Kíróníkà Kejì 27:1-9
-
Jótámù di ọba Júdà (1-9)
27 Ẹni ọdún mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n (25) ni Jótámù+ nígbà tó jọba, ọdún mẹ́rìndínlógún (16) ló sì fi ṣàkóso ní Jerúsálẹ́mù. Orúkọ ìyá rẹ̀ ni Jérúṣà ọmọ Sádókù.+
2 Ó ń ṣe ohun tí ó tọ́ ní ojú Jèhófà bí Ùsáyà bàbá rẹ̀ ti ṣe,+ àmọ́ ní tirẹ̀, kò wọ ibi tí kò yẹ kó wọ̀ nínú tẹ́ńpìlì Jèhófà.+ Síbẹ̀, àwọn èèyàn náà ṣì ń hùwà ibi.
3 Ó kọ́ ẹnubodè apá òkè ilé Jèhófà,+ ó kọ́ ohun púpọ̀ sórí ògiri Ófélì.+
4 Ó tún kọ́ àwọn ìlú+ sí agbègbè olókè Júdà,+ ó sì kọ́ àwọn ibi olódi+ àti àwọn ilé gogoro+ sí agbègbè onígi.
5 Ó bá ọba àwọn ọmọ Ámónì jà,+ ó sì borí wọn níkẹyìn, tí ó fi jẹ́ pé ní ọdún yẹn, àwọn ọmọ Ámónì fún un ní ọgọ́rùn-ún (100) tálẹ́ńtì* fàdákà àti ẹgbẹ̀rún mẹ́wàá (10,000) òṣùwọ̀n kọ́ọ̀* àlìkámà* àti ẹgbẹ̀rún mẹ́wàá (10,000) ti ọkà bálì. Àwọn ọmọ Ámónì tún san èyí fun un ní ọdún kejì àti ní ọdún kẹta.+
6 Báyìí ni Jótámù ń lágbára sí i, nítorí ó pinnu* láti máa rìn ní ọ̀nà Jèhófà Ọlọ́run rẹ̀.
7 Ní ti ìyókù ìtàn Jótámù, gbogbo àwọn ogun tó jà àti àwọn ọ̀nà rẹ̀, ó wà lákọsílẹ̀ nínú Ìwé Àwọn Ọba Ísírẹ́lì àti ti Júdà.+
8 Ẹni ọdún mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n (25) ni nígbà tó jọba, ọdún mẹ́rìndínlógún (16) ló sì fi ṣàkóso ní Jerúsálẹ́mù.+
9 Níkẹyìn, Jótámù sinmi pẹ̀lú àwọn baba ńlá rẹ̀, wọ́n sì sin ín sí Ìlú Dáfídì.+ Áhásì ọmọ rẹ̀ sì jọba ní ipò rẹ̀.+
Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé
^ Tálẹ́ńtì kan jẹ́ kìlógíráàmù 34.2. Wo Àfikún B14.
^ Kọ́ọ̀ kan jẹ́ Lítà 220. Wo Àfikún B14.
^ Tàbí “wíìtì.”
^ Tàbí “múra.”

