Jẹ́nẹ́sísì 46:1-34
46 Ísírẹ́lì bá kó gbogbo ohun tó ní,* ó sì gbéra. Nígbà tó dé Bíá-ṣébà,+ ó rúbọ sí Ọlọ́run Ísákì+ bàbá rẹ̀.
2 Lẹ́yìn náà, Ọlọ́run bá Ísírẹ́lì sọ̀rọ̀ lójú ìran ní òru, ó ní: “Jékọ́bù, Jékọ́bù!” Ó dáhùn pé: “Èmi nìyí!”
3 Ó sọ pé: “Èmi ni Ọlọ́run tòótọ́, Ọlọ́run bàbá+ rẹ. Má bẹ̀rù láti lọ sí Íjíbítì, torí ibẹ̀ ni màá ti sọ ọ́ di orílẹ̀-èdè ńlá.+
4 Èmi fúnra mi yóò bá ọ lọ sí Íjíbítì, èmi fúnra mi yóò sì mú ọ pa dà wá láti ibẹ̀,+ Jósẹ́fù yóò sì gbé ọwọ́ rẹ̀ lé ojú rẹ.”*+
5 Lẹ́yìn náà, Jékọ́bù kúrò ní Bíá-ṣébà, àwọn ọmọkùnrin Ísírẹ́lì sì fi kẹ̀kẹ́ tí Fáráò fi ránṣẹ́ gbé Jékọ́bù bàbá wọn àti àwọn ọmọ wọn àti àwọn ìyàwó wọn.
6 Wọ́n kó agbo ẹran wọn àti ẹrù wọn dání, èyí tí wọ́n ti ní nílẹ̀ Kénáánì. Jékọ́bù àti gbogbo àwọn ọmọ rẹ̀ wá dé sí ilẹ̀ Íjíbítì.
7 Ó kó àwọn ọmọkùnrin rẹ̀ àti àwọn ọmọ ọmọ rẹ̀ lọ́kùnrin dání wá sí Íjíbítì, pẹ̀lú àwọn ọmọbìnrin rẹ̀ àti àwọn ọmọ ọmọ rẹ̀ lóbìnrin. Gbogbo ọmọ rẹ̀ ló kó wá.
8 Orúkọ àwọn ọmọkùnrin Ísírẹ́lì tó wá sí Íjíbítì + nìyí, Jékọ́bù àti àwọn ọmọ rẹ̀: Rúbẹ́nì+ ni àkọ́bí Jékọ́bù.
9 Àwọn ọmọ Rúbẹ́nì ni Hánókù, Pálù, Hésírónì àti Kámì.+
10 Àwọn ọmọ Síméónì+ ni Jémúélì, Jámínì, Óhádì, Jákínì, Sóhárì àti Ṣéọ́lù+ ọmọ obìnrin ará Kénáánì.
11 Àwọn ọmọ Léfì+ ni Gẹ́ṣónì, Kóhátì àti Mérárì.+
12 Àwọn ọmọ Júdà+ ni Éérì, Ónánì, Ṣélà,+ Pérésì+ àti Síírà.+ Àmọ́ Éérì àti Ónánì kú ní ilẹ̀ Kénáánì.+
Àwọn ọmọ Pérésì ni Hésírónì àti Hámúlù.+
13 Àwọn ọmọ Ísákà ni Tólà, Púfà, Íóbù àti Ṣímúrónì.+
14 Àwọn ọmọ Sébúlúnì+ ni Sérédì, Élónì àti Jálíẹ́lì.+
15 Àwọn ni ọmọkùnrin tí Líà bí fún Jékọ́bù ní Padani-árámù, pẹ̀lú Dínà+ ọmọbìnrin rẹ̀. Gbogbo àwọn ọmọkùnrin àti ọmọbìnrin rẹ̀* jẹ́ mẹ́tàlélọ́gbọ̀n (33).
16 Àwọn ọmọ Gádì+ ni Sífíónì, Hágì, Ṣúnì, Ésíbónì, Érì, Áródì àti Árélì.+
17 Àwọn ọmọkùnrin Áṣérì+ ni Ímúnà, Íṣífà, Íṣífì àti Bẹráyà, pẹ̀lú Sírà arábìnrin wọn.
Àwọn ọmọ Bẹráyà ni Hébà àti Málíkíélì.+
18 Àwọn ni ọmọ Sílípà,+ tí Lábánì fún Líà ọmọ rẹ̀. Ó bí wọn fún Jékọ́bù: gbogbo wọn jẹ́ mẹ́rìndínlógún (16).*
19 Àwọn ọmọ Réṣẹ́lì ìyàwó Jékọ́bù ni Jósẹ́fù+ àti Bẹ́ńjámínì.+
20 Ásénátì+ ọmọ Pọ́tíférà àlùfáà Ónì* bí Mánásè+ àti Éfúrémù+ fún Jósẹ́fù ní ilẹ̀ Íjíbítì.
