Jóṣúà 5:1-15

  • Wọ́n dádọ̀dọ́ ní Gílígálì (1-9)

  • Wọ́n ṣe Ìrékọjá; mánà ò rọ̀ mọ́ (10-12)

  • Olórí àwọn ọmọ ogun Jèhófà (13-15)

5  Gbàrà tí gbogbo ọba àwọn Ámórì,+ tí wọ́n wà lápá ìwọ̀ oòrùn* Jọ́dánì àti gbogbo ọba àwọn ọmọ Kénáánì,+ tí wọ́n wà létí òkun gbọ́ pé Jèhófà ti mú kí omi Jọ́dánì gbẹ níwájú àwọn ọmọ Ísírẹ́lì títí wọ́n fi sọdá, ọkàn wọn domi,*+ kò sì sí ẹni tó ní ìgboyà mọ́* torí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì.+  Ìgbà yẹn ni Jèhófà sọ fún Jóṣúà pé: “Fi akọ òkúta ṣe àwọn ọ̀bẹ fún ara rẹ, kí o sì tún dádọ̀dọ́*+ àwọn ọkùnrin Ísírẹ́lì lẹ́ẹ̀kejì.”  Jóṣúà wá fi akọ òkúta ṣe àwọn ọ̀bẹ, ó sì dádọ̀dọ́ àwọn ọkùnrin Ísírẹ́lì ní Gibeati-háárálótì.*+  Ìdí tí Jóṣúà fi dádọ̀dọ́ wọn ni pé: Gbogbo ọkùnrin tó wà nínú àwọn èèyàn náà, tí wọ́n kúrò ní Íjíbítì, gbogbo ọkùnrin ogun,* ti kú sínú aginjù lẹ́nu ìrìn àjò wọn lẹ́yìn tí wọ́n kúrò ní Íjíbítì.+  Gbogbo àwọn tó kúrò ní Íjíbítì ló dádọ̀dọ́, ṣùgbọ́n gbogbo àwọn tí wọ́n bí ní aginjù lẹ́nu ìrìn àjò wọn lẹ́yìn tí wọ́n kúrò ní Íjíbítì kò tíì dádọ̀dọ́.  Àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ti fi ogójì (40) ọdún+ rìn ní aginjù, títí gbogbo orílẹ̀-èdè náà fi kú, ìyẹn àwọn ọkùnrin ogun tó kúrò ní Íjíbítì, tí wọn ò fetí sí ohùn Jèhófà.+ Jèhófà búra fún wọn pé òun kò ní jẹ́ kí wọ́n rí ilẹ̀+ tí Jèhófà búra fún àwọn baba ńlá wọn pé òun máa fún wa,+ ilẹ̀ tí wàrà àti oyin ti ń ṣàn.+  Ó fi àwọn ọmọ wọn rọ́pò wọn.+ Àwọn yìí ni Jóṣúà dádọ̀dọ́ wọn; aláìdádọ̀dọ́ ni wọ́n torí pé wọn ò tíì dádọ̀dọ́ lẹ́nu ìrìn àjò wọn.  Nígbà tí wọ́n dádọ̀dọ́ gbogbo orílẹ̀-èdè náà tán, wọ́n dúró síbi tí wọ́n pàgọ́ sí títí ara wọn fi jinná.  Jèhófà wá sọ fún Jóṣúà pé: “Mo yí ẹ̀gàn Íjíbítì kúrò lórí yín lónìí.” Wọ́n wá ń pe ibẹ̀ ní Gílígálì*+ títí di òní yìí. 10  Àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ṣì dúró sí Gílígálì tí wọ́n pàgọ́ sí, wọ́n ṣe Ìrékọjá ní ìrọ̀lẹ́ ọjọ́ kẹrìnlá oṣù,+ ní aṣálẹ̀ tó tẹ́jú ní Jẹ́ríkò. 11  Wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí í jẹ èso ilẹ̀ náà ní ọjọ́ tó tẹ̀ lé Ìrékọjá, wọ́n jẹ búrẹ́dì aláìwú+ àti àyangbẹ ọkà lọ́jọ́ yẹn kan náà. 12  Mánà ò rọ̀ fún wọn ní ọjọ́ tó tẹ̀ lé ọjọ́ tí wọ́n jẹ lára èso ilẹ̀ náà; àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ò rí mánà kó mọ́,+ wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí í jẹ èso ilẹ̀ Kénáánì ní ọdún yẹn.+ 13  Nígbà tí Jóṣúà wà nítòsí Jẹ́ríkò, ó gbójú sókè, ó sì rí ọkùnrin kan+ tó dúró níwájú rẹ̀, tó fa idà yọ.+ Jóṣúà lọ bá a, ó sì bi í pé: “Ṣé tiwa lò ń ṣe ni, àbí tàwọn ọ̀tá wa?” 14  Ó fèsì pé: “Rárá o, mo wá gẹ́gẹ́ bí olórí* àwọn ọmọ ogun Jèhófà.”+ Ni Jóṣúà bá dojú bolẹ̀, ó sì wólẹ̀, ó sọ fún un pé: “Kí ni olúwa mi fẹ́ sọ fún ìránṣẹ́ rẹ̀?” 15  Olórí àwọn ọmọ ogun Jèhófà wá sọ fún Jóṣúà pé: “Bọ́ bàtà ẹsẹ̀ rẹ, torí ilẹ̀ mímọ́ ni ibi tí o dúró sí.” Jóṣúà sì ṣe bẹ́ẹ̀ lójú ẹsẹ̀.+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé

Ní Héb., “lápá ibi tí òkun wà ní.”
Tàbí “ìpayà bá wọn.”
Ní Héb., “kò sì sí ẹ̀mí kankan mọ́ nínú wọn.”
Tàbí “kọlà fún.”
Ó túmọ̀ sí “Òkè Adọ̀dọ́.”
Tàbí “àwọn ọkùnrin tó dàgbà tó láti jagun.”
Ó túmọ̀ sí “Yí; Yí Kúrò.”
Tàbí “balógun.”