Jẹ́nẹ́sísì 31:1-55

  • Jékọ́bù yọ́ lọ sí Kénáánì (1-18)

  • Lábánì lé Jékọ́bù bá (19-35)

  • Jékọ́bù àti Lábánì dá májẹ̀mú (36-55)

31  Nígbà tó yá, ó gbọ́ ohun tí àwọn ọmọ Lábánì ń sọ pé: “Jékọ́bù ti gba gbogbo ohun tí bàbá wa ní, ó sì ti kó gbogbo ọrọ̀+ yìí jọ látinú àwọn ohun tí bàbá wa ní.”  Tí Jékọ́bù bá wo ojú Lábánì, ó ń rí i pé ìwà rẹ̀ sí òun ti yí pa dà.+  Níkẹyìn, Jèhófà sọ fún Jékọ́bù pé: “Pa dà sí ilẹ̀ àwọn bàbá rẹ àti sọ́dọ̀ àwọn mọ̀lẹ́bí+ rẹ, mi ò sì ní fi ọ́ sílẹ̀.”  Jékọ́bù wá ránṣẹ́ pe Réṣẹ́lì àti Líà pé kí wọ́n wá sínú pápá níbi tí agbo ẹran rẹ̀ wà,  ó sì sọ fún wọn pé: “Mo rí i pé bàbá yín ti yíwà pa dà sí mi,+ àmọ́ Ọlọ́run bàbá mi ò fi mí sílẹ̀.+  Ó dájú pé ẹ̀yin fúnra yín mọ̀ pé gbogbo okun+ mi ni mo fi sin bàbá yín.  Bàbá yín sì ti fẹ́ rẹ́ mi jẹ, ìgbà mẹ́wàá ló ti yí ohun tó yẹ kó jẹ́ èrè mi pa dà; àmọ́ Ọlọ́run ò jẹ́ kó pa mí lára.  Tó bá sọ pé, ‘Àwọn aláwọ̀ tó-tò-tó ló máa jẹ́ èrè rẹ,’ ìgbà yẹn ni gbogbo ẹran á bí aláwọ̀ tó-tò-tó; àmọ́ tó bá sọ pé, ‘Àwọn abilà ló máa jẹ́ èrè rẹ,’ ìgbà yẹn ni gbogbo ẹran á bí abilà.+  Ọlọ́run wá ń gba ẹran ọ̀sìn bàbá yín kúrò lọ́wọ́ rẹ̀, ó sì ń mú kó di tèmi. 10  Nígbà kan tí àwọn ẹran fẹ́ gùn, mo lá àlá, mo wòkè, mo sì rí i pé àwọn òbúkọ abilà, aláwọ̀ tó-tò-tó àti àwọn tó lámì lára+ ń gun àwọn ẹran náà. 11  Áńgẹ́lì Ọlọ́run tòótọ́ pè mí lójú àlá, ó ní, ‘Jékọ́bù!’ mo sì fèsì pé, ‘Èmi nìyí.’ 12  Ó wá sọ pé, ‘Jọ̀ọ́ wòkè, wàá sì rí i pé gbogbo àwọn òbúkọ abilà, aláwọ̀ tó-tò-tó àti àwọn tó lámì lára ló ń gun àwọn ẹran náà, torí mo ti rí gbogbo ohun tí Lábánì ń ṣe sí ọ.+ 13  Èmi ni Ọlọ́run tòótọ́ tó bá ọ sọ̀rọ̀ ní Bẹ́tẹ́lì,+ níbi tí o ti da òróró sórí òpó tí o gbé sílẹ̀, tí o sì ti jẹ́ ẹ̀jẹ́ fún mi.+ Wá gbéra báyìí, kí o kúrò ní ilẹ̀ yìí, kí o sì pa dà sí ilẹ̀ tí wọ́n ti bí ọ.’”+ 14  Ni Réṣẹ́lì àti Líà bá fèsì pé: “Ṣé ìpín kankan ṣì ṣẹ́ kù ní ilé bàbá wa tí a lè jogún ni? 15  Ṣebí àjèjì ló kà wá sí? Ó kúkú ti tà wá, ó sì ń ná gbogbo owó tó gbà lórí wa.