Ìsíkíẹ́lì 20:1-49

  • Ìtàn nípa bí Ísírẹ́lì ṣe ṣọ̀tẹ̀ (1-32)

  • Ọlọ́run ṣèlérí pé òun yóò dá Ísírẹ́lì pa dà sórí ilẹ̀ wọn (33-44)

  • Sọ tẹ́lẹ̀ nípa gúúsù (45-49)

20  Ní ọdún keje, ní oṣù karùn-ún, ní ọjọ́ kẹwàá oṣù náà, àwọn kan lára àwọn àgbààgbà Ísírẹ́lì wá, wọ́n sì jókòó síwájú mi kí wọ́n lè wádìí ọ̀rọ̀ lọ́dọ̀ Jèhófà.  Jèhófà bá mi sọ̀rọ̀, ó ní:  “Ọmọ èèyàn, bá àwọn àgbààgbà Ísírẹ́lì sọ̀rọ̀, kí o sì sọ fún wọn pé, ‘Ohun tí Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ sọ nìyí: “Ṣé ọ̀dọ̀ mi lẹ ti fẹ́ wádìí ọ̀rọ̀ ni? ‘Bí mo ti wà láàyè, mi ò ní dá yín lóhùn,’+ ni Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ wí.”’  “Ṣé o ṣe tán láti dá wọn lẹ́jọ́?* Ọmọ èèyàn, ṣé o ṣe tán láti dá wọn lẹ́jọ́? Jẹ́ kí wọ́n mọ àwọn ohun ìríra tí àwọn baba ńlá wọn ṣe.+  Sọ fún wọn pé, ‘Ohun tí Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ sọ nìyí: “Ní ọjọ́ tí mo yan Ísírẹ́lì,+ mo tún búra* fún ọmọ* ilé Jékọ́bù, mo sì jẹ́ kí wọ́n mọ̀ mí ní ilẹ̀ Íjíbítì.+ Àní, mo búra fún wọn, mo sì sọ pé, ‘Èmi ni Jèhófà Ọlọ́run yín.’  Ní ọjọ́ yẹn, mo búra fún wọn pé màá mú wọn kúrò ní ilẹ̀ Íjíbítì lọ sí ilẹ̀ tí mo ṣàwárí* fún wọn, ilẹ̀ tí wàrà àti oyin ti ń ṣàn.+ Ibi tó rẹwà* jù ní gbogbo ilẹ̀ náà.  Mo wá sọ fún wọn pé, ‘Kí kálukú yín ju ohun ìríra tó wà níwájú rẹ̀ nù; ẹ má fi àwọn òrìṣà ẹ̀gbin* Íjíbítì sọ ara yín di ẹlẹ́gbin.+ Èmi ni Jèhófà Ọlọ́run yín.’+  “‘“Àmọ́ wọ́n ṣọ̀tẹ̀ sí mi, kò sì wù wọ́n láti fetí sí mi. Wọn ò ju ohun ìríra tó wà níwájú wọn nù, wọn ò sì fi àwọn òrìṣà ẹ̀gbin Íjíbítì sílẹ̀.+ Torí náà, mo pinnu pé màá bínú sí wọn, inú mi á sì ru sí wọn gidigidi ní ilẹ̀ Íjíbítì.  Àmọ́, mo gbé ìgbésẹ̀ torí orúkọ mi, kí wọ́n má bàa kó ẹ̀gàn bá a lójú àwọn orílẹ̀-èdè, láàárín àwọn tí wọ́n ń gbé.+ Torí nígbà tí mo mú wọn* kúrò ní ilẹ̀ Íjíbítì, mo jẹ́ kí wọ́n* mọ̀ mí níṣojú àwọn orílẹ̀-èdè yìí.+ 10  Torí náà, mo mú wọn kúrò ní ilẹ̀ Íjíbítì, mo sì mú wọn wá sí aginjù.+ 11  “‘“Mo wá fún wọn ní àwọn àṣẹ mi, mo sì jẹ́ kí wọ́n mọ àwọn ìdájọ́ mi,+ èyí tó lè mú kí ẹni tó bá ń pa wọ́n mọ́ wà láàyè.+ 12  Mo tún fún wọn ní àwọn sábáàtì mi,+ kó lè jẹ́ àmì láàárín èmi àti àwọn,+ kí wọ́n lè mọ̀ pé èmi Jèhófà ló ń sọ wọ́n di mímọ́. 13  “‘“Àmọ́, ilé Ísírẹ́lì ṣọ̀tẹ̀ sí mi ní aginjù.