Hósíà 12:1-14

  • Éfúrémù ní láti pa dà sọ́dọ̀ Jèhófà (1-14)

    • Jékọ́bù bá Ọlọ́run jà (3)

    • Jékọ́bù sunkún kó lè rí ojú rere Ọlọ́run (4)

12  “Ẹ̀fúùfù ni Éfúrémù fi ṣe oúnjẹ. Ó sì ń sá tẹ̀ lé ẹ̀fúùfù ìlà oòrùn láti àárọ̀ ṣúlẹ̀. Ó mú kí irọ́ àti ìwà ipá pọ̀ sí i. Ó bá Ásíríà dá májẹ̀mú,+ ó sì gbé òróró lọ sí Íjíbítì.+   Jèhófà máa pe Júdà lẹ́jọ́;+Ó máa pe Jékọ́bù wá jíhìn nítorí àwọn ọ̀nà rẹ̀,Ó sì máa san án lẹ́san àwọn iṣẹ́ ọwọ́ rẹ̀.+   Nígbà tó wà nínú ìyá rẹ̀, ó gbá arákùnrin rẹ̀ mú ní gìgísẹ̀,+Ó sì fi gbogbo okun rẹ̀ bá Ọlọ́run wọ̀jà.+   Ó bá áńgẹ́lì kan jà títí ó fi borí. Ó sunkún, ó sì bẹ̀ ẹ́ pé kó ṣojúure sí òun.”+ Ọlọ́run rí i ní Bẹ́tẹ́lì, ibẹ̀ ni Ó sì ti bá wa sọ̀rọ̀,+   Jèhófà Ọlọ́run àwọn ọmọ ogun+ ni,Jèhófà sì ni orúkọ tí a fi ń rántí rẹ̀.*+   “Torí náà, pa dà sọ́dọ̀ Ọlọ́run rẹ,+Má ṣe jẹ́ kí ìfẹ́ tí kì í yẹ̀ àti ìdájọ́ òdodo bọ́ mọ́ ẹ lọ́wọ́,+Sì máa ní ìrètí nínú Ọlọ́run rẹ nígbà gbogbo.   Àmọ́ ọwọ́ oníṣòwò* ni òṣùwọ̀n ẹ̀tàn wà;Ó fẹ́ràn lílu jìbìtì.+   Éfúrémù ń sọ pé, ‘Ní tòótọ́, mo ti di ọlọ́rọ̀;+Mo ti ní ọrọ̀.+ Nínú gbogbo làálàá mi, wọn ò ní rí àìtọ́ tàbí ẹ̀ṣẹ̀ kankan.’   Ṣùgbọ́n èmi ni Jèhófà Ọlọ́run rẹ láti ilẹ̀ Íjíbítì wá.+ Màá tún mú kí o máa gbé inú àwọn àgọ́Bí ìgbà àkókò tí a ti yàn.* 10  Mo bá àwọn wòlíì sọ̀rọ̀,+Mo mú kí ìran tí wọ́n rí pọ̀ sí i,Mo sì tipasẹ̀ àwọn wòlíì ṣe àkàwé. 11  Ẹ̀tàn*+ àti àìṣòótọ́ ti wà ní Gílíádì. Wọ́n ti fi àwọn akọ màlúù rúbọ ní Gílígálì,+Àwọn pẹpẹ wọn sì dà bí àwọn òkúta tí a tò jọ sí àárín àwọn ebè inú oko.+ 12  Jékọ́bù sá lọ sí agbègbè* Árámù;*+Ísírẹ́lì+ ṣiṣẹ́ níbẹ̀ nítorí àtifẹ́ ìyàwó,+Ó sì ń da àgùntàn nítorí ìyàwó.+ 13  Jèhófà tipasẹ̀ wòlíì kan mú Ísírẹ́lì jáde kúrò ní Íjíbítì,+Ó sì fi wòlíì kan ṣọ́ ọ.+ 14  Éfúrémù ti dá ẹ̀ṣẹ̀ tó burú jáì;+Ẹ̀bi ẹ̀jẹ̀ tó ta sílẹ̀ wà lórí rẹ̀;Olúwa rẹ̀ á sì san án lẹ́san ẹ̀gàn rẹ̀.”+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé

Tàbí “orúkọ ìrántí rẹ̀.”
Tàbí “olówò.”
Tàbí kó jẹ́, “àjọyọ̀.”
Tàbí “Ohun abàmì; Ohun àdììtú.”
Tàbí “Síríà.”
Ní Héb., “ilẹ̀.”