Ẹ́kísódù 38:1-31

  • Pẹpẹ ẹbọ sísun (1-7)

  • Ó fi bàbà ṣe bàsíà (8)

  • Àgbàlá (9-20)

  • Wọ́n ka àwọn ohun èlò àgọ́ ìjọsìn (21-31)

38  Ó fi igi bọn-ọ̀n-ní ṣe pẹpẹ ẹbọ sísun. Ẹ̀gbẹ́ rẹ̀ mẹ́rẹ̀ẹ̀rin dọ́gba, gígùn rẹ̀ jẹ́ ìgbọ̀nwọ́* márùn-ún, fífẹ̀ rẹ̀ jẹ́ ìgbọ̀nwọ́ márùn-ún, gíga rẹ̀ sì jẹ́ ìgbọ̀nwọ́ mẹ́ta.+  Ó wá ṣe àwọn ìwo sí igun rẹ̀ mẹ́rẹ̀ẹ̀rin. Pẹpẹ náà àti àwọn ìwo rẹ̀ jẹ́ ọ̀kan. Lẹ́yìn náà, ó fi bàbà bò ó.+  Lẹ́yìn ìyẹn, ó ṣe gbogbo ohun èlò pẹpẹ náà, àwọn korobá, àwọn ṣọ́bìrì, àwọn abọ́, àwọn àmúga àti àwọn ìkóná. Bàbà ló fi ṣe gbogbo ohun èlò rẹ̀.  Ó tún fi bàbà ṣe àgbàyan* tó rí bí àwọ̀n fún pẹpẹ náà, sí ọwọ́ ìsàlẹ̀ etí rẹ̀, ó wọnú pẹpẹ náà níbi àárín.  Ó rọ òrùka mẹ́rin sí igun mẹ́rẹ̀ẹ̀rin nítòsí àgbàyan bàbà náà, kí wọ́n lè gba àwọn ọ̀pá dúró.  Lẹ́yìn náà, ó fi igi bọn-ọ̀n-ní ṣe àwọn ọ̀pá, ó sì fi bàbà bò wọ́n.  Ó ki àwọn ọ̀pá náà bọnú àwọn òrùka tó wà lẹ́gbẹ̀ẹ́ pẹpẹ náà láti máa fi gbé e. Ó ṣe pẹpẹ náà bí àpótí onípákó tí inú rẹ̀ jìn.  Lẹ́yìn náà, ó fi bàbà ṣe bàsíà+ àti ẹsẹ̀ bàsíà náà; ó lo dígí* àwọn obìnrin tí wọ́n ṣètò pé kí wọ́n máa ṣiṣẹ́ ìsìn ní ẹnu ọ̀nà àgọ́ ìpàdé.  Ó wá ṣe àgbàlá.+ Ó fi aṣọ ọ̀gbọ̀* lílọ́ tó dáa ṣe àwọn aṣọ ìdábùú tó jẹ́ ọgọ́rùn-ún (100) ìgbọ̀nwọ́ tó máa wà ní apá gúúsù àgbàlá náà, níbi tó dojú kọ gúúsù.+ 10  Ó ní ogún (20) òpó àti ogún (20) ìtẹ́lẹ̀ oníhò tí wọ́n fi bàbà ṣe, fàdákà ni wọ́n sì fi ṣe ìkọ́ àwọn òpó náà àti àwọn ohun tó so wọ́n pọ̀.* 11  Bákan náà, ó ṣe àwọn aṣọ ìdábùú tó jẹ́ ọgọ́rùn-ún (100) ìgbọ̀nwọ́ tí wọ́n máa ta sí apá àríwá. Bàbà ni wọ́n fi ṣe ogún (20) òpó wọn àti ogún (20) ìtẹ́lẹ̀ oníhò wọn. Fàdákà ni wọ́n fi ṣe ìkọ́ àwọn òpó náà àti àwọn ohun tó so wọ́n pọ̀.* 12  Àmọ́ àádọ́ta (50) ìgbọ̀nwọ́ ni àwọn aṣọ ìdábùú tí wọ́n ta sí apá ìwọ̀ oòrùn. Òpó mẹ́wàá àti ìtẹ́lẹ̀ mẹ́wàá tó ní ihò wà níbẹ̀, fàdákà ni wọ́n sì fi ṣe àwọn òpó náà àti àwọn ohun tó so wọ́n pọ̀.* 13  Fífẹ̀ apá ìlà oòrùn tí oòrùn ti ń yọ jẹ́ àádọ́ta (50) ìgbọ̀nwọ́. 14  Àwọn aṣọ ìdábùú tó jẹ́ ìgbọ̀nwọ́ mẹ́ẹ̀ẹ́dógún (15) wà ní ẹ̀gbẹ́ kan, pẹ̀lú òpó mẹ́ta àti ìtẹ́lẹ̀ mẹ́ta tó ní ihò. 15  Àwọn aṣọ ìdábùú tó jẹ́ ìgbọ̀nwọ́ mẹ́ẹ̀ẹ́dógún (15) sì wà ní ẹ̀gbẹ́ kejì, lápá kejì ẹnu ọ̀nà àgbàlá náà, pẹ̀lú òpó mẹ́ta àti ìtẹ́lẹ̀ mẹ́ta tó ní ihò. 16  Aṣọ ọ̀gbọ̀ lílọ́ tó dáa ni wọ́n fi ṣe gbogbo aṣọ ìdábùú tí wọ́n máa ta yí àgbàlá náà ká. 17  Bàbà ni wọ́n fi ṣe ìtẹ́lẹ̀ oníhò àwọn òpó náà, fàdákà ni wọ́n fi ṣe àwọn ìkọ́ wọn àti àwọn ohun tó so wọ́n pọ̀,* wọ́n fi fàdákà bo orí àwọn òpó náà, fàdákà sì ni wọ́n fi ṣe àwọn ohun tí wọ́n fi ń de nǹkan pọ̀ mọ́ gbogbo òpó inú àgbàlá náà.