Hósíà 8:1-14
8 “Fi ìwo sí ẹnu rẹ!+
Ọ̀tá kan ń bọ̀ bí ẹyẹ idì sí ilé Jèhófà,+Torí pé wọ́n ti da májẹ̀mú mi,+ wọ́n sì ti rú òfin mi.+
2 Wọ́n ké pè mí, wọ́n ní ‘Ọlọ́run wa, àwa Ísírẹ́lì ti mọ̀ ọ́!’+
3 Ísírẹ́lì ti kọ ohun rere sílẹ̀.+
Kí ọ̀tá máa lépa rẹ̀.
4 Wọ́n ti fi àwọn ọba jẹ, ṣùgbọ́n kì í ṣe láti ọ̀dọ̀ mi.
Wọ́n ti yan àwọn ìjòyè, ṣùgbọ́n èmi kò fọwọ́ sí i.
Wọ́n ti fi fàdákà wọn àti wúrà wọn ṣe àwọn òrìṣà,+Kí wọ́n lè pa run.+
5 Mo ti kọ ọmọ màlúù rẹ sílẹ̀, ìwọ Samáríà.+
Mo bínú sí yín gidigidi.+
Ìgbà wo lẹ máa tó jáwọ́ nínú ìwà àìmọ́?
6 Torí láti Ísírẹ́lì ni èyí ti wá.
Ohun tí oníṣẹ́ ọnà ṣe ni, kì í ṣe Ọlọ́run;Ọmọ màlúù Samáríà yóò di èérún.
7 Nítorí afẹ́fẹ́ ni wọ́n ń gbìn,Ìjì sì ni wọ́n máa ká.+
Kò sí pòròpórò kankan tó ní ọkà tí ó gbó;*+Ohunkóhun tó bá hù kò ní so èso tó wúlò fún ìyẹ̀fun.
Bí èyíkéyìí bá sì so, àwọn àjèjì* yóò gbé e mì.+
8 Ọ̀tá ló máa gbé Ísírẹ́lì mì.+
Wọ́n á wà láàárín àwọn orílẹ̀-èdè,+Bí ohun èlò tí kò wúlò.
9 Nítorí wọ́n ti lọ sí Ásíríà,+ bíi kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ inú igbó tó dá wà.
Éfúrémù ti lọ gba àwọn aṣẹ́wó láti fi ṣe olólùfẹ́.+
10 Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àárín àwọn orílẹ̀-èdè ni wọ́n ti gbà wọ́n,Màá kó àwọn náà jọ;Wọ́n á bẹ̀rẹ̀ sí í jìyà+ nítorí ẹrù tí ọba àti àwọn ìjòyè dì lé wọn.
11 Torí Éfúrémù ti mọ pẹpẹ púpọ̀ kó lè máa dẹ́ṣẹ̀.+
Àwọn pẹpẹ náà ló sì fi ń dẹ́ṣẹ̀.+
12 Mo kọ ohun púpọ̀ nípa òfin* mi fún un,Àmọ́ ohun àjèjì ni wọ́n kà wọ́n sí.+
13 Wọ́n ń fi ẹran rúbọ sí mi, wọ́n sì jẹ ẹran náà,Ṣùgbọ́n inú Jèhófà kò dùn sí ẹbọ wọn.+
Ó máa rántí ẹ̀ṣẹ̀ wọn, á sì fìyà jẹ wọ́n nítorí ẹ̀ṣẹ̀ wọn.+
Wọ́n ti yíjú* sí Íjíbítì.+
14 Ísírẹ́lì ti gbàgbé Ẹni Tó Dá A,+ ó sì ti kọ́ àwọn tẹ́ńpìlì,+Júdà ti kọ́ ìlú olódi púpọ̀.+
Àmọ́ màá sọ iná sí àwọn ìlú rẹ̀,Á sì jó àwọn ilé gogoro ìlú kọ̀ọ̀kan run.”+

