Hósíà 6:1-11

  • Ẹ jẹ́ ká pa dà sọ́dọ̀ Jèhófà (1-3)

  • Ìfẹ́ tí kì í yẹ̀ tí àwọn èèyàn náà ní tètè ń pòórá (4-6)

    • Ìfẹ́ tí kì í yẹ̀ sàn ju ẹbọ lọ (6)

  • Ìwà àìnítìjú tí àwọn èèyàn náà hù (7-11)

6  “Ẹ wá, ẹ jẹ́ kí a pa dà sọ́dọ̀ Jèhófà,Torí ó ti fà wá ya pẹ́rẹpẹ̀rẹ,+ ṣùgbọ́n á mú wa lára dá. Ó ti kọ lù wá, ṣùgbọ́n á di ọgbẹ́ wa.  2  Á mú wa sọ jí lẹ́yìn ọjọ́ méjì. Á gbé wa dìde ní ọjọ́ kẹta,A ó sì máa wà láàyè níwájú rẹ̀.  3  A ó mọ Jèhófà, a ó sì fi ìtara wá ìmọ̀ rẹ̀. Jíjáde rẹ̀ dájú bí àfẹ̀mọ́jú;Yóò wá bá wa bí ọ̀wààrà òjò,Bí òjò ìgbà ìrúwé tó máa ń rin ilẹ̀.”  4  “Kí ni màá ṣe sí ọ̀rọ̀ rẹ, ìwọ Éfúrémù? Kí ni màá sì ṣe sí ọ̀rọ̀ rẹ, ìwọ Júdà? Nítorí ìfẹ́ tí kì í yẹ̀ tí o sọ pé o ní dà bí ìkùukùu òwúrọ̀,Àti bí ìrì tó tètè ń pòórá.  5  Ìdí nìyẹn tí màá fi gé wọn lulẹ̀ nípasẹ̀ àwọn wòlíì;+Màá fi ọ̀rọ̀ ẹnu mi pa wọ́n.+ Ìdájọ́ lórí wọn yóò sì tàn bí ìmọ́lẹ̀.+  6  Nítorí pé ìfẹ́ tí kì í yẹ̀* ni inú mi dùn sí, kì í ṣe ẹbọÀti ìmọ̀ nípa Ọlọ́run dípò odindi ẹbọ sísun.+  7  Ṣùgbọ́n bí èèyàn lásán-làsàn, wọ́n ti tẹ májẹ̀mú lójú.+ Wọ́n ti hùwà àìṣòótọ́ sí mi ní ilẹ̀ wọn.  8  Gílíádì jẹ́ ìlú àwọn aṣebi,+Ìtàjẹ̀sílẹ̀ pọ̀ níbẹ̀.+  9  Ẹgbẹ́ àwọn àlùfáà dà bí àwọn jàǹdùkú* tó lúgọ de ẹnì kan. Wọ́n ń pa èèyàn lójú ọ̀nà ní Ṣékémù,+Torí pé ìwà àìnítìjú ni wọ́n ń hù. 10  Mo ti rí ohun tó burú jáì ní ilé Ísírẹ́lì. Éfúrémù ń ṣe ìṣekúṣe níbẹ̀;+Ísírẹ́lì ti sọ ara rẹ̀ di ẹlẹ́gbin.+ 11  Àmọ́, ìwọ Júdà, a ti dá àkókò ìkórè fún ọ,Nígbà tí mo bá kó àwọn èèyàn mi tó wà ní oko ẹrú pa dà.”+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé

^ Tàbí “àánú.”
^ Tàbí “àwọn akónilẹ́rù.”