Jẹ́nẹ́sísì 41:1-57

  • Jósẹ́fù túmọ̀ àlá Fáráò (1-36)

  • Fáráò gbé Jósẹ́fù ga (37-46a)

  • Jósẹ́fù ń bójú tó ọ̀rọ̀ oúnjẹ (46b-57)

41  Lẹ́yìn ọdún méjì gbáko, Fáráò lá àlá+ pé òun dúró létí odò Náílì.  Màlúù méje tó rẹwà tó sì sanra ń jáde bọ̀ látinú odò náà, wọ́n sì ń jẹ koríko+ tó wà ní odò Náílì.  Lẹ́yìn náà, màlúù méje míì tí kò lẹ́wà, tó sì rù ń jáde bọ̀ látinú odò Náílì, wọ́n dúró létí odò Náílì lẹ́gbẹ̀ẹ́ àwọn màlúù tó sanra.  Àwọn màlúù tí kò lẹ́wà, tó sì rù wá jẹ àwọn màlúù méje tó rẹwà, tó sì sanra ní àjẹrun. Ni Fáráò bá jí.  Ó pa dà lọ sùn, ó sì lá àlá míì. Ṣírí ọkà méje tó yọmọ dáadáa, tó sì dára+ jáde láti ara pòròpórò kan.  Lẹ́yìn náà, ṣírí ọkà méje tó tín-ín-rín, tí atẹ́gùn ìlà oòrùn sì ti jó gbẹ hù jáde.  Àwọn ṣírí ọkà tó tín-ín-rín náà wá ń gbé ṣírí ọkà méje tó yọmọ dáadáa, tó sì dára mì. Ni Fáráò bá jí, ó sì rí i pé àlá ni òun lá.  Àmọ́ nígbà tí ilẹ̀ mọ́, ọkàn rẹ̀ ò balẹ̀. Ó wá ránṣẹ́ pe gbogbo àlùfáà onídán nílẹ̀ Íjíbítì àti gbogbo àwọn amòye ilẹ̀ náà. Fáráò rọ́ àwọn àlá rẹ̀ fún wọn, àmọ́ kò sẹ́nì kankan tó lè túmọ̀ wọn fún Fáráò.  Ni olórí agbọ́tí bá sọ fún Fáráò pé: “Màá jẹ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ mi lónìí. 10  Fáráò bínú sí àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀. Ó fi èmi àti olórí alásè+ sínú ẹ̀wọ̀n ní ilé olórí ẹ̀ṣọ́. 11  Lẹ́yìn náà, àwa méjèèjì lá àlá ní alẹ́ ọjọ́ kan náà. Àlá tí kálukú wa lá ní ìtúmọ̀+ tirẹ̀. 12  Ọ̀dọ́kùnrin kan tó jẹ́ Hébérù wà níbẹ̀ pẹ̀lú wa, ìránṣẹ́ olórí ẹ̀ṣọ́+ ni. Nígbà tí a rọ́ àlá wa fún un,+ ó túmọ̀ àlá kálukú fún un. 13  Bó ṣe túmọ̀ rẹ̀ fún wa gẹ́lẹ́ ló rí. Èmi pa dà sẹ́nu iṣẹ́ mi, àmọ́ wọ́n gbé ẹnì kejì kọ́.”+ 14  Fáráò bá ránṣẹ́ pe Jósẹ́fù,+ wọ́n sì sáré mú un wá látinú ẹ̀wọ̀n.*+ Ó fá irun rẹ̀, ó pààrọ̀ aṣọ rẹ̀, ó sì wọlé lọ bá Fáráò. 15  Fáráò sọ fún Jósẹ́fù pé: “Mo lá àlá kan, àmọ́ kò sẹ́ni tó lè túmọ̀ rẹ̀. Ṣùgbọ́n mo ti gbọ́ pé tí wọ́n bá rọ́ àlá fún ọ, o lè túmọ̀ rẹ̀.”