Ẹ́kísódù 4:1-31

  • Iṣẹ́ àmì mẹ́ta tí Mósè máa ṣe (1-9)

  • Mósè ní òun ò kúnjú ìwọ̀n (10-17)

  • Mósè pa dà sí Íjíbítì (18-26)

  • Mósè àti Áárónì tún jọ pàdé (27-31)

4  Àmọ́ Mósè fèsì pé: “Tí wọn ò bá gbà mí gbọ́ ńkọ́, tí wọn ò sì fetí sí mi?+ Torí wọ́n á sọ pé, ‘Jèhófà ò fara hàn ọ́.’”  Jèhófà bi í pé: “Kí ló wà lọ́wọ́ rẹ yẹn?” Ó fèsì pé: “Ọ̀pá ni.”  Ọlọ́run sọ pé: “Jù ú sílẹ̀.” Ó jù ú sílẹ̀, ló bá di ejò;+ Mósè sì sá fún un.  Jèhófà sọ fún Mósè pé: “Na ọwọ́ mú un níbi ìrù.” Ó nawọ́ mú un, ó sì di ọ̀pá lọ́wọ́ rẹ̀.  Ọlọ́run wá sọ pé, “Èyí á jẹ́ kí wọ́n gbà gbọ́ pé Jèhófà Ọlọ́run àwọn baba ńlá wọn, Ọlọ́run Ábúráhámù, Ọlọ́run Ísákì àti Ọlọ́run Jékọ́bù+ ti fara hàn ọ́.”+  Jèhófà tún sọ fún un pé: “Jọ̀ọ́, ki ọwọ́ rẹ bọ inú aṣọ rẹ lápá òkè.” Ó wá ki ọwọ́ bọ inú aṣọ rẹ̀. Nígbà tó yọ ọ́ jáde, ẹ̀tẹ̀ ti bò ó lọ́wọ́, ó sì funfun bíi yìnyín!+  Ọlọ́run wá sọ pé: “Dá ọwọ́ rẹ pa dà sínú aṣọ rẹ lápá òkè.” Ó sì dá ọwọ́ rẹ̀ pa dà sínú aṣọ rẹ̀. Nígbà tó yọ ọ́ jáde nínú aṣọ, ó ti pa dà sí bó ṣe wà tẹ́lẹ̀!  Ó sọ pé: “Tí wọn ò bá gbà ọ́ gbọ́, tí wọn ò sì fiyè sí àmì àkọ́kọ́, ó dájú pé wọ́n á gba àmì kejì gbọ́.+  Síbẹ̀, tí wọn ò bá gba àmì méjèèjì yìí gbọ́, tí wọn ò sì fetí sí ọ, kí o bu omi díẹ̀ látinú odò Náílì, kí o sì dà á sórí ilẹ̀, omi tí o bù nínú odò Náílì yóò sì di ẹ̀jẹ̀ lórí ilẹ̀.”+ 10  Mósè wá sọ fún Jèhófà pé: “Má bínú, Jèhófà, mi ò lè sọ̀rọ̀ dáadáa ṣáájú àkókò yìí àti lẹ́yìn tí o bá ìránṣẹ́ rẹ sọ̀rọ̀, torí ọ̀rọ̀ mi ò já geere,* ahọ́n mi sì wúwo.”+ 11  Jèhófà sọ fún un pé: “Ta ló fún èèyàn ní ẹnu, ta ló sì ń mú kó má lè sọ̀rọ̀, kó ya adití, kó ríran kedere tàbí kó fọ́jú? Ǹjẹ́ kì í ṣe èmi Jèhófà ni? 12  Torí náà, lọ, màá wà pẹ̀lú rẹ bí o ṣe ń sọ̀rọ̀,* màá sì kọ́ ọ ní ohun tí o máa sọ.”+ 13  Àmọ́ Mósè sọ pé: “Má bínú, Jèhófà, jọ̀ọ́ rán ẹnikẹ́ni tí o bá fẹ́.” 14  Jèhófà wá bínú sí Mósè, ó sì sọ pé: “Áárónì ẹ̀gbọ́n rẹ+ tó jẹ́ ọmọ Léfì ńkọ́? Mo mọ̀ pé ó lè sọ̀rọ̀ dáadáa. Ó sì ti ń bọ̀ wá bá ọ níbí báyìí. Tó bá rí ọ, inú rẹ̀ yóò dùn.+ 15  Kí o bá a sọ̀rọ̀, kí o sì fi àwọn ọ̀rọ̀ náà sí ẹnu rẹ̀,+ màá wà pẹ̀lú ẹ̀yin méjèèjì bí o ṣe ń sọ̀rọ̀,+ màá sì kọ́ yín ní ohun tí ẹ máa ṣe. 16  Yóò bá ọ bá àwọn èèyàn náà sọ̀rọ̀, òun ló máa jẹ́ agbẹnusọ fún ọ, ìwọ yóò sì dà bí Ọlọ́run fún un.