21 Àwọn ọmọ Bẹ́ńjámínì+ ni Bélà, Békérì, Áṣíbélì, Gérà,+ Náámánì, Éhì, Róṣì, Múpímù, Húpímù+ àti Áádì.+
22 Àwọn ni ọmọ tí Réṣẹ́lì bí fún Jékọ́bù: gbogbo wọn jẹ́ mẹ́rìnlá (14).*
23 Ọmọ* Dánì+ ni Húṣímù.+
24 Àwọn ọmọ Náfútálì+ ni Jáséélì, Gúnì, Jésérì àti Ṣílẹ́mù.+
25 Àwọn ni ọmọ Bílíhà, tí Lábánì fún Réṣẹ́lì ọmọ rẹ̀. Ó bí wọn fún Jékọ́bù: gbogbo wọn jẹ́ méje.*
26 Gbogbo ọmọ Jékọ́bù* tó bá a lọ sí Íjíbítì, yàtọ̀ sí ìyàwó àwọn ọmọ rẹ̀ jẹ́ mẹ́rìndínláàádọ́rin (66).+
27 Ọmọ méjì* ni Jósẹ́fù bí ní Íjíbítì. Gbogbo ará* ilé Jékọ́bù tó wá sí Íjíbítì jẹ́ àádọ́rin (70).+
28 Jékọ́bù rán Júdà+ ṣáájú pé kó lọ sọ fún Jósẹ́fù pé òun ti wà lọ́nà Góṣénì. Nígbà tí wọ́n dé ilẹ̀ Góṣénì,+
29 Jósẹ́fù múra kẹ̀kẹ́ ẹṣin rẹ̀ sílẹ̀, ó sì lọ pàdé Ísírẹ́lì bàbá rẹ̀ ní Góṣénì. Nígbà tó dé ọ̀dọ̀ rẹ̀, ó dì mọ́ ọn* lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀, ó sì sunkún fúngbà díẹ̀.*
30 Ísírẹ́lì wá sọ fún Jósẹ́fù pé: “Mo lè wá kú báyìí; mo ti rí ojú rẹ, mo sì wá mọ̀ pé o ṣì wà láàyè.”
31 Jósẹ́fù wá sọ fún àwọn arákùnrin rẹ̀ àti agbo ilé bàbá rẹ̀ pé: “Ẹ jẹ́ kí n lọ bá Fáráò,+ kí n sì sọ fún un pé, ‘Àwọn arákùnrin mi àti agbo ilé bàbá mi láti ilẹ̀ Kénáánì ti wá bá mi níbí.+
32 Olùṣọ́ àgùntàn+ ni wọ́n, wọ́n sì ní àwọn ẹran ọ̀sìn.+ Wọ́n ti kó agbo ẹran wọn àti ọ̀wọ́ ẹran wọn àti gbogbo ohun ìní wọn wá.’+
33 Tí Fáráò bá pè yín, tó sì bi yín pé, ‘Iṣẹ́ wo lẹ̀ ń ṣe?’
34 Kí ẹ sọ pé, ‘Àti kékeré ni àwa ìránṣẹ́ rẹ ti ń tọ́jú ẹran ọ̀sìn, àwa àti àwọn baba ńlá+ wa,’ kí ẹ lè máa gbé ilẹ̀ Góṣénì,+ torí àwọn ará Íjíbítì+ kórìíra gbogbo àwọn tó ń da àgùntàn.”
Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé
^ Tàbí “gbogbo àwọn èèyàn rẹ̀.”
^ Ìyẹn ni pé yóò fi ọwọ́ rẹ̀ pa ojú Jékọ́bù dé tó bá kú.
^ Tàbí “Ọkàn gbogbo àwọn ọmọkùnrin àti ọmọbìnrin rẹ̀.”
^ Tàbí “ọkàn mẹ́rìndínlógún.”
^ Ìyẹn, Heliopólísì.
^ Tàbí “ọkàn mẹ́rìnlá.”
^ Ní Héb., “Àwọn ọmọ.”
^ Tàbí “ọkàn méje.”
^ Tàbí “Gbogbo ọkàn tó wá láti ara Jékọ́bù.”
^ Tàbí “Ọkàn méjì.”
^ Tàbí “Gbogbo àwọn ọkàn.”
^ Ní Héb., “rọ̀ mọ́ ọrùn rẹ̀.”
^ Tàbí “sunkún ní ọrùn rẹ̀ léraléra.”