Jóṣúà 11:1-23

  • Wọ́n gba àwọn ìlú tó wà ní àríwá (1-15)

  • Àwọn ilẹ̀ tí Jóṣúà ṣẹ́gun (16-23)

11  Gbàrà tí Jábínì ọba Hásórì gbọ́ nípa rẹ̀, ó ránṣẹ́ sí Jóbábù ọba Mádónì,+ sí ọba Ṣímúrónì, ọba Ákíṣáfù,+  àwọn ọba agbègbè olókè tó wà ní apá àríwá, àwọn tó wà ní pẹ̀tẹ́lẹ̀* apá gúúsù Kínérétì, àwọn tó wà ní Ṣẹ́fẹ́là àti ní gẹ̀rẹ́gẹ̀rẹ́ Dórì+ ní ìwọ̀ oòrùn,  àwọn ọmọ Kénáánì+ lápá ìlà oòrùn àti ìwọ̀ oòrùn, àwọn Ámórì,+ àwọn ọmọ Hétì, àwọn Pérísì, àwọn ará Jébúsì ní agbègbè olókè àti àwọn Hífì+ ní ìsàlẹ̀ Hámónì+ ní ilẹ̀ Mísípà.  Wọ́n kó gbogbo ọmọ ogun wọn jáde, wọ́n pọ̀ bí iyanrìn etí òkun, pẹ̀lú ọ̀pọ̀lọpọ̀ ẹṣin àti kẹ̀kẹ́ ogun.  Gbogbo àwọn ọba yìí ṣe àdéhùn láti pàdé, wọ́n wá, wọ́n sì jọ pàgọ́ síbi omi Mérómù láti bá Ísírẹ́lì jà.  Torí náà, Jèhófà sọ fún Jóṣúà pé: “Má ṣe jẹ́ kí ẹ̀rù wọn bà ọ́,+ torí ní ìwòyí ọ̀la, màá fi gbogbo wọn lé Ísírẹ́lì lọ́wọ́ láti pa wọ́n. Kí o já iṣan ẹsẹ̀*+ àwọn ẹṣin wọn, kí o sì dáná sun àwọn kẹ̀kẹ́ ogun wọn.”  Jóṣúà àti gbogbo ọkùnrin ogun wá gbéjà kò wọ́n lójijì lẹ́gbẹ̀ẹ́ omi Mérómù.  Jèhófà fi wọ́n lé Ísírẹ́lì lọ́wọ́,+ wọ́n ṣẹ́gun wọn, wọ́n lé wọn títí dé Sídónì Ńlá+ àti Misirefoti-máímù+ àti Àfonífojì Mísípè lápá ìlà oòrùn, wọ́n sì pa wọ́n láìku ẹnì kankan.+  Jóṣúà wá ṣe ohun tí Jèhófà sọ fún un sí wọn; ó já iṣan ẹsẹ̀ àwọn ẹṣin wọn, ó sì dáná sun àwọn kẹ̀kẹ́ ogun wọn.+ 10  Lẹ́yìn náà, Jóṣúà pa dà, ó sì gba Hásórì, o fi idà pa ọba rẹ̀,+ torí pé Hásórì ni olórí gbogbo àwọn ìlú yìí tẹ́lẹ̀. 11  Wọ́n fi idà pa gbogbo àwọn* tó ń gbé ibẹ̀ run pátápátá.+ Wọn ò dá ohun eléèémí kankan sí.+ Lẹ́yìn náà, ó dáná sun Hásórì. 12  Jóṣúà gba gbogbo ìlú àwọn ọba yìí, ó sì fi idà ṣẹ́gun gbogbo ọba wọn.+ Ó pa wọ́n run,+ bí Mósè ìránṣẹ́ Jèhófà ṣe pa á láṣẹ. 13  Àmọ́ Ísírẹ́lì ò dáná sun ìkankan nínú àwọn ìlú tó wà lórí òkìtì, àfi Hásórì; òun nìkan ni Jóṣúà dáná sun. 14  Gbogbo ẹrù àwọn ìlú yìí àti ẹran ọ̀sìn wọn ni àwọn ọmọ Ísírẹ́lì kó fún ara wọn.+ Àmọ́ wọ́n fi idà pa gbogbo èèyàn títí wọ́n fi pa gbogbo wọn run.+ Wọn ò dá ẹnikẹ́ni tó ń mí sí.+ 15  Bí Jèhófà ṣe pàṣẹ fún Mósè ìránṣẹ́ rẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni Mósè ṣe pa á láṣẹ fún Jóṣúà,+ Jóṣúà sì ṣe bẹ́ẹ̀ gẹ́lẹ́. Gbogbo ohun tí Jèhófà pa láṣẹ fún Mósè ni Jóṣúà ṣe láìṣẹ́ ìkankan kù.+ 16  Jóṣúà ṣẹ́gun gbogbo ilẹ̀ yìí, agbègbè olókè, gbogbo Négébù,+ gbogbo ilẹ̀ Góṣénì, Ṣẹ́fẹ́là,+ Árábà+ àti agbègbè olókè Ísírẹ́lì àti Ṣẹ́fẹ́là rẹ̀,* 17  láti Òkè Hálákì, tó lọ dé Séírì àti títí lọ dé Baali-gádì,+ ní Àfonífojì Lẹ́bánónì, ní ìsàlẹ̀ Òkè Hámónì,+ ó mú gbogbo ọba wọn, ó ṣẹ́gun wọn, ó sì pa wọ́n. 18  Ó ṣe díẹ̀ tí Jóṣúà fi bá gbogbo àwọn ọba yìí jagun. 19  Kò sí ìlú kankan tó bá àwọn ọmọ Ísírẹ́lì rẹ́ àfi àwọn Hífì tó ń gbé ní Gíbíónì.+ Gbogbo àwọn yòókù ni wọ́n bá jà tí wọ́n sì ṣẹ́gun wọn.+ 20  Jèhófà fàyè gbà á kí ọkàn wọn le,+ tí wọ́n fi bá Ísírẹ́lì jagun, kó lè pa wọ́n run láì ṣojú àánú sí wọn rárá.+ Ìparun tọ́ sí wọn, bí Jèhófà ṣe pa á láṣẹ fún Mósè.+ 21  Ìgbà yẹn ni Jóṣúà pa àwọn Ánákímù+ run kúrò ní agbègbè olókè, ní Hébúrónì, Débírì, Ánábù àti gbogbo agbègbè olókè Júdà àti gbogbo agbègbè olókè Ísírẹ́lì. Jóṣúà pa àwọn àtàwọn ìlú wọn run.+ 22  Ánákímù kankan ò ṣẹ́ kù ní ilẹ̀ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì;+ Gásà,+ Gátì+ àti Áṣídódì+ nìkan ni wọ́n ṣẹ́ kù sí. 23  Jóṣúà wá gba gbogbo ilẹ̀ náà, bí Jèhófà ṣe ṣèlérí fún Mósè,+ Jóṣúà sì fi ṣe ogún fún Ísírẹ́lì, bí ìpín wọn, pé kí wọ́n pín in láàárín àwọn ẹ̀yà wọn.+ Ogun sì dáwọ́ dúró ní ilẹ̀ náà.+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé

Tàbí “Árábà.”
Tàbí “já pátì.”
Tàbí “ọkàn.”
Tàbí “òkè kéékèèké rẹ̀.”