Émọ́sì 4:1-13

  • Ohun tó máa ṣẹlẹ̀ sí àwọn abo màlúù Báṣánì (1-3)

  • Jèhófà kórìíra ìjọsìn èké Ísírẹ́lì (4, 5)

  • Ísírẹ́lì kò gba ìbáwí (6-13)

    • “Múra sílẹ̀ láti pàdé Ọlọ́run rẹ” (12)

    • ‘Ọlọ́run ń sọ èrò rẹ̀ fún àwọn èèyàn’ (13)

4  “Ẹ gbọ́ ọ̀rọ̀ yìí, ẹ̀yin abo màlúù Báṣánì,Tó wà lórí òkè Samáríà,+Ẹ̀yin obìnrin tó ń lu àwọn aláìní ní jìbìtì,+ tó sì ń ni àwọn tálákà lára,Tó ń sọ fún àwọn ọkọ* wọn pé, ‘Ẹ gbé ọtí wá ká mu!’   Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ ti fi ìjẹ́mímọ́ rẹ̀ búra pé,‘“Wò ó! Ọjọ́ ń bọ̀ nígbà tó máa fi ìkọ́ alápatà gbé yín sókèTí á sì fi ìwọ̀ ẹja gbé àwọn tó ṣẹ́ kù lára yín.   Kálukú yín máa gba àlàfo ara ògiri tó wà níwájú rẹ̀ jáde lọ;A ó sì lé yín sí Hámọ́nì,” ni Jèhófà wí.’   ‘Ẹ wá sí Bẹ́tẹ́lì, kí ẹ sì dẹ́ṣẹ̀,*+Àti sí Gílígálì kí ẹ dá ẹ̀ṣẹ̀ kún ẹ̀ṣẹ̀!+ Ẹ mú àwọn ẹbọ yín wá+ ní òwúrọ̀,Ẹ sì mú ìdá mẹ́wàá+ yín wá ní ọjọ́ kẹta.   Ẹ fi búrẹ́dì tó ní ìwúkàrà rú ẹbọ ìdúpẹ́;+Ẹ sì kéde àwọn ọrẹ àtinúwá yín! Nítorí ohun tí ẹ fẹ́ nìyẹn, ẹ̀yin ọmọ Ísírẹ́lì,’ ni Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ wí.   ‘Ní tèmi, mo mú kí eyín yín mọ́ nítorí àìsí oúnjẹ* ní gbogbo àwọn ìlú yínMi ò sì jẹ́ kí oúnjẹ wà ní gbogbo ilé yín;+Síbẹ̀, ẹ kò pa dà sọ́dọ̀ mi,’+ ni Jèhófà wí.   ‘Mo tún fawọ́ òjò sẹ́yìn kúrò lọ́dọ̀ yín nígbà tí ìkórè ṣì ku oṣù mẹ́ta;+Mo mú kí òjò rọ̀ sí ìlú kan àmọ́ mi ò jẹ́ kó rọ̀ sí ìlú míì. Òjò máa rọ̀ sí ilẹ̀ kan,Àmọ́ ilẹ̀ tí òjò kò rọ̀ sí máa gbẹ.   Àwọn èèyàn ìlú méjì tàbí mẹ́ta ń rọ́ lọ sí ìlú kan ṣoṣo kí wọ́n lè mu omi,+Àmọ́ kò tẹ́ wọn lọ́rùn;Síbẹ̀, ẹ kò pa dà sọ́dọ̀ mi,’+ ni Jèhófà wí.   ‘Mo fi ooru tó ń jóni àti èbíbu* kọ lù yín.+ Ẹ̀ ń mú kí àwọn ọgbà yín àti oko àjàrà yín di púpọ̀,+Ṣùgbọ́n eéṣú ló jẹ igi ọ̀pọ̀tọ́ yín àti igi ólífì yín run;Síbẹ̀, ẹ kò pa dà sọ́dọ̀ mi,’+ ni Jèhófà wí. 10  ‘Mo rán àjàkálẹ̀ àrùn sáàárín yín bíi ti Íjíbítì.+ Mo fi idà pa àwọn ọ̀dọ́kùnrin yín,+ mo sì gba àwọn ẹṣin yín.+ Mo mú kí òórùn àwọn tó kú ní ibùdó yín gba afẹ́fẹ́ kan;+Síbẹ̀, ẹ kò pa dà sọ́dọ̀ mi,’ ni Jèhófà wí. 11  ‘Mo pa ilẹ̀ yín runBí Ọlọ́run ṣe pa Sódómù àti Gòmórà run.+ Ẹ sì dà bí igi tí a fà yọ kúrò nínú iná;Síbẹ̀, ẹ kò pa dà sọ́dọ̀ mi,’+ ni Jèhófà wí. 12  Torí náà, màá tún fìyà jẹ ọ́, ìwọ Ísírẹ́lì. Nítorí ohun tí màá ṣe sí ọ yìí,Múra sílẹ̀ láti pàdé Ọlọ́run rẹ, ìwọ Ísírẹ́lì. 13  Nítorí, wò ó! Òun ló dá àwọn òkè+ àti afẹ́fẹ́;+Ó ń sọ èrò Rẹ̀ fún àwọn èèyàn,Ó ń sọ ìmọ́lẹ̀ di òkùnkùn,+Ó ń rìn lórí àwọn ibi gíga ayé;+Jèhófà Ọlọ́run àwọn ọmọ ogun ni orúkọ rẹ̀.”

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé

Tàbí “àwọn ọ̀gá.”
Tàbí “ṣọ̀tẹ̀.”
Tàbí “mi ò fún yín lóúnjẹ.”
Ìyẹn, kí nǹkan bu.