Sí Àwọn Ará Gálátíà 4:1-31
4 Ní báyìí, mo sọ pé nígbà tí ajogún náà bá ṣì jẹ́ ọmọdé, kò yàtọ̀ sí ẹrú, bó tilẹ̀ jẹ́ olúwa ohun gbogbo,
2 àmọ́ ó wà lábẹ́ àwọn alábòójútó àti àwọn ìríjú títí di ọjọ́ tí bàbá rẹ̀ ti yàn.
3 Bákan náà, ní tiwa, nígbà tí a wà lọ́mọdé, àwọn èrò àti ìṣe ayé* ń mú wa lẹ́rú.+
4 Àmọ́ nígbà tí àkókò tó, Ọlọ́run rán Ọmọ rẹ̀, ẹni tí obìnrin bí,+ tí ó sì wà lábẹ́ òfin,+
5 kí ó lè ra àwọn tó wà lábẹ́ òfin,+ kí ó sì tipa bẹ́ẹ̀ tú wọn sílẹ̀, kí a lè rí ìsọdọmọ gbà.+
6 Nítorí pé ẹ jẹ́ ọmọ, Ọlọ́run ti rán ẹ̀mí+ Ọmọ rẹ̀ sínú ọkàn wa,+ ó sì ń ké jáde pé: “Ábà,* Bàbá!”+
7 Torí náà, ẹ kì í ṣe ẹrú mọ́, ọmọ ni yín; tí ẹ bá sì jẹ́ ọmọ, ẹ tún jẹ́ ajogún nípasẹ̀ Ọlọ́run.+
8 Síbẹ̀, nígbà tí ẹ kò mọ Ọlọ́run, ẹ̀ ń ṣẹrú àwọn tí kì í ṣe ọlọ́run.
9 Àmọ́ ní báyìí tí ẹ ti mọ Ọlọ́run, tàbí ká kúkú sọ pé, tí Ọlọ́run ti mọ̀ yín, kí ló dé tí ẹ tún ń pa dà sí àwọn ohun àkọ́bẹ̀rẹ̀ tó jẹ́ aláìlera+ àti aláìníláárí,* tí ẹ sì tún fẹ́ ṣẹrú wọn?+
10 Ẹ̀ ń pa àwọn ọjọ́ àti oṣù+ àti àsìkò àti ọdún mọ́ délẹ̀délẹ̀.
11 Ẹ̀rù ń bà mí nítorí yín, kó má lọ jẹ́ pé lásán ni gbogbo wàhálà tí mo ṣe lórí yín.
12 Ẹ̀yin ará, mo bẹ̀ yín, ẹ dà bí èmi, nítorí èmi náà ti máa ń ṣe bíi tiyín tẹ́lẹ̀.+ Ẹ ò ṣe àìtọ́ kankan sí mi.
13 Ṣùgbọ́n ẹ mọ̀ pé àìsàn tó ṣe mí ló jẹ́ kí n kọ́kọ́ láǹfààní láti kéde ìhìn rere fún yín.
14 Bó tiẹ̀ jẹ́ pé àdánwò ni àìlera mi jẹ́ fún yín, ẹ ò fojú pa mí rẹ́, ẹ ò sì kórìíra mi;* àmọ́ ṣe lẹ gbà mí bí áńgẹ́lì Ọlọ́run, bíi Kristi Jésù.
15 Ibo ni ayọ̀ tí ẹ ní tẹ́lẹ̀ wà? Nítorí mo jẹ́rìí yín pé, ká ló ṣeé ṣe ni, ẹ lè yọ ojú yín fún mi.+
16 Ṣé mo ti wá di ọ̀tá yín torí pé mo sọ òótọ́ fún yín ni?
17 Àwọn kan ń wá ọ̀nà lójú méjèèjì láti fà yín sábẹ́ ara wọn, àmọ́ kì í ṣe fún ire yín; ṣe ni wọ́n fẹ́ fà yín kúrò lọ́dọ̀ mi, kó lè máa yá yín lára láti tẹ̀ lé wọn.
18 Síbẹ̀, ó dáa tí ẹnì kan bá ń wá yín lójú méjèèjì fún ire yín, tí kì í ṣe nígbà tí mo bá wà lọ́dọ̀ yín nìkan,
19 ẹ̀yin ọmọ mi kéékèèké,+ tí mo tún tìtorí yín wà nínú ìrora ìbímọ títí ẹ ó fi lè gbé Kristi yọ* nínú yín.
20 Ó wù mí kí n wà lọ́dọ̀ yín ní báyìí, kí n sì sọ̀rọ̀ lọ́nà tó yàtọ̀, torí ọkàn mi ń dààmú nítorí yín.
21 Ẹ sọ fún mi, ẹ̀yin tí ẹ fẹ́ wà lábẹ́ òfin, Ṣé ẹ ò gbọ́ ohun tí Òfin sọ ni?
22 Bí àpẹẹrẹ, ó wà lákọsílẹ̀ pé Ábúráhámù ní ọmọkùnrin méjì, ọ̀kan látọ̀dọ̀ ìránṣẹ́bìnrin,+ èkejì látọ̀dọ̀ obìnrin tó lómìnira;+
23 àmọ́ èyí tí ìránṣẹ́bìnrin bí jẹ́ lọ́nà ti ẹ̀dá,*+ èyí tí obìnrin tó lómìnira sì bí jẹ́ nípasẹ̀ ìlérí.+
24 A lè fi àwọn nǹkan yìí ṣe àkàwé; àwọn obìnrin yìí dúró fún májẹ̀mú méjì, èyí tó wá láti Òkè Sínáì,+ tó ń bí ọmọ fún ìsìnrú, ni Hágárì.
25 Hágárì dúró fún Sínáì,+ òkè kan ní Arébíà, ó sì ṣe rẹ́gí pẹ̀lú Jerúsálẹ́mù ti òní, torí ó ń ṣẹrú pẹ̀lú àwọn ọmọ rẹ̀.
26 Àmọ́ Jerúsálẹ́mù ti òkè ní òmìnira, òun sì ni ìyá wa.
27 Nítorí ó wà lákọsílẹ̀ pé: “Máa yọ̀ ṣẹ̀ṣẹ̀, ìwọ àgàn tí kò bímọ; bú sígbe ayọ̀, ìwọ obìnrin tí kò ní ìrora ìbímọ; nítorí àwọn ọmọ obìnrin tó ti di ahoro pọ̀ ju ti obìnrin tó ní ọkọ lọ.”+
28 Tóò, ẹ̀yin ará, ẹ̀yin náà jẹ́ ọmọ ìlérí bí Ísákì ṣe jẹ́.+
29 Àmọ́ bó ṣe rí nígbà yẹn tí èyí tí a bí lọ́nà ti ẹ̀dá* bẹ̀rẹ̀ sí í ṣe inúnibíni sí èyí tí a bí lọ́nà ti ẹ̀mí,+ bẹ́ẹ̀ náà ló ṣe rí ní báyìí.+
30 Síbẹ̀, kí ni ìwé mímọ́ sọ? “Lé ìránṣẹ́bìnrin náà àti ọmọkùnrin rẹ̀ jáde, nítorí ọmọ ìránṣẹ́bìnrin náà kò ní bá ọmọ obìnrin tó lómìnira pín ogún lọ́nàkọnà.”+
31 Nítorí náà, ẹ̀yin ará, a kì í ṣe ọmọ ìránṣẹ́bìnrin, ọmọ obìnrin tó lómìnira ni wá.

