

  • Jèhófà mú kí ìjì kan tó lágbára jà (4-6)

  • Jónà ló fa wàhálà tó dé bá wọn (7-13)

  • Wọ́n ju Jónà sínú òkun tó ń ru gùdù (14-16)

  • Ẹja ńlá kan gbé Jónà mì (17)

1  Jèhófà bá Jónà*+ ọmọ Ámítáì sọ̀rọ̀, ó ní:  “Gbéra, lọ sí Nínéfè+ ìlú ńlá náà, kí o sì kéde ìdájọ́ mi fún wọn, torí mo ti rí gbogbo ìwà burúkú wọn.”  Àmọ́ Jónà fẹ́ lọ sí Táṣíṣì, kó lè sá fún Jèhófà. Torí náà, ó gbéra, ó lọ sí Jópà, ó sì rí ọkọ̀ òkun kan tó ń lọ sí Táṣíṣì. Ó san owó ọkọ̀, ó sì wọlé láti bá wọn lọ sí Táṣíṣì, kó lè sá fún Jèhófà.  Lẹ́yìn náà, Jèhófà mú kí ìjì kan tó lágbára jà lórí òkun, ìjì náà sì le débi pé ọkọ̀ náà fẹ́rẹ̀ẹ́ ya.  Ẹ̀rù ba àwọn atukọ̀ òkun náà gan-an, kálukú wọn sì bẹ̀rẹ̀ sí í ké pe ọlọ́run rẹ̀ pé kó ran òun lọ́wọ́. Ni wọ́n bá ń ju àwọn nǹkan tó wà nínú ọkọ̀ náà sínú òkun, kó lè fúyẹ́.+ Àmọ́ Jónà ti lọ dùbúlẹ̀ sí ìsàlẹ̀ ọkọ̀* náà, ó sì ti sùn lọ fọnfọn.  Lẹ́yìn náà, ọ̀gá àwọn atukọ̀ lọ bá a, ó sì sọ fún un pé: “Kí ló dé tí ò ń sùn? Dìde, ké pe ọlọ́run rẹ! Bóyá Ọlọ́run tòótọ́ á tiẹ̀ ṣàánú wa, ká má bàa ṣègbé.”+  Wọ́n wá sọ fún ara wọn pé: “Ẹ wá, ẹ jẹ́ ká ṣẹ́ kèké,+ ká lè mọ ẹni tó fa àjálù yìí.” Ni wọ́n bá ṣẹ́ kèké, kèké sì mú Jónà.+  Torí náà, wọ́n bi í pé: “Jọ̀ọ́ sọ fún wa, ta ló fa àjálù yìí? Iṣẹ́ wo lò ń ṣe, ibo lo ti wá? Ọmọ orílẹ̀-èdè wo ni ọ́, ẹ̀yà wo lo sì ti wá?”  Jónà fèsì pé: “Hébérù ni mí. Jèhófà Ọlọ́run ọ̀run, Ẹni tó dá òkun àti ilẹ̀ gbígbẹ ni mò ń sìn.”* 10  Èyí dẹ́rù ba àwọn ọkùnrin náà gan-an, wọ́n sì bí i pé: “Kí lo ṣe?” (Àwọn ọkùnrin náà ti mọ̀ pé ó ń sá fún Jèhófà, torí ó ti sọ fún wọn.) 11  Wọ́n wá bi í pé: “Kí ni ká ṣe sí ọ, kí òkun bàa lè pa rọ́rọ́ fún wa?” Torí ìjì náà túbọ̀ ń le sí i. 12  Ó fèsì pé: “Ẹ gbé mi, kí ẹ sì jù mí sínú òkun, òkun yóò sì pa rọ́rọ́ fún yín; torí mo mọ̀ pé èmi ni mo fa ìjì líle tó dé bá yín.” 13  Àmọ́ àwọn ọkùnrin náà fi gbogbo okun wọn tukọ̀ náà* kí wọ́n lè ṣẹ́rí rẹ̀ pa dà sí etíkun, ṣùgbọ́n wọn ò rí i ṣe, torí ìjì náà ń le sí i níbi tí wọ́n wà. 14  Ni wọ́n bá ké pe Jèhófà, wọ́n sì sọ pé: “Jèhófà, jọ̀ọ́, má ṣe jẹ́ ká ṣègbé nítorí ọkùnrin yìí!* Jèhófà, jọ̀ọ́ má ka ẹ̀jẹ̀ aláìṣẹ̀ sí wa lọ́rùn, torí o ti ṣe ohun tí o fẹ́.” 15  Lẹ́yìn náà, wọ́n gbé Jónà, wọ́n sì jù ú sínú òkun; bí òkun náà ṣe pa rọ́rọ́ nìyẹn. 16  Èyí mú kí àwọn ọkùnrin náà bẹ̀rù Jèhófà gan-an,+ torí náà, wọ́n rúbọ sí Jèhófà, wọ́n sì jẹ́ ẹ̀jẹ́. 17  Jèhófà wá mú kí ẹja ńlá kan gbé Jónà mì, ọjọ́ mẹ́ta* sì ni Jónà fi wà nínú ikùn ẹja náà.+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé

Ó túmọ̀ sí “Àdàbà.”
Tàbí “ọkọ̀ òkun alájà òkè.”
Ní Héb., “bẹ̀rù.”
Tàbí “wá bí wọ́n ṣe máa kọjá.”
Tàbí “nítorí ọkàn ọkùnrin yìí!”
Ní Héb., “ọ̀sán mẹ́ta àti òru mẹ́ta.”