Hósíà 4:1-19

  • Jèhófà pe Ísírẹ́lì lẹ́jọ́ (1-8)

    • Kò sí ìmọ̀ Ọlọ́run ní ilẹ̀ náà (1)

  • Ísírẹ́lì bọ̀rìṣà, ó sì ṣe ìṣekúṣe (9-19)

    • Ẹ̀mí ìṣekúṣe mú kí wọ́n ṣìnà (12)

4  Ẹ gbọ́ ọ̀rọ̀ Jèhófà, ẹ̀yin èèyàn Ísírẹ́lì,Jèhófà yóò pe àwọn tó ń gbé ilẹ̀ náà lẹ́jọ́,+Nítorí kò sí òtítọ́ tàbí ìfẹ́ tí kì í yẹ̀ ní ilẹ̀ náà, bẹ́ẹ̀ ni kò sí ìmọ̀ Ọlọ́run.+  2  Ìbúra èké, irọ́ pípa+ àti ìpànìyàn+Olè jíjà àti àgbèrè+ ti gbilẹ̀,Ìtàjẹ̀sílẹ̀ ń gorí ìtàjẹ̀sílẹ̀.+  3  Ìdí nìyẹn tí ilẹ̀ náà á fi ṣọ̀fọ̀+Tí gbogbo àwọn tó ń gbé orí rẹ̀ á sì gbẹ dà nù;Àwọn ẹran inú igbó àti ẹyẹ ojú ọ̀run,Àní títí kan àwọn ẹja inú òkun, yóò ṣègbé.  4  “Àmọ́, kí ẹnikẹ́ni má ṣe bá wọn jiyàn tàbí kó bá wọn wí,+Torí àwọn èèyàn rẹ dà bí àwọn tó ń bá àlùfáà jiyàn.+  5  Torí náà, wọ́n á fẹsẹ̀ kọ ní ọ̀sán gangan,Wòlíì á sì fẹsẹ̀ kọ pẹ̀lú wọn, bíi pé alẹ́ ni. Màá sì pa ìyá wọn lẹ́nu mọ́.*  6  A ó pa àwọn èèyàn mi lẹ́nu mọ́,* torí pé wọn kò ní ìmọ̀. Nítorí pé wọ́n ti kọ̀ láti mọ̀ mí,+Èmi náà á kọ̀ wọ́n pé kí wọ́n má ṣe àlùfáà mi mọ́;Àti nítorí pé wọ́n gbàgbé òfin* Ọlọ́run wọn,+Èmi náà á gbàgbé àwọn ọmọ wọn.  7  Bí wọ́n ṣe ń pọ̀ sí i, bẹ́ẹ̀ ni wọ́n ṣe túbọ̀ ń ṣẹ̀ mí.+ Màá sọ ògo wọn di ìtìjú.*  8  Wọ́n* ń bọ́ ara wọn nípasẹ̀ ẹ̀ṣẹ̀ àwọn èèyàn mi,Àṣìṣe wọn ni wọ́n sì ń fẹ́.*  9  Bó ṣe rí fún àwọn èèyàn náà ló ṣe máa rí fún àwọn àlùfáà;Màá pè wọ́n wá jíhìn nítorí ìwà wọn,Màá sì san èrè iṣẹ́ wọn pa dà fún wọn.+ 10  Wọ́n á jẹun, ṣùgbọ́n wọn kò ní yó.+ Wọ́n á di oníṣekúṣe,* síbẹ̀ wọn kò ní rí ọmọ bí,+Torí pé wọn kò bọ̀wọ̀ fún Jèhófà. 11  Ìṣekúṣe* àti wáìnì àti wáìnì tuntunMáa ń mú èrò rere kúrò lọ́kàn ẹni.*+ 12  Àwọn èèyàn mi ń wádìí lọ́dọ̀ àwọn òrìṣà tí wọ́n fi igi ṣe,Wọ́n ń ṣe ohun tí ọ̀pá* wọn sọ fún wọn;Nítorí pé ẹ̀mí ìṣekúṣe* ti mú kí wọ́n ṣìnà,Ìṣekúṣe* wọn ni kò jẹ́ kí wọ́n tẹrí ba fún Ọlọ́run wọn. 13  Orí àwọn òkè ńlá ni wọ́n ti ń rúbọ,+Orí àwọn òkè kéékèèké ni wọ́n sì ti ń mú àwọn ẹbọ rú èéfín,Lábẹ́ àwọn igi ràgàjì* àti àwọn igi tórásì àti onírúurú igi ńlá,+Torí pé ibòji àwọn igi náà dára. Ìdí nìyẹn tí àwọn ọmọbìnrin yín fi ń ṣe ìṣekúṣe*Tí aya àwọn ọmọ yín sì ń ṣe àgbèrè. 14  Èmi kì yóò mú kí àwọn ọmọbìnrin yín jíhìn torí pé wọ́n ṣe ìṣekúṣe*Àti aya àwọn ọmọ yín torí pé wọ́n ṣe àgbèrè. Nítorí pé àwọn ọkùnrin yín ń bá àwọn aṣẹ́wó kẹ́gbẹ́Wọ́n sì ń rúbọ pẹ̀lú àwọn aṣẹ́wó tẹ́ńpìlì;Àwọn èèyàn tí kò lóye+ yìí yóò pa run. 15  Bí o tilẹ̀ ń ṣe ìṣekúṣe,* ìwọ Ísírẹ́lì,+Má ṣe jẹ́ kí Júdà jẹ̀bi.+ Má ṣe wá sí Gílígálì+ tàbí Bẹti-áfénì,+Má sì ṣe búra pé, ‘Bí Jèhófà ti wà láàyè!’+ 16  Nítorí Ísírẹ́lì ti di alágídí bíi màlúù tó lágídí.+ Ǹjẹ́ Jèhófà yóò ṣe olùṣọ́ àgùntàn wọn bí ọmọ àgbò nínú ibi ìjẹko tó tẹ́jú?* 17  Éfúrémù ti dara pọ̀ mọ́ àwọn òrìṣà.+ Ẹ fi í sílẹ̀! 18  Nígbà tí ọtí bíà wọn* tán,Wọ́n di oníṣekúṣe.* Àwọn alákòóso* rẹ̀ sì nífẹ̀ẹ́ àbùkù.+ 19  Afẹ́fẹ́ yóò gbá a lọ,Àwọn ẹbọ wọn yóò sì kó ìtìjú bá wọn.”