+ 16  Jósẹ́fù dá Fáráò lóhùn pé: “Mi ò já mọ́ nǹkan kan! Ọlọ́run yóò sọ ohun tó máa ṣẹlẹ̀ sí Fáráò.”+ 17  Fáráò wá sọ fún Jósẹ́fù pé: “Lójú àlá mi, mo dúró létí odò Náílì. 18  Màlúù méje tó rẹwà tó sì sanra ń jáde bọ̀ látinú odò náà, wọ́n sì ń jẹ koríko+ tó wà ní odò Náílì. 19  Lẹ́yìn náà, màlúù méje míì tí ìrísí wọn ò dáa, tí wọn ò lẹ́wà rárá, tí wọ́n sì rù ń jáde bọ̀. Mi ò rí irú màlúù tí ìrísí wọn burú tó bẹ́ẹ̀ rí ní gbogbo ilẹ̀ Íjíbítì. 20  Àwọn màlúù tí kò dáa tí wọ́n sì rù kan egungun yẹn wá ń jẹ màlúù méje àkọ́kọ́ tó sanra ní àjẹrun. 21  Àmọ́ nígbà tí wọ́n jẹ wọ́n tán, kò sẹ́ni tó lè mọ̀ pé wọ́n jẹ nǹkan kan, torí kò hàn lára wọn. Ni mo bá jí. 22  “Lẹ́yìn ìyẹn, mo lá àlá pé ṣírí ọkà méje tó yọmọ dáadáa, tó sì dára+ jáde láti ara pòròpórò kan. 23  Lẹ́yìn náà, ṣírí ọkà méje tó ti rọ, tó tín-ín-rín, tí atẹ́gùn ìlà oòrùn sì ti jó gbẹ hù jáde. 24  Àwọn ṣírí ọkà tín-ín-rín náà wá ń gbé ṣírí ọkà méje tó dára mì. Mo ti rọ́ àlá yìí fún àwọn àlùfáà onídán,+ àmọ́ kò sẹ́ni tó lè sọ ìtúmọ̀ rẹ̀ fún mi.”+ 25  Jósẹ́fù sọ fún Fáráò pé: “Ọ̀kan náà ni àwọn àlá Fáráò, ohun kan náà ni wọ́n sì túmọ̀ sí. Ọlọ́run tòótọ́ ti jẹ́ kí Fáráò mọ ohun tí òun fẹ́ ṣe.+ 26  Màlúù méje tó dára náà dúró fún ọdún méje. Bẹ́ẹ̀ náà ni àwọn ṣírí ọkà méje tó dára dúró fún ọdún méje. Ọ̀kan náà ni àwọn àlá náà, ohun kan náà ni wọ́n sì túmọ̀ sí. 27  Màlúù méje tó rù kan egungun, tí wọn ò sì dáa tí wọ́n jáde wá lẹ́yìn wọn dúró fún ọdún méje. Àwọn òfìfo ṣírí ọkà méje tí atẹ́gùn ìlà oòrùn ti jó gbẹ yóò jẹ́ ọdún méje ìyàn. 28  Bó ṣe rí ni mo sọ fún Fáráò: Ọlọ́run tòótọ́ ti fi ohun tó fẹ́ ṣe han Fáráò. 29  “Ọdún méje ni nǹkan yóò fi pọ̀ rẹpẹtẹ ní gbogbo ilẹ̀ Íjíbítì. 30  Àmọ́ lẹ́yìn ìyẹn, ó dájú pé ìyàn máa mú fún ọdún méje. Ó dájú pé gbogbo ohun tó pọ̀ rẹpẹtẹ nílẹ̀ Íjíbítì yóò di ohun ìgbàgbé, ìyàn yóò sì run ilẹ̀+ náà. 31  Wọn ò sì ní rántí ìgbà tí nǹkan pọ̀ rẹpẹtẹ ní ilẹ̀ náà torí ìyàn tó máa mú, torí pé ìyàn náà á mú gidigidi. 