Ìsíkíẹ́lì 5:1-17

  • Bí Jerúsálẹ́mù ṣe máa pa run (1-17)

    • Wòlíì pín irun rẹ̀ tó fá sí ọ̀nà mẹ́ta (1-4)

    • Ìwà Jerúsálẹ́mù burú ju ti àwọn orílẹ̀-èdè lọ (7-9)

    • Ìyà mẹ́ta tó máa jẹ àwọn ọlọ̀tẹ̀ (12)

5  “Ní tìrẹ, ọmọ èèyàn, mú idà kan tó mú kí o lè lò ó bí abẹ ìfárí. Fá orí rẹ àti irùngbọ̀n rẹ, kí o sì mú òṣùwọ̀n kí o lè wọn irun náà, kí o sì pín in.  O máa fi iná sun ìdá mẹ́ta irun náà nínú ìlú náà nígbà tí ọjọ́ tí wọ́n dó tì í bá pé.+ O máa kó ìdá mẹ́ta míì, o sì máa fi idà gé e káàkiri ìlú náà,+ kí o wá fọ́n ìdá mẹ́ta yòókù sínú afẹ́fẹ́, èmi yóò sì mú idà kí n lè lé wọn bá.+  “Kí o tún mú fọ́nrán díẹ̀ nínú irun náà, kí o sì wé e mọ́ aṣọ rẹ.  Kí o mú díẹ̀ sí i lára rẹ̀, kí o jù ú sínú iná, kí o sì sun ún di eérú. Láti ibẹ̀ ni iná yóò ti ran gbogbo ilé Ísírẹ́lì.+  “Ohun tí Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ sọ nìyí: ‘Èyí ni Jerúsálẹ́mù. Mo ti fi í sí àárín àwọn orílẹ̀-èdè, àwọn ìlú sì yí i ká.  Àmọ́, ó ti kọ àwọn ìdájọ́ àti àṣẹ mi, ìwà rẹ̀ sì burú ju ti àwọn orílẹ̀-èdè àti àwọn ìlú tó yí i ká lọ.+ Torí wọ́n ti kọ àwọn ìdájọ́ mi, wọn ò sì tẹ̀ lé àwọn àṣẹ mi.’  “Torí náà, ohun tí Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ sọ nìyí: ‘Torí pé agídí yín pọ̀ ju ti àwọn orílẹ̀-èdè tó yí yín ká, tí ẹ kò tẹ̀ lé àwọn àṣẹ mi, tí ẹ sì kọ àwọn ìdájọ́ mi; àmọ́ ẹ tẹ̀ lé ìdájọ́ àwọn orílẹ̀-èdè tó yí yín ká,+  ohun tí Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ sọ nìyí: “Èmi yóò kọjú ìjà sí ọ, ìwọ ìlú,+ èmi fúnra mi yóò sì ṣèdájọ́ ní àárín rẹ lójú àwọn orílẹ̀-èdè.+  Ohun tí mi ò ṣe rí ni màá ṣe fún ọ, mi ò sì tún ní ṣe irú rẹ̀ mọ́, torí gbogbo ohun ìríra tí ò ń ṣe.+ 10  “‘“Ṣe ni àwọn bàbá tó wà ní àárín yín yóò jẹ àwọn ọmọ wọn,+ àwọn ọmọ yóò sì jẹ àwọn bàbá wọn, màá ṣe ìdájọ́ yín, màá sì fọ́n àwọn tó ṣẹ́ kù nínú yín káàkiri.”’*+ 11  “‘Torí náà, bí mo ti wà láàyè,’ ni Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ wí, ‘torí pé ẹ fi àwọn òrìṣà ẹ̀gbin yín àti àwọn ohun ìríra tí ẹ̀ ń ṣe sọ ibi mímọ́ mi di aláìmọ́,+ èmi náà yóò kọ̀ yín;* mi ò ní ṣàánú yín, mi ò sì ní yọ́nú sí yín.+ 12  Àjàkálẹ̀ àrùn* tàbí ìyàn máa pa ìdá mẹ́ta lára yín. Wọ́n á sì fi idà pa ìdá mẹ́ta míì láyìíká yín.+ Màá fọ́n ìdá mẹ́ta yòókù káàkiri,* màá sì fa idà yọ láti fi lé wọn.+ 13  Mi ò sì ní bínú mọ́, inú mi ò ní ru sí wọn mọ́, màá ti tẹ́ ara mi lọ́rùn.+ Nígbà tí mo bá ti bínú gidigidi sí wọn tán, wọ́n á mọ̀ pé èmi, Jèhófà, ti sọ pé èmi nìkan ni mo fẹ́ kí ẹ máa jọ́sìn.+ 14  “‘Èmi yóò sọ ọ́ di ahoro, màá sì mú kí àwọn orílẹ̀-èdè tó yí ọ ká àti àwọn tó ń kọjá lọ máa gàn ọ́.+ 15  Wọ́n á gàn ọ́, wọ́n á sì fi ọ́ ṣẹlẹ́yà.+ Wọ́n á kọ́gbọ́n lára rẹ, ẹ̀rù á sì ba àwọn orílẹ̀-èdè tó yí ọ ká, nígbà tí mo bá fi ìbínú àti ìrunú dá ọ lẹ́jọ́ tí mo sì fìyà jẹ ọ́ gidigidi. Èmi, Jèhófà, ti sọ ọ́. 16  “‘Màá fi ìyàn kọ lù wọ́n, ó máa pa wọ́n run bí ìgbà tí mo bá ta wọ́n ní ọfà olóró. Ọfà tí mo bá ta yóò run yín.+ Màá mú kí ìyàn náà le sí i torí pé màá dáwọ́ oúnjẹ yín dúró.*+ 17  Màá fi ìyàn kọ lù yín, màá rán àwọn ẹranko burúkú sí yín,+ wọ́n á sì pa yín lọ́mọ jẹ. Àjàkálẹ̀ àrùn máa bò yín, ìtàjẹ̀sílẹ̀ á kún ilẹ̀ yín, màá sì fi idà kọ lù yín.+ Èmi, Jèhófà, ti sọ ọ́.’”

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé

Ní Héb., “sínú gbogbo afẹ́fẹ́.”
Tàbí “dín yín kù.”
Tàbí “àìsàn.”
Ní Héb., “sínú gbogbo afẹ́fẹ́.”
Ní Héb., “èmi yóò ṣẹ́ ọ̀pá búrẹ́dì.” Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ àwọn ọ̀pá tí wọ́n fi ń tọ́jú búrẹ́dì.