Ìsíkíẹ́lì 30:1-26

  • Ohun tó máa ṣẹlẹ̀ sí Íjíbítì (1-19)

    • Ọlọ́run sọ tẹ́lẹ̀ pé Nebukadinésárì máa gbógun wá (10)

  • Ọlọ́run fòpin sí agbára Fáráò (20-26)

30  Jèhófà tún bá mi sọ̀rọ̀, ó ní:  “Ọmọ èèyàn, sọ tẹ́lẹ̀, kí o sì sọ pé, ‘Ohun tí Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ sọ nìyí: “Ẹ pohùn réré ẹkún, kí ẹ sì sọ pé, ‘Áà, ọjọ́ náà ń bọ̀!’   Torí ọjọ́ náà sún mọ́lé, àní ọjọ́ Jèhófà sún mọ́lé.+ Ọjọ́ ìkùukùu* ni yóò jẹ́,+ àkókò ìdájọ́ àwọn orílẹ̀-èdè.+   Idà yóò dojú kọ Íjíbítì, ìbẹ̀rù á sì bo Etiópíà nígbà tí òkú bá sùn ní Íjíbítì;Wọ́n ti kó ọrọ̀ rẹ̀, wọ́n sì ti wó ìpìlẹ̀ rẹ̀.+   Etiópíà,+ Pútì,+ Lúdì àti onírúurú èèyàn náà*Àti Kúbù, pẹ̀lú àwọn ọmọ ilẹ̀ májẹ̀mú,*Idà ni yóò pa gbogbo wọn.”’   Ohun tí Jèhófà sọ nìyí: ‘Àwọn tó ń ti Íjíbítì lẹ́yìn pẹ̀lú yóò ṣubú,Agbára tó ń mú kó gbéra ga yóò sì wálẹ̀.’+ “‘Idà ni yóò pa wọ́n ní ilẹ̀ náà, láti Mígídólì+ dé Síénè,’+ ni Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ wí.  ‘Wọ́n á di ahoro ju àwọn ilẹ̀ yòókù lọ, àwọn ìlú rẹ̀ á sì di ahoro ju àwọn ìlú yòókù lọ.+  Wọ́n á sì wá mọ̀ pé èmi ni Jèhófà nígbà tí mo bá dá iná sí Íjíbítì, tí mo sì tẹ gbogbo àwọn tó bá a ṣàdéhùn rẹ́.  Ní ọjọ́ yẹn, èmi yóò rán àwọn òjíṣẹ́ nínú àwọn ọkọ̀ òkun, kí wọ́n lè mú kí Etiópíà tó dá ara rẹ̀ lójú gbọ̀n rìrì; ẹ̀rù yóò bà wọ́n ní ọjọ́ ìdájọ́ tó ń bọ̀ wá sórí Íjíbítì, torí ó dájú pé ó máa dé.’ 10  “Ohun tí Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ sọ nìyí: ‘Èmi yóò mú kí Nebukadinésárì* ọba Bábílónì pa ọ̀pọ̀ rẹpẹtẹ àwọn ará Íjíbítì run.+ 11  Òun àti àwọn ọmọ ogun rẹ̀, àwọn tó burú jù nínú àwọn orílẹ̀-èdè+ yóò wá láti pa ilẹ̀ náà run. Wọ́n á fa idà wọn yọ láti bá Íjíbítì jà, wọ́n á sì fi òkú àwọn tí wọ́n pa kún ilẹ̀ náà.+ 12  Èmi yóò sọ àwọn omi tó ń ṣàn láti odò Náílì+ di ilẹ̀ gbígbẹ, èmi yóò sì ta ilẹ̀ náà fún àwọn èèyàn burúkú. Màá mú kí àwọn àjèjì sọ ilẹ̀ náà àti gbogbo ohun tó wà nínú rẹ̀ di ahoro.+ Èmi Jèhófà ti sọ̀rọ̀.’ 13  “Ohun tí Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ sọ nìyí: ‘Èmi yóò tún pa àwọn òrìṣà ẹ̀gbin* run, màá sì pa àwọn ọlọ́run Nófì*+ tí kò ní láárí run. Kò ní sí ọmọ Íjíbítì tó máa ṣe olórí* mọ́, màá sì mú kí ìbẹ̀rù wà ní ilẹ̀ Íjíbítì.