32  Ẹ̀ẹ̀mejì ni Fáráò lá àlá yìí torí pé Ọlọ́run tòótọ́ ti fìdí ọ̀rọ̀ náà múlẹ̀ gbọn-in, Ọlọ́run tòótọ́ yóò sì mú kó ṣẹlẹ̀ láìpẹ́. 33  “Ní báyìí, kí Fáráò wá ọkùnrin kan tó jẹ́ olóye, tó sì jẹ́ ọlọ́gbọ́n, kó fi ṣe olórí ilẹ̀ Íjíbítì. 34  Kí Fáráò ṣe nǹkan kan lórí ọ̀rọ̀ yìí, kó yan àwọn alábòójútó ní ilẹ̀ náà, kó sì gba ìdá márùn-ún irè oko ilẹ̀ Íjíbítì ní ọdún méje tí ọ̀pọ̀ rẹpẹtẹ+ bá fi wà. 35  Kí wọ́n kó gbogbo oúnjẹ jọ ní àwọn ọdún tó ń bọ̀ yìí tí nǹkan máa ṣẹnuure, kí Fáráò sì pàṣẹ pé kí wọ́n kó ọ̀pọ̀ rẹpẹtẹ ọkà tí wọ́n á jẹ pa mọ́ sí àwọn ìlú, kí wọ́n sì tọ́jú rẹ̀.+ 36  Oúnjẹ yẹn ni kí wọ́n máa jẹ nígbà tí ìyàn bá mú fún ọdún méje ní ilẹ̀ Íjíbítì, kí ìyàn+ má bàa run ilẹ̀ náà.” 37  Ohun tó sọ yìí dára lójú Fáráò àti gbogbo àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀. 38  Torí náà, Fáráò sọ fún àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ pé: “Ǹjẹ́ ọkùnrin míì wà tó ní ẹ̀mí Ọlọ́run bí ẹni yìí?” 39  Ni Fáráò bá sọ fún Jósẹ́fù pé: “Níwọ̀n bó ti jẹ́ pé Ọlọ́run ló jẹ́ kí o mọ gbogbo èyí, kò sí ẹni tó lóye, tó sì jẹ́ ọlọ́gbọ́n bíi tìẹ. 40  Ìwọ ni màá fi ṣe olórí ilé mi, gbogbo àwọn èèyàn mi yóò sì máa ṣègbọràn sí ọ délẹ̀délẹ̀.+ Ipò ọba* mi nìkan ni màá fi jù ọ́ lọ.” 41  Fáráò tún sọ fún Jósẹ́fù pé: “Wò ó, èmi yóò fi ọ́ ṣe olórí gbogbo ilẹ̀ Íjíbítì.”+ 42  Fáráò wá bọ́ òrùka àṣẹ tó wà lọ́wọ́ rẹ̀, ó sì fi sí ọwọ́ Jósẹ́fù. Ó wọ aṣọ ọ̀gbọ̀* tó dáa fún un, ó sì fi ẹ̀gbà wúrà sí i lọ́rùn. 43  Ó tún mú kí ó gun kẹ̀kẹ́ ẹṣin rẹ̀ kejì tó lọ́lá, ó sì ní kí wọ́n máa kígbe níwájú rẹ̀ pé, “Áfírékì!”* Bó ṣe fi Jósẹ́fù ṣe olórí gbogbo ilẹ̀ Íjíbítì nìyẹn. 44  Fáráò tún sọ fún Jósẹ́fù pé: “Èmi ni Fáráò, àmọ́ ẹnì kankan ò gbọ́dọ̀ ṣe ohunkóhun* ní gbogbo ilẹ̀ Íjíbítì,+ láìjẹ́ pé o fọwọ́ sí i.” 45  Lẹ́yìn náà, Fáráò sọ Jósẹ́fù ní Safenati-pánéà, ó sì fún un ní Ásénátì+ ọmọ Pọ́tíférà àlùfáà Ónì* pé kó fi ṣe aya. Jósẹ́fù wá bẹ̀rẹ̀ sí í bójú tó* ilẹ̀ Íjíbítì.+ 46  Ẹni ọgbọ̀n (30) ọdún+ ni Jósẹ́fù nígbà tó dúró níwájú* Fáráò ọba Íjíbítì. Lẹ́yìn náà, Jósẹ́fù kúrò níwájú Fáráò, ó sì lọ káàkiri gbogbo ilẹ̀ Íjíbítì. 