+ Wọn ò tẹ̀ lé àwọn àṣẹ mi, wọ́n sì kọ àwọn ìdájọ́ mi, èyí tó lè mú kí ẹni tó bá ń pa wọ́n mọ́ wà láàyè. Wọ́n sọ àwọn sábáàtì mi di aláìmọ́ pátápátá. Torí náà, mo pinnu pé màá bínú sí wọn nínú aginjù kí n lè pa wọ́n run.+ 14  Mo gbé ìgbésẹ̀ torí orúkọ mi, kí wọ́n má bàa kó ẹ̀gàn bá a lójú àwọn orílẹ̀-èdè tí wọ́n rí i nígbà tí mo mú wọn* jáde.+ 15  Mo tún búra fún wọn nínú aginjù pé mi ò ní mú wọn wá sí ilẹ̀ tí mo fún wọn,+ ilẹ̀ tí wàrà àti oyin ti ń ṣàn,+ ibi tó rẹwà* jù ní gbogbo ilẹ̀ náà, 16  torí pé wọ́n kọ àwọn ìdájọ́ mi, wọn ò tẹ̀ lé àwọn àṣẹ mi, wọ́n sì sọ àwọn sábáàtì mi di aláìmọ́ torí ọkàn wọn ń fà sí àwọn òrìṣà ẹ̀gbin wọn.+ 17  “‘“Àmọ́ mo* ṣàánú wọn, mi ò sì pa wọ́n run; mi ò pa wọ́n rẹ́ ní aginjù. 18  Mo sọ fún àwọn ọmọ wọn nínú aginjù pé,+ ‘Ẹ ò gbọ́dọ̀ pa ìlànà àwọn baba ńlá yín mọ́,+ ẹ ò gbọ́dọ̀ tẹ̀ lé ìdájọ́ wọn, ẹ ò sì gbọ́dọ̀ fi àwọn òrìṣà ẹ̀gbin wọn sọ ara yín di ẹlẹ́gbin. 19  Èmi ni Jèhófà Ọlọ́run yín. Ẹ máa tẹ̀ lé àwọn àṣẹ mi, kí ẹ rìn nínú àwọn ìdájọ́ mi, kí ẹ sì máa pa wọ́n mọ́.+ 20  Ẹ sọ àwọn sábáàtì mi di mímọ́,+ kó sì jẹ́ àmì láàárín èmi àti ẹ̀yin, kí ẹ lè mọ̀ pé èmi ni Jèhófà Ọlọ́run yín.’+ 21  “‘“Àmọ́ àwọn ọmọ náà bẹ̀rẹ̀ sí í ṣọ̀tẹ̀ sí mi.+ Wọn ò tẹ̀ lé àwọn àṣẹ mi mọ́, wọn ò tẹ̀ lé àwọn ìdájọ́ mi, wọn ò sì rìn nínú rẹ̀, èyí tó lè mú kí ẹni tó bá ń pa wọ́n mọ́ wà láàyè. Wọ́n sọ àwọn sábáàtì mi di aláìmọ́. Torí náà, mo pinnu pé màá bínú sí wọn, inú mi á sì ru sí wọn gidigidi ní aginjù.+ 22  Àmọ́ mi ò ṣe bẹ́ẹ̀,+ mo sì gbé ìgbésẹ̀ nítorí orúkọ mi,+ kí wọ́n má bàa kó ẹ̀gàn bá a lójú àwọn orílẹ̀-èdè tó rí i nígbà tí mo mú wọn* jáde. 23  Bákan náà, mo búra fún wọn nínú aginjù pé màá fọ́n wọn ká sí àwọn orílẹ̀-èdè, màá sì tú wọn ká sí àwọn ilẹ̀,+ 24  torí wọn ò pa àwọn ìdájọ́ mi mọ́, wọ́n sì kọ àwọn àṣẹ mi sílẹ̀,+ wọ́n sọ àwọn sábáàtì mi di aláìmọ́, wọ́n sì ń tẹ̀ lé* àwọn òrìṣà ẹ̀gbin tí àwọn baba ńlá wọn ń sìn.+ 25  Mo tún gbà wọ́n láyè láti tẹ̀ lé àwọn ìlànà tí kò dáa àti àwọn ìdájọ́ tí kò lè mú kí wọ́n wà láàyè.+ 26  Mo jẹ́ kí àwọn ẹbọ tí wọ́n ń rú sọ wọ́n di aláìmọ́, bí wọ́n ṣe ń sun àwọn àkọ́bí ọmọ wọn nínú iná,+ kí n lè sọ wọ́n di ahoro, kí wọ́n lè mọ̀ pé èmi ni Jèhófà.”’ 27  “Torí náà, ọmọ èèyàn, bá ilé Ísírẹ́lì sọ̀rọ̀, kí o sì sọ fún wọn pé, ‘Ohun tí Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ sọ nìyí: “Bí àwọn baba ńlá yín ṣe sọ̀rọ̀ òdì sí mi nìyẹn tí wọ́n hùwà àìṣòótọ́ sí mi. 28  Mo mú wọn wá sí ilẹ̀ tí mo búra pé màá fún wọn.