Jẹ́nẹ́sísì 20:1-18

  • Ọlọ́run gba Sérà lọ́wọ́ Ábímélékì (1-18)

20  Ábúráhámù wá ṣí ibùdó rẹ̀ kúrò níbẹ̀+ lọ sí ilẹ̀ Négébù, ó sì ń gbé láàárín Kádéṣì+ àti Ṣúrì.+ Nígbà tó ń gbé* ní Gérárì,+  Ábúráhámù tún sọ nípa Sérà ìyàwó rẹ̀ pé: “Àbúrò mi ni.”+ Ni Ábímélékì ọba Gérárì bá ránṣẹ́ pe Sérà, ó sì mú un sọ́dọ̀.+  Lẹ́yìn náà, Ọlọ́run bá Ábímélékì sọ̀rọ̀ lójú àlá ní òru, ó sọ fún un pé: “Wò ó, o ti kú tán torí obìnrin tí o mú yìí,+ ó ti lọ́kọ, ìyàwó oníyàwó+ sì ni.”  Àmọ́ Ábímélékì kò tíì sún mọ́ ọn.* Torí náà, ó sọ pé: “Jèhófà, ṣé o máa pa orílẹ̀-èdè tí kò mọwọ́ mẹsẹ̀* run ni?  Ṣebí ọkùnrin náà sọ fún mi pé, ‘Àbúrò mi ni,’ obìnrin náà sì sọ pé, ‘Ẹ̀gbọ́n mi ni’? Òótọ́ inú ni mo fi ṣe ohun tí mo ṣe yìí, ọwọ́ mi mọ́.”  Ọlọ́run tòótọ́ sọ fún un lójú àlá pé: “Mo mọ̀ pé òótọ́ inú lo fi ṣe ohun tí o ṣe, torí ẹ̀ ni mi ò fi jẹ́ kí o dẹ́ṣẹ̀ sí mi. Ìdí nìyẹn tí mi ò fi jẹ́ kí o fọwọ́ kàn án.  Dá ìyàwó ọkùnrin náà pa dà, torí wòlíì+ ni, ó máa bá ọ bẹ̀bẹ̀,+ o ò sì ní kú. Àmọ́ tí o kò bá dá a pa dà, ó dájú pé wàá kú, ìwọ àti gbogbo àwọn tó jẹ́ tìrẹ.”  Ábímélékì jí ní àárọ̀ kùtù, ó pe gbogbo àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀, ó sọ gbogbo nǹkan yìí fún wọn, ẹ̀rù sì bà wọ́n gan-an.  Ábímélékì wá pe Ábúráhámù, ó sì sọ fún un pé: “Kí lo ṣe sí wa yìí? Ẹ̀ṣẹ̀ wo ni mo ṣẹ̀ ọ́, tí o fi fẹ́ fi ìyà ẹ̀ṣẹ̀ tó pọ̀ tó báyìí jẹ èmi àti àwọn èèyàn mi? Ohun tí o ṣe sí mi yìí ò dáa.” 10  Ábímélékì bi Ábúráhámù pé: “Kí lo ní lọ́kàn tó o fi ṣe báyìí?”+ 11  Ábúráhámù fèsì pé: “Èrò mi ni pé, ‘Ó dájú pé àwọn èèyàn tó wà níbí kò bẹ̀rù Ọlọ́run, wọ́n á sì pa mí torí ìyàwó+ mi.’ 12  Àbúrò mi ni lóòótọ́ o, bàbá kan náà ló bí wa, àmọ́ a kì í ṣọmọ ìyá kan náà, mo sì mú un ṣaya.+ 13  Torí náà, nígbà tí Ọlọ́run mú kí n kúrò ní ilé bàbá mi,+ mo sọ fún un pé: ‘Bí o ṣe máa fi hàn pé ìfẹ́ tí kì í yẹ̀ lo ní sí mi nìyí: Gbogbo ibi tí a bá lọ, máa sọ nípa mi pé, “Ẹ̀gbọ́n mi ni.”’”+ 14  Ìgbà náà ni Ábímélékì mú àwọn àgùntàn àti màlúù pẹ̀lú àwọn ìránṣẹ́ lọ́kùnrin àti lóbìnrin, ó kó wọn fún Ábúráhámù, ó sì dá Sérà ìyàwó rẹ̀ pa dà fún un. 15  Ábímélékì tún sọ pé: “Ilẹ̀ mi nìyí. Ibi tó bá wù ọ́ ni kó o máa gbé níbẹ̀.” 16  Ó sì sọ fún Sérà pé: “Mo fún ẹ̀gbọ́n+ rẹ ní ẹgbẹ̀rún (1,000) ẹyọ fàdákà. Ó jẹ́ àmì pé o ò mọwọ́ mẹsẹ̀* lójú gbogbo àwọn tó wà pẹ̀lú rẹ àti lójú gbogbo èèyàn, wọn ò sì ní pẹ̀gàn rẹ mọ́.” 17  Ábúráhámù bẹ̀rẹ̀ sí í rawọ́ ẹ̀bẹ̀ sí Ọlọ́run tòótọ́, Ọlọ́run sì mú Ábímélékì àti ìyàwó rẹ̀ lára dá, pẹ̀lú àwọn ẹrúbìnrin rẹ̀, wọ́n sì wá ń bímọ; 18  nítorí Jèhófà ti mú kí gbogbo obìnrin ilé Ábímélékì di àgàn* torí Sérà, ìyàwó+ Ábúráhámù.

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé

Tàbí “tó jẹ́ àjèjì.”
Ìyẹn ni pé, kò tíì bá a ní àṣepọ̀.
Tàbí “tó jẹ́ olódodo.”
Ní Héb., “Ìbòjú ló jẹ́ fún ọ.”
Tàbí “ti sé gbogbo ilé ọlẹ̀ pa ní ilé Ábímélékì.”