47  Ní ọdún méje tí ọ̀pọ̀ rẹpẹtẹ fi wà, ilẹ̀ náà méso jáde wọ̀ǹtìwọnti.* 48  Ó sì ń kó gbogbo oúnjẹ jọ ní ilẹ̀ Íjíbítì fún ọdún méje náà, ó ń kó oúnjẹ pa mọ́ sí àwọn ìlú. Ó máa ń kó àwọn irè oko agbègbè ìlú kọ̀ọ̀kan pa mọ́ sí ìlú náà. 49  Jósẹ́fù sì ń kó ọ̀pọ̀ rẹpẹtẹ ọkà pa mọ́, ó pọ̀ bí iyanrìn etíkun, débi pé wọn ò lè wọ̀n ọ́n torí kò ṣeé wọ̀n mọ́. 50  Jósẹ́fù+ ti bí ọmọkùnrin méjì kí ìyàn tó bẹ̀rẹ̀ sí í mú. Ásénátì ọmọ Pọ́tíférà àlùfáà Ónì* ló bí àwọn ọmọ náà fún un. 51  Jósẹ́fù sọ àkọ́bí rẹ̀ ní Mánásè,*+ torí ó sọ pé, “Ọlọ́run ti mú kí n gbàgbé gbogbo ìdààmú tó bá mi àti gbogbo ilé bàbá mi.” 52  Ó sì sọ èkejì ní Éfúrémù,*+ torí ó sọ pé, “Ọlọ́run ti mú kí n di púpọ̀ ní ilẹ̀ tí mo ti jìyà.”+ 53  Ọdún méje tí nǹkan fi pọ̀ rẹpẹtẹ ní ilẹ̀ Íjíbítì wá dópin,+ 54  ìyàn ọdún méje sì bẹ̀rẹ̀, bí Jósẹ́fù ṣe sọ.+ Ìyàn mú ní gbogbo àwọn ilẹ̀, àmọ́ oúnjẹ*+ wà ní gbogbo ilẹ̀ Íjíbítì. 55  Àmọ́ nígbà tó yá, ìyàn náà dé gbogbo ilẹ̀ Íjíbítì, àwọn èèyàn sì bẹ̀rẹ̀ sí í ké pe Fáráò pé kó fún àwọn ní oúnjẹ.+ Fáráò wá sọ fún gbogbo ará Íjíbítì pé: “Ẹ lọ bá Jósẹ́fù, kí ẹ sì ṣe ohunkóhun tó bá sọ.”+ 56  Ìyàn náà kò dáwọ́ dúró ní gbogbo ilẹ̀.+ Jósẹ́fù wá bẹ̀rẹ̀ sí í ṣí gbogbo ibi tó kó ọkà pa mọ́ sí láwọn ìlú náà, ó sì ń tà á fún àwọn ará Íjíbítì+ torí ìyàn náà mú gidigidi ní ilẹ̀ Íjíbítì. 57  Àwọn èèyàn láti ibi gbogbo sì ń lọ sí Íjíbítì kí wọ́n lè ra oúnjẹ lọ́dọ̀ Jósẹ́fù torí ìyàn náà mú gidigidi ní gbogbo ilẹ̀.+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé

Ní Héb., “kòtò omi; ihò.”
Tàbí “Ìtẹ́.”
Tàbí “aṣọ àtàtà.”
Ó jọ pé ọ̀rọ̀ yìí túmọ̀ sí pé kí wọ́n bọlá fún un kí wọ́n sì bọ̀wọ̀ fún un.
Ní Héb., “gbé ọwọ́ tàbí ẹsẹ̀ rẹ̀ sókè.”
Ìyẹn, Heliopólísì.
Tàbí “lọ káàkiri.”
Tàbí “nígbà tó bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ lọ́dọ̀.”
Ní Héb., “ní ẹ̀kúnwọ́-ẹ̀kúnwọ́.”
Ìyẹn, Heliopólísì.
Ó túmọ̀ sí “Ẹni Tó Ń Múni Gbàgbé; Amúnigbàgbé.”
Ó túmọ̀ sí “Èso Ìlọ́po Méjì.”
Tàbí “búrẹ́dì.”