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé

^ Tàbí “pa ìyá wọn run.”
^ Tàbí “pa àwọn èèyàn mi run.”
^ Tàbí “ìtọ́ni.”
^ Tàbí kó jẹ́, “Wọ́n ti fi ìtìjú rọ́pò ògo mi.”
^ Ìyẹn, àwọn àlùfáà.
^ Tàbí “gbé ọkàn sókè sí.” Wo Àlàyé Ọ̀rọ̀, “Ọkàn.”
^ Tàbí “oníṣekúṣe paraku; aṣẹ́wó.”
^ Ní Héb., “ń mú ọkàn kúrò.”
^ Tàbí “Iṣẹ́ aṣẹ́wó.”
^ Tàbí “ọ̀pá woṣẹ́woṣẹ́.”
^ Tàbí “iṣẹ́ aṣẹ́wó.”
^ Tàbí “Iṣẹ́ aṣẹ́wó.”
^ Tàbí “igi óákù.”
^ Tàbí “iṣẹ́ aṣẹ́wó.”
^ Tàbí “iṣẹ́ aṣẹ́wó.”
^ Tàbí “iṣẹ́ aṣẹ́wó.”
^ Ní Héb., “ibi aláyè gbígbòòrò?”
^ Tàbí “bíà tí wọ́n fi wíìtì ṣe.”
^ Tàbí “oníṣekúṣe paraku; aṣẹ́wó.”
^ Ní Héb., “Àwọn apata.”