+ Nígbà tí wọ́n rí gbogbo òkè tó ga àti àwọn igi tí ewé kún orí rẹ̀,+ wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí í rú àwọn ẹbọ wọn, wọ́n sì ń mú àwọn ọrẹ wọn tó ń múnú bí mi lọ síbẹ̀. Wọ́n ń gbé àwọn ẹbọ wọn tó ní òórùn dídùn* lọ síbẹ̀, wọ́n sì ń da àwọn ọrẹ ohun mímu wọn sílẹ̀ níbẹ̀. 29  Mo wá bi wọ́n pé, ‘Kí ni ìtumọ̀ ibi gíga tí ẹ̀ ń lọ yìí? (Wọ́n ṣì ń pè é ní Ibi Gíga títí dòní.)’”’+ 30  “Kí o wá sọ fún ilé Ísírẹ́lì pé, ‘Ohun tí Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ sọ nìyí: “Ṣé ẹ fẹ́ sọ ara yín di ẹlẹ́gbin bíi ti àwọn baba ńlá yín ni, tí wọ́n ń tẹ̀ lé àwọn òrìṣà ẹ̀gbin wọn kí wọ́n lè bá wọn ṣe àgbèrè ẹ̀sìn?+ 31  Ṣé ẹ ṣì ń sọ ara yín di ẹlẹ́gbin títí dòní olónìí, tí ẹ̀ ń rúbọ sí gbogbo òrìṣà ẹ̀gbin yín, tí ẹ̀ ń sun àwọn ọmọ yín nínú iná?+ Ṣé ó wá yẹ kí n dá yín lóhùn pẹ̀lú gbogbo ohun tí ẹ ṣe yìí, ilé Ísírẹ́lì?”’+ “‘Bí mo ti wà láàyè,’ ni Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ wí, ‘mi ò ní dá yín lóhùn.+ 32  Ohun tí ẹ sì ní lọ́kàn* nígbà tí ẹ̀ ń sọ pé: “Ẹ jẹ́ ká dà bí àwọn orílẹ̀-èdè, bí àwọn ìdílé tó jẹ́ ọmọ ilẹ̀ míì, tí wọ́n ń jọ́sìn* igi àti òkúta,”+ kò ní ṣẹlẹ̀ láé.’” 33  “‘Bí mo ti wà láàyè,’ ni Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ wí, ‘ọwọ́ agbára, apá tí mo nà jáde àti ìbínú ni màá fi ṣàkóso yín.+ 34  Èmi yóò mú yín jáde láàárín àwọn èèyàn, màá sì fi ọwọ́ agbára, apá tí mo nà jáde àti ìbínú kó yín jọ láti àwọn ilẹ̀ tí ẹ ti fọ́n ká sí.+ 35  Èmi yóò mú yín wá sínú aginjù àwọn èèyàn, màá sì dá yín lẹ́jọ́ níbẹ̀ ní ojúkojú.+ 36  “‘Bí mo ṣe dá àwọn baba ńlá yín lẹ́jọ́ nínú aginjù ilẹ̀ Íjíbítì, bẹ́ẹ̀ ni màá ṣe dá yín lẹ́jọ́,’ ni Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ wí. 37  ‘Màá mú kí ẹ kọjá lábẹ́ ọ̀pá olùṣọ́ àgùntàn,+ màá sì mú kí ẹ tẹ̀ lé* májẹ̀mú náà. 38  Àmọ́ èmi yóò mú àwọn ọlọ̀tẹ̀ àti àwọn tó ń ṣẹ̀ mí kúrò láàárín yín.+ Màá mú wọn kúrò ní ilẹ̀ àjèjì tí wọ́n wà, àmọ́ wọn ò ní wọ ilẹ̀ Ísírẹ́lì;+ ẹ ó sì wá mọ̀ pé èmi ni Jèhófà.’ 39  “Ní tìrẹ, ìwọ ilé Ísírẹ́lì, ohun tí Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ sọ nìyí, ‘Kí kálukú yín lọ sin àwọn òrìṣà ẹ̀gbin rẹ̀.+ Àmọ́, tí ẹ kò bá fetí sí mi lẹ́yìn náà, ẹ ò ní lè fi àwọn ẹbọ yín àti àwọn òrìṣà ẹ̀gbin yín kó ẹ̀gàn bá orúkọ mímọ́ mi mọ́.’+ 40  “‘Torí ní òkè mímọ́ mi, ní òkè gíga Ísírẹ́lì,+ ni gbogbo ilé Ísírẹ́lì yóò ti sìn mí ní ilẹ̀ náà, gbogbo wọn pátá,’ ni Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ wí.+ ‘Inú mi yóò dùn sí wọn níbẹ̀, èmi yóò sì béèrè ọrẹ yín àti àwọn àkọ́so ẹ̀bùn yín, gbogbo ohun mímọ́ yín.+ 41  Òórùn dídùn* náà yóò mú kí inú mi dùn sí yín, nígbà tí mo bá mú yín jáde láàárín àwọn èèyàn, tí mo sì kó yín jọ láti àwọn ilẹ̀ tí ẹ fọ́n ká sí;+ màá sì fi hàn pé mo jẹ́ mímọ́ láàárín yín níṣojú àwọn orílẹ̀-èdè.’+ 42  “‘Ẹ ó sì wá mọ̀ pé èmi ni Jèhófà,+ nígbà tí mo bá mú yín wá sí ilẹ̀ Ísírẹ́lì,+ sí ilẹ̀ tí mo búra pé màá fún àwọn baba ńlá yín. 43  Ibẹ̀ ni ẹ ó sì ti rántí gbogbo ìwà àti ìṣe yín tí ẹ fi sọ ara yín di aláìmọ́,+ ẹ ó sì kórìíra ara* yín nítorí gbogbo ohun búburú tí ẹ ṣe.+ 44  Ẹ ó sì wá mọ̀ pé èmi ni Jèhófà nígbà tí mo bá dojú ìjà kọ yín nítorí orúkọ mi,+ kì í ṣe nítorí ìwà búburú yín tàbí ìwà ìbàjẹ́ yín, ìwọ ilé Ísírẹ́lì,’ ni Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ wí.” 45  Jèhófà tún bá mi sọ̀rọ̀, ó ní: 46  “Ọmọ èèyàn, yíjú sí gúúsù, kí o kéde ọ̀rọ̀ fún gúúsù, kí o sì sọ tẹ́lẹ̀ fún igbó tó wà ní oko gúúsù. 47  Sọ fún igbó tó wà ní gúúsù pé, ‘Gbọ́ ọ̀rọ̀ Jèhófà. Ohun tí Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ sọ nìyí: “Èmi yóò dáná sun ọ́,+ yóò sì jó gbogbo igi tútù àti gbogbo igi gbígbẹ inú rẹ run. Iná tó ń jó náà kò ní kú,+ yóò sì jó gbogbo ojú láti gúúsù dé àríwá. 48  Gbogbo ẹlẹ́ran ara* yóò wá rí i pé èmi Jèhófà, ló dáná sun ún, iná náà kò sì ní kú.”’”+ 49  Mo sì sọ pé: “Áà, Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ! Ohun tí wọ́n ń sọ nípa mi ni pé, ‘Ṣebí àlọ́* lásán ló ń pa?’”

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé

Tàbí “láti kéde ìdájọ́ lé wọn lórí?”
Ní Héb., “gbé ọwọ́ mi sókè.”
Ní Héb., “èso.”
Tàbí “ṣe amí rẹ̀.”
Tàbí “tó ní ọ̀ṣọ́.”
Ó ṣeé ṣe kí ọ̀rọ̀ Hébérù yìí ní í ṣe pẹ̀lú ọ̀rọ̀ tí wọ́n ń lò fún “ìgbẹ́,” wọ́n sì máa ń lò ó fún ohun tí wọ́n bá kórìíra.
Ìyẹn, Ísírẹ́lì.
Ìyẹn, Ísírẹ́lì.
Ìyẹn, Ísírẹ́lì.
Tàbí “tó ní ọ̀ṣọ́.”
Ní Héb., “ojú mi.”
Ìyẹn, Ísírẹ́lì.
Ní Héb., “ojú wọn ò kúrò lára.”
Tàbí “tuni lójú.” Ní Héb., “atura.”
Ní Héb., “ní ẹ̀mí.”
Tàbí “ṣe ìránṣẹ́ fún; sin.”
Ní Héb., “wọnú ìdè.”
Tàbí “tó tuni lójú.” Ní Héb., “atura.”
Ní Héb., “ojú.”
Tàbí “èèyàn.”
Tàbí “òwe.”