+ 16  Àwa àtàwọn ọmọ+ wa la ni gbogbo ọrọ̀ tí Ọlọ́run gbà lọ́wọ́ bàbá wa. Torí náà, ṣe gbogbo ohun tí Ọlọ́run ní kí o ṣe.”+ 17  Jékọ́bù wá dìde, ó sì gbé àwọn ọmọ rẹ̀ àti àwọn ìyàwó rẹ̀ sórí àwọn ràkúnmí,+ 18  ó sì bẹ̀rẹ̀ sí í da agbo ẹran rẹ̀ àti gbogbo ohun tí ó ti ní,+ àwọn ẹran ọ̀sìn tó wá di tirẹ̀ ní Padani-árámù, ó dà wọ́n lọ sọ́dọ̀ Ísákì bàbá rẹ̀ ní ilẹ̀ Kénáánì.+ 19  Nígbà tí Lábánì lọ rẹ́ irun àwọn àgùntàn rẹ̀, Réṣẹ́lì jí àwọn ère tẹ́ráfímù*+ tó jẹ́ ti bàbá+ rẹ̀. 20  Àmọ́, Jékọ́bù lo ọgbọ́n ẹ̀wẹ́ fún Lábánì ará Arémíà, torí kò sọ fún un pé òun fẹ́ sá lọ. 21  Ó sá lọ, ó sì sọdá Odò,*+ òun àti gbogbo ohun tó ní. Ó wá forí lé agbègbè olókè Gílíádì.+ 22  Ní ọjọ́ kẹta, Lábánì gbọ́ pé Jékọ́bù ti sá lọ. 23  Ló bá mú àwọn arákùnrin* rẹ̀ dání, wọ́n sì ń lé e, lẹ́yìn tí wọ́n rin ìrìn àjò ọjọ́ méje, wọ́n lé e bá ní agbègbè olókè Gílíádì. 24  Ọlọ́run bá Lábánì ará Arémíà+ sọ̀rọ̀ lójú àlá ní òru,+ ó sọ fún un pé: “Ṣọ́ ohun tí o máa sọ fún Jékọ́bù, ì báà jẹ́ rere tàbí búburú.”*+ 25  Lábánì lọ bá Jékọ́bù lẹ́yìn tí Jékọ́bù ti pa àgọ́ rẹ̀ sórí òkè, tí Lábánì àtàwọn arákùnrin rẹ̀ pẹ̀lú sì ti pàgọ́ sí agbègbè olókè Gílíádì. 26  Lábánì bi Jékọ́bù pé: “Kí lo ṣe yìí? Kí nìdí tí o fi lo ọgbọ́n ẹ̀wẹ́ fún mi, tí o wá kó àwọn ọmọ mi lọ bí ẹrú tí wọ́n fi idà mú? 27  Kí ló dé tí o fi sá lọ láìjẹ́ kí n mọ̀, tí o lo ọgbọ́n ẹ̀wẹ́ fún mi, tó ò sì sọ fún mi? Ká ní o sọ fún mi ni, ṣebí tayọ̀tayọ̀ ni ǹ bá fi sìn ọ́ sọ́nà, pẹ̀lú orin, ìlù tanboríìnì àti háàpù? 28  Àmọ́ o ò jẹ́ kí n fi ẹnu ko àwọn ọmọ mi àtàwọn ọmọ ọmọ* mi lẹ́nu. Ìwà òmùgọ̀ lo hù yìí. 29  Mo lágbára láti fìyà jẹ ọ́, àmọ́ Ọlọ́run bàbá rẹ bá mi sọ̀rọ̀ lóru àná pé, ‘Ṣọ́ ohun tí o máa sọ fún Jékọ́bù, ì báà jẹ́ rere tàbí búburú.’