Jẹ́nẹ́sísì 43:1-34

  • Àwọn ẹ̀gbọ́n Jósẹ́fù pa dà sí Íjíbítì; pẹ̀lú Bẹ́ńjámínì (1-14)

  • Jósẹ́fù tún rí àwọn arákùnrin rẹ̀ (15-23)

  • Jósẹ́fù jẹun pẹ̀lú àwọn arákùnrin rẹ̀ (24-34)

43  Ìyàn náà mú gidigidi ní ilẹ̀+ náà.  Torí náà, nígbà tí wọ́n jẹ ọkà tí wọ́n gbé wá láti Íjíbítì+ tán, bàbá wọn sọ fún wọn pé: “Ẹ pa dà lọ ra oúnjẹ díẹ̀ wá fún wa.”  Júdà wá sọ fún un pé: “Ọkùnrin náà ti kìlọ̀ fún wa pé, ‘Ẹ ò gbọ́dọ̀ tún fojú kàn mí mọ́ àfi tí ẹ bá mú àbúrò yín dání.’+  Tí o bá jẹ́ kí àbúrò wa bá wa lọ, a máa lọ síbẹ̀, a sì máa ra oúnjẹ wá fún ọ.  Àmọ́ tí o ò bá jẹ́ kó bá wa lọ, a ò ní lọ, torí ọkùnrin náà sọ fún wa pé, ‘Ẹ ò gbọ́dọ̀ tún fojú kàn mí mọ́ àfi tí ẹ bá mú àbúrò yín dání.’”+  Ísírẹ́lì+ wá bi wọ́n pé: “Kí ló dé tí ẹ sọ fún ọkùnrin náà pé ẹ ní àbúrò míì, tí ẹ sì fi ìyẹn fa wàhálà yìí bá mi?”  Wọ́n fèsì pé: “Ọkùnrin náà bi wá nípa ara wa àti àwọn mọ̀lẹ́bí wa pé, ‘Ṣé bàbá yín ṣì wà láàyè? Ṣé ẹ ní arákùnrin míì?’ A sì sọ òótọ́ fún un.+ Báwo la ṣe fẹ́ mọ̀ pé yóò sọ pé, ‘Ẹ mú àbúrò yín wá’?”+  Júdà wá rọ Ísírẹ́lì bàbá rẹ̀ pé: “Jẹ́ kí ọmọ náà bá mi lọ,+ sì jẹ́ ká máa lọ ká lè wà láàyè, ká má bàa kú,+ àwa àti ìwọ àti àwọn ọmọ+ wa.  Mo fi dá ọ lójú pé kò sóhun tó máa ṣe ọmọ náà.*+ Ọwọ́ mi ni kí o ti béèrè rẹ̀. Tí mi ò bá mú un pa dà wá bá ọ, kí n sì fà á lé ọ lọ́wọ́, a jẹ́ pé mo ti ṣẹ̀ ọ́ títí láé nìyẹn. 10  Tí kì í bá ṣe pé a fi falẹ̀ ni, à bá ti lọ ibẹ̀ lẹ́ẹ̀mejì ká sì ti dé báyìí.” 11  Ísírẹ́lì bàbá wọn wá sọ fún wọn pé: “Tọ́rọ̀ bá rí bẹ́ẹ̀, ohun tí ẹ máa ṣe nìyí: Ẹ kó àwọn ohun tó dáa jù ní ilẹ̀ yìí sínú àwọn àpò yín, kí ẹ gbé e lọ fún ọkùnrin náà bí ẹ̀bùn:+ básámù+ díẹ̀, oyin díẹ̀, gọ́ọ̀mù lábídánọ́mù, èèpo+ igi olóje, ẹ̀pà pítáṣíò àti álímọ́ńdì. 12  Ẹ mú owó ìlọ́po méjì dání; kí ẹ sì mú owó tí wọ́n dá pa dà sí ẹnu àpò+ yín dání. Bóyá àṣìṣe ni. 13  Ẹ mú àbúrò yín, kí ẹ sì máa lọ, ẹ pa dà sọ́dọ̀ ọkùnrin náà. 14  Kí Ọlọ́run Olódùmarè mú kí ọkùnrin náà ṣàánú yín, kó lè fi arákùnrin yín kan tó kù àti Bẹ́ńjámínì sílẹ̀. Àmọ́ ní tèmi, tó bá jẹ́ pé ọ̀fọ̀ yóò ṣẹ̀ mí+ lóòótọ́, kó ṣẹ̀ mí!” 15  Àwọn ọkùnrin náà wá mú ẹ̀bùn yìí, wọ́n mú owó ìlọ́po méjì, wọ́n sì mú Bẹ́ńjámínì dání. Wọ́n gbéra, wọ́n forí lé Íjíbítì, wọ́n sì tún lọ síwájú Jósẹ́fù.+ 16  Nígbà tí Jósẹ́fù rí Bẹ́ńjámínì pẹ̀lú wọn, ojú ẹsẹ̀ ló sọ fún ọkùnrin tó ń bójú tó ilé rẹ̀ pé: “Mú àwọn ọkùnrin náà lọ sínú ilé, kí o pa ẹran, kí o sì se oúnjẹ, torí àwọn ọkùnrin náà yóò bá mi jẹun ní ọ̀sán.” 17  Lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀, ọkùnrin náà ṣe ohun tí Jósẹ́fù sọ,+ ó sì mú wọn lọ sí ilé Jósẹ́fù. 18  Àmọ́ ẹ̀rù ba àwọn ọkùnrin náà nígbà tí wọ́n mú wọn lọ sí ilé