Jóṣúà 20:1-9

  • Àwọn ìlú ààbò (1-9)

20  Jèhófà wá sọ fún Jóṣúà pé: 2  “Sọ fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì pé, ‘Ẹ yan àwọn ìlú ààbò fún ara yín,+ èyí tí mo ní kí Mósè sọ fún yín nípa rẹ̀, 3  kí ẹni tí kò bá mọ̀ọ́mọ̀ pààyàn tàbí tó ṣèèṣì pa èèyàn* lè sá lọ síbẹ̀. Àwọn ìlú náà á sì jẹ́ ìlú ààbò fún yín lọ́wọ́ ẹni tó ń gbẹ̀san ẹ̀jẹ̀.+ 4  Kí ẹni náà sá lọ sí ọ̀kan nínú àwọn ìlú yìí,+ kó dúró sí ẹnubodè ìlú náà,+ kó sì ro ẹjọ́ rẹ̀ ní etí àwọn àgbààgbà ìlú náà. Kí wọ́n wá gbà á sínú ìlú náà, kí wọ́n fún un ní ibì kan, kó sì máa bá wọn gbé. 5  Tí ẹni tó ń gbẹ̀san ẹ̀jẹ̀ bá ń lé e, kí wọ́n má fi apààyàn náà lé e lọ́wọ́, torí ṣe ló ṣèèṣì* pa ẹnì kejì rẹ̀, kò sì kórìíra rẹ̀ tẹ́lẹ̀.+ 6  Kó máa gbé ìlú náà, títí dìgbà tí wọ́n máa gbọ́ ẹjọ́ rẹ̀ níwájú àpéjọ,+ kó sì wà níbẹ̀ títí àlùfáà àgbà tí wọ́n yàn sípò nígbà yẹn fi máa kú.+ Lẹ́yìn náà, apààyàn náà lè pa dà sí ìlú tó ti sá kúrò, ó sì lè wọ ìlú rẹ̀ àti ilé rẹ̀.’”+ 7  Torí náà, wọ́n ya Kédéṣì+ ní Gálílì sọ́tọ̀* ní agbègbè olókè Náfútálì, Ṣékémù+ ní agbègbè olókè Éfúrémù àti Kiriati-ábà,+ ìyẹn Hébúrónì, ní agbègbè olókè Júdà. 8  Ní agbègbè Jọ́dánì, lápá ìlà oòrùn Jẹ́ríkò, wọ́n yan Bésérì+ ní aginjù tó wà lórí ilẹ̀ tó tẹ́jú* látinú ilẹ̀ ẹ̀yà Rúbẹ́nì, Rámótì+ ní Gílíádì látinú ilẹ̀ ẹ̀yà Gádì àti Gólánì+ ní Báṣánì látinú ilẹ̀ ẹ̀yà Mánásè.+ 9  Àwọn ìlú yìí ni wọ́n yàn fún gbogbo ọmọ Ísírẹ́lì àtàwọn àjèjì tó ń gbé láàárín wọn, kí ẹnikẹ́ni tó bá ṣèèṣì pa èèyàn* lè sá lọ síbẹ̀,+ kí ẹni tó ń gbẹ̀san ẹ̀jẹ̀ má bàa pa á kí wọ́n tó gbọ́ ẹjọ́ rẹ̀ níwájú àpéjọ náà.+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé

^ Tàbí “pa ọkàn.”
^ Tàbí “kò mọ̀ọ́mọ̀.”
^ Ní Héb., “wọ́n ka Kédéṣì ní Gálílì sí mímọ́.”
^ Tàbí “òkè tí orí rẹ̀ rí pẹrẹsẹ.”
^ Tàbí “pa ọkàn.”