Àwọn Ọba Kejì 14:1-29

  • Amasááyà di ọba Júdà (1-6)

  • Ó bá Édómù àti Ísírẹ́lì jà (7-14)

  • Ikú Jèhóáṣì ọba Ísírẹ́lì (15, 16)

  • Ikú Amasááyà (17-22)

  • Jèróbóámù Kejì di ọba Ísírẹ́lì (23-29)

14  Ní ọdún kejì Jèhóáṣì+ ọmọ Jèhóáhásì ọba Ísírẹ́lì, Amasááyà ọmọ Jèhóáṣì ọba Júdà di ọba.  Ẹni ọdún mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n (25) ni nígbà tó jọba, ọdún mọ́kàndínlọ́gbọ̀n (29) ló sì fi ṣàkóso ní Jerúsálẹ́mù. Orúkọ ìyá rẹ̀ ni Jèhóádínì láti Jerúsálẹ́mù.+  Ó ń ṣe ohun tí ó tọ́ ní ojú Jèhófà, àmọ́ kì í ṣe bíi ti Dáfídì+ baba ńlá rẹ̀. Gbogbo ohun tí Jèhóáṣì bàbá rẹ̀ ṣe ni òun náà ṣe.+  Àmọ́ kò mú àwọn ibi gíga kúrò,+ àwọn èèyàn náà ṣì ń rúbọ, wọ́n sì ń mú ẹbọ rú èéfín ní àwọn ibi gíga.+  Nígbà tí ìjọba rẹ̀ ti fìdí múlẹ̀ dáadáa, ó pa àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ tí wọ́n pa bàbá rẹ̀ ọba.+  Àmọ́ kò pa ọmọ àwọn apààyàn náà, gẹ́gẹ́ bí àṣẹ Jèhófà tó wà lákọsílẹ̀ nínú ìwé Òfin Mósè, pé: “Kí a má pa àwọn bàbá nítorí àwọn ọmọ wọn, kí a má sì pa àwọn ọmọ nítorí àwọn bàbá wọn; ṣùgbọ́n kí a pa kálukú nítorí ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀.”+  Ó pa àwọn ọmọ Édómù+ ní Àfonífojì Iyọ̀,+ ẹgbẹ̀rún mẹ́wàá (10,000) èèyàn ló kú, ó sì gba ìlú Sẹ́ẹ́là lójú ogun,+ orúkọ ìlú náà sì di Jókítéélì títí di òní yìí.  Nígbà náà, Amasááyà rán àwọn òjíṣẹ́ sí Jèhóáṣì ọmọ Jèhóáhásì ọmọ Jéhù ọba Ísírẹ́lì pé: “Wá, jẹ́ ká dojú ìjà kọ ara wa.”*+  Jèhóáṣì ọba Ísírẹ́lì ránṣẹ́ sí Amasááyà ọba Júdà, pé: “Èpò ẹlẹ́gùn-ún tó wà ní Lẹ́bánónì ránṣẹ́ sí igi kédárì tó wà ní Lẹ́bánónì, pé, ‘Fi ọmọbìnrin rẹ fún ọmọkùnrin mi kó fi ṣe aya.’ Àmọ́, ẹranko kan láti Lẹ́bánónì kọjá, ó sì tẹ èpò ẹlẹ́gùn-ún náà pa. 10  Òótọ́ ni pé o ti ṣẹ́gun Édómù,+ torí bẹ́ẹ̀ ni ìgbéraga fi wọ̀ ẹ́ lẹ́wù. Dúró sí ilé* rẹ, kí o sì jẹ́ kí ògo rẹ máa múnú rẹ dùn. Kí ló dé tí wàá fi fa àjálù bá ara rẹ, tí wàá sì gbé ara rẹ àti Júdà ṣubú?” 11  Ṣùgbọ́n Amasááyà ò gbọ́.+ Torí náà, Jèhóáṣì ọba Ísírẹ́lì jáde lọ, òun àti Amasááyà ọba Júdà sì dojú ìjà kọra ní Bẹti-ṣémẹ́ṣì,+ tó jẹ́ ti Júdà.+ 12  Ísírẹ́lì ṣẹ́gun Júdà, kálukú sì sá lọ sí ilé* rẹ̀. 13  Jèhóáṣì ọba Ísírẹ́lì mú Amasááyà ọba Júdà, ọmọ Jèhóáṣì ọmọ Ahasáyà, ní Bẹti-ṣémẹ́ṣì. Lẹ́yìn náà, wọ́n wá sí Jerúsálẹ́mù, ó sì ṣe àlàfo sára ògiri Jerúsálẹ́mù láti Ẹnubodè Éfúrémù+ títí dé Ẹnubodè Igun,+ ọgọ́rùn-ún mẹ́rin (400) ìgbọ̀nwọ́.* 14  Ó kó gbogbo wúrà àti fàdákà pẹ̀lú gbogbo ohun èlò tó wà ní ilé Jèhófà àti ní àwọn ibi tí wọ́n ń kó ìṣúra sí ní ilé* ọba àti àwọn tí wọ́n mú lóǹdè. Lẹ́yìn náà, ó pa dà sí Samáríà. 