Jẹ́nẹ́sísì 38:1-30
-
Júdà àti Támárì (1-30)
38 Ní àkókò yẹn, Júdà kúrò lọ́dọ̀ àwọn arákùnrin rẹ̀, ó sì pàgọ́ rẹ̀ sí tòsí ọkùnrin ará Ádúlámù kan tó ń jẹ́ Hírà.
2 Ibẹ̀ ni Júdà ti rí ọmọbìnrin ara Kénáánì+ kan tó ń jẹ́ Ṣúà. Ó mú un, ó bá a lò pọ̀,
3 ó sì lóyún. Lẹ́yìn náà, ó bí ọmọkùnrin kan, ó sì pe orúkọ rẹ̀ ní Éérì.+
4 Ó tún lóyún, ó bí ọmọkùnrin kan, ó sì pe orúkọ rẹ̀ ní Ónánì.
5 Ó tún bí ọmọkùnrin míì, ó sì pe orúkọ rẹ̀ ní Ṣélà. Ìlú Ákísíbù+ ni ó* wà nígbà tí obìnrin náà bí i.
6 Nígbà tó yá, Júdà fẹ́ ìyàwó fún Éérì àkọ́bí rẹ̀, Támárì+ ni orúkọ rẹ̀.
7 Àmọ́ inú Jèhófà ò dùn sí Éérì, àkọ́bí Júdà; torí náà, Jèhófà pa á.
8 Torí ìyẹn, Júdà sọ fún Ónánì pé: “Bá ìyàwó ẹ̀gbọ́n rẹ lò pọ̀, kí o ṣú u lópó, kí o sì mú kí ẹ̀gbọ́n+ rẹ ní ọmọ.”
9 Àmọ́ Ónánì mọ̀ pé ọmọ náà ò ní jẹ́ tòun.+ Torí náà, nígbà tó bá ìyàwó ẹ̀gbọ́n rẹ̀ lò pọ̀, ó fi àtọ̀ rẹ̀ ṣòfò sórí ilẹ̀, kí ẹ̀gbọ́n+ rẹ̀ má bàa ní ọmọ.
10 Ohun tó ṣe yìí burú lójú Jèhófà; torí náà, ó pa+ òun náà.
11 Júdà sọ fún Támárì ìyàwó ọmọ rẹ̀ pé: “Lọ máa ṣe opó ní ilé bàbá rẹ títí Ṣélà ọmọ mi yóò fi dàgbà,” torí ó sọ lọ́kàn ara rẹ̀ pé: “Òun náà lè kú bíi ti àwọn ẹ̀gbọ́n+ rẹ̀.” Támárì wá lọ ń gbé ní ilé bàbá rẹ̀.
12 Lẹ́yìn àkókò díẹ̀, ìyàwó Júdà tó jẹ́ ọmọ Ṣúà+ kú. Júdà ṣọ̀fọ̀ rẹ̀, lẹ́yìn náà, òun àti Hírà ọ̀rẹ́ rẹ̀, ará Ádúlámù+ lọ sọ́dọ̀ àwọn tó ń rẹ́ irun àgùntàn rẹ̀ ní Tímúnà.+
13 Àwọn kan sọ fún Támárì pé: “Bàbá ọkọ rẹ ń lọ sí Tímúnà láti rẹ́ irun àwọn àgùntàn rẹ̀.”
14 Ló bá bọ́ aṣọ opó rẹ̀, ó fi aṣọ bojú, ó sì fi ìborùn borí rẹ̀. Ó wá jókòó sí ẹnu ọ̀nà Énáímù, tó wà ní ọ̀nà Tímúnà, torí ó rí i pé Ṣélà ti dàgbà, bàbá rẹ̀ kò sì tíì sọ pé kí òun di ìyàwó+ Ṣélà.
15 Nígbà tí Júdà rí i, ó rò pé aṣẹ́wó ni, torí ó fi nǹkan bojú.
16 Torí náà, ó yà sọ́dọ̀ rẹ̀ lẹ́gbẹ̀ẹ́ ọ̀nà, ó sì sọ pé: “Jọ̀ọ́, jẹ́ kí n bá ọ lò pọ̀,” ṣùgbọ́n kò mọ̀ pé ìyàwó ọmọ+ òun ni. Obìnrin náà bi í pé: “Kí lo máa fún mi tí o bá bá mi lò pọ̀?”
