Diutarónómì 33:1-29

  • Mósè súre fún àwọn ẹ̀yà wọn (1-29)

    • “Ọwọ́ ayérayé” Jèhófà (27)

33  Bí Mósè èèyàn Ọlọ́run tòótọ́ ṣe súre fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì kó tó kú nìyí.+ 2  Ó sọ pé: “Jèhófà wá láti Sínáì,+Ó sì tàn sórí wọn láti Séírì. Ògo rẹ̀ tàn láti agbègbè olókè Páránì,+Ọ̀kẹ́ àìmọye* àwọn ẹni mímọ́+ sì wà pẹ̀lú rẹ̀,Àwọn jagunjagun+ rẹ̀ wà ní ọwọ́ ọ̀tún rẹ̀.  3  Ó nífẹ̀ẹ́ àwọn èèyàn rẹ̀;+Gbogbo ẹni mímọ́ wọn wà ní ọwọ́ rẹ.+ Wọ́n jókòó sẹ́gbẹ̀ẹ́ ẹsẹ̀ rẹ;+Wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí í tẹ́tí sí ọ̀rọ̀ rẹ.+  4  (Mósè fún wa ní àṣẹ kan, òfin kan,+Tó jẹ́ ohun ìní ìjọ Jékọ́bù.)+  5  Ó sì di ọba ní Jéṣúrúnì,*+Nígbà tí àwọn olórí àwọn èèyàn náà kóra jọ,+Pẹ̀lú gbogbo ẹ̀yà Ísírẹ́lì.+  6  Kí Rúbẹ́nì yè, kó má sì kú,+Kí iye àwọn èèyàn rẹ̀ má sì dín kù.”+  7  Ó sì súre fún Júdà+ pé: “Ìwọ Jèhófà, gbọ́ ohùn Júdà,+Kí o sì mú un pa dà sọ́dọ̀ àwọn èèyàn rẹ̀. Ọwọ́ rẹ̀ ti gbèjà* ohun tó jẹ́ tirẹ̀,Ràn án lọ́wọ́ kó lè borí àwọn ọ̀tá rẹ̀.”+  8  Ó sọ nípa Léfì pé:+ “Túmímù rẹ* àti Úrímù  + rẹ jẹ́ ti ẹni tó jẹ́ adúróṣinṣin sí ọ,+Ẹni tí o dán wò ní Másà.+ O bẹ̀rẹ̀ sí í bá a fà á lẹ́gbẹ̀ẹ́ omi Mẹ́ríbà,+   9  Ẹni tó sọ nípa bàbá àti ìyá rẹ̀ pé, ‘Mi ò kà wọ́n sí.’ Ó tiẹ̀ tún kọ àwọn arákùnrin rẹ̀,+Ó sì pa àwọn ọmọ rẹ̀ tì. Torí wọ́n tẹ̀ lé ọ̀rọ̀ rẹ,Wọ́n sì pa májẹ̀mú rẹ mọ́.+  10  Jẹ́ kí wọ́n fi àwọn ìdájọ́ rẹ kọ́ Jékọ́bù,+Kí wọ́n sì fi Òfin rẹ kọ́ Ísírẹ́lì.+ Jẹ́ kí wọ́n sun tùràrí láti mú òórùn dídùn jáde sí ọ*+Àti odindi ẹbọ lórí pẹpẹ rẹ.+  11  Bù kún agbára rẹ̀, Jèhófà,Kí inú rẹ sì dùn sí iṣẹ́ ọwọ́ rẹ̀. Fọ́ ẹsẹ̀* àwọn tó dìde sí i,Kí àwọn tó kórìíra rẹ̀ má bàa dìde mọ́.”  12  Ó sọ nípa Bẹ́ńjámínì pé:+ “Kí ẹni ọ̀wọ́n Jèhófà máa gbé láìséwu lọ́dọ̀ rẹ̀;Bó ṣe ń dáàbò bò ó ní gbogbo ọjọ́,Á máa gbé láàárín èjìká rẹ̀.”  13  Ó sọ nípa Jósẹ́fù pé:+ “Kí Jèhófà bù kún ilẹ̀ rẹ̀+Pẹ̀lú àwọn ohun tó dáa láti ọ̀run,Pẹ̀lú ìrì àti omi tó ń sun láti ilẹ̀,+  14  Pẹ̀lú àwọn ohun tó dáa tí oòrùn mú jáde,Àti ohun tó dáa tó ń mú jáde lóṣooṣù,+  15  Pẹ̀lú àwọn ohun tó dáa jù láti àwọn òkè àtijọ́,*+Àti àwọn ohun tó dáa láti àwọn òkè tó ti wà tipẹ́,  16  Pẹ̀lú àwọn ohun tó dáa ní ayé àti ohun tó kún inú rẹ̀,+Kí Ẹni tó ń gbé inú igi ẹlẹ́gùn-ún+ sì tẹ́wọ́ gbà á. Kí wọ́n wá sí orí Jósẹ́fù,Sí àtàrí ẹni tí a yà sọ́tọ̀ lára àwọn arákùnrin rẹ̀.+  17  Iyì rẹ̀ dà bíi ti àkọ́bí akọ màlúù,Ìwo akọ màlúù igbó sì ni àwọn ìwo rẹ̀. Ó máa fi ti* àwọn èèyàn,Gbogbo wọn pa pọ̀ títí dé àwọn ìkángun ayé. Ẹgbẹẹgbàárùn-ún Éfúrémù  + ni wọ́n,Ẹgbẹẹgbẹ̀rún Mánásè sì ni wọ́n.”  18  Ó sọ nípa Sébúlúnì pé:+ “Ìwọ Sébúlúnì, máa yọ̀ bí o ṣe ń jáde lọ,Àti ìwọ Ísákà, nínú àwọn àgọ́ rẹ.+  19  Wọ́n á pe àwọn èèyàn wá sórí òkè. Ibẹ̀ ni wọ́n á ti rú àwọn ẹbọ òdodo. Torí wọ́n á kó látinú ọ̀pọ̀ rẹpẹtẹ ọrọ̀ inú* òkun,Àti àwọn ohun* tó fara pa mọ́ sínú iyẹ̀pẹ̀.”  20  Ó sọ nípa Gádì pé:+ “Ìbùkún ni fún ẹni tó ń mú kí àwọn ààlà Gádì+ fẹ̀ sí i. Ó dùbúlẹ̀ síbẹ̀ bíi kìnnìún,Tó múra tán láti fa apá ya, àní àtàrí.  21  Ó máa mú ìpín àkọ́kọ́ fún ara rẹ̀,+Torí ibẹ̀ ni ìpín látọwọ́ ẹni tó fúnni ní òfin wà ní ìpamọ́.+ Àwọn olórí àwọn èèyàn náà máa kóra jọ. Ó máa mú òdodo Jèhófà ṣẹÀti àwọn ìdájọ́ rẹ̀ pẹ̀lú Ísírẹ́lì.”  22  Ó sọ nípa Dánì pé:+ “Ọmọ kìnnìún ni Dánì.+ Ó máa bẹ́ jáde láti Báṣánì.”+  23  Ó sọ nípa Náfútálì pé:+ “Jèhófà ti tẹ́wọ́ gba NáfútálìÓ sì ti bù kún un lọ́pọ̀lọpọ̀. Gba ìwọ̀ oòrùn àti gúúsù.”  24  Ó sọ nípa Áṣérì pé:+ “A fi àwọn ọmọ bù kún Áṣérì. Kó rí ojúure àwọn arákùnrin rẹ̀,Kó sì ki ẹsẹ̀ rẹ̀ bọ inú òróró.*  25  Irin àti bàbà ni wọ́n fi ṣe ohun tí wọ́n fi ń ti ẹnubodè rẹ,+O sì máa wà láìséwu ní gbogbo ọjọ́ rẹ.*  26  Kò sí ẹni tó dà bí Ọlọ́run tòótọ́+ Jéṣúrúnì,+Tó ń la ọ̀run kọjá kó lè ràn ọ́ lọ́wọ́,Tó sì ń gun àwọsánmà* nínú ọlá ńlá rẹ̀.+  27  Ọlọ́run jẹ́ ibi ààbò láti ìgbà àtijọ́,+Ọwọ́ ayérayé rẹ̀ wà lábẹ́ rẹ.+ Ó máa lé ọ̀tá kúrò níwájú rẹ,+Ó sì máa sọ pé, ‘Pa wọ́n run!’+  28  Ísírẹ́lì á máa gbé láìséwu,Orísun Jékọ́bù sì máa wà lọ́tọ̀,Ní ilẹ̀ tí ọkà àti wáìnì tuntun+ wà,Tí ìrì á máa sẹ̀ lójú ọ̀run rẹ̀.+  29  Aláyọ̀ ni ọ́, ìwọ Ísírẹ́lì!+ Ta ló dà bí rẹ,+Àwọn èèyàn tó ń gbádùn ìgbàlà Jèhófà,+Apata tó ń dáàbò bò ọ́,+Àti idà ọlá ńlá rẹ? Àwọn ọ̀tá rẹ máa ba búrúbúrú níwájú rẹ,+Wàá sì rìn lórí ẹ̀yìn* wọn.”

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé

^ Tàbí “ẹgbẹẹgbàárùn-ún.”
^ Ó túmọ̀ sí “Adúróṣinṣin,” orúkọ oyè tí wọ́n fún Ísírẹ́lì.
^ Tàbí “jà fún.”
^ Nínú ẹsẹ yìí, “rẹ” àti “ọ” ń tọ́ka sí Ọlọ́run.
^ Ní Héb., “sínú imú rẹ.”
^ Tàbí “ìbàdí.”
^ Tàbí kó jẹ́, “àwọn òkè ìlà oòrùn.”
^ Tàbí “kan.”
^ Ní Héb., “fa ọ̀pọ̀ rẹpẹtẹ ohun tó wà nínú.”
^ Tàbí “ìṣúra.”
^ Tàbí “wẹ ẹsẹ̀ rẹ̀ nínú òróró.”
^ Ní Héb., “Agbára rẹ yóò sì rí bí àwọn ọjọ́ rẹ.”
^ Tàbí “ìkùukùu.”
^ Tàbí kó jẹ́, “àwọn ibi gíga.”