Hósíà 9:1-17

  • Ẹ̀ṣẹ̀ Éfúrémù mú kí Ọlọ́run kọ̀ ọ́ (1-17)

    • Wọ́n fi ara wọn fún ọlọ́run tó ń tini lójú (10)

9  “Má ṣe yọ̀, ìwọ Ísírẹ́lì,+Má sì dunnú bí àwọn èèyàn. Nítorí pé ìṣekúṣe* ti mú ọ kúrò lọ́dọ̀ Ọlọ́run rẹ.+ O ti nífẹ̀ẹ́ owó iṣẹ́ aṣẹ́wó lórí gbogbo ibi ìpakà.+  2  Àmọ́ ibi ìpakà àti ibi tí wọ́n ti ń fún wáìnì kò ní fún wọn lóúnjẹ,Wáìnì tuntun á sì já wọn kulẹ̀.+  3  Wọn kò ní gbé ilẹ̀ Jèhófà mọ́;+Kàkà bẹ́ẹ̀, Éfúrémù á pa dà sí Íjíbítì,Wọ́n á sì jẹ ohun àìmọ́ ní Ásíríà.+  4  Wọn ò ní da ọrẹ wáìnì jáde sí Jèhófà mọ́;+Àwọn ẹbọ wọn kò sì ní mú inú rẹ̀ dùn.+ Wọ́n dà bí oúnjẹ ọ̀fọ̀;Gbogbo àwọn tó bá jẹ ẹ́ á sọ ara wọn di ẹlẹ́gbin. Nítorí àwọn nìkan* ni oúnjẹ wọn wà fún;Kò ní wọ ilé Jèhófà.  5  Kí lẹ ó ṣe ní ọjọ́ ìpàdé,*Ní ọjọ́ àjọyọ̀ Jèhófà?  6  Wò ó! wọ́n á ní láti sá lọ nítorí ìparun.+ Íjíbítì á kó wọn jọ,+ Mémúfísì á sì sin wọ́n.+ Èsìsì ló máa bo àwọn ohun iyebíye tí wọ́n fi fàdákà ṣe,Àwọn igi ẹlẹ́gùn-ún á sì wà nínú àgọ́ wọn.  7  Àkókò ìbẹ̀wò á dé,+Àkókò ìjìyà á sì dé,Ísírẹ́lì á mọ̀ nípa rẹ̀. Wòlíì wọn á ya òmùgọ̀, ọkùnrin tó ní ìmísí á sì ya wèrè;Ìkórìíra tí wọ́n ní sí ọ pọ̀, nítorí ẹ̀ṣẹ̀ rẹ pọ̀.”  8  Nígbà kan rí, olùṣọ́ + Éfúrémù ń gbọ́ ti Ọlọ́run mi.+ Àmọ́ ní báyìí, ọ̀nà àwọn wòlíì rẹ̀+ dà bíi pańpẹ́ pẹyẹpẹyẹ;Ìkórìíra wà ní ilé Ọlọ́run rẹ̀.  9  Wọ́n ti lọ jìnnà nínú fífa ìparun, bíi ti ìgbà àwọn ará Gíbíà.+ Ó máa rántí ẹ̀ṣẹ̀ wọn, á sì fìyà jẹ wọ́n nítorí ẹ̀ṣẹ̀ wọn.+ 10  “Mo rí Ísírẹ́lì bí ẹni rí èso àjàrà ní aginjù.+ Mo rí àwọn baba ńlá rẹ̀ bí ẹni rí àkọ́so igi ọ̀pọ̀tọ́. Àmọ́ wọ́n lọ bá Báálì Péórì;+Wọ́n fi ara wọn fún ohun ìtìjú,*+Wọ́n di ohun ìríra, wọ́n sì wá dà bí ohun tí wọ́n nífẹ̀ẹ́. 11  Ògo Éfúrémù fò lọ bí ẹyẹ;Kò ní bímọ, kò ní lóyún, kódà ọlẹ̀ kò ní sọ nínú rẹ̀.+ 12  Bí wọ́n tilẹ̀ tọ́ ọmọ wọn dàgbà,Màá pa wọ́n, tí kò fi ní ku ìkankan;+Nígbà tí mo bá pa dà lẹ́yìn wọn, wọ́n gbé!+ 13  Éfúrémù tí a gbìn sí ibi ìjẹko, dà bíi Tírè+ sí mi;Ní báyìí, Éfúrémù gbọ́dọ̀ kó àwọn ọmọ rẹ̀ jáde fún pípa.” 14  Fún wọn ní ohun tó yẹ kí o fún wọn, Jèhófà;Fún wọn ní ilé ọmọ tí kò lè gba oyún dúró àti ọmú gbígbẹ.* 15  “Gílígálì + ni gbogbo ìwà ibi wọn ti ṣẹlẹ̀, ibẹ̀ ni mo ti kórìíra wọn. Màá lé wọn kúrò ní ilé mi nítorí iṣẹ́ ibi wọn.+ Mi ò ní nífẹ̀ẹ́ wọn mọ́;+Gbogbo olórí wọn ya alágídí. 16  A ó gé Éfúrémù lulẹ̀ bí igi.+ Gbòǹgbò wọn á gbẹ dà nù, wọn ò sì ní lè so èso kankan. Bí wọ́n tilẹ̀ bímọ, màá pa àwọn ọmọ wọn tí wọ́n fẹ́ràn.” 17  Ọlọ́run mi yóò kọ̀ wọ́n,Torí wọn kò fetí sí i,+Wọ́n á sì di ìsáǹsá láàárín àwọn orílẹ̀-èdè.+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé

^ Tàbí “iṣẹ́ aṣẹ́wó.”
^ Tàbí “ọkàn wọn nìkan.”
^ Tàbí “ní ọjọ́ àsè tí ẹ yàn.”
^ Tàbí “ọlọ́run tó ń tini lójú.”
^ Tàbí “pẹlẹbẹ.”