17 Ó fèsì pé: “Màá fi ọmọ ewúrẹ́ kan ránṣẹ́ látinú agbo ẹran mi.” Àmọ́ obìnrin náà sọ pé: “Ṣé o máa fi nǹkan ṣe ìdúró títí dìgbà tí wàá fi ewúrẹ́ náà ránṣẹ́?”
18 Ó bi í pé: “Kí ni kí n fi ṣe ìdúró fún ọ?” Obìnrin náà fèsì pé: “Òrùka èdìdì+ rẹ, okùn rẹ àti ọ̀pá ọwọ́ rẹ.” Ló bá kó o fún un, ó sì bá a lò pọ̀, obìnrin náà sì lóyún fún un.
19 Lẹ́yìn náà, ó gbéra, ó sì kúrò níbẹ̀, ó mú ìborùn kúrò, ó sì wọ aṣọ opó rẹ̀.
20 Júdà fi ọmọ ewúrẹ́ náà rán ọ̀rẹ́ rẹ̀ ará Ádúlámù,+ kó bàa lè gba ohun tó fi ṣe ìdúró pa dà lọ́wọ́ obìnrin náà, àmọ́ kò rí i.
21 Ó bi àwọn tó ń gbé ibi tí obìnrin náà wà pé: “Ibo ni aṣẹ́wó tẹ́ńpìlì tó wà ní Énáímù lẹ́gbẹ̀ẹ́ ọ̀nà yẹn wà?” Àmọ́ wọ́n fèsì pé: “Aṣẹ́wó tẹ́ńpìlì kankan ò sí níbí yìí rí.”
22 Níkẹyìn, ó pa dà sọ́dọ̀ Júdà, ó sì sọ pé: “Mi ò rí i, àwọn èèyàn ibẹ̀ náà sọ pé, ‘Aṣẹ́wó tẹ́ńpìlì kankan ò sí níbí yìí rí.’”
23 Júdà wá sọ pé: “Jẹ́ kó máa mú un lọ, ká má bàa di ẹni àbùkù. Mo kúkú ti fi ọmọ ewúrẹ́ yìí ránṣẹ́, ṣùgbọ́n o ò rí obìnrin náà.”
24 Àmọ́, ní nǹkan bí oṣù mẹ́ta lẹ́yìn ìgbà yẹn, wọ́n sọ fún Júdà pé: “Támárì ìyàwó ọmọ rẹ ṣe aṣẹ́wó, ó sì ti lóyún nídìí iṣẹ́ aṣẹ́wó tó ṣe.” Ni Júdà bá sọ pé: “Ẹ mú un jáde ká sì sun ún.”+
25 Nígbà tí wọ́n mú un jáde, ó ránṣẹ́ sí bàbá ọkọ rẹ̀ pé: “Ọkùnrin tó ni àwọn nǹkan yìí ló fún mi lóyún.” Ó tún sọ pé: “Jọ̀ọ́, wo òrùka èdìdì yìí, okùn àti ọ̀pá+ yìí kí o lè mọ ẹni tó ni ín.”
26 Ni Júdà bá yẹ̀ ẹ́ wò, ó sì sọ pé: “Òdodo rẹ̀ ju tèmi lọ, torí mi ò fún un ní Ṣélà ọmọ mi.”+ Kò sì bá a lò pọ̀ mọ́ lẹ́yìn ìyẹn.
27 Nígbà tó tó àkókò tó máa bímọ, ìbejì ló wà nínú rẹ̀.
28 Bó ṣe ń bímọ, ọ̀kan na ọwọ́ jáde, ni agbẹ̀bí bá mú òwú aláwọ̀ rírẹ̀dòdò, ó sì so ó mọ́ ọwọ́ rẹ̀, ó ní: “Èyí ló kọ́kọ́ jáde.”
29 Àmọ́ bó ṣe fa ọwọ́ rẹ̀ pa dà, arákùnrin rẹ̀ jáde, obìnrin náà sì sọ pé: “Wo bí o ṣe dọ́gbẹ́ sí ìyá rẹ lára kí o tó lè jáde!” Torí náà, wọ́n pe orúkọ rẹ̀ ní Pérésì.*+
30 Lẹ́yìn náà, arákùnrin rẹ̀ jáde, òun ni wọ́n so òwú pupa mọ́ lọ́wọ́, wọ́n sì pe orúkọ rẹ̀ ní Síírà.+