Jẹ́nẹ́sísì 48:1-22

  • Jékọ́bù súre fún àwọn ọmọkùnrin Jósẹ́fù méjèèjì (1-12)

  • Ìbùkún Éfúrémù ló pọ̀ jù (13-22)

48  Lẹ́yìn nǹkan wọ̀nyí, wọ́n sọ fún Jósẹ́fù pé: “Wò ó, ara bàbá rẹ ò yá.” Ló bá mú àwọn ọmọ rẹ̀ méjèèjì dání lọ síbẹ̀, ìyẹn Mánásè àti Éfúrémù.+  Wọ́n sì sọ fún Jékọ́bù pé: “Jósẹ́fù ọmọ rẹ ti dé.” Torí náà, Ísírẹ́lì tiraka, ó sì dìde jókòó lórí ibùsùn rẹ̀.  Jékọ́bù wá sọ fún Jósẹ́fù pé: “Ọlọ́run Olódùmarè fara hàn mí ní Lúsì nílẹ̀ Kénáánì, ó sì súre fún mi.+  Ó sọ fún mi pé, ‘Màá mú kí o bímọ, màá sì mú kí o di púpọ̀, màá sọ ọ́ di àwùjọ àwọn èèyàn,+ màá sì fún àtọmọdọ́mọ* rẹ ní ilẹ̀ yìí kó lè di ohun ìní wọn títí láé.’+  Tèmi+ ni àwọn ọmọ rẹ méjèèjì tí o bí ní ilẹ̀ Íjíbítì kí n tó wá sọ́dọ̀ rẹ ní Íjíbítì. Éfúrémù àti Mánásè yóò di tèmi bí Rúbẹ́nì àti Síméónì ṣe jẹ́ tèmi.+  Àmọ́ àwọn ọmọ tí o bá bí lẹ́yìn wọn yóò jẹ́ tìrẹ. Orúkọ àwọn ẹ̀gbọ́n wọn ni wọ́n á máa fi pe ogún wọn.+  Ní tèmi, nígbà tí mò ń bọ̀ láti Pádánì, Réṣẹ́lì kú+ lẹ́gbẹ̀ẹ́ mi nílẹ̀ Kénáánì, nígbà tí ọ̀nà ṣì jìn sí Éfúrátì.+ Mo sì sin ín níbẹ̀ lójú ọ̀nà Éfúrátì, ìyẹn Bẹ́tílẹ́hẹ́mù.”+  Lẹ́yìn náà, Ísírẹ́lì rí àwọn ọmọ Jósẹ́fù, ó sì bi í pé: “Àwọn wo nìyí?”  Jósẹ́fù dá a lóhùn pé: “Àwọn ọmọ tí Ọlọ́run fún mi níbí+ ni.” Ni Ísírẹ́lì bá sọ pé: “Jọ̀ọ́ mú wọn wá sọ́dọ̀ mi, kí n lè súre fún wọn.”+ 10  Ojú Ísírẹ́lì ti di bàìbàì torí ó ti darúgbó, kò sì ríran dáadáa. Jósẹ́fù mú wọn sún mọ́ ọ̀dọ̀ Ísírẹ́lì. Ísírẹ́lì fi ẹnu kò wọ́n lẹ́nu, ó sì gbá wọn mọ́ra. 11  Ísírẹ́lì sọ fún Jósẹ́fù pé: “Mi ò rò pé mo lè rí ọ mọ́,+ àmọ́ Ọlọ́run ti jẹ́ kí n tún rí ọmọ* rẹ.” 12  Jósẹ́fù wá gbé wọn kúrò ní orúnkún Ísírẹ́lì, ó tẹrí ba, ó sì wólẹ̀. 13  Jósẹ́fù wá mú àwọn méjèèjì, ó mú Éfúrémù+ sí ọwọ́ ọ̀tún rẹ̀ tó jẹ́ apá òsì Ísírẹ́lì, ó sì mú Mánásè+ sí ọwọ́ òsì rẹ̀ tó jẹ́ apá ọ̀tún Ísírẹ́lì, ó mú wọn sún mọ́ ọ̀dọ̀ Ísírẹ́lì. 14  Àmọ́ Ísírẹ́lì gbé ọwọ́ ọ̀tún rẹ̀ lé orí Éfúrémù bó tiẹ̀ jẹ́ pé òun ni àbúrò, ó sì gbé ọwọ́ òsì rẹ̀ lé orí Mánásè. Ó mọ̀ọ́mọ̀ ṣe bẹ́ẹ̀ ni, torí Mánásè ni àkọ́bí.+ 15  Ó wá súre fún Jósẹ́fù, ó sì sọ pé:+ “Ọlọ́run tòótọ́, tí àwọn bàbá mi Ábúráhámù àti Ísákì bá rìn,+Ọlọ́run tòótọ́ tó ń bójú tó mi ní gbogbo ọjọ́ ayé mi títí dòní,+ 16  Áńgẹ́lì tó ń gbà mí lọ́wọ́ gbogbo àjálù,+ jọ̀ọ́ bù kún àwọn ọmọ+ yìí. Jẹ́ kí wọ́n máa fi orúkọ mi pè wọ́n àti orúkọ àwọn bàbá mi, Ábúráhámù àti Ísákì,Jẹ́ kí wọ́n pọ̀ rẹpẹtẹ ní ayé.”+ 17  Nígbà tí Jósẹ́fù rí i pé bàbá òun ò gbé ọwọ́ ọ̀tún rẹ̀ kúrò lórí Éfúrémù, kò dùn mọ́ ọn nínú, ó sì gbìyànjú láti mú ọwọ́ bàbá rẹ̀ kúrò lórí Éfúrémù, kó sì gbé e sórí Mánásè. 18  Jósẹ́fù sọ fún bàbá rẹ̀ pé: “Bẹ́ẹ̀ kọ́ bàbá mi, àkọ́bí+ nìyí. Gbé ọwọ́ ọ̀tún rẹ lé e lórí.” 19  Àmọ́ bàbá rẹ̀ ò gbà, ó sì sọ pé: “Mo mọ̀, ọmọ mi, mo mọ̀. Òun náà á di èèyàn púpọ̀, yóò sì di ẹni ńlá. Àmọ́, àbúrò rẹ̀ máa jù ú lọ,+ àwọn ọmọ* rẹ̀ yóò sì pọ̀ bí àwọn orílẹ̀-èdè.”+ 20  Ó sì súre fún wọn ní ọjọ́+ yẹn, ó ní: “Kí Ísírẹ́lì máa fi orúkọ rẹ súre pé,‘Kí Ọlọ́run mú kí o dà bí Éfúrémù àti Mánásè.’” Ó wá ń fi Éfúrémù ṣáájú Mánásè. 21  Lẹ́yìn náà, Ísírẹ́lì sọ fún Jósẹ́fù pé: “Wò ó, mi ò ní pẹ́ kú,+ àmọ́ ó dájú pé Ọlọ́run ò ní fi yín sílẹ̀, yóò sì mú yín pa dà sí ilẹ̀ àwọn baba ńlá+ yín. 22  Ní tèmi, ilẹ̀* tí mo fún ọ fi ọ̀kan ju ti àwọn arákùnrin rẹ lọ, èyí tí mo fi idà àti ọrun mi gbà lọ́wọ́ àwọn Ámórì.”

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé

Ní Héb., “èso.”
Ní Héb., “èso.”
Ní Héb., “èso.”
Tàbí “gẹ̀rẹ́gẹ̀rẹ́ ilẹ̀.” Ní Héb., “èjìká ilẹ̀.”