+ 14  Màá pa Pátírọ́sì+ run, màá dá iná sí Sóánì, màá sì dá Nóò* lẹ́jọ́.+ 15  Màá bínú sí Sínì, ibi ààbò Íjíbítì, màá sì pa àwọn ará Nóò run. 16  Màá dá iná sí Íjíbítì; ìbẹ̀rù á bo Sínì, wọ́n á ya wọ Nóò, wọ́n á sì gbógun ti Nófì* ní ojúmọmọ! 17  Idà ni yóò pa àwọn géńdé ọkùnrin Ónì* àti Píbésétì, wọ́n á sì kó àwọn ìlú náà lọ sí oko ẹrú. 18  Ojú ọjọ́ yóò ṣókùnkùn ní Tehafínéhésì nígbà tí mo bá ṣẹ́ àwọn ọ̀pá àjàgà Íjíbítì níbẹ̀.+ Agbára tó ń mú kó gbéra ga yóò dópin,+ ìkùukùu* á bò ó, àwọn ìlú rẹ̀ yóò sì lọ sí oko ẹrú.+ 19  Èmi yóò dá Íjíbítì lẹ́jọ́, wọ́n á sì wá mọ̀ pé èmi ni Jèhófà.’” 20  Ní ọdún kọkànlá, ní oṣù kìíní, ní ọjọ́ keje, Jèhófà bá mi sọ̀rọ̀, ó ní: 21  “Ọmọ èèyàn, mo ti kán apá Fáráò ọba Íjíbítì; wọn ò ní dì í kó lè jinná tàbí kí wọ́n fi aṣọ wé e kó lè lágbára tó láti di idà mú.” 22  “Torí náà, ohun tí Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ sọ nìyí: ‘Èmi yóò kọjú ìjà sí Fáráò ọba Íjíbítì,+ màá sì kán apá rẹ̀ méjèèjì, èyí tó ti kán tẹ́lẹ̀ àtèyí tí kò tíì kán,+ màá sì mú kí idà já bọ́ lọ́wọ́ rẹ̀.+ 23  Màá wá tú àwọn ará Íjíbítì ká sáàárín àwọn orílẹ̀-èdè, màá sì fọ́n wọn ká sí àwọn ilẹ̀.+ 24  Èmi yóò fún ọwọ́ ọba Bábílónì lágbára,*+ màá sì fi idà mi sí i lọ́wọ́.+ Èmi yóò ṣẹ́ apá Fáráò, yóò sì kérora gidigidi bí ẹni tó ń kú lọ níwájú rẹ̀.* 25  Èmi yóò fún ọwọ́ ọba Bábílónì lágbára, àmọ́ ọwọ́ Fáráò yóò rọ; wọ́n á sì wá mọ̀ pé èmi ni Jèhófà nígbà tí mo bá fi idà mi sọ́wọ́ ọba Bábílónì, tó sì fì í, kó lè bá ilẹ̀ Íjíbítì jà.+ 26  Màá sì tú àwọn ará Íjíbítì ká sáàárín àwọn orílẹ̀-èdè, màá fọ́n wọn ká sí àwọn ilẹ̀,+ wọn yóò sì wá mọ̀ pé èmi ni Jèhófà.’”

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé

Tàbí “àwọsánmà.”
Tàbí “gbogbo àwọn tó wá láti àwọn orílẹ̀-èdè míì.”
Ó lè jẹ́ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì tó gbára lé Íjíbítì ló tọ́ka sí.
Ní Héb., “Nebukadirésárì,” ọ̀nà míì tí wọ́n ń gbà kọ orúkọ yìí.
Tàbí “ọmọ ọba.”
Tàbí “Mémúfísì.”
Ó ṣeé ṣe kí ọ̀rọ̀ Hébérù yìí ní í ṣe pẹ̀lú ọ̀rọ̀ tí wọ́n ń lò fún “ìgbẹ́,” wọ́n sì máa ń lò ó fún ohun tí wọ́n bá kórìíra.
Ìyẹn, Tíbésì.
Tàbí “Mémúfísì.”
Ìyẹn, Heliopólísì.
Tàbí “àwọsánmà.”
Tàbí “Èmi yóò fi kún agbára ọba Bábílónì.”
Ìyẹn, níwájú ọba Bábílónì.