Sí Àwọn Ará Gálátíà 1:1-24

  • Ìkíni (1-5)

  • Kò sí ìhìn rere míì (6-9)

  • Ọ̀dọ̀ Ọlọ́run ni ìhìn rere tí Pọ́ọ̀lù ń wàásù ti wá (10-12)

  • Bí Pọ́ọ̀lù ṣe yí pa dà àti àwọn ohun tó kọ́kọ́ ṣe (13-24)

1  Pọ́ọ̀lù, àpọ́sítélì, tí kì í ṣe látọwọ́ àwọn èèyàn tàbí nípasẹ̀ èèyàn kan, bí kò ṣe nípasẹ̀ Jésù Kristi+ àti Ọlọ́run tó jẹ́ Baba,+ ẹni tó gbé e dìde kúrò nínú ikú  àti gbogbo àwọn ará tó wà pẹ̀lú mi, sí àwọn ìjọ tó wà ní Gálátíà:  Kí inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí àti àlàáfíà látọ̀dọ̀ Ọlọ́run, Baba wa àti Jésù Kristi Olúwa wà pẹ̀lú yín.  Ó fi ara rẹ̀ lélẹ̀ nítorí àwọn ẹ̀ṣẹ̀ wa,+ kó lè gbà wá sílẹ̀ nínú ètò àwọn nǹkan* búburú ìsinsìnyí,+ gẹ́gẹ́ bí ìfẹ́ Ọlọ́run àti Baba wa,+  ẹni tí ògo jẹ́ tirẹ̀ títí láé àti láéláé. Àmín.  Ó yà mí lẹ́nu pé ẹ ti sáré yà kúrò* lọ́dọ̀ Ẹni tó fi inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí Kristi pè yín, ẹ sì ń lọ sínú oríṣi ìhìn rere míì.+  Kì í kúkú ṣe pé ìhìn rere míì wà; àmọ́ àwọn kan wà tó ń dá wàhálà sílẹ̀ fún yín,+ tí wọ́n sì fẹ́ yí ìhìn rere nípa Kristi po.  Àmọ́ ṣá o, bí àwa tàbí áńgẹ́lì kan láti ọ̀run bá kéde ohun kan fún yín pé ó jẹ́ ìhìn rere, àmọ́ tó yàtọ̀ sí ìhìn rere tí a ti kéde fún yín, kí ó di ẹni ègún.  Bí a ṣe sọ ṣáájú, mo tún ń sọ ọ́ báyìí pé, Ẹnikẹ́ni tí ì báà jẹ́ tó bá ń kéde ohun kan fún yín pé ó jẹ́ ìhìn rere, àmọ́ tó yàtọ̀ sí ìhìn rere tí ẹ ti gbà, kí ó di ẹni ègún. 10  Ṣé ojú rere èèyàn ni mò ń wá báyìí ni àbí ti Ọlọ́run? Àbí ìfẹ́ èèyàn ni mo fẹ́ ṣe? Tó bá jẹ́ pé ìfẹ́ èèyàn ni mo ṣì ń ṣe, á jẹ́ pé èmi kì í ṣe ẹrú Kristi. 11  Ẹ̀yin ará, mo fẹ́ kí ẹ mọ̀ pé ìhìn rere tí mo kéde fún yín kì í ṣe látọ̀dọ̀ èèyàn;+ 12  nítorí mi ò gbà á lọ́wọ́ èèyàn, bẹ́ẹ̀ ni a ò fi kọ́ mi, àmọ́ ó jẹ́ nípasẹ̀ ìfihàn látọwọ́ Jésù Kristi. 13  Ẹ ti gbọ́ nípa ìwà mi tẹ́lẹ̀ nínú Ìsìn Àwọn Júù,+ pé mò ń ṣe inúnibíni tó gbóná* sí ìjọ Ọlọ́run, mo sì ń dà á rú;+ 14  mò ń tẹ̀ síwájú nínú Ìsìn Àwọn Júù ju ọ̀pọ̀ nínú àwọn tí a jọ jẹ́ ẹgbẹ́ lórílẹ̀-èdè mi, torí mo ní ìtara púpọ̀ fún àṣà àwọn baba mi.+ 15  Àmọ́ nígbà tí Ọlọ́run, ẹni tó yọ mí nínú ikùn ìyá mi, tó sì pè mí nípasẹ̀ inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí rẹ̀,+ rí i pé ó dára 16  láti ṣí Ọmọ rẹ̀ payá nípasẹ̀ mi, kí n lè kéde ìhìn rere nípa rẹ̀ fún àwọn orílẹ̀-èdè,+ mi ò lọ fọ̀rọ̀ lọ ẹnikẹ́ni* lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀; 17  bẹ́ẹ̀ ni mi ò lọ sí Jerúsálẹ́mù lọ́dọ̀ àwọn tó jẹ́ àpọ́sítélì ṣáájú mi, àmọ́ mo lọ sí Arébíà, lẹ́yìn náà, mo pa dà sí Damásíkù.+ 18  Ọdún mẹ́ta lẹ́yìn náà, mo lọ sí Jerúsálẹ́mù+ lọ́dọ̀ Kéfà,*+ mo sì lo ọjọ́ mẹ́ẹ̀ẹ́dógún (15) lọ́dọ̀ rẹ̀. 19  Àmọ́ mi ò rí ìkankan nínú àwọn àpọ́sítélì yòókù, àfi Jémíìsì+ àbúrò Olúwa. 20  Ní ti àwọn ohun tí mò ń kọ sí yín, mo fi dá yín lójú níwájú Ọlọ́run pé mi ò parọ́. 21  Lẹ́yìn ìyẹn, mo lọ sí agbègbè Síríà àti ti Sìlíṣíà.+ 22  Àmọ́ àwọn ìjọ Jùdíà tó wà ní ìṣọ̀kan pẹ̀lú Kristi kò dá mi mọ̀. 23  Wọ́n kàn máa ń gbọ́ pé: “Ọkùnrin tó ń ṣe inúnibíni sí wa tẹ́lẹ̀+ ti ń kéde ìhìn rere nípa ẹ̀sìn* tí òun fúnra rẹ̀ ń gbógun tì tẹ́lẹ̀.”+ 24  Torí náà, wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí í yin Ọlọ́run lógo nítorí mi.

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé

Tàbí “àsìkò.” Wo Àlàyé Ọ̀rọ̀.
Tàbí “a ti sáré mú yín kúrò.”
Ní Grk., “tó dé ìwọ̀n tó pọ̀ lápọ̀jù.”
Ní Grk., “ẹran ara àti ẹ̀jẹ̀.”
Wọ́n tún ń pè é ní Pétérù.
Ní Grk., “ìgbàgbọ́.”