Sí Fílémónì 1:1-25

  • Ìkíni (1-3)

  • Ìfẹ́ àti ìgbàgbọ́ Fílémónì (4-7)

  • Pọ́ọ̀lù bá Ónísímù bẹ̀bẹ̀ (8-22)

  • Ìkíni tó fi parí ọ̀rọ̀ rẹ̀ (23-25)

1  Pọ́ọ̀lù, tí wọ́n fi sẹ́wọ̀n+ nítorí Kristi Jésù, àti Tímótì+ arákùnrin wa, sí Fílémónì, ẹni ọ̀wọ́n tí a jọ ń ṣiṣẹ́, 2  àti sí Áfíà arábìnrin wa àti Ákípọ́sì+ tí a jọ jẹ́ ọmọ ogun àti sí ìjọ tó wà ní ilé rẹ:+ 3  Kí inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí àti àlàáfíà Ọlọ́run tó jẹ́ Baba wa àti ti Jésù Kristi Olúwa máa wà pẹ̀lú rẹ. 4  Mo máa ń dúpẹ́ lọ́wọ́ Ọlọ́run mi nígbà gbogbo tí mo bá rántí rẹ nínú àdúrà mi,+ 5  bí mo ṣe ń gbọ́ nípa ìgbàgbọ́ rẹ àti ìfẹ́ tí o ní sí Jésù Olúwa àti sí gbogbo ẹni mímọ́. 6  Àdúrà mi ni pé kí ìgbàgbọ́ jẹ́ kí o mọ gbogbo ohun rere tí Kristi mú kí a ní. 7  Arákùnrin mi, nígbà tí mo gbọ́ nípa ìfẹ́ rẹ, inú mi dùn gan-an, ara sì tù mí torí pé o ti mú kí ara tu àwọn ẹni mímọ́.* 8  Nítorí náà, bó tilẹ̀ jẹ́ pé ẹnu mi gbà á láti pàṣẹ fún ọ pé kí o ṣe ohun tó tọ́ torí bí mo ṣe jẹ́ sí Kristi, 9  mi ò ní ṣe bẹ́ẹ̀, màá rọ̀ ẹ́ torí ìfẹ́ tí o ní àti bí o ṣe mọ̀ pé àgbàlagbà ni mí tí mo sì tún wà lẹ́wọ̀n báyìí torí Kristi Jésù. 10  Mò ń bẹ̀ ọ́ nítorí Ónísímù+ ọmọ mi, tí mo di bàbá rẹ̀+ nígbà tí mo wà lẹ́wọ̀n.* 11  Kò wúlò fún ọ tẹ́lẹ̀, àmọ́ ní báyìí, ó ti wúlò fún èmi àti ìwọ. 12  Ó ti di ẹni bí ọkàn mi,* mo sì ń rán an pa dà sọ́dọ̀ rẹ. 13  Nítorí ìwọ ò sí níbí, ó wù mí kó ṣì wà lọ́dọ̀ mi, kó lè máa ràn mí lọ́wọ́ lákòókò yìí tí mo wà lẹ́wọ̀n nítorí ìhìn rere.+ 14  Àmọ́ mi ò fẹ́ ṣe ohunkóhun láìjẹ́ pé o fọwọ́ sí i, kí ohun rere tí o fẹ́ ṣe lè ti ọkàn rẹ wá, kó má sì jẹ́ àfipáṣe.+ 15  Ó lè jẹ́ torí èyí ló fi sá kúrò fún ìgbà díẹ̀,* kó lè pa dà sọ́dọ̀ rẹ títí láé, 16  kì í ṣe bí ẹrú mọ́,+ àmọ́ bí ẹni tó ju ẹrú lọ, bí arákùnrin ọ̀wọ́n.+ Bó ṣe jẹ́ sí mi gan-an nìyẹn, kí n má ṣẹ̀ṣẹ̀ wá sọ bó ṣe jẹ́ sí ọ nípa tara àti nínú Olúwa. 17  Torí náà, tí o bá kà mí sí ọ̀rẹ́* rẹ, fi ìfẹ́ gbà á tọwọ́tẹsẹ̀ bí o ṣe máa gbà mí. 18  Yàtọ̀ síyẹn, tó bá ti ṣẹ̀ ọ́ lọ́nàkọnà tàbí tó jẹ ọ́ ní gbèsè ohunkóhun, kà á sí mi lọ́rùn. 19  Èmi Pọ́ọ̀lù ni mò ń fi ọwọ́ ara mi kọ̀wé yìí: Màá san án pa dà, bó tilẹ̀ jẹ́ pé ìwọ náà jẹ mí ní gbèsè ara rẹ. 20  Arákùnrin mi, mo fẹ́ kí o ṣe nǹkan yìí fún mi torí bí a ṣe jẹ́ nínú Olúwa. Jọ̀ọ́, jẹ́ kí ara tù mí* torí bí a ṣe jẹ́ sí Kristi. 21  Mò ń kọ̀wé sí ọ torí ó dá mi lójú pé o máa ṣe ohun tí mo sọ. Mo sì mọ̀ pé wàá ṣe jù bẹ́ẹ̀ lọ pàápàá. 22  Bákan náà, mo tún fẹ́ kí o bá mi ṣètò ibi tí màá dé sí, torí mo ní ìrètí pé wọ́n á jẹ́ kí n pa dà sọ́dọ̀ yín,* lọ́lá àdúrà tí ẹ̀ ń gbà fún mi.+ 23  Épáfírásì+ tí a jọ wà lẹ́wọ̀n torí Kristi Jésù ń kí ọ, 24  Máàkù, Àrísítákọ́sì,+ Démà+ àti Lúùkù+ tí gbogbo wa jọ ń ṣiṣẹ́ tún kí ọ. 25  Kí inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí Jésù Kristi Olúwa máa wà pẹ̀lú ẹ̀mí tí o fi hàn.

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé

^ Tàbí “o ti mú kí ara tu ọkàn àwọn ẹni mímọ́.”
^ Ní Grk., “wà nínú ìdè.”
^ Tàbí “ẹni tí mo fẹ́ràn gan-an.”
^ Ní Grk., “wákàtí kan.”
^ Ní Grk., “alájọpín.”
^ Tàbí “tu ọkàn mi.”
^ Tàbí “tú mi sílẹ̀ fún yín.”