+ 18  Fọ́nrán òwú aláwọ̀ búlúù, òwú aláwọ̀ pọ́pù, òwú aláwọ̀ rírẹ̀dòdò àti aṣọ ọ̀gbọ̀ lílọ́ tó dáa tí wọ́n hun pọ̀ ni wọ́n fi ṣe aṣọ* tí wọ́n máa ta sí ẹnu ọ̀nà àgbàlá náà. Gígùn rẹ̀ jẹ́ ogún (20) ìgbọ̀nwọ́, gíga rẹ̀ sì jẹ́ ìgbọ̀nwọ́ márùn-ún, gíga rẹ̀ dọ́gba pẹ̀lú àwọn aṣọ ìdábùú tí wọ́n ta sí àgbàlá náà.+ 19  Bàbà ni wọ́n fi ṣe òpó wọn mẹ́rẹ̀ẹ̀rin àti ìtẹ́lẹ̀ oníhò wọn mẹ́rẹ̀ẹ̀rin. Fàdákà ni wọ́n fi ṣe àwọn ìkọ́ wọn, wọ́n sì fi fàdákà bo orí àwọn òpó náà àti àwọn ohun tó so wọ́n pọ̀.* 20  Bàbà ni wọ́n fi ṣe gbogbo èèkàn àgọ́ ìjọsìn náà àti àwọn tó wà yí ká àgbàlá náà.+ 21  Àwọn nǹkan yìí ni wọ́n kà pé ó wà nínú àgọ́ ìjọsìn, àgọ́ Ẹ̀rí.+ Mósè ló pàṣẹ pé kí àwọn ọmọ Léfì+ kà á, kí Ítámárì ọmọ àlùfáà Áárónì sì darí wọn.+ 22  Bẹ́sálẹ́lì+ ọmọ Úráì ọmọ Húrì látinú ẹ̀yà Júdà ṣe gbogbo ohun tí Jèhófà pa láṣẹ fún Mósè. 23  Òhólíábù+ ọmọ Áhísámákì látinú ẹ̀yà Dánì sì wà pẹ̀lú rẹ̀, ó jẹ́ oníṣẹ́ ọnà, ó máa ń kóṣẹ́ sí aṣọ, ó sì máa ń hun aṣọ pẹ̀lú fọ́nrán òwú aláwọ̀ búlúù, òwú aláwọ̀ pọ́pù, òwú aláwọ̀ rírẹ̀dòdò àti aṣọ ọ̀gbọ̀ tó dáa. 24  Gbogbo wúrà tí wọ́n lò fún gbogbo iṣẹ́ ibi mímọ́ náà dọ́gba pẹ̀lú iye wúrà ọrẹ fífì,+ ó jẹ́ tálẹ́ńtì* mọ́kàndínlọ́gbọ̀n (29) àti ọgọ́rùn-ún méje ó lé ọgbọ̀n (730) ṣékélì,* ìwọ̀n ṣékélì ibi mímọ́.* 25  Fàdákà àwọn tó forúkọ sílẹ̀ lára àpéjọ náà sì jẹ́ ọgọ́rùn-ún (100) tálẹ́ńtì àti ẹgbẹ̀rún kan ó lé ọgọ́rùn-ún méje àti márùndínlọ́gọ́rin (1,775) ṣékélì, ìwọ̀n ṣékélì ibi mímọ́.* 26  Ìlàjì ṣékélì tó jẹ́ ìwọ̀n ṣékélì ibi mímọ́* ni ìlàjì ṣékélì ẹnì kọ̀ọ̀kan, ìyẹn gbogbo ẹni tó wà lára àwọn tó forúkọ sílẹ̀ láti ẹni ogún (20) ọdún sókè,+ wọ́n jẹ́ ọgbọ̀n ọ̀kẹ́ ó lé ẹgbẹ̀rún mẹ́ta ààbọ̀ àti àádọ́ta (603,550).+ 27  Ọgọ́rùn-ún (100) tálẹ́ńtì ni wọ́n fi rọ àwọn ìtẹ́lẹ̀ oníhò ibi mímọ́ àti àwọn ìtẹ́lẹ̀ oníhò ti aṣọ ìdábùú; ọgọ́rùn-ún (100) tálẹ́ńtì ni wọ́n fi ṣe ọgọ́rùn-ún (100) ìtẹ́lẹ̀ oníhò, tálẹ́ńtì kan fún ìtẹ́lẹ̀ oníhò kọ̀ọ̀kan.+ 28  Nínú ẹgbẹ̀rún kan ó lé ọgọ́rùn-ún méje àti márùndínlọ́gọ́rin (1,775) ṣékélì ló ti ṣe ìkọ́ àwọn òpó, tó bo orí wọn, tó sì so wọ́n pọ̀. 29  Bàbà tí wọ́n fi ṣe ọrẹ* jẹ́ àádọ́rin (70) tálẹ́ńtì àti ẹgbẹ̀rún méjì ó lé ọgọ́rùn-ún mẹ́rin (2,400) ṣékélì. 30  Èyí ló fi ṣe àwọn ìtẹ́lẹ̀ oníhò ẹnu ọ̀nà àgọ́ ìpàdé, pẹpẹ bàbà àti àgbàyan rẹ̀ tó fi bàbà ṣe, gbogbo ohun èlò pẹpẹ, 31  àwọn ìtẹ́lẹ̀ oníhò tó wà yí ká àgbàlá náà, àwọn ìtẹ́lẹ̀ oníhò ẹnu ọ̀nà àgbàlá àti gbogbo èèkàn àgọ́ ìjọsìn náà àti gbogbo èèkàn+ tó wà yí ká àgbàlá náà.

