Jóẹ́lì 1:1-20

  • Àwọn kòkòrò ṣọṣẹ́ gan-an (1-14)

  • “Ọjọ́ Jèhófà sún mọ́lé” (15-20)

    • Wòlíì náà ké pe Jèhófà (19, 20)

1  Ọ̀rọ̀ tí Jèhófà bá Jóẹ́lì* ọmọ Pétúélì sọ nìyí:  2  “Ẹ gbọ́ ọ̀rọ̀ yìí, ẹ̀yin àgbààgbà,Kí ẹ sì fetí sílẹ̀, gbogbo ẹ̀yin tó ń gbé ilẹ̀ náà.* Ǹjẹ́ irú nǹkan báyìí ti ṣẹlẹ̀ rí níṣojú yín,Tàbí nígbà ayé àwọn baba ńlá yín?+  3  Ẹ sọ nípa rẹ̀ fún àwọn ọmọ yín,Kí àwọn ọmọ yín náà sọ fún àwọn ọmọ wọn,Kí àwọn ọmọ wọn sì sọ fún ìran tó tẹ̀ lé wọn.  4  Ohun tí eéṣú tó ń jẹ nǹkan run jẹ kù, ni ọ̀wọ́ eéṣú jẹ;+Ohun tí ọ̀wọ́ eéṣú jẹ kù, ni eéṣú tí kò níyẹ̀ẹ́ jẹ;Ohun tí eéṣú tí kò níyẹ̀ẹ́ jẹ kù, ni ọ̀yánnú eéṣú jẹ.+  5  Ẹ jí, ẹ̀yin ọ̀mùtípara,+ kí ẹ sì sunkún! Ẹ pohùn réré ẹkún, gbogbo ẹ̀yin tó ń mu wáìnì,Torí wọ́n ti gba wáìnì dídùn lẹ́nu yín.+  6  Torí orílẹ̀-èdè kan ti gòkè wá sí ilẹ̀ mi, ó lágbára gan-an, kò sì lóǹkà.+ Eyín kìnnìún ni eyín rẹ̀,+ páárì ẹ̀rẹ̀kẹ́ rẹ̀ náà sì jẹ́ ti kìnnìún.  7  Ó ti pa àjàrà mi run, ó sì sọ igi ọ̀pọ̀tọ́ mi di kùkùté,Ó bó èèpo wọn kanlẹ̀, ó sì jù wọ́n dà nù,Ẹ̀ka àwọn igi náà sì di funfun.  8  Pohùn réré ẹkún bíi ti wúńdíá* tó wọ aṣọ ọ̀fọ̀*Torí olólùfẹ́* rẹ̀ tó kú.*  9  Kò sí ọrẹ ọkà+ àti ọrẹ ohun mímu+ ní ilé Jèhófà mọ́;Àwọn àlùfáà, àwọn òjíṣẹ́ Jèhófà, ń ṣọ̀fọ̀. 10  Wọ́n ti pa oko run, ilẹ̀ sì ń ṣọ̀fọ̀;+Wọ́n ti run ọkà, wáìnì tuntun ti gbẹ táútáú, òróró sì ti tán.+ 11  Inú àwọn àgbẹ̀ bà jẹ́, àwọn tó ń rẹ́wọ́ àjàrà pohùn réré ẹkún,Torí àlìkámà* àti ọkà bálì;Ìkórè oko sì ti pa run. 12  Àjàrà ti gbẹ,Igi ọ̀pọ̀tọ́ sì ti kú. Bẹ́ẹ̀ náà ni igi pómégíránétì, igi ọ̀pẹ àti igi ápù,Gbogbo igi oko ti gbẹ dà nù;+Ìdùnnú àwọn èèyàn ti di ìtìjú. 13  Ẹ wọ aṣọ ọ̀fọ̀,* ẹ̀yin àlùfáà, kí ẹ sì ṣọ̀fọ̀;*Ẹ pohùn réré ẹkún, ẹ̀yin tó ń ṣiṣẹ́ níwájú pẹpẹ.+ Ẹ wọlé, kí ẹ sì wọ aṣọ ọ̀fọ̀* mọ́jú, ẹ̀yin ìránṣẹ́ Ọlọ́run mi;Torí àwọn èèyàn ò mú ọrẹ ọkà+ àti ọrẹ ohun mímu+ wá sílé Ọlọ́run yín. 14  Ẹ kéde* ààwẹ̀; ẹ pe àpéjọ ọlọ́wọ̀.+ Ẹ kó àwọn àgbààgbà àti gbogbo àwọn tó ń gbé ilẹ̀ náà jọ,Sí ilé Jèhófà Ọlọ́run yín,+ kí ẹ sì ké pe Jèhófà pé kó ràn yín lọ́wọ́. 15  Ó mà ṣe o! Torí ọjọ́ náà,Ọjọ́ Jèhófà sún mọ́lé,+Ó sì máa jẹ́ ọjọ́ ìparun látọ̀dọ̀ Olódùmarè! 16  Wọ́n ti gbé oúnjẹ kúrò níwájú wa,Kò sì sí ayọ̀ àti ìdùnnú nílé Ọlọ́run wa mọ́. 17  Àwọn èso* ti bà jẹ́ kí wọ́n tó fi ṣọ́bìrì kó o. Àwọn ilé ìkẹ́rùsí ti di ahoro. Wọ́n ti ya àwọn ibi tí wọ́n ń tọ́jú ọkà sí lulẹ̀, torí ọkà ti gbẹ dà nù. 18  Kódà, àwọn ẹran ọ̀sìn ń kérora! Ìdààmú bá àwọn agbo màlúù, wọ́n sì ń rìn gbéregbère torí wọn ò rí ewéko jẹ. Àwọn agbo àgùntàn sì jẹ nínú ìyà náà. 19  Jèhófà, ìwọ ni màá ké pè;+Torí iná ti run àwọn ibi ìjẹko nínú aginjù,Ọwọ́ iná sì ti jẹ gbogbo igi oko run. 20  Kódà, àwọn ẹran inú igbó ń wá ọ,Torí àwọn odò tó ń ṣàn ti gbẹ,Iná sì ti run àwọn ibi ìjẹko nínú aginjù.”

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé

^ Ó túmọ̀ sí “Jèhófà Ni Ọlọ́run.”
^ Tàbí “ayé.”
^ Tàbí “ọmọbìnrin.”
^ Ní Héb., “aṣọ àpò ìdọ̀họ.”
^ Tàbí “ọkọ.”
^ Ní Héb., “ọkọ ìgbà èwe rẹ̀.”
^ Tàbí “wíìtì.”
^ Ní Héb., “Ẹ di ara yín lámùrè.”
^ Tàbí “lu igẹ̀ yín.”
^ Ní Héb., “aṣọ àpò ìdọ̀họ.”
^ Ní Héb., “Ẹ sọ ààwẹ̀ di mímọ́.”
^ Tàbí kó jẹ́, “ọ̀pọ̀tọ́ gbígbẹ.”