Jósẹ́fù, wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí í sọ pé: “Torí owó tí wọ́n dá pa dà sínú àpò wa nígbà yẹn ni wọ́n ṣe mú wa wá síbí. Wọ́n máa wá gbéjà kò wá, wọ́n á sọ wá di ẹrú, wọ́n á sì gba àwọn kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́+ wa!” 19  Torí náà, wọ́n lọ bá ọkùnrin tó ń bójú tó ilé Jósẹ́fù, wọ́n sì bá a sọ̀rọ̀ ní ẹnu ọ̀nà ilé náà. 20  Wọ́n ní: “Jọ̀ọ́, olúwa mi! A ti kọ́kọ́ wá ra oúnjẹ+ níbí. 21  Àmọ́ nígbà tí a dé ibi tí a fẹ́ wọ̀ sí, tí a sì ṣí àwọn àpò wa, a rí owó kálukú ní ẹnu àpò rẹ̀, gbogbo owó+ wa la bá níbẹ̀. Torí náà, a fẹ́ fi ọwọ́ ara wa dá a pa dà. 22  A sì tún mú owó wá sí i ká lè ra oúnjẹ. A ò mọ ẹni tó fi owó wa sínú àwọn àpò+ wa.” 23  Ọkùnrin náà sọ fún wọn pé: “Ó dáa. Ẹ má bẹ̀rù. Ọlọ́run yín àti Ọlọ́run bàbá yín ló fi ìṣúra sínú àpò yín. Èmi ni mo kọ́kọ́ gba owó yín.” Lẹ́yìn náà, ó mú Síméónì jáde wá bá wọn.+ 24  Ọkùnrin náà wá mú wọn wá sínú ilé Jósẹ́fù, ó fún wọn ní omi kí wọ́n fi fọ ẹsẹ̀ wọn, ó sì fún àwọn kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ wọn ní oúnjẹ. 25  Wọ́n ṣètò ẹ̀bùn+ náà de Jósẹ́fù kó tó dé ní ọ̀sán, torí wọ́n ti gbọ́ pé àwọn máa jẹun níbẹ̀.+ 26  Nígbà tí Jósẹ́fù wọnú ilé, wọ́n gbé ẹ̀bùn wọn wá fún un nínú ilé, wọ́n sì wólẹ̀ fún un.+ 27  Lẹ́yìn náà, ó béèrè àlàáfíà wọn, ó sì bi wọ́n pé: “Bàbá yín tó ti dàgbà tí ẹ sọ̀rọ̀ rẹ̀ ńkọ́? Ṣé ó ṣì wà láàyè?”+ 28  Wọ́n fèsì pé: “Àlàáfíà ni bàbá wa tó jẹ́ ìránṣẹ́ rẹ wà. Ó ṣì wà láàyè.” Wọ́n wá tẹrí ba, wọ́n sì wólẹ̀.+ 29  Nígbà tó wòkè, tó sì rí Bẹ́ńjámínì àbúrò rẹ̀, ọmọ ìyá+ rẹ̀, ó bi wọ́n pé: “Ṣé àbúrò yín tó kéré jù tí ẹ sọ̀rọ̀ rẹ̀ fún mi nìyí?”+ Ó sọ pé: “Kí Ọlọ́run ṣojúure sí ọ, ọmọ mi.” 30  Jósẹ́fù sáré jáde, torí ọkàn rẹ̀ fà sí àbúrò rẹ̀ débi pé kò lè mú un mọ́ra mọ́, ó sì wá ibì kan láti sunkún. Ó wọnú yàrá àdáni kan, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí í sunkún níbẹ̀.+ 31  Lẹ́yìn náà, ó fọ ojú rẹ̀, ó sì jáde. Ó mọ́kàn le, ó sì sọ pé: “Ẹ gbé oúnjẹ wá.” 32  Wọ́n gbé oúnjẹ tirẹ̀ fún un lọ́tọ̀, tiwọn náà wà lọ́tọ̀, àwọn ará Íjíbítì tí wọ́n wà lọ́dọ̀ rẹ̀ sì jẹun lọ́tọ̀, torí àwọn ará Íjíbítì kò lè bá àwọn Hébérù jẹun, torí pé ohun ìríra ló jẹ́ lójú àwọn ará Íjíbítì.+ 33  Àwọn arákùnrin rẹ̀* jókòó síwájú rẹ̀, látorí àkọ́bí tó ní ẹ̀tọ́ àkọ́bí+ dórí èyí tó kéré jù, wọ́n sì ń wo ara wọn tìyanutìyanu. 34  Ó sì ń bù lára oúnjẹ tó wà lórí tábìlì rẹ̀ fún wọn, àmọ́ ìlọ́po márùn-ún èyí tó bù fún àwọn yòókù+ ló ń bù fún Bẹ́ńjámínì. Wọ́n wá ń jẹun pẹ̀lú rẹ̀, wọ́n sì ń mu títí wọ́n fi jẹun yó.

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé

Tàbí “Màá ṣe onídùúró fún ọmọ náà.”
Ní Héb., “Wọ́n.”