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé

Ìgbọ̀nwọ́ kan jẹ́ sẹ̀ǹtímítà 44.5 (ínǹṣì 17.5). Wo Àfikún B14.
Tàbí “ayanran.”
Ìyẹn, àwọn dígí tí wọ́n fi irin tó ń dán gbinrin ṣe.
Tàbí “aṣọ àtàtà.”
Tàbí “òrùka wọn” tí wọ́n fi ń so nǹkan pọ̀.
Tàbí “òrùka wọn” tí wọ́n fi ń so nǹkan pọ̀.
Tàbí “òrùka wọn” tí wọ́n fi ń so nǹkan pọ̀.
Tàbí “òrùka wọn” tí wọ́n fi ń so nǹkan pọ̀.
Tàbí “aṣọ ìdábùú.”
Tàbí “òrùka wọn” tí wọ́n fi ń so nǹkan pọ̀.
Ṣékélì kan jẹ́ gíráàmù 11.4. Wo Àfikún B14.
Tàbí “ṣékélì mímọ́.”
Tálẹ́ńtì kan jẹ́ kìlógíráàmù 34.2. Wo Àfikún B14.
Tàbí “ṣékélì mímọ́.”
Tàbí “ṣékélì mímọ́.”
Tàbí “ọrẹ fífì.”