Ìsíkíẹ́lì 4:1-17

  • Bí wọ́n ṣe máa dó ti Jerúsálẹ́mù (1-17)

    • Ó ru ẹ̀bi fún 390 ọjọ́ àti 40 ọjọ́ (4-7)

4  “Ìwọ ọmọ èèyàn, gbé bíríkì kan, kí o sì gbé e síwájú rẹ. Ya àwòrán Jerúsálẹ́mù sórí rẹ̀.  Dó tì í,+ fi iyẹ̀pẹ̀ mọ odi yí i ká,+ mọ òkìtì láti dó tì í,+ pàgọ́ yí i ká, kí o sì gbé àwọn igi tí wọ́n fi ń fọ́ ògiri+ yí i ká.  Gbé agbada onírin, kí o sì fi ṣe ògiri onírin láàárín ìwọ àti ìlú náà. Kí o wá dojú kọ ọ́, kí a sì dó tì í; ìwọ ni kí o dó tì í. Àmì ni èyí jẹ́ fún ilé Ísírẹ́lì.+  “Kí o wá fi ẹ̀gbẹ́ rẹ òsì dùbúlẹ̀, kí o sì di ẹ̀bi ilé Ísírẹ́lì ru ara rẹ.*+ Iye ọjọ́ tí o bá fi dùbúlẹ̀ ni wàá fi ru ẹ̀bi wọn.  Èmi yóò sì mú kí o fi irínwó dín mẹ́wàá (390) ọjọ́ ru ẹ̀bi ilé Ísírẹ́lì,+ èyí tó dọ́gba pẹ̀lú iye ọdún tí wọ́n fi jẹ̀bi.  O sì gbọ́dọ̀ lo ọjọ́ náà pé. “Lẹ́ẹ̀kan sí i, ìwọ yóò fi ẹ̀gbẹ́ rẹ ọ̀tún dùbúlẹ̀, ìwọ yóò sì di ẹ̀bi ilé Júdà+ ru ara rẹ fún ogójì (40) ọjọ́. Ọjọ́ kan fún ọdún kan, ọjọ́ kan fún ọdún kan ni mo là kalẹ̀ fún ọ.  Ìwọ yóò sì yíjú sí Jerúsálẹ́mù láti dó tì í,+ láìfi aṣọ bo apá rẹ, kí o sì sọ àsọtẹ́lẹ̀ sórí rẹ̀.  “Wò ó! èmi yóò fi okùn dè ọ́, kí o má bàa yí ẹ̀gbẹ́ rẹ pa dà, títí ìwọ yóò fi parí ọjọ́ tí wàá fi dó tì í.  “Kí o sì mú àlìkámà,* ọkà bálì, ẹ̀wà pàkálà, ẹ̀wà lẹ́ńtìlì, jéró àti ọkà sípẹ́ẹ̀tì, kí o kó wọn sínú ìkòkò kan, kí o sì fi wọ́n ṣe búrẹ́dì tí wàá jẹ. Iye ọjọ́ tí o fi ẹ̀gbẹ́ rẹ dùbúlẹ̀ ni wàá fi jẹ ẹ́, ìyẹn irínwó dín mẹ́wàá (390) ọjọ́.+ 10  Ìwọ yóò wọn oúnjẹ tí ó tó ogún (20) ṣékélì,* òun sì ni wàá máa jẹ lójúmọ́. Ó ní àkókò tí wàá máa jẹ ẹ́. 11  “Ṣe ni wàá máa wọn omi tí o fẹ́ mu, ìdá mẹ́fà òṣùwọ̀n hínì* lo máa wọ̀n. Tí àkókò bá tó ni wàá mu ún. 12  “O máa jẹ ẹ́ bí ìgbà tí ò ń jẹ búrẹ́dì ribiti tí wọ́n fi ọkà bálì ṣe; ojú wọn lo ti máa ṣe é, wàá sì fi ìgbẹ́ èèyàn dá iná rẹ̀, èyí tó ti gbẹ.” 13  Jèhófà wá sọ pé: “Bí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ṣe máa jẹ oúnjẹ wọn láàárín àwọn orílẹ̀-èdè tí màá fọ́n wọn ká sí nìyẹn, oúnjẹ àìmọ́ ni wọ́n máa jẹ.”+ 14  Ní mo bá sọ pé: “Rárá o, Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ! Láti kékeré títí di báyìí, mi* ò jẹ òkú ẹran rí tàbí ẹran tí wọ́n fà ya+ tó máa sọ mí di aláìmọ́, mi ò sì jẹ ẹran kankan tó jẹ́ aláìmọ́* rí.”+ 15  Ó sọ fún mi pé: “Ó dáa, màá jẹ́ kí o lo ìgbẹ́ màlúù dípò ti èèyàn, òun lo sì máa fi dá iná tí wàá fi ṣe búrẹ́dì.” 16  Lẹ́yìn náà, ó sọ fún mi pé: “Ọmọ èèyàn, mi ò ní jẹ́ kí oúnjẹ wà* ní Jerúsálẹ́mù,+ ṣe ni wọ́n máa wọn búrẹ́dì tí wọ́n fẹ́ jẹ látinú ìwọ̀nba tí wọ́n ní,+ ọkàn wọn ò sì ní balẹ̀. Wọ́n máa wọn omi tí wọ́n fẹ́ mu látinú ìwọ̀nba tí wọ́n ní, ẹ̀rù á sì máa bà wọ́n.+ 17  Ohun tó máa ṣẹlẹ̀ yìí máa jẹ́ kí ẹnu yà wọ́n, bí wọ́n ṣe ń wo ara wọn, ẹ̀ṣẹ̀ wọn á sì mú kí wọ́n ṣègbé torí pé wọn ò ní búrẹ́dì àti omi tí ó tó.

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé

Ní Héb., “rù ú,” ìyẹn, kí Ìsíkíẹ́lì fi ẹ̀gbẹ́ òsì rẹ̀ rù ú.
Tàbí “wíìtì.”
Nǹkan bíi 230 gíráàmù. Wo Àfikún B14.
Nǹkan bíi Lítà 0.6. Wo Àfikún B14.
Tàbí “ọkàn mi.”
Tàbí “èèwọ̀.”
Ní Héb., “èmi yóò ṣẹ́ ọ̀pá búrẹ́dì.” Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ àwọn ọ̀pá tí wọ́n fi ń tọ́jú búrẹ́dì.