Kíróníkà Kejì 1:1-17

  • Sólómọ́nì béèrè ọgbọ́n (1-12)

  • Ọrọ̀ Sólómọ́nì (13-17)

1  Sólómọ́nì ọmọ Dáfídì ń lágbára sí i nínú ìjọba rẹ̀, Jèhófà Ọlọ́run rẹ̀ wà pẹ̀lú rẹ̀, ó sì sọ ọ́ di ẹni ńlá tó ta yọ.+  Sólómọ́nì ránṣẹ́ pe gbogbo Ísírẹ́lì, àwọn olórí ẹgbẹẹgbẹ̀rún àti ti ọgọ́rọ̀ọ̀rún, àwọn onídàájọ́ àti gbogbo àwọn ìjòyè Ísírẹ́lì, àwọn olórí agbo ilé.  Nígbà náà, Sólómọ́nì àti gbogbo ìjọ náà lọ sí ibi gíga tó wà ní Gíbíónì,+ torí pé ibẹ̀ ni àgọ́ ìpàdé Ọlọ́run tòótọ́ wà, èyí tí Mósè ìránṣẹ́ Jèhófà pa ní aginjù.  Àmọ́, Dáfídì ti gbé Àpótí Ọlọ́run tòótọ́ wá láti Kiriati-jéárímù+ sí ibi tí Dáfídì ṣètò sílẹ̀ fún un; ó ti pa àgọ́ fún un ní Jerúsálẹ́mù.+  Wọ́n ti gbé pẹpẹ bàbà+ tí Bẹ́sálẹ́lì+ ọmọ Úráì ọmọ Húrì ṣe sí iwájú àgọ́ ìjọsìn Jèhófà; Sólómọ́nì àti gbogbo ìjọ sì máa ń gbàdúrà níwájú rẹ̀.*  Sólómọ́nì wá rú àwọn ẹbọ níbẹ̀ níwájú Jèhófà, ẹgbẹ̀rún (1,000) ẹran ẹbọ sísun ló sì fi rúbọ lórí pẹpẹ bàbà+ tó wà ní àgọ́ ìpàdé.  Ní òru yẹn, Ọlọ́run fara han Sólómọ́nì, ó sì sọ fún un pé: “Béèrè ohun tí wàá fẹ́ kí n fún ọ.”+  Ni Sólómọ́nì bá sọ fún Ọlọ́run pé: “O ti fi ìfẹ́ tí kì í yẹ̀ hàn sí Dáfídì bàbá mi+ lọ́nà tó ga, o sì ti fi mí jọba ní ipò rẹ̀.+  Ní báyìí, Jèhófà Ọlọ́run, mú ìlérí tí o ṣe fún Dáfídì bàbá mi ṣẹ,+ nítorí o ti fi mí jọba lórí àwọn èèyàn tó pọ̀ bí erùpẹ̀ ilẹ̀.+ 10  Fún mi ní ọgbọ́n àti ìmọ̀+ tí màá fi máa darí àwọn èèyàn yìí,* nítorí ta ló lè ṣe ìdájọ́ àwọn èèyàn rẹ tó pọ̀ yìí?”+ 11  Lẹ́yìn náà, Ọlọ́run sọ fún Sólómọ́nì pé: “Nítorí ohun tí ọkàn rẹ fẹ́ yìí àti pé o ò béèrè ọlá, ọrọ̀ àti ògo tàbí ikú* àwọn tó kórìíra rẹ, bẹ́ẹ̀ ni o ò béèrè ẹ̀mí gígùn,* àmọ́ o béèrè ọgbọ́n àti ìmọ̀ kí o lè máa ṣe ìdájọ́ àwọn èèyàn mi tí mo fi ọ́ jọba lé lórí,+ 12  màá fún ọ ní ọgbọ́n àti ìmọ̀; màá tún fún ọ ní ọlá àti ọrọ̀ àti iyì irú èyí tí àwọn ọba tó ṣáájú rẹ kò ní, kò sì ní sí èyí tó máa ní irú rẹ̀ lẹ́yìn rẹ.”+ 13  Nítorí náà, Sólómọ́nì dé láti ibi gíga tó wà ní Gíbíónì,+ láti iwájú àgọ́ ìpàdé, sí Jerúsálẹ́mù; ó sì ń ṣàkóso Ísírẹ́lì. 14  Sólómọ́nì ń kó kẹ̀kẹ́ ẹṣin àti ẹṣin jọ;* ó ní ẹgbẹ̀rún kan ó lé ọgọ́rùn-ún mẹ́rin (1,400) kẹ̀kẹ́ ẹṣin àti ẹgbẹ̀rún méjìlá (12,000) ẹṣin,*+ ó sì kó wọn sí àwọn ìlú kẹ̀kẹ́ ẹṣin+ àti sí tòsí ọba ní Jerúsálẹ́mù.+ 15  Ọba mú kí fàdákà àti wúrà tó wà ní Jerúsálẹ́mù pọ̀ rẹpẹtẹ bí òkúta,+ ó sì mú kí igi kédárì pọ̀ rẹpẹtẹ bí àwọn igi síkámórè tó wà ní Ṣẹ́fẹ́là.+ 16  Íjíbítì ni wọ́n ti ń kó àwọn ẹṣin wá fún Sólómọ́nì,+ àwùjọ àwọn oníṣòwò ọba á sì ra agbo ẹṣin* náà ní iye kan.+ 17  Ọgọ́rùn-ún mẹ́fà (600) fàdákà ni wọ́n ń ra kẹ̀kẹ́ ẹṣin kọ̀ọ̀kan láti Íjíbítì, àádọ́jọ (150) fàdákà sì ni wọ́n ń ra ẹṣin kọ̀ọ̀kan; wọ́n á wá fi wọ́n ránṣẹ́ sí gbogbo ọba àwọn ọmọ Hétì àti àwọn ọba Síríà.

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé

Tàbí “máa ń wádìí lọ́dọ̀ Rẹ̀ níbẹ̀.”
Ní Héb., “tí màá fi máa jáde níwájú àwọn èèyàn yìí, tí màá sì fi máa wọlé.”
Tàbí “ọkàn.”
Ní Héb., “ọ̀pọ̀ ọjọ́.”
Tàbí “àwọn agẹṣin.”
Tàbí “àwọn agẹṣin.”
Tàbí kó jẹ́, “láti Íjíbítì àti Kúè; àwọn oníṣòwò ọba á rà wọ́n láti Kúè,” ó lè jẹ́ pé Sìlíṣíà ló ń tọ́ka sí.