*+ 17  Kí o mú ọ̀pá yìí dání, kí o sì fi ṣe àwọn iṣẹ́ àmì náà.”+ 18  Mósè wá pa dà sọ́dọ̀ Jẹ́tírò bàbá ìyàwó rẹ̀,+ ó sì sọ fún un pé: “Jọ̀ọ́, mo fẹ́ pa dà lọ sọ́dọ̀ àwọn arákùnrin mi tó wà ní Íjíbítì kí n lè rí i bóyá wọ́n ṣì wà láàyè.” Jẹ́tírò sọ fún Mósè pé: “Máa lọ ní àlàáfíà.” 19  Lẹ́yìn náà, Jèhófà sọ fún Mósè ní Mídíánì pé: “Pa dà lọ sí Íjíbítì, torí gbogbo àwọn tó fẹ́ pa ọ́* ti kú.”+ 20  Mósè wá gbé ìyàwó rẹ̀ àtàwọn ọmọ rẹ̀ sórí kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́, ó forí lé ilẹ̀ Íjíbítì. Mósè sì mú ọ̀pá Ọlọ́run tòótọ́ dání. 21  Jèhófà wá sọ fún Mósè pé: “Tí o bá dé Íjíbítì, rí i pé gbogbo iṣẹ́ ìyanu tí mo fún ọ lágbára láti ṣe lo ṣe níwájú Fáráò.+ Àmọ́, màá jẹ́ kí ọkàn rẹ̀ le,+ kò sì ní jẹ́ kí àwọn èèyàn náà lọ.+ 22  Kí o sọ fún Fáráò pé, ‘Ohun tí Jèhófà sọ nìyí: “Ọmọ mi ni Ísírẹ́lì, àkọ́bí mi ni.+ 23  Mò ń sọ fún ọ pé, Jẹ́ kí ọmọ mi máa lọ kó lè sìn mí. Àmọ́ tí o ò bá jẹ́ kó lọ, màá pa ọmọkùnrin rẹ, àkọ́bí rẹ.”’”+ 24  Lójú ọ̀nà ibi tí wọ́n dé sí, Jèhófà  + pàdé rẹ̀, ó sì fẹ́ pa á.+ 25  Ni Sípórà+ bá mú akọ òkúta,* ó dádọ̀dọ́* ọmọ rẹ̀, ó sì mú kí adọ̀dọ́ rẹ̀ kan ẹsẹ̀ rẹ̀, ó ní: “Torí ọkọ ẹlẹ́jẹ̀ lo jẹ́ fún mi.” 26  Torí náà, Ó jẹ́ kó lọ. Ìdádọ̀dọ́ náà ló mú kí obìnrin náà pè é ní “ọkọ ẹlẹ́jẹ̀” nígbà yẹn. 27  Jèhófà wá sọ fún Áárónì pé: “Lọ bá Mósè nínú aginjù.”+ Torí náà, ó lọ pàdé rẹ̀ ní òkè Ọlọ́run tòótọ́,+ ó sì fi ẹnu kò ó lẹ́nu láti kí i. 28  Mósè sọ gbogbo ọ̀rọ̀ Jèhófà, ẹni tó rán an, fún Áárónì,+ ó sì sọ fún un nípa gbogbo iṣẹ́ àmì tó pa láṣẹ pé kó ṣe.+ 29  Lẹ́yìn náà, Mósè àti Áárónì lọ, wọ́n sì kó gbogbo àgbààgbà àwọn ọmọ Ísírẹ́lì jọ.+ 30  Áárónì sọ gbogbo ọ̀rọ̀ tí Jèhófà sọ fún Mósè fún wọn, ó sì ṣe àwọn iṣẹ́ àmì náà+ níṣojú àwọn èèyàn náà. 31  Èyí mú kí àwọn èèyàn náà gbà á gbọ́.+ Nígbà tí wọ́n gbọ́ pé Jèhófà ti yíjú sí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì+ àti pé ó ti rí ìyà tó ń jẹ àwọn,+ wọ́n tẹrí ba, wọ́n sì wólẹ̀.

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé

Ní Héb., “ẹnu mi wúwo.”
Ní Héb., “màá wà pẹ̀lú ẹnu rẹ.”
Tàbí “ìwọ yóò jẹ́ àṣojú Ọlọ́run fún un.”
Tàbí “àwọn tó ń wá ọkàn rẹ.”
Tàbí “kọlà.”
Tàbí “ọ̀bẹ tí wọ́n fi òkúta ṣe.”