15  Ní ti ìyókù ìtàn Jèhóáṣì, ohun tí ó ṣe àti agbára rẹ̀ àti bí ó ṣe bá Amasááyà ọba Júdà jà, ǹjẹ́ kò wà lákọsílẹ̀ nínú ìwé ìtàn ìgbà àwọn ọba Ísírẹ́lì? 16  Níkẹyìn, Jèhóáṣì sinmi pẹ̀lú àwọn baba ńlá rẹ̀, wọ́n sì sin ín sí Samáríà+ pẹ̀lú àwọn ọba Ísírẹ́lì; Jèróbóámù*+ ọmọ rẹ̀ sì jọba ní ipò rẹ̀. 17  Amasááyà+ ọmọ Jèhóáṣì ọba Júdà lo ọdún mẹ́ẹ̀ẹ́dógún (15) sí i lẹ́yìn ikú Jèhóáṣì+ ọmọ Jèhóáhásì ọba Ísírẹ́lì.+ 18  Ní ti ìyókù ìtàn Amasááyà, ǹjẹ́ kò wà lákọsílẹ̀ nínú ìwé ìtàn ìgbà àwọn ọba Júdà? 19  Nígbà tó yá, àwọn kan dìtẹ̀ mọ́ ọn+ ní Jerúsálẹ́mù, ó sì sá lọ sí Lákíṣì, àmọ́ wọ́n rán àwọn kan tẹ̀ lé e lọ sí Lákíṣì, wọ́n sì pa á síbẹ̀. 20  Nítorí náà, wọ́n fi ẹṣin gbé e pa dà, wọ́n sì sin ín sí Jerúsálẹ́mù pẹ̀lú àwọn baba ńlá rẹ̀ ní Ìlú Dáfídì.+ 21  Lẹ́yìn náà, gbogbo àwọn èèyàn Júdà mú Asaráyà*+ tó jẹ́ ọmọ ọdún mẹ́rìndínlógún (16),+ wọ́n sì fi í jọba ní ipò Amasááyà bàbá rẹ̀.+ 22  Ó tún Élátì+ kọ́, ó sì dá a pa dà fún Júdà lẹ́yìn tí ọba* ti sinmi pẹ̀lú àwọn baba ńlá rẹ̀.+ 23  Ní ọdún kẹẹ̀ẹ́dógún Amasááyà ọmọ Jèhóáṣì ọba Júdà, Jèróbóámù+ ọmọ Jèhóáṣì ọba Ísírẹ́lì di ọba ní Samáríà, ọdún mọ́kànlélógójì (41) ló sì fi ṣàkóso. 24  Ó ń ṣe ohun tó burú ní ojú Jèhófà. Kò jáwọ́ nínú gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ tí Jèróbóámù ọmọ Nébátì mú kí Ísírẹ́lì dá.+ 25  Ó gba ààlà ilẹ̀ Ísírẹ́lì pa dà láti Lebo-hámátì*+ títí dé Òkun Árábà,*+ gẹ́gẹ́ bí ọ̀rọ̀ tí Jèhófà Ọlọ́run Ísírẹ́lì gbẹnu ìránṣẹ́ rẹ̀ sọ, ìyẹn Jónà+ ọmọ Ámítáì, wòlíì tó wá láti Gati-héférì.+ 26  Nítorí Jèhófà ti rí i pé ìpọ́njú tó bá Ísírẹ́lì pọ̀ gan-an.+ Kò sẹ́ni tó ṣẹ́ kù tó lè ran Ísírẹ́lì lọ́wọ́, títí kan àwọn aláìní tàbí àwọn aláìlera. 27  Àmọ́ Jèhófà ti ṣèlérí pé òun kò ní pa orúkọ Ísírẹ́lì rẹ́ kúrò lábẹ́ ọ̀run.+ Torí náà, ó lo Jèróbóámù ọmọ Jèhóáṣì láti gbà wọ́n.+ 28  Ní ti ìyókù ìtàn Jèróbóámù àti gbogbo ohun tí ó ṣe àti agbára rẹ̀, bí ó ṣe jà àti bí ó ṣe gba Damásíkù+ àti Hámátì+ pa dà fún Júdà ní Ísírẹ́lì, ǹjẹ́ kò wà lákọsílẹ̀ nínú ìwé ìtàn ìgbà àwọn ọba Ísírẹ́lì? 29  Níkẹyìn, Jèróbóámù sinmi pẹ̀lú àwọn baba ńlá rẹ̀, àwọn ọba Ísírẹ́lì; Sekaráyà+ ọmọ rẹ̀ sì jọba ní ipò rẹ̀.

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé

Tàbí “jẹ́ ká wojú ara wa.”
Tàbí “ààfin.”
Ní Héb., “àgọ́.”
Nǹkan bíi mítà 178 (ẹsẹ̀ bàtà 584). Wo Àfikún B14.
Tàbí “ààfin.”
Ìyẹn, Jèróbóámù Kejì.
Ó túmọ̀ sí “Jèhófà Ti Ṣèrànwọ́.” Wọ́n pè é ní Ùsáyà ní 2Ọb 15:13; 2Kr 26:1-23; Ais 6:1 àti Sek 14:5.
Ìyẹn, Amasááyà bàbá rẹ̀.
Tàbí “àbáwọlé Hámátì.”
Ìyẹn, Òkun Iyọ̀ tàbí Òkun Òkú.