+ 30  O ti kúrò báyìí torí ó ń wù ọ́ pé kí o pa dà sí ilé bàbá rẹ, àmọ́ kí ló dé tí o jí àwọn ọlọ́run+ mi kó?” 31  Jékọ́bù dá Lábánì lóhùn pé: “Ẹ̀rù ló bà mí, torí mò ń sọ lọ́kàn ara mi pé, ‘O lè fipá gba àwọn ọmọ rẹ lọ́wọ́ mi.’ 32  Ẹnikẹ́ni tí o bá rí àwọn ọlọ́run rẹ lọ́wọ́ rẹ̀ yóò kú. Wo inú àwọn ẹrù mi níṣojú àwọn arákùnrin wa, kí o sì mú ohun tó bá jẹ́ tìrẹ.” Àmọ́ Jékọ́bù ò mọ̀ pé Réṣẹ́lì ló jí i. 33  Torí náà, Lábánì wọnú àgọ́ Jékọ́bù, ó sì wọnú àgọ́ Líà àti àgọ́ àwọn ẹrúbìnrin+ méjèèjì, àmọ́ kò rí i. Ó wá jáde nínú àgọ́ Líà, ó sì wọnú àgọ́ Réṣẹ́lì. 34  Àmọ́ Réṣẹ́lì ti kó àwọn ère tẹ́ráfímù náà sínú apẹ̀rẹ̀ tí àwọn obìnrin máa ń gbé sórí ràkúnmí, ó sì jókòó lé wọn. Lábánì wá gbogbo inú àgọ́ náà, àmọ́ kò rí àwọn ère náà. 35  Réṣẹ́lì sọ fún bàbá rẹ̀ pé: “Má ṣe bínú olúwa mi, mi ò lè dìde níwájú rẹ, torí mò ń ṣe nǹkan oṣù lọ́wọ́.”*+ Ó sì fara balẹ̀ wá a, àmọ́ kò rí àwọn ère tẹ́ráfímù náà.+ 36  Inú wá bí Jékọ́bù, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí í sọ̀rọ̀ sí Lábánì. Ó sọ fún Lábánì pé: “Kí ni mo ṣe fún ọ, kí sì ni ẹ̀ṣẹ̀ mi, tí o fi ń lé mi kiri lójú méjèèjì? 37  Ní báyìí tí o ti wo inú gbogbo ẹrù mi, kí lo rí tó jẹ́ ti ilé rẹ? Kó o síbí, níwájú àwọn arákùnrin mi àtàwọn arákùnrin rẹ, kí wọ́n sì ṣèdájọ́ láàárín àwa méjèèjì. 38  Ní gbogbo ogún (20) ọdún tí mo fi wà pẹ̀lú rẹ, oyún ò bà jẹ́+ lára àwọn àgùntàn rẹ àtàwọn ewúrẹ́ rẹ, mi ò sì jẹ nínú àwọn àgbò rẹ rí. 39  Mi ò mú ẹran èyíkéyìí tí ẹranko+ ti fà ya wá fún ọ. Èmi ni mò ń forí fá àdánù rẹ̀. Ì báà jẹ́ ọ̀sán tàbí òru ni wọ́n jí ẹran, o máa ń sọ pé kí n dí i pa dà fún ọ. 40  Oòrùn máa ń pa mí lọ́sàn-án, òtútù máa ń mú mi lóru, oorun sì máa ń dá lójú mi.+ 41  Ó ti pé ogún (20) ọdún báyìí tí mo ti wà nílé rẹ. Mo fi ọdún mẹ́rìnlá (14) sìn ọ́ torí àwọn ọmọbìnrin rẹ méjèèjì, mo sì fi ọdún mẹ́fà sìn ọ́ torí agbo ẹran rẹ, ìgbà mẹ́wàá+ lo yí ohun tó yẹ kó jẹ́ èrè mi pa dà. 42  Ká ní Ọlọ́run bàbá mi,+ Ọlọ́run Ábúráhámù àti Ẹni tí Ísákì ń bẹ̀rù*+ kò tì mí lẹ́yìn ni, ọwọ́ òfo lò bá ní kí n kúrò lọ́dọ̀ rẹ. Ọlọ́run ti rí ìyà tó ń jẹ mí àti iṣẹ́ àṣekára tí mo fi ọwọ́ mi ṣe, ìdí nìyẹn tó fi bá ọ wí lóru àná.”+ 43  Lábánì wá dá Jékọ́bù lóhùn pé: “Ọmọ mi làwọn obìnrin yìí, ọmọ mi sì làwọn ọmọ yìí, èmi ni mo ni àwọn agbo ẹran yìí, èmi àtàwọn ọmọbìnrin mi ló ni gbogbo ohun tí ò ń wò yìí. Kò sóhun búburú kankan tí mo lè ṣe sí wọn lónìí tàbí sí àwọn ọmọ tí wọ́n bí. 44  Ó yá, jẹ́ ká jọ dá májẹ̀mú, èmi àti ìwọ, ìyẹn ló máa jẹ́ ẹ̀rí láàárín wa.” 45  Jékọ́bù gbé òkúta kan, ó sì gbé e dúró bí òpó.+ 46  Jékọ́bù sọ fún àwọn arákùnrin rẹ̀ pé: “Ẹ ṣa òkúta!” Wọ́n sì ṣa òkúta, wọ́n wá kó o jọ láti fi ṣe òkìtì. Lẹ́yìn náà, wọ́n jẹun níbẹ̀ lórí òkìtì òkúta náà. 47  Lábánì sì pè é ní Jegari-sáhádútà,* ṣùgbọ́n Jékọ́bù pè é ní Gáléédì.* 48  Lẹ́yìn náà, Lábánì sọ pé: “Òkìtì yìí jẹ́ ẹ̀rí láàárín èmi àti ìwọ lónìí.” Ìdí nìyẹn tó fi pe orúkọ rẹ̀ ní Gáléédì+ 49  àti Ilé Ìṣọ́, torí ó sọ pé: “Kí Jèhófà máa ṣọ́ èmi àti ìwọ tí a ò bá sí nítòsí ara wa. 50  Tó o bá fìyà jẹ àwọn ọmọ mi, tí o sì ń fẹ́ ìyàwó lé wọn, bí èèyàn kankan ò tiẹ̀ sí pẹ̀lú wa, má gbàgbé pé Ọlọ́run ni ẹlẹ́rìí láàárín èmi àti ìwọ.” 51  Lábánì tún sọ fún Jékọ́bù pé: “Wo òkìtì òkúta yìí àti òpó tí mo gbé dúró láàárín èmi àti ìwọ. 52  Òkìtì òkúta yìí jẹ́ ẹ̀rí, òpó yìí náà sì jẹ́ ẹ̀rí,+ pé mi ò ní kọjá òkìtì yìí láti ṣe ọ́ níkà àti pé ìwọ náà ò ní kọjá òkìtì yìí láti ṣe mí níkà. 53  Kí Ọlọ́run Ábúráhámù+ àti Ọlọ́run Náhórì, Ọlọ́run bàbá wọn ṣèdájọ́ láàárín wa.” Jékọ́bù sì fi Ẹni tí Ísákì bàbá rẹ̀ ń bẹ̀rù búra.*+ 54  Lẹ́yìn náà, Jékọ́bù rúbọ lórí òkè náà, ó sì pe àwọn arákùnrin rẹ̀ pé kí wọ́n wá jẹun. Torí náà, wọ́n jẹun, wọ́n sì sun òkè náà mọ́jú. 55  Àmọ́ Lábánì jí ní àárọ̀ kùtù, ó fi ẹnu ko àwọn ọmọ ọmọ*+ rẹ̀ àti àwọn ọmọ rẹ̀ lẹ́nu, ó sì súre fún wọn.+ Lẹ́yìn náà, Lábánì kúrò níbẹ̀, ó sì pa dà sílé.+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé

Tàbí “àwọn òrìṣà ìdílé; àwọn òrìṣà.”
Ìyẹn, odò Yúfírétì.
Tàbí “mọ̀lẹ́bí.”
Ní Héb., “Ṣọ́ ara rẹ, kí o má bàa sọ ohun rere àti búburú fún Jékọ́bù.”
Ní Héb., “àwọn ọmọkùnrin.”
Ní Héb., “ohun tí obìnrin ń ṣe.”
Ní Héb., “ìbẹ̀rù Ísákì.”
Ó túmọ̀ sí “Òkìtì Ẹ̀rí” lédè Árámáíkì.
Ó túmọ̀ sí “Òkìtì Ẹ̀rí” lédè Hébérù.
Ní Héb., “fi ìbẹ̀rù Ísákì búra.”
Ní Héb., “